Gẹnẹsisi 30 – YCB & NIV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 30:1-43

1Nígbà tí Rakeli rí i pe òun kò bímọ, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara sí Lea, arábìnrin rẹ̀, ó sì wí fún Jakọbu pé, “Fún mi lọ́mọ, bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, èmi ó kú!”

2Inú sì bí Jakọbu sí i, ó sì wí pé, “Èmi ha wà ní ipò Ọlọ́run, ẹni tí ó mú ọ yàgàn bí?”

3Nígbà náà ni Rakeli wí pé, “Biliha ìránṣẹ́bìnrin mi nìyìí, bá a lòpọ̀, kí ó ba à le bí ọmọ fún mi, kí èmi si le è tipasẹ̀ rẹ̀ ní ọmọ.”

4Báyìí ni Rakeli fi Biliha fún Jakọbu ní aya, ó sì bá a lòpọ̀. 5Biliha sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Jakọbu. 6Rakeli sì wí pé, “Ọlọ́run ti ṣe ìdájọ́ mi; ó sì ti gbọ́ ohùn ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì fún mi ni ọmọkùnrin kan.” Nítorí ìdí èyí ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ní Dani.

7Biliha, ọmọ ọ̀dọ̀ Rakeli sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kejì fún Jakọbu. 8Nígbà náà ni Rakeli wí pé, “Mo ti bá ẹ̀gbọ́n mi ja ìjàkadì ńlá, èmi sì ti borí.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Naftali.

9Nígbà tí Lea sì ri pé òun ko tún lóyún mọ́, ó sì fi ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, Silipa fún Jakọbu bí aya. 10Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ Lea sì bí ọmọkùnrin kan fún Jakọbu. 11Nígbà náà ni Lea wí pé, “Orí rere ni èyí!” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Gadi.

12Silipa ọmọ ọ̀dọ̀ Lea sì tún bí ọmọkùnrin kejì fún Jakọbu. 13Nígbà náà ni Lea wí pé, “Mo ní ayọ̀ gidigidi! Àwọn ọmọbìnrin yóò sì máa pe mí ní Alábùkún fún.” Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Aṣeri.

14Ní ọjọ́ kan, ní àkókò ìkórè ọkà jéró, Reubeni jáde lọ sí oko, ó sì rí èso mándrákì, ó sì mú un tọ Lea ìyá rẹ̀ wá. Rakeli sì wí fún Lea pé, “Jọ̀wọ́ fún mi ní ara èso mándrákì tí ọmọ rẹ mú wá.”

15Ṣùgbọ́n Lea dalóhùn pé, “Ọkọ mi tí o gbà kò tó kọ́? Ṣe ìwọ yóò tún gba èso mándrákì ọmọ mi pẹ̀lú?”

Rakeli sì dáhùn pé, “Ó dára, yóò sùn tì ọ́ lálẹ́ yìí nítorí èso mándrákì ọmọ rẹ.”

16Nítorí náà, nígbà tí Jakọbu ti oko dé ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ náà, Lea jáde lọ pàdé rẹ̀, ó sì wí pé, “O ní láti sun ọ̀dọ̀ mi ní alẹ́ yìí nítorí mo ti fi èso mándrákì tí ọmọ mi wá bẹ̀ ọ́ lọ́wẹ̀.” Nítorí náà ni Jakọbu sùn tì í ní alẹ́ ọjọ́ náà.

17Ọlọ́run sì gbọ́ ti Lea, ó sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin karùn-ún fún Jakọbu. 18Nígbà náà ni Lea wí pé, “Ọlọ́run ti sẹ̀san ọmọ ọ̀dọ̀ mi ti mo fi fún ọkọ mi fún mi,” ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Isakari.

19Lea sì tún lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kẹfà fún Jakọbu. 20Nígbà náà ni Lea tún wí pé “Ọlọ́run ti fún mi ní ẹ̀bùn iyebíye, nígbà yìí ni ọkọ mi yóò máa bu ọlá fún mi.” Nítorí náà ni ó ṣe pe orúkọ rẹ̀ ni Sebuluni.

21Lẹ́yìn èyí, ó sì bí ọmọbìnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Dina.

22Nígbà náà ni Ọlọ́run rántí Rakeli, Ọlọ́run sì gbọ́ tirẹ̀, ó sì ṣí i ní inú. 23Ó lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan ó sì wí pé, “Ọlọ́run ti mú ẹ̀gàn mi kúrò.” 24Ó sì pe orúkọ rẹ̀ ni Josẹfu, ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ kí Olúwa kí ó fi ọmọkùnrin mìíràn kún un fún mi.”

Agbo ẹran Jakọbu pọ̀ sí i

25Lẹ́yìn tí Rakeli ti bí Josẹfu, Jakọbu wí fún Labani pé, “Jẹ́ kí èmi máa lọ sí ilẹ̀ mi tí mo ti wá. 26Kó àwọn ọmọ àti ìyàwó mi fún mi, àwọn ẹni tí mo ti torí wọn sìn ọ́. Ki èmi lè máa bá ọ̀nà mi lọ. O sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ tó.”

27Ṣùgbọ́n Labani wí fún un pé, “Bí o bá ṣe pé mo rí ojúrere rẹ, jọ̀wọ́ dúró, nítorí, mo ti ṣe àyẹ̀wò rẹ, mo sì rí i pé Olúwa bùkún mi nítorí rẹ. 28Sọ ohun tí o fẹ́ gẹ́gẹ́ bí owó iṣẹ́ ẹ̀ rẹ, èmi yóò sì san án.”

29Jakọbu sì wí fún un pé, “Ìwọ sá à mọ bí mo ti ṣiṣẹ́ sìn ọ́ àti bí ẹran ọ̀sìn rẹ ti pọ̀ si lábẹ́ ìtọ́jú mi. 30Ìwọ̀nba díẹ̀ sá à ni o ní kí èmi tó dé, ó sì ti pọ̀ sí i gidigidi, Olúwa sì ti bùkún ọ nínú gbogbo èyí tí mo ṣe. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, nígbà wo ní èmi yóò pèsè fún ìdílé tèmi.”

31Ó sì tún béèrè wí pé, “Kín ni kí èmi ó fi fún ọ?”

Jakọbu dáhùn pé, “Má fun mi ni ohunkóhun, ṣùgbọ́n bí ìwọ yóò bá ṣe ohun tí mo fẹ́ sọ yìí, èmi yóò sì máa bá ọ tọ́jú àwọn agbo ẹran rẹ, èmi yóò sì máa bọ́ wọn. 32Jẹ́ kí èmi kí ó la agbo ẹran kọjá ní òní, èmi yóò sì mú gbogbo àgùntàn onílà àti èyí tí ó ní àmì, àti gbogbo àgbò dúdú pẹ̀lú ewúrẹ́ onílà tàbí tí ó ní àmì. Àwọn wọ̀nyí ni yóò dúró fún owó iṣẹ́ mi. 33Òtítọ́ inú mi yóò sì jẹ́rìí fún mi ní ọjọ́ iwájú nígbà tí ìwọ bá wo owó iṣẹ́ mi tí ìwọ san fún mi, yóò sì ṣe pé gbogbo èyí tí kì í bá ṣe onílà tàbí alámì nínú ewúrẹ́ tàbí tí kì í ṣe dúdú nínú àgùntàn, tí o bá rí ni ọ̀dọ̀ mi ni kí o kà sí mi lọ́rùn pé jíjí ni mo jí gbé.”

34Labani sì dáhùn pé, “Mo fi ara mọ́ ọn, ṣe bí ìwọ ti wí.” 35Ní ọjọ́ náà gan an ni Labani kó gbogbo ewúrẹ́ tí ó ní àmì tàbí ilà (àti òbúkọ àti abo, tí ó ní funfun díẹ̀ lára), pẹ̀lú gbogbo àgùntàn dúdú, ó sì fi wọ́n sí ìtọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀. 36Ibi tí Labani àti Jakọbu sì wà sí ara wọn, sì tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta. Jakọbu sì ń tọ́jú agbo ẹran Labani tí ó kù.

37Nígbà náà ni Jakọbu gé ọ̀pá tẹ́ẹ́rẹ́ tútù kan lára igi Poplari, àti igi almondi àti igi Pileeni. Ó sì bó èèpo kúrò ní ibi kọ̀ọ̀kan lára igi náà láti fún igi náà ní àwọ̀ ju ẹyọ kan lọ. 38Ó sì mú àwọn ọ̀pá wọ̀nyí tì sí ọ̀ọ́kán agbada omi níbi tí àwọn ẹran ti lè rí i nígbà tí wọ́n bá wá mu omi. 39Tí àwọn ẹran bá sì ń gùn, níwájú àwọn ọ̀pá náà, wọn sì bí àwọn ẹran onílà àti alámì, àwọn tí ó ní tótòtó lára. 40Nígbà náà ni ó ya àwọn abo ẹran kúrò nínú agbo ẹran Labani, ó sì yà wọ́n sọ́tọ̀ kúrò lára àgbò, ó sì mú kí wọn máa gùn pẹ̀lú àwọn àgbò Jakọbu dúdú nìkan, bẹ́ẹ̀ ni ó kó agbo ẹran jọ fún ara rẹ̀ láti ara agbo ẹran Labani. 41Nígbàkígbà tí àwọn ẹran tí ó lera bá ń gùn, Jakọbu yóò fi àwọn ọ̀pá wọ̀nyí lélẹ̀ níwájú wọn, ní ibi tí wọn ti ń mu omi. 42Ṣùgbọ́n tí ó bá jẹ́ wí pé wọn kò lera, kò ní fi àwọn ọ̀pá náà lélẹ̀. Nítorí náà, àwọn tí kò lera ń jẹ́ ti Labani, nígbà tí àwọn tí ó lera ń jẹ́ ti Jakọbu. 43Nítorí ìdí èyí, Jakọbu di ọlọ́rọ̀ gidigidi, agbo ẹran rẹ̀ pọ̀ àti àwọn ìránṣẹ́kùnrin, ìránṣẹ́bìnrin pẹ̀lú ìbákasẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

New International Version

Genesis 30:1-43

1When Rachel saw that she was not bearing Jacob any children, she became jealous of her sister. So she said to Jacob, “Give me children, or I’ll die!”

2Jacob became angry with her and said, “Am I in the place of God, who has kept you from having children?”

3Then she said, “Here is Bilhah, my servant. Sleep with her so that she can bear children for me and I too can build a family through her.”

4So she gave him her servant Bilhah as a wife. Jacob slept with her, 5and she became pregnant and bore him a son. 6Then Rachel said, “God has vindicated me; he has listened to my plea and given me a son.” Because of this she named him Dan.30:6 Dan here means he has vindicated.

7Rachel’s servant Bilhah conceived again and bore Jacob a second son. 8Then Rachel said, “I have had a great struggle with my sister, and I have won.” So she named him Naphtali.30:8 Naphtali means my struggle.

9When Leah saw that she had stopped having children, she took her servant Zilpah and gave her to Jacob as a wife. 10Leah’s servant Zilpah bore Jacob a son. 11Then Leah said, “What good fortune!”30:11 Or “A troop is coming!” So she named him Gad.30:11 Gad can mean good fortune or troop.

12Leah’s servant Zilpah bore Jacob a second son. 13Then Leah said, “How happy I am! The women will call me happy.” So she named him Asher.30:13 Asher means happy.

14During wheat harvest, Reuben went out into the fields and found some mandrake plants, which he brought to his mother Leah. Rachel said to Leah, “Please give me some of your son’s mandrakes.”

15But she said to her, “Wasn’t it enough that you took away my husband? Will you take my son’s mandrakes too?”

“Very well,” Rachel said, “he can sleep with you tonight in return for your son’s mandrakes.”

16So when Jacob came in from the fields that evening, Leah went out to meet him. “You must sleep with me,” she said. “I have hired you with my son’s mandrakes.” So he slept with her that night.

17God listened to Leah, and she became pregnant and bore Jacob a fifth son. 18Then Leah said, “God has rewarded me for giving my servant to my husband.” So she named him Issachar.30:18 Issachar sounds like the Hebrew for reward.

19Leah conceived again and bore Jacob a sixth son. 20Then Leah said, “God has presented me with a precious gift. This time my husband will treat me with honor, because I have borne him six sons.” So she named him Zebulun.30:20 Zebulun probably means honor.

21Some time later she gave birth to a daughter and named her Dinah.

22Then God remembered Rachel; he listened to her and enabled her to conceive. 23She became pregnant and gave birth to a son and said, “God has taken away my disgrace.” 24She named him Joseph,30:24 Joseph means may he add. and said, “May the Lord add to me another son.”

Jacob’s Flocks Increase

25After Rachel gave birth to Joseph, Jacob said to Laban, “Send me on my way so I can go back to my own homeland. 26Give me my wives and children, for whom I have served you, and I will be on my way. You know how much work I’ve done for you.”

27But Laban said to him, “If I have found favor in your eyes, please stay. I have learned by divination that the Lord has blessed me because of you.” 28He added, “Name your wages, and I will pay them.”

29Jacob said to him, “You know how I have worked for you and how your livestock has fared under my care. 30The little you had before I came has increased greatly, and the Lord has blessed you wherever I have been. But now, when may I do something for my own household?”

31“What shall I give you?” he asked.

“Don’t give me anything,” Jacob replied. “But if you will do this one thing for me, I will go on tending your flocks and watching over them: 32Let me go through all your flocks today and remove from them every speckled or spotted sheep, every dark-colored lamb and every spotted or speckled goat. They will be my wages. 33And my honesty will testify for me in the future, whenever you check on the wages you have paid me. Any goat in my possession that is not speckled or spotted, or any lamb that is not dark-colored, will be considered stolen.”

34“Agreed,” said Laban. “Let it be as you have said.” 35That same day he removed all the male goats that were streaked or spotted, and all the speckled or spotted female goats (all that had white on them) and all the dark-colored lambs, and he placed them in the care of his sons. 36Then he put a three-day journey between himself and Jacob, while Jacob continued to tend the rest of Laban’s flocks.

37Jacob, however, took fresh-cut branches from poplar, almond and plane trees and made white stripes on them by peeling the bark and exposing the white inner wood of the branches. 38Then he placed the peeled branches in all the watering troughs, so that they would be directly in front of the flocks when they came to drink. When the flocks were in heat and came to drink, 39they mated in front of the branches. And they bore young that were streaked or speckled or spotted. 40Jacob set apart the young of the flock by themselves, but made the rest face the streaked and dark-colored animals that belonged to Laban. Thus he made separate flocks for himself and did not put them with Laban’s animals. 41Whenever the stronger females were in heat, Jacob would place the branches in the troughs in front of the animals so they would mate near the branches, 42but if the animals were weak, he would not place them there. So the weak animals went to Laban and the strong ones to Jacob. 43In this way the man grew exceedingly prosperous and came to own large flocks, and female and male servants, and camels and donkeys.