Gẹnẹsisi 42 – YCB & NTLR

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 42:1-38

Àwọn arákùnrin Josẹfu lọ sí Ejibiti

1Nígbà tí Jakọbu mọ̀ pé ọkà wà ní Ejibiti, ó wí fún àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin pé, “Èéṣe tí ẹ ń wo ara yín lásán?” 242.2: Ap 7.12.“Mo tí gbọ́ pé ọkà wà ní ilẹ̀ Ejibiti. Ẹ sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibẹ̀ kí ẹ sì rà wá fún wa, kí a má ba à kú.”

3Nígbà náà ni mẹ́wàá nínú àwọn arákùnrin Josẹfu sọ̀kalẹ̀ lọ sí Ejibiti láti ra ọkà. 4Ṣùgbọ́n Jakọbu kò rán Benjamini àbúrò Josẹfu lọ pẹ̀lú wọn nítorí ẹ̀rù ń bà á kí aburú má ba à ṣẹlẹ̀ sí i. 542.5: Ap 7.11.Nítorí náà, àwọn ọmọ Israẹli wà lára àwọn tó lọ Ejibiti lọ ra oúnjẹ nítorí ìyàn náà mú ni ilẹ̀ Kenaani pẹ̀lú.

6Nísinsin yìí, Josẹfu ni alábojútó fún gbogbo ilẹ̀ Ejibiti, òun sì ni ó ń bojútó ọkà títà fún gbogbo ènìyàn ìlú náà. Nítorí náà nígbà tí àwọn arákùnrin Josẹfu dé, wọ́n tẹríba, wọ́n sì foríbalẹ̀ fún Josẹfu. 7Lọ́gán tí Josẹfu ti rí àwọn arákùnrin rẹ̀ ni ó ti dá wọn mọ̀, ṣùgbọ́n ó ṣe bí i wí pé kò mọ̀ wọ́n, ó sì sọ̀rọ̀ líle sí wọn. Ó béèrè pé, “Níbo ni ẹ ti wá?”

Wọ́n sì dáhùn pé, “Láti ilẹ̀ Kenaani ni a ti wá ra oúnjẹ.”

8Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, Josẹfu mọ àwọn arákùnrin rẹ̀, síbẹ̀ àwọn arákùnrin rẹ̀ kò mọ̀ ọ́n. 942.9: Gẹ 37.5-10.Nígbà náà ni ó rántí àlá rẹ̀ tí ó lá sí wọn, ó sì wí fún wọn pé, “Amí42.9 tí ó túmọ̀ sí, Ayọ́lẹ̀wò ni yín, ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.”

10Wọ́n dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́ olúwa wa, àwọn ìránṣẹ́ rẹ wá láti ra oúnjẹ ni. 11Ọmọ baba ni wá, olóòtítọ́ ènìyàn sì ni wá pẹ̀lú, àwa kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò.”

12Ó wí fún wọn pé, “Rárá! Ẹ wá láti wo àṣírí ilẹ̀ wa ni.”

13Ṣùgbọ́n wọ́n tún dáhùn pé, “Arákùnrin méjìlá ni àwa ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ baba kan náà, tí ó ń gbé ní ilẹ̀ Kenaani. Èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wa ń bẹ lọ́dọ̀ baba wa, ọ̀kan sì ti kú.”

14Josẹfu wí fún wọn pé, “Bí mo ti wí fún un yín náà ni, Ayọ́lẹ̀wò ni yín! 15Èyí sì ni a ó fi dán an yín wò, èmi búra pé, níwọ̀n ìgbà tí Farao bá wà láààyè, ẹ kì yóò kúrò níbí, àyàfi bí arákùnrin yín kan tókù bá wá sí ibí. 16Ẹ rán ọ̀kan nínú yín lọ láti mú arákùnrin yín wá, àwa yóò fi ẹ̀yin tókù pamọ́ sínú túbú, kí àwa ba à lè mọ bóyá òtítọ́ ni ẹ̀yin ń wí. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé irọ́ ni ẹ̀yin ń pa, ní òtítọ́ bí Farao ti ń bẹ láààyè ayọ́lẹ̀wò ni yín!” 17Ó sì fi gbogbo wọn sínú túbú fún ọjọ́ mẹ́ta.

18Ní ọjọ́ kẹta, Josẹfu wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀yin yóò ṣe kí ẹ̀yin ba à le yè nítorí mo bẹ̀rù Ọlọ́run. 19Tí ó bá jẹ́ pé olóòtítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ jẹ́ kí ọ̀kan nínú yín dúró ni túbú ní ìhín, nígbà tí àwọn yòókù yín yóò gbé ọkà lọ fún àwọn ará ilé e yín tí ebi ń pa. 20Ṣùgbọ́n ẹ gbọdọ̀ mú arákùnrin tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn yín wá, kí n ba à le mọ òtítọ́ ohun ti ẹ ń wí, kí ẹ má ba à kú.” Wọn sì gbà láti ṣe èyí.

21Wọ́n ń sọ ọ́ láàrín ara wọn wí pé, “Àwa jẹ̀bi nítòótọ́ nípa ti arákùnrin wa. A rí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀ nígbà tí ó ń bẹ̀ wá nítorí ẹ̀mí rẹ̀, ṣùgbọ́n a kò gbẹ́bẹ̀, nítorí náà ni ìdààmú yìí fi dé bá wa.”

2242.22: Gẹ 37.21,22.Reubeni dá wọn ní ohùn pé, “Èmi kò wí fún yín pé kí ẹ má se ṣẹ̀ sí ọmọdékùnrin náà? Ṣùgbọ́n ẹ kò gbọ́! Ṣùgbọ́n nísinsin yìí a ń béèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ wa.” 23Wọn kò sì mọ̀ pé, Josẹfu ń gbọ́ wọn ní àgbọ́yé nítorí ògbufọ̀ ni ó ń lò tẹ́lẹ̀.

24Ó yípadà kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún. Ó sì tún yí padà sí wọn, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní sọ̀rọ̀. Ó mú Simeoni kúrò láàrín wọn, ó sì dè é ní ojú wọn.

25Josẹfu pàṣẹ pé kí wọn bu ọkà kún inú àpò wọn, kí wọn sì mú owó ẹnìkọ̀ọ̀kan padà sínú àpò rẹ̀, kí wọn sì fún wọn ní ohun tí wọn yóò lò nírín-àjò wọn padà sílé. Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe èyí fún wọn, 26wọn gbé ẹrù wọn lé kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, wọn sì padà lọ sí ilé.

27Níbi tí wọ́n ti dúró láti sùn lóru ọjọ́ náà, ọ̀kan nínú wọn tú àpò rẹ̀ láti mú oúnjẹ fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, ó sì rí owó rẹ̀ ní ẹnu àpò rẹ̀. 28Ó sì wí fún àwọn arákùnrin rẹ̀ pé, “a ti dá owó mi padà, òun nìyí ní ẹnu àpò mi.”

Ẹ̀rù bà wọ́n, wọ́n sì ń gbọ̀n, wọ́n sì wí pé, “Èwo nìyí tí Ọlọ́run ṣe sí wa yìí.”

29Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Jakọbu baba wọn ní ilẹ̀ Kenaani, wọ́n ròyìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ fún un wí pé, 30“Ọkùnrin náà tí í ṣe alábojútó ilẹ̀ náà, sọ̀rọ̀ líle sí wa, ó sì fi ẹ̀sùn kàn wá pé a wá yọ́ ilẹ̀ náà wò ni. 31Ṣùgbọ́n, a wí fún un pé, ‘Rárá o, olóòtítọ́ ènìyàn ni wá, a kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò. 32Arákùnrin méjìlá ni wá, ọmọ baba kan náà, ọ̀kan ti kú, èyí tí ó jẹ́ àbíkẹ́yìn wà lọ́dọ̀ baba wa ni ilẹ̀ Kenaani.’

33“Nígbà náà ni ọkùnrin tí ó jẹ́ alábojútó ilẹ̀ náà wí fún wa pé, ‘Báyìí ni n ó ṣe mọ̀ bóyá olóòtítọ́ ènìyàn ni yín, ẹ fi ọ̀kan nínú àwọn arákùnrin yín sílẹ̀ níbí, pẹ̀lú mi, ẹ sì mú oúnjẹ lọ fún àwọn ará ilé yín tí ebi ń pa kú lọ, lọ́wọ́ ìyàn. 34Ṣùgbọ́n ẹ mú arákùnrin yín tí ó kéré jùlọ wá fún mi kí n le mọ̀ pé dájúdájú ẹ kì í ṣe ayọ́lẹ̀wò bí kò ṣe ènìyàn tòótọ́. Nígbà náà ni n ó mú arákùnrin yín padà fún un yín, lẹ́yìn náà ẹ le máa wá ṣe òwò bí ó ti wù yín ní ilẹ̀ yìí.’ ”

35Bí wọ́n sì ti ń tú àpò ẹrù wọn, ẹnìkọ̀ọ̀kan bá owó tí ó san fún ọjà náà lẹ́nu àpò rẹ̀! Ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi, àwọn àti baba wọn. 36Jakọbu baba wọn wí fún wọn pé, “Ẹ ti mú mi pàdánù àwọn ọmọ mi. N kò rí Josẹfu mọ́, bẹ́ẹ̀ ni n kò sì rí Simeoni náà mọ. Ẹ sì tún fẹ́ mú Benjamini lọ. Èmi ni gbogbo ohun búburú yìí wá ń ṣẹlẹ̀ sí!”

37Nígbà náà ni Reubeni wí fún baba rẹ̀ pé, “Pa àwọn ọmọ mi méjèèjì bí n kò bá mú Benjamini padà wá fún ọ, èmi ni kí o fà á lé lọ́wọ́, n ó sì mu un padà wá.”

38Ṣùgbọ́n Jakọbu wí pé, “Ọmọ mi kì yóò bá a yín lọ, ẹ̀gbọ́n rẹ̀ ti kú, òun nìkan sì ni ó kù nínú àwọn ọmọ ìyá rẹ̀. Bí ohunkóhun bá ṣẹlẹ̀ sí i, ìbànújẹ́ ni yóò sì pa mi kú ni ọjọ́ ogbó mi yìí.”

Nouă Traducere În Limba Română

Geneza 42:1-38

Prima călătorie a fraților lui Iosif în Egipt

1Când Iacov a aflat1 Lit.: a văzut. că în Egipt se găsesc grâne, le‑a zis fiilor săi: „De ce vă uitați unii la alții?“ 2Și a zis: „Iată, am auzit că în Egipt se găsesc grâne. Coborâți în Egipt și cumpărați‑ne de acolo grâne, pentru ca să trăim și să nu murim.“ 3Zece dintre frații lui Iosif au coborât să cumpere grâne din Egipt. 4Dar Iacov nu l‑a trimis și pe Beniamin, fratele lui Iosif, împreună cu frații săi, pentru că se gândea să nu i se întâmple vreo nenorocire. 5Astfel, pentru că era foamete și în țara Canaan, fiii lui Israel s‑au dus să cumpere grâne din Egipt împreună cu alți oameni care mergeau într-acolo.

6Iosif era stăpânul țării, cel care vindea grâne întregului popor al țării. Când frații lui Iosif au ajuns la el, s‑au plecat cu fața la pământ înaintea lui. 7De îndată ce și‑a văzut frații, Iosif i‑a recunoscut, dar s‑a prefăcut că nu‑i cunoaște și le‑a vorbit cu asprime.

El i‑a întrebat:

– De unde veniți?

Ei au răspuns:

– Din țara Canaan, ca să cumpărăm mâncare.

8Iosif i‑a recunoscut pe frații săi, dar ei nu l‑au recunoscut.

9Iosif și‑a amintit visele pe care le‑a avut despre ei și le‑a zis:

– Voi sunteți cercetași și ați venit să vedeți părțile vulnerabile ale țării!

10Ei au răspuns:

– Nu, stăpâne, robii tăi au venit să cumpere mâncare. 11Toți suntem fiii aceluiași om. Suntem oameni cinstiți. Robii tăi nu sunt cercetași.

12Dar el le‑a zis:

– Nu‑i adevărat, ci voi ați venit să vedeți părțile vulnerabile ale țării!

13Ei au răspuns:

– Noi, robii tăi, suntem doisprezece frați, fiii aceluiași om din țara Canaan. Iată, cel mai mic este azi cu tatăl nostru, iar unul nu mai este.

14Dar Iosif le‑a zis:

– Sunteți cercetași, așa cum v‑am spus! 15Iată cum veți fi testați: pe viața lui Faraon că nu veți ieși din acest loc decât dacă vine aici fratele vostru mai mic! 16Trimiteți‑l pe unul dintre voi să‑l aducă pe fratele vostru, iar ceilalți dintre voi veți fi închiși, pentru ca vorbele voastre să fie puse la încercare și să se vadă dacă spuneți adevărul. Dacă nu, pe viața lui Faraon, sigur sunteți cercetași!

17Și i‑a pus sub pază pentru trei zile.

18A treia zi, Iosif le‑a zis:

– Faceți acest lucru și veți trăi; eu mă tem de Dumnezeu. 19Dacă sunteți oameni cinstiți, unul dintre voi să rămână sub pază, iar ceilalți mergeți, duceți grâne familiilor voastre înfometate 20și aduceți‑l la mine pe fratele vostru mai mic. Așa vor fi adeverite cuvintele voastre și nu veți muri.

Ei au făcut întocmai.

21Atunci și‑au zis unul altuia:

– Cu siguranță suntem vinovați pentru ceea ce i‑am făcut fratelui nostru, căci am văzut tulburarea sufletului său când căuta bunăvoința noastră, dar nu l‑am ascultat. De aceea a venit peste noi tulburarea acesta.

22Ruben le‑a răspuns, zicând:

– Nu v‑am spus eu: „Să nu păcătuiți împotriva băiatului!“? Dar n‑ați ascultat. Iată, trebuie să dăm socoteală pentru sângele lui.

23Ei nu știau că Iosif îi înțelege, pentru că vorbea cu ei printr‑un traducător. 24Iosif a plecat de lângă ei și a plâns. Apoi s‑a întors și le‑a vorbit din nou. L‑a luat pe Simeon și l‑a legat înaintea ochilor lor. 25Apoi a poruncit să li se umple sacii cu grâne, să se pună fiecăruia argintul înapoi în sac și să li se dea provizii pentru călătorie. După ce li s‑au făcut aceste lucruri, 26ei au încărcat grânele pe măgari și au plecat de acolo. 27Când unul dintre ei și‑a deschis sacul ca să dea nutreț măgarului său, în locul în care au înnoptat, și‑a văzut argintul. Iată, acesta era la gura sacului său. 28El le‑a zis fraților săi: „Argintul mi‑a fost dat înapoi. Iată‑l chiar în sacul meu!“ Atunci li s‑au înmuiat inimile și și‑au zis unul altuia tremurând: „Ce ne‑a făcut Dumnezeu?“

29Când au ajuns la tatăl lor, Iacov, în țara Canaan, i‑au istorisit tot ce li se întâmplase, zicând:

30– Acel om, stăpânul țării, ne‑a vorbit aspru și ne‑a luat drept cercetași ai țării. 31Dar noi i‑am zis: „Suntem oameni cinstiți, nu suntem cercetași. 32Suntem doisprezece frați, fiii aceluiași tată. Unul dintre noi nu mai este, iar cel mai mic este acum cu tatăl nostru în țara Canaan.“ 33Atunci, omul acela, stăpânul țării, ne‑a zis: „Iată cum voi ști dacă sunteți oameni cinstiți: lăsați‑l pe unul dintre frații voștri, luați grâne pentru familiile voastre înfometate și plecați. 34Dar aduceți‑mi‑l pe fratele vostru mai mic și voi ști că nu sunteți cercetași, ci oameni cinstiți. Apoi vi‑l voi da înapoi pe fratele vostru și veți putea face negoț în țară.34 Sau: să străbateți liber țara.

35În timp ce‑și goleau sacii, iată că punga cu argint a fiecăruia era în sacul lui. Văzând pungile cu argint, ei și tatăl lor s‑au temut.

36Tatăl lor, Iacov, le‑a zis:

– Voi m‑ați lăsat fără copii. Iosif nu mai este, Simeon nu mai este, și vreți să‑l luați și pe Beniamin. Toate acestea sunt împotriva mea!

37Atunci Ruben i‑a vorbit tatălui său, zicând:

– Să‑i omori pe cei doi fii ai mei, dacă nu ți‑l voi aduce înapoi pe Beniamin. Lasă‑l în grija mea și ți‑l voi aduce înapoi.

38Dar el a răspuns:

– Fiul meu nu va coborî cu voi, pentru că fratele său este mort și doar el a mai rămas. Dacă i se va întâmpla vreo nenorocire în călătoria pe care o faceți, în durere îmi veți coborî capul încărunțit în Locuința Morților.