Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 7:1-24

1Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Noa pé, “Wọ inú ọkọ̀ lọ ìwọ àti gbogbo ìdílé rẹ, nítorí ìwọ nìkan ni mo rí bí olódodo nínú ìran yìí. 2Mú méje méje nínú àwọn ẹran tí ó mọ́, akọ àti abo, mú méjì méjì takọ tabo nínú àwọn ẹran aláìmọ́. 3Sì mú méje méje pẹ̀lú nínú onírúurú ẹyẹ, takọ tabo ni kí o mú wọn, wọlé sínú ọkọ̀ pẹ̀lú rẹ, kí á ba à lè pa wọ́n mọ́ láààyè ní gbogbo ayé. 4Nítorí ní ọjọ́ méje sí ìhín, èmi yóò rọ òjò sórí ilẹ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, èmi yóò sì pa gbogbo ohun alààyè tí mo ti dá run kúrò lórí ilẹ̀.”

5Noa sì ṣe ohun gbogbo tí Ọlọ́run pàṣẹ fún un.

6Noa jẹ́ ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún (600) nígbà tí ìkún omi dé sórí ilẹ̀. 77.7: Mt 24.38; Lk 17.27.Noa àti ìyàwó rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn aya ọmọ rẹ̀ sì wọ inú ọkọ láti sá àsálà fún ìkún omi. 8Méjì méjì ni àwọn ẹran tí ó mọ́ àti aláìmọ́, ti ẹyẹ àti ti gbogbo àwọn ẹ̀dá afàyàfà, 9akọ àti abo ni wọ́n wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa. 10Lẹ́yìn ọjọ́ keje, ìkún omi sì dé sí ayé.

117.11,12: 2Pt 3.6.Ní ọjọ́ kẹtà-dínlógún oṣù kejì, tí Noa pé ọmọ ẹgbẹ̀ta ọdún, ni gbogbo ìsun ibú ya, fèrèsé ìṣàn omi ọ̀run sì ṣí sílẹ̀. 12Òjò àrọ̀ìrọ̀dá sì rọ̀ fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru.

13Ní ọjọ́ tí ìkún omi yóò bẹ̀rẹ̀ gan an ni Noa àti Ṣemu, Hamu àti Jafeti pẹ̀lú aya Noa àti aya àwọn ọmọ rẹ̀ wọ inú ọkọ̀. 14Wọ́n mú ẹranko igbó àti ohun ọ̀sìn ní onírúurú wọn, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ẹyẹ àti àwọn ohun abìyẹ́ ni onírúurú wọn. 15Méjì méjì ni gbogbo ẹ̀dá tí ó ní èémí ìyè nínú wọlé pẹ̀lú Noa sínú ọkọ̀. 16Gbogbo wọ́n wọlé ní takọ tabo bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún Noa, Olúwa sì tì wọn mọ́ inú ọkọ̀.

17Òjò náà sì rọ̀ ní àrọ̀ìrọ̀dá fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ọkọ̀ náà sì ń léfòó lórí omi, kúrò lórí ilẹ̀ bí omi náà ti ń pọ̀ sí i. 18Bí omi náà ti ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ náà ni ọkọ̀ náà sì ń léfòó lójú omi. 19Omi náà pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tí ó bo gbogbo àwọn òkè gíga tí ó wà lábẹ́ ọ̀run. 20Omi náà kún bo àwọn òkè, bí ìwọ̀n ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. 21Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ parun: ẹyẹ, ohun ọ̀sìn, ẹranko igbó, àwọn ẹ̀dá afàyàfà àti ènìyàn. 22Gbogbo ohun tí ó wà lórí ìyàngbẹ ilẹ̀ tó ní èémí ìyè ní ihò imú wọn ni ó kú. 23Gbogbo ohun alààyè tí ó wà lórí ilẹ̀ ayé ni a parẹ́: ènìyàn àti ẹranko, àwọn ohun tí ń rìn nílẹ̀, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run pátápátá ló ṣègbé. Noa àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ọkọ̀ ni ó ṣẹ́kù.

24Omi náà sì bo ilẹ̀ fún àádọ́jọ ọjọ́ (150).

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

創世記 7:1-24

洪水氾濫

1耶和華對挪亞說:「你和你一家都進入方舟,因為這個世代只有你在我眼中是義人。 2潔淨的動物,你要每樣帶七公七母,不潔淨的動物每樣帶一公一母, 3飛鳥每樣帶七公七母,叫牠們以後可以在地上繁衍後代。 4因為七天之後,我要在地上降雨四十晝夜,毀滅我所造的一切生靈。」 5凡耶和華所吩咐的,挪亞都照辦了。

6洪水氾濫的那一年,挪亞正好六百歲。 7挪亞與妻子、兒子們和兒媳們都進了方舟,躲避洪水。 8潔淨的動物、不潔淨的動物、飛禽和地上的一切爬蟲, 9都一公一母成對地到挪亞那裡,進了方舟,正如上帝對挪亞的吩咐。 10那七天過後,洪水在地上氾濫起來。

11挪亞六百歲那年的二月7·11 二月」按猶太曆計算,本卷書所用月份都是按猶太曆計算。十七日,所有深淵的泉源都裂開了,天上的水閘也打開了, 12地上傾盆大雨降了四十晝夜。 13那天,挪亞與他的兒子雅弗,還有挪亞的妻子和三個兒媳婦都進了方舟。 14所有的野獸、牲畜、地上的爬蟲和飛鳥都按種類進入方舟。 15-16這些動物都一公一母成對地到挪亞那裡,進入方舟,正如上帝對挪亞的吩咐。耶和華關上了方舟的門。

17洪水在地上氾濫了四十天,水不斷地往上漲,把方舟漂了起來。 18洪水來勢洶洶,淹沒大地,方舟漂浮在水面上。 19水勢越來越大,把天下各處的高山都淹沒了。 20水淹沒了群山,水面高出群山七米。 21世上所有的飛禽、走獸、牲畜、爬蟲和人類都死了。 22在陸地上所有用鼻孔呼吸的生靈都死了。 23地上的人類、飛禽走獸和爬蟲等一切生靈都被毀滅了,只剩下挪亞和跟他同在方舟裡的生靈。 24洪水淹沒大地一百五十天。