Gẹnẹsisi 13 – YCB & NTLR

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 13:1-18

Ìpinyà Abramu àti Lọti

1Abramu sì gòkè láti Ejibiti lọ sí ìhà gúúsù, pẹ̀lú aya rẹ̀ àti ohun gbogbo tí ó ní àti Lọti pẹ̀lú. 2Abramu sì ti di ọlọ́rọ̀ gidigidi; ní ẹran ọ̀sìn, ó ní fàdákà àti wúrà.

3Láti gúúsù, ó ń lọ láti ibìkan sí ibòmíràn títí ó fi dé ilẹ̀ Beteli, ní ibi tí àgọ́ rẹ̀ ti wà ní ìṣáájú rí, lágbedeméjì Beteli àti Ai. 4Ní ibi pẹpẹ tí ó ti tẹ́ síbẹ̀ ní ìṣáájú, níbẹ̀ ni Abramu sì ń ké pe orúkọ Olúwa.

5Àti Lọti pẹ̀lú, tí ó ń bá Abramu rìn kiri, ní agbo ẹran, ọ̀wọ́ ẹran àti àgọ́. 6Ṣùgbọ́n ilẹ̀ náà kò le gbà wọ́n tí wọ́n bá ń gbé pọ̀, nítorí, ohun ìní wọn pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́, dé bi wí pé wọn kò le è gbé pọ̀. 7Èdè-àìyedè sì bẹ̀rẹ̀ láàrín àwọn darandaran Abramu àti ti Lọti. Àwọn ará Kenaani àti àwọn ará Peresi sì ń gbé ní ilẹ̀ náà nígbà náà.

8Abramu sì wí fún Lọti pé, “Èmi bẹ̀ ọ́, má ṣe jẹ́ kí èdè-àìyedè kí ó wà láàrín èmi àti ìrẹ, àti láàrín àwọn darandaran wa, nítorí pé ẹbí kan ni àwa ṣe. 9Gbogbo ilẹ̀ ha kọ́ nìyí níwájú rẹ? Jẹ́ kí a pínyà. Bí ìwọ bá lọ sí apá ọ̀tún, èmi yóò lọ sí apá òsì, bí ó sì ṣe òsì ni ìwọ lọ, èmi yóò lọ sí apá ọ̀tún.”

1013.10: Gẹ 2.10.Lọti sì gbójú sókè, ó sì ri wí pé gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ni omi rin dáradára bí ọgbà Olúwa, bí ilẹ̀ Ejibiti, ní ọ̀nà Soari. (Èyí ní ìṣáájú kí Olúwa tó pa Sodomu àti Gomorra run.) 11Nítorí náà Lọti yan gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani yìí fún ara rẹ̀, ó sì ń lọ sí ọ̀nà ìlà-oòrùn. Òun àti Abramu sì pínyà. 12Abramu ń gbé ni ilẹ̀ Kenaani, Lọti sì jókòó ní ìlú agbègbè àfonífojì náà, ó sì pàgọ́ rẹ̀ títí dé Sodomu. 13Ṣùgbọ́n àwọn ọkùnrin Sodomu jẹ́ ènìyàn búburú, wọn sì ń dẹ́ṣẹ̀ gidigidi ni iwájú Olúwa.

14Olúwa sì wí fún Abramu lẹ́yìn ìpinyà òun àti Lọti pé, “Gbé ojú rẹ sókè nísinsin yìí, kí o sì wò láti ibi tí o gbé wà a nì lọ sí ìhà àríwá àti sí ìhà gúúsù, sí ìlà-oòrùn àti sí ìwọ̀ rẹ̀. 1513.15: Ap 7.5; Ga 3.16.Gbogbo ilẹ̀ tí ìwọ ń wò o nì ni èmi ó fi fún ọ àti irú-ọmọ rẹ láéláé. 16Èmi yóò mú kí irú-ọmọ rẹ kí ó pọ̀ bí erùpẹ̀ ilẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí ó bá ṣe pé ẹnikẹ́ni bá le è ka erùpẹ̀ ilẹ̀, nígbà náà ni yóò tó lè ka irú-ọmọ rẹ. 17Dìde, rìn òró àti ìbú ilẹ̀ náà já, nítorí ìwọ ni Èmi yóò fi fún.”

18Nígbà náà ni Abramu kó àgọ́ rẹ̀, ó sì wá, ó sì jókòó ní ẹ̀gbẹ́ igi ńlá igbó Mamre, tí ó wà ní Hebroni. Níbẹ̀ ni ó gbé tẹ́ pẹpẹ kan sí fún Olúwa.

Nouă Traducere În Limba Română

Geneza 13:1-18

Despărțirea lui Avram de Lot

1Avram s‑a suit din Egipt în Neghev1, 3 Vezi nota de la 12:9. împreună cu soția lui și cu tot ce avea, iar Lot a mers împreună cu el. 2Avram era foarte bogat în turme, în argint și în aur.

3Din Neghev, el a călătorit până la Betel, până la locul în care fusese cortul lui la început, între Betel și Ai, 4până la locul în care el făcuse un altar mai înainte. Acolo, Avram a chemat Numele Domnului.

5Lot, care a mers împreună cu Avram, avea și el turme, cirezi și corturi. 6Dar ținutul locuit nu‑i mai încăpea. Aveau atât de multe bunuri, încât nu mai puteau locui împreună. 7De asemenea, s‑a iscat o ceartă între păstorii turmelor lui Avram și păstorii turmelor lui Lot. În vremea aceea canaaniții și periziții locuiau în Canaan. 8Atunci Avram i‑a zis lui Lot: „Te rog, să nu fie ceartă între mine și tine, nici între păstorii mei și păstorii tăi, căci suntem frați8 Cu sensul de rude.. 9Nu este oare toată țara înaintea ta? Desparte‑te de mine, te rog! Dacă tu o iei la stânga, eu o voi lua la dreapta, iar dacă tu o iei la dreapta, eu o voi lua la stânga.“ 10Lot și‑a ridicat ochii și a văzut că toată Câmpia Iordanului până la Țoar era bine udată în întregime, precum grădina Domnului, precum țara Egiptului. Aceasta s‑a întâmplat înainte ca Domnul să fi distrus Sodoma și Gomora. 11Lot și‑a ales toată Câmpia Iordanului și a pornit spre răsărit. Astfel, ei s‑au despărțit unul de celălalt. 12Avram a locuit în țara Canaan, iar Lot a locuit între cetățile câmpiei și și‑a așezat cortul aproape de Sodoma. 13Oamenii din Sodoma erau răi, foarte păcătoși înaintea Domnului.

14Domnul i‑a zis lui Avram după ce Lot s‑a despărțit de el: „Ridică‑ți ochii acum și, din locul în care ești, privește spre nord și spre sud, spre răsărit și spre apus, 15pentru că toată țara pe care o vezi ți‑o voi da ție și seminței15-16 Vezi nota de la 12:7. tale pentru totdeauna. 16Îți voi face sămânța ca pulberea pământului, astfel încât, dacă cineva poate număra pulberea pământului, și sămânța ta va putea fi numărată. 17Ridică‑te, străbate țara în lung și în lat, pentru că ție ți‑o voi da.“

18Astfel, Avram și‑a mutat cortul și a venit să locuiască lângă stejarii lui Mamre, în Hebron, unde a zidit un altar Domnului.