Gẹnẹsisi 18 – YCB & GKY

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 18:1-33

Àwọn àlejò mẹ́ta

1Olúwa sì farahan Abrahamu nítòsí àwọn igi ńlá Mamre, bí ó ti jókòó ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, nígbà tí ọjọ́-kanrí tí oòrùn sì mú. 218.2: Hb 13.2.Abrahamu gbójú sókè, ó sì rí àwọn ọkùnrin mẹ́ta tí wọn dúró nítòsí rẹ̀. Nígbà tí ó rí wọn, ó sáré láti lọ pàdé wọn, ó sì tẹríba bí ó ti ń kí wọn.

3Ó wí pé, “Bí mo bá rí ojúrere yín Olúwa mi, ẹ má ṣe lọ láì yà sọ́dọ̀ ìránṣẹ́ yín. 4Ẹ jẹ́ kí a bu omi díẹ̀ wá kí ẹ̀yin kí ó wẹ ẹsẹ̀ yín, kí ẹ sì sinmi lábẹ́ igi níhìn-ín. 5Ẹ jẹ́ kí n wá oúnjẹ wá fún un yín, kí ẹ̀yin kí ó lè jẹ, kí ara sì tù yín, kí ẹ si tẹ̀síwájú ní ọ̀nà yín, nígbà tí ẹ ti yà ní ọ̀dọ̀ ìránṣẹ́ yín.”

Wọn sì wí pé “Ó dára.”

6Abrahamu sì yára tọ Sara aya rẹ̀ lọ nínú àgọ́, ó wí pé, “Tètè mú òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dáradára mẹ́ta kí o sì pò ó pọ̀, kí o sì ṣe oúnjẹ.”

7Abrahamu sì tún sáré lọ sí ibi agbo ẹran, ó sì mú ọmọ màlúù kan fún ìránṣẹ́ rẹ̀, ìránṣẹ́ náà sì tètè ṣè é. 8Ó sì mú wàrà àti mílíìkì àti màlúù tí ó ti pèsè, ó sì gbé síwájú wọn. Ó sì dúró nítòsí wọn lábẹ́ igi bí wọn ti ń jẹ ẹ́.

9Wọn béèrè pé, “Sara aya rẹ ń kọ́?”

Ó dáhùn pé, “Ó wà nínú àgọ́.”

1018.10: Ro 9.9.Nígbà náà ni Olúwa wí fún un pé, “Èmi yóò sì tún padà tọ̀ ọ́ wá nítòótọ́ ní ìwòyí àmọ́dún; Sara aya rẹ yóò sì bí ọmọkùnrin kan.”

Sara sì ń dẹtí gbọ́ láti ẹnu-ọ̀nà àgọ́ tí ó wà lẹ́yìn ọkùnrin náà. 11Abrahamu àti Sara sì ti di arúgbó, Sara sì ti kọjá àsìkò ìbímọ. 1218.12: 1Pt 3.6.Nítorí náà, Sara rẹ́rìn-ín nínú ara rẹ̀ bí ó ti ń rò ó lọ́kàn rẹ̀ pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo ti di arúgbó tán tí olúwa mi pẹ̀lú sì ti gbó jọ̀kújọ̀kú, èmi yóò ha tún lè bímọ?”

13Nígbà náà ni Olúwa wí fún Abrahamu pé, “Kín ló dé tí Sara fi rẹ́rìn-ín tí ó sì wí pé, ‘Èmi yóò ha bímọ nítòótọ́, nígbà tí mo di ẹni ogbó tán?’ 1418.14: Mt 19.26; Mk 10.27; Lk 1.37; Ro 9.9.Ǹjẹ́ ohunkóhun wà tí ó ṣòro jù fún Olúwa? Èmi ó padà tọ̀ ọ́ wá ní ìwòyí àmọ́dún, Sara yóò sì bí ọmọkùnrin.”

15Ẹ̀rù sì ba Sara, ó sì sẹ́ pé òun kò rẹ́rìn-ín.

Ṣùgbọ́n Olúwa wí fún un pé, “Dájúdájú ìwọ rẹ́rìn-ín.”

Abrahamu bẹ Olúwa nítorí Sodomu

16Nígbà tí àwọn ọkùnrin náà dìde láti máa lọ, wọn kọjú sí ọ̀nà Sodomu, Abrahamu sì sìn wọ́n dé ọ̀nà. 17Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Ǹjẹ́ èmi yóò ha pa ohun tí mo fẹ́ ṣe mọ́ fún Abrahamu bí? 1818.18: Gẹ 12.3; Ap 3.25; Ga 3.8.Dájúdájú Abrahamu yóò sá à di orílẹ̀-èdè ńlá àti alágbára, àti gbogbo orílẹ̀-èdè ayé ni a ó bùkún fún nípasẹ̀ rẹ̀. 19Nítorí tí èmi ti yàn án láti kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ará ilé rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀, láti máa pa ọ̀nà Olúwa mọ nípa ṣíṣe olóòtítọ́ àti olódodo: kí Olúwa le è mú ìlérí rẹ̀ fún Abrahamu ṣẹ.”

20Olúwa sì wí pé, igbe Sodomu àti Gomorra pọ̀ púpọ̀ àti pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn burú jọjọ. 21“Èmi yóò sọ̀kalẹ̀ síbẹ̀ láti ṣe ìwádìí igbe tí ó dé sí etí ìgbọ́ mi nípa wọn, kí èmi sì mọ òtítọ́ tí ó wà níbẹ̀.”

22Àwọn ọkùnrin náà yí padà, wọ́n sì ń lọ sí ìhà Sodomu. Ṣùgbọ́n Abrahamu dúró níbẹ̀ níwájú Olúwa. 23Nígbà náà ni Abrahamu súnmọ́ ọ̀dọ̀ Olúwa, ó sì wí pé, “Ìwọ yóò ha pa olódodo ènìyàn àti ènìyàn búburú run papọ̀ bí?” 24“Bí ó bá ṣe pé ìwọ rí àádọ́ta olódodo nínú ìlú náà, ìwọ yóò ha run ún, ìwọ kì yóò ha dá ìlú náà sí nítorí àwọn àádọ́ta olódodo tí ó wà nínú rẹ̀ náà? 25Kò jẹ́ rí bẹ́ẹ̀! Dájúdájú ìwọ kì yóò ṣe ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀, láti pa olódodo pẹ̀lú àwọn ènìyàn rere àti àwọn ènìyàn búburú. Dájúdájú, ìwọ kì yóò ṣe èyí tí ó tọ́ bi?”

26Olúwa wí pé, “Bí mo bá rí àádọ́ta olódodo ní ìlú Sodomu, èmi yóò dá ìlú náà sí nítorí tiwọn.”

27Abrahamu sì tún tẹ̀síwájú pé, “Wò ó nísinsin yìí, níwọ̀n bí èmi ti ní ìgboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ níwájú Olúwa, èmi ẹni tí í ṣe erùpẹ̀ àti eérú, 28bí ó bá ṣe pe olódodo márùndínláàádọ́ta ni ó wà nínú ìlú, ìwọ yóò ha pa ìlú náà run nítorí ènìyàn márùn-ún bí?”

Olúwa dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo márùndínláàádọ́ta nínú rẹ̀.”

29Òun sì tún wí lẹ́ẹ̀kan si pé, “Bí ó bá ṣe pé ogójì ni ń kọ́?”

Olúwa sì tún wí pé, “Èmi kì yóò pa ìlú náà run bí mo bá rí olódodo ogójì nínú rẹ̀.”

30Abrahamu sì tún bẹ Olúwa pé, “Kí Olúwa má ṣe bínú, ṣùgbọ́n èmi yóò sọ̀rọ̀. Bí ó bá ṣe pé ọgbọ̀n ni a rí níbẹ̀ ń kọ́?”

Olúwa dáhùn pé, “Bí mó bá rí ọgbọ̀n, èmi kì yóò pa ìlú run.”

31Abrahamu wí pé, “Níwọ́n bí mo ti ní ìgboyà láti bá Olúwa sọ̀rọ̀ báyìí, jẹ́ kí n tẹ̀síwájú. Bí o bá ṣe pé olódodo ogún péré ni ó wà nínú ìlú náà ń kọ́?”

Olúwa sì dáhùn pé, “Èmi kì yóò pa á run nítorí ogún ènìyàn náà.”

32Abrahamu sì wí pé, “Jọ̀wọ́ má ṣe bínú Olúwa. Jẹ́ kí ń béèrè lẹ́ẹ̀kan si. Bí ó bá ṣe pé ènìyàn mẹ́wàá ni ó jẹ́ olódodo ń kọ́?”

Olúwa wí pé, “Nítorí ènìyàn mẹ́wàá náà, èmi kì yóò pa á run.”

33Olúwa sì bá tirẹ̀ lọ, nígbà tí ó bá Abrahamu sọ̀rọ̀ tán, Abrahamu sì padà sílé.

Holy Bible in Gĩkũyũ

Kĩambĩrĩria 18:1-33

Ageni arĩa Atatũ

118:1 Kĩam 13:18; Ahib 11:9Mũthenya ũmwe Jehova nĩ oimĩrĩire Iburahĩmu rĩrĩa aikarĩte mũromo-inĩ wa hema yake hakuhĩ na mĩtĩ ĩrĩa mĩnene ya mĩgandi ya Mamure, ihinda rĩa mĩaraho. 218:2 Kĩam 18:16, 22; Ahib 13:2Na rĩrĩ, Iburahĩmu aatiira maitho-rĩ, akĩona andũ atatũ marũgamĩte o hakuhĩ nake. Rĩrĩa aamoonire, akĩhiũha akiuma mũromo-inĩ wa hema yake, agĩthiĩ kũmatũnga, na agĩturumithia ũthiũ wake thĩ.

318:3 1Sam 1:18Akiuga atĩrĩ, “Mwathi wakwa, angĩkorwo nĩndetĩkĩrĩka maitho-inĩ maku, ndũkahĩtũke ndungata yaku. 418:4 Kĩam 19:2; 43:24; Luk 7:44Reke tũũĩ tũnini tũrehwo, na inyuĩ inyuothe mwĩthambe magũrũ na mũhurũke kĩĩruru-inĩ kĩa mũtĩ ũyũ. 518:5 Atiir 13:15; 19:5Na niĩ thiĩ ndĩmũrehere kĩndũ gĩa kũrĩa, nĩgeetha mũcookwo nĩ hinya, kuona atĩ nĩmwagĩũka kwa ndungata yanyu, nĩguo mũcooke mwĩthiĩre.”

Makĩmũcookeria atĩrĩ, “Nĩ wega mũno, ĩka o ũguo woiga.”

618:6 Kĩam 19:3; 2Sam 13:8Nĩ ũndũ ũcio Iburahĩmu akĩhiũha agĩthiĩ hema-inĩ kũrĩ Sara, akĩmwĩra atĩrĩ, “Oya ibaba ithatũ18:6 nĩ ta kilo 22. cia mũtu ũrĩa mũhinyu wega, ũũkande na ũruge mĩgate naihenya.”

718:7 1Sam 28:24; Luk 15:23Ningĩ Iburahĩmu agĩtengʼera rũũru-inĩ, agĩthuura njaũ njega na njororo, akĩmĩnengera ndungata, nayo ĩkĩmĩthĩnja naihenya. 818:8 Isa 7:15, 22Ningĩ Iburahĩmu akĩmarehera iria imata na iria rĩa mwĩtha, na nyama cia njaũ ĩyo yathĩnjĩtwo, agĩciiga hau mbere yao. Nake akĩrũgama hakuhĩ nao mũtĩ-inĩ rĩrĩa maarĩĩaga.

918:9 Kĩam 3:9; Ahib 11:9Maarĩkia kũrĩa makĩmũũria atĩrĩ, “Sara mũtumia waku-rĩ, arĩ kũ?”

Iburahĩmu akĩmacookeria atĩrĩ, “Arĩ kũũrĩa hema thĩinĩ.”

1018:10 Arom 9:9; Atiir 6:19Nake Jehova akiuga atĩrĩ, “Ti-itherũ nĩngooka kũrĩ we rĩngĩ hĩndĩ o ta ĩno mwaka ũyũ ũroka, na Sara mũtumia waku nĩagaciara kaana ga kahĩĩ.”

Nake Sara nĩathikagĩrĩria arĩ hau mũromo-inĩ wa hema ĩrĩa yarĩ thuutha wa Iburahĩmu. 1118:11 Kĩam 17:17; Arom 4:19Na rĩrĩ, Iburahĩmu na Sara maarĩ akũrũ na magatindĩka mĩaka yao ma, nake Sara akahĩtũkia mĩaka ya gũciara. 1218:12 Kĩam 17:17; 1Pet 3:6Nĩ ũndũ ũcio, Sara agĩĩthekera, akĩĩyũria atĩrĩ, “Thuutha wa gũkũra ũũ-rĩ, na mwathi wakwa nĩ mũkũrũ-rĩ, no ngĩgĩe na gĩkeno kĩu?”

13Nake Jehova akĩũria Iburahĩmu atĩrĩ, “Nĩ kĩĩ gĩatũma Sara atheke na eyũrie, ‘Ti-itherũ no ngĩe na mwana ndĩ mũkũrũ ũguo?’ 1418:14 Jer 32:17Kaĩ kũrĩ ũndũ ũngĩrema Jehova? Mwaka ũyũ ũroka-rĩ, nĩngacooka ihinda rĩrĩa rĩamũre, nake Sara nĩagaciara kaana ga kahĩĩ.”

15Sara agĩĩtigĩra mũno, nĩ ũndũ ũcio akĩheenania, akiuga atĩrĩ, “Niĩ ndinatheka.”

Nowe Jehova akiuga atĩrĩ, “Nĩ ma nĩwatheka.”

Iburahĩmu Gũthaithanĩrĩra Sodomu

1618:16 Kĩam 18:2Rĩrĩa andũ acio mookĩrire mathiĩ-rĩ, makĩerekera na Sodomu,18:16 Itũũra rĩa Sodomu rĩrĩ o harĩa rĩarĩ mwena wa gũthini wa Iria rĩa Cumbĩ. nake Iburahĩmu agĩtwarana nao amoimagarie. 1718:17 Amos 3:7Hĩndĩ ĩyo Jehova akĩĩyũria atĩrĩ, “No hithe Iburahĩmu ũrĩa ndĩrenda gwĩka? 1818:18 Agal 3:8Ti-itherũ Iburahĩmu nĩagatuĩka rũrĩrĩ rũnene na rwa hinya, na ndũrĩrĩ ciothe cia thĩ nĩikarathimwo nĩ ũndũ wake. 1918:19 Gũcook 4:9-10; 6:7; Jer 23:5Nĩgũkorwo nĩndĩmũthuurĩte nĩgeetha onagĩrĩrie ciana ciake, na nyũmba yake, na arĩa magooka thuutha wake, kũrũmagia mĩthiĩre ya Jehova na ũndũ wa gwĩkaga ũrĩa kwagĩrĩire, na kĩhooto, nĩgeetha Jehova akaahingĩria Iburahĩmu ũrĩa aamwĩrĩire.”

2018:20 Ezek 16:46 Ningĩ Jehova akiuga atĩrĩ, “Mũkayo wĩgiĩ Sodomu na Gomora nĩ mũnene mũno, naguo wĩhia wao nĩ mũũru mũno. 21Nĩ ũndũ ũcio niĩ nĩngũikũrũka thiĩ nyone kana ũũru ũrĩa mekĩte nĩũigana ikaya rĩrĩa rĩnginyĩire. Na aakorwo tiguo-rĩ, nĩngũmenya ũrĩa ngwĩka.”

22Nĩ ũndũ ũcio andũ acio makiuma hau magĩthiĩ merekeire Sodomu, no Iburahĩmu agĩtigwo arũgamĩte mbere ya Jehova. 2318:23 Ndar 16:22; 2Pet 2:9Nake Iburahĩmu agĩkuhĩrĩria Jehova akĩmũũria atĩrĩ, “Andũ arĩa athingu ũkũmaniinanĩria hamwe na arĩa aaganu? 2418:24 Jer 5:1Ĩ kũngĩkorwo kũrĩ na andũ mĩrongo ĩtano athingu itũũra-inĩ rĩu inene? Ti-itherũ no ũrĩniine na ndũrĩhonokie nĩ ũndũ wa andũ acio mĩrongo ĩtano athingu marĩ kuo? 2518:25 Ayub 8:3, 20; Isa 3:10-11; Arom 3:6Ũroaga gwĩka ũndũ ta ũcio, wa kũũraganĩria arĩa athingu hamwe na arĩa aaganu, arĩa athingu na arĩa aaganu ũmataranĩrie ũndũ ũmwe. Ũroaga gwĩka ũndũ ta ũcio! Mũtuanĩri ciira wa thĩ yothe-rĩ, githĩ ndagĩrĩirwo nĩ gwĩka ũrĩa kwagĩrĩire?”

26Nake Jehova akiuga atĩrĩ, “Ingĩkora andũ mĩrongo ĩtano athingu kũu itũũra rĩu inene rĩa Sodomu-rĩ, nĩngũhonokia kũndũ kũu guothe nĩ ũndũ wao.”

2718:27 Kĩam 2:7; Ayub 2:8Ningĩ Iburahĩmu akĩaria rĩngĩ, akiuga atĩrĩ: “Rĩu tondũ nĩngĩĩũmĩrĩirie nginya ndaaria na Mwathani, o na gũtuĩka ndĩ o rũkũngũ na mũhu-rĩ, atĩrĩ, 28ĩ hangĩaga andũ atano a acio mĩrongo ĩtano athingu? Nĩ ũngĩniina itũũra rĩu inene rĩothe nĩ ũndũ wa kwaga acio atano?”

Jehova akĩmwĩra atĩrĩ, “Ingĩkora andũ mĩrongo ĩna na atano kuo, ndikũrĩniina.”

29O rĩngĩ Iburahĩmu akĩmwarĩria akĩmũũria atĩrĩ, “Ĩ ũngĩkora andũ mĩrongo ĩna tu kuo?”

Nake akiuga atĩrĩ, “Nĩ ũndũ wa acio mĩrongo ĩna-rĩ, ndikũrĩniina.”

3018:30 Thaam 32:22Ningĩ Iburahĩmu akiuga atĩrĩ, “Mwathani aroaga kũrakara, no areke njarie. Ĩ ũngĩkora andũ mĩrongo ĩtatũ kuo?”

Nake akĩmũcookeria atĩrĩ, “Ndikũrĩniina ingĩkora andũ mĩrongo ĩtatũ kuo.”

31Iburahĩmu akiuga atĩrĩ, “Rĩu tondũ nĩngĩĩũmĩrĩirie nginya ndaaria na Mwathani-rĩ, ĩ kũngĩoneka o andũ mĩrongo ĩĩrĩ kuo?”

Nake Jehova akiuga atĩrĩ, “Nĩ ũndũ wa acio mĩrongo ĩĩrĩ, ndikũrĩniina.”

3218:32 Atiir 6:39Ningĩ akiuga atĩrĩ, “Mwathani aroaga kũrakara no areke njarie rĩngĩ rĩmwe. Ĩ kũngĩoneka o andũ ikũmi kuo?”

Nake Jehova agĩcookia, akiuga atĩrĩ, “Nĩ ũndũ wa acio ikũmi-rĩ, ndikũrĩniina.”

3318:33 Kĩam 31:55Rĩrĩa Jehova aarĩkirie kwaria na Iburahĩmu, agĩĩthiĩra, nake Iburahĩmu agĩcooka mũciĩ.