Gẹnẹsisi 28 – YCB & JCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 28:1-22

1Nítorí náà Isaaki pe Jakọbu, ó sì súre fún un, ó sì pàṣẹ fún un pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ fẹ́ aya láàrín àwọn ọmọbìnrin Kenaani. 2Dípò bẹ́ẹ̀ lọ sí Padani-Aramu, sí ilé Betueli, baba ìyá rẹ, kí ìwọ kí ó sì fẹ́ aya fún ara rẹ nínú àwọn ọmọbìnrin Labani arákùnrin ìyá rẹ. 3Kí Ọlọ́run Olódùmarè El-Ṣaddai kí ó bùkún fún ọ, kí ó sì mú ọ bí sí i, kí ó sì mú ọ pọ̀ sí i ní iye títí tí ìwọ yóò di àgbájọ àwọn ènìyàn. 428.4: Gẹ 17.4-8.Kí Ọlọ́run kí ó fún ìwọ àti irú-ọmọ rẹ ní ìre tí ó sú fún Abrahamu, kí ìwọ kí ó le gba ilẹ̀ níbi tí a ti ń ṣe àtìpó yìí, ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti fi fún Abrahamu.” 5Bẹ́ẹ̀ ni Isaaki sì rán Jakọbu lọ. Ó sì lọ sí Padani-Aramu, lọ́dọ̀ Labani ọmọ Betueli, ará Aramu, tí í ṣe arákùnrin Rebeka ìyá Jakọbu àti Esau.

6Nígbà tí Esau gbọ́ pé, Isaaki ti súre fún Jakọbu, ó sì ti rán Jakọbu lọ sí Padani-Aramu láti fẹ́ aya níbẹ̀ àti pé nígbà tí ó súre fún un, ó kìlọ̀ fun un pé, kò gbọdọ̀ fẹ́ nínú àwọn ọmọbìnrin Kenaani 7àti pé, Jakọbu ti gbọ́rọ̀ sí ìyá àti baba rẹ̀ lẹ́nu, ó sì ti lọ sí Padani-Aramu. 8Nígbà náà ni Esau mọ bí Isaaki baba rẹ ti kórìíra àwọn ọmọbìnrin Kenaani tó. 9Nítorí náà Esau tọ Iṣmaeli lọ, ó sì fẹ́ Mahalati, arábìnrin Nebaioti, ọmọbìnrin Iṣmaeli tí í ṣe ọmọ Abrahamu. Ó fẹ́ ẹ, kún àwọn ìyàwó tí ó ti ní tẹ́lẹ̀.

Àlá Jakọbu ní Beteli

10Jakọbu kúrò ní Beerṣeba, ó sì kọrí sí ìlú Harani. 11Nígbà tí ó dé ibìkan, ó dúró ní òru náà nítorí tí ilẹ̀ ti ń ṣú, ó sì gbé òkúta kan ó fi ṣe ìrọ̀rí, ó sì sùn. 1228.12: Jh 1.51.Ó sì lá àlá pé, a gbé àkàsọ̀ kan dúró ti ó fi ìdí lélẹ̀, orí rẹ̀ sì kan ọ̀run, àwọn angẹli Ọlọ́run sì ń gòkè, wọ́n sì ń sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀. 1328.13: Gẹ 13.14,15.Olúwa sì dúró lókè rẹ̀, ó sì wí pé, “Èmi ni Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, ìwọ àti ìran rẹ ni èmi yóò fi ilẹ̀ tí ìwọ dùbúlẹ̀ sórí rẹ̀ yìí fún. 1428.14: Gẹ 12.3; 22.18.Ìran rẹ yóò pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, ìwọ yóò sì tànkálẹ̀ dé ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn, àti dé gúúsù àti àríwá. A ó sì bùkún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nípasẹ̀ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ. 15Èmi wà pẹ̀lú rẹ, èmi yóò sì pa ọ mọ́ ní ibikíbi tí ìwọ bá lọ, èmi yóò sì mú ọ padà wá sí ilẹ̀ yìí ní àlàáfíà. Èmi kì yóò fi ọ sílẹ̀ ní ìgbà kan, títí tí èmi yóò fi mú gbogbo ìlérí mi ṣẹ.”

16Nígbà tí Jakọbu jí lójú oorun rẹ̀, ó rò nínú ara rẹ̀ pé, “Dájúdájú Olúwa ń bẹ ní ìhín yìí, èmi kò sì mọ̀.” 17Ẹ̀rù sì bà á, ó sì wí pé, “Ìhín yìí ní ẹ̀rù gidigidi; ibí kì í ṣe ibòmíràn bí kò ṣe ilé Ọlọ́run, àní ẹnu ibodè ọ̀run nìyìí.”

18Jakọbu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀, ó sì gbé òkúta tí ó fi ṣe ìrọ̀rí lélẹ̀ bí ọ̀wọ́n, ó sì da òróró si lórí. 19Ó sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Beteli, 28.19 tí ó túmọ̀ sí, Ilé Ọlọ́run bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìlú náà ń jẹ́ Lusi tẹ́lẹ̀ rí.

20Jakọbu sì jẹ́ ẹ̀jẹ́ níbẹ̀ pé, “Bí Ọlọ́run yóò bá wà pẹ̀lú mi, tí yóò sì pa mí mọ́ ní ìrìnàjò mi tí mo ń lọ, tí yóò sì fún mi ní oúnjẹ láti jẹ àti aṣọ láti wọ̀, 21tí mo sì padà sílé baba mi ní àlàáfíà, nígbà náà Olúwa ni yóò jẹ́ Ọlọ́run mi, 22Òkúta yìí tí mo gbé kalẹ̀ bí ọ̀wọ́n yóò jẹ́ ilé Ọlọ́run, nínú gbogbo ohun tí ìwọ ó fi fún mi, èmi yóò sì fi ìdámẹ́wàá rẹ̀ fún ọ.”

Japanese Contemporary Bible

創世記 28:1-22

28

1そこで、イサクはヤコブを呼び寄せ、祝福して言いました。 2「おまえはカナン人の女と結婚してはいけない。パダン・アラムに、ベトエルといってな、おまえのおじいさんの家がある。すぐにそこへ行きなさい。ラバン伯父さんの娘と結婚するのだ。 3全能の神様がおまえを祝福し、たくさんの子どもを授けてくださり、たくさんの部族を持つ大きな国にしてくださるように。 4おじいさんのアブラハムに約束されたすばらしい祝福が、おまえと子孫に受け継がれるように。私たちは今ここでは外国人だが、おまえの代になって、この地を手に入れることができるように祈る。神様がおじいさんに約束されたように。」

5こうしてイサクは、ヤコブをパダン・アラムのラバンのもとへ送りました。アラム人ベトエルの子ラバンは、リベカの兄で、ヤコブの伯父に当たります。

6-8エサウは、父親がこの土地の娘たちを快く思っていないこと、そして両親が、ヤコブの結婚相手をカナン人の女からではなくパダン・アラムで見つけるために、ヤコブを祝福したうえで送り出したことを知りました。ヤコブも両親の言いつけどおり出発したといいます。 9それでエサウは、伯父イシュマエルの家へ行き、今いる妻のほかに、さらに妻をめとりました。アブラハムの子イシュマエルの娘で、ネバヨテの妹マハラテでした。

10さて、ヤコブはベエル・シェバを出発し、ハランへ向かいました。 11とある場所まで来ると、日がとっぷり暮れたので、野営することにしました。あたりに転がっている石を枕に、ごろんと横になりました。

12その晩のことです。ヤコブは不思議な夢を見ました。目の前に天までも届く階段がそびえ、神の使いが上ったり下りたりしているのです。 13ふと見ると、神がそばに立っておられます。「わたしは神、アブラハムの神、あなたの父イサクの神、主である。あなたがいま寝ている土地はあなたのものだ。それを、あなたとその子孫に与えよう。 14子孫は地のちりのように多くなり、東西南北、あらゆる方角に増え広がり、この地全体に住みつくだろう。あなたとあなたの子孫によって、世界中の国々が祝福される。 15あなたがどこへ行こうと、わたしはいつも共にいて、あなたを助ける。無事この地に帰れるように必ず守ろう。約束のものをすべて渡すまで、わたしはいつでも共にいる。」

16-17そこで目が覚めました。「主はここにもおられる。気づかなかったが、ここは神様の家なのだ。おそれ多くも天国への入口だったのだ。」ヤコブは怖くなって思わず叫びました。 18次の朝早く起き、枕にした石を立てて記念の柱とし、オリーブ油を注ぎかけました。 19そして、そこをベテル〔「神の家」の意〕と名づけました。そのあたりは以前、ルズと呼ばれていました。

20ヤコブは神に誓いました。「神様、もし主がこの旅で私を助け、守ってくださり、衣食にも不自由させず、 21無事に父の家に帰してくださって、私の神様となってくださるなら、 22この記念の柱を礼拝の場所とし、神様から頂いた物すべての十分の一を必ずおささげします。」