Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 41:1-57

Àwọn àlá Farao

1Nígbà tí odindi ọdún méjì sì ti kọjá, Farao lá àlá: ó rí ara rẹ̀ tó dúró ní etí odò Naili. 2Nígbà náà ni màlúù méje jáde láti inú odò, wọ́n dára láti wò, wọ́n sì sanra, wọ́n sì ń jẹ koríko. 3Lẹ́yìn àwọn wọ̀nyí, ni àwọn màlúù méje mìíràn tí kò lẹ́wà tí ó sì rù jáde wá láti inú odò Naili, wọ́n sì dúró ti àwọn méje tí ó sanra tí ó wà ní bèbè odò náà. 4Àwọn màlúù tí ó rù, tí kò sì lẹ́wà sì gbé àwọn tí ó lẹ́wà tí ó sanra jẹ. Nígbà náà ni Farao jí.

5Ó sì tún padà sùn, ó sì lá àlá mìíràn: ó rí síírí ọkà méje tí ó kún, ó yómọ, ó sì dára, ó sì jáde lára igi ọkà kan ṣoṣo. 6Lẹ́yìn wọn ni síírí ọkà méje mìíràn yọ, wọn kò yómọ, afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù. 7Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ (ọmọ rẹ̀ kò tóbi) wọ̀nyí sì gbé àwọn tí ó yómọ (ọmọ rẹ̀ tóbi) mì. Nígbà náà ni Farao jí lójú oorun, ó sì rí i pé àlá ni.

841.8: Da 2.2.Ní òwúrọ̀, ọkàn rẹ̀ dàrú, nítorí náà, ó ránṣẹ́ pe gbogbo àwọn onídán àti ọ̀mọ̀ran ilẹ̀ Ejibiti. Farao rọ́ àlá rẹ̀ fún wọn, ṣùgbọ́n kò rí ọ̀kan nínú wọn tí ó le sọ ìtumọ̀ àlá náà fún un.

9Nígbà náà ni olórí agbọ́tí wí fún Farao pé, “Lónìí ni mo rántí ẹ̀ṣẹ̀ mi. 10Nígbà kan tí Farao bínú sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, tí ó sì fi èmi àti olórí alásè sínú ẹ̀wọ̀n ní ilé olórí ẹ̀ṣọ́. 11Ọ̀kọ̀ọ̀kan wa lá àlá, àlá kọ̀ọ̀kan sì ní ìtumọ̀ tirẹ̀. 12Ọmọkùnrin ará Heberu kan tí ó jẹ́ ìránṣẹ́ olórí ẹ̀ṣọ́ wà níbẹ̀ pẹ̀lú wa. A rọ́ àwọn àlá wa fún un, ó sì túmọ̀ wọn fún wa, ó sọ ìtumọ̀ àlá ẹnìkọ̀ọ̀kan fún un. 13Bí ó sì ti túmọ̀ àlá wọ̀nyí náà ni ohun gbogbo rí. A dá mi padà sí ipò mi, a sì so ọkùnrin kejì kọ́ sórí ọ̀wọ̀n.”

14Nítorí náà Farao ránṣẹ́ pe Josẹfu, wọn sì mú un wá kíákíá láti inú ìhámọ́. Nígbà tí ó fá irun rẹ̀, tí ó sì pààrọ̀ aṣọ rẹ̀, ó wá síwájú Farao.

15Farao wí fún Josẹfu, “Mo lá àlá kan, kò sì sí ẹni tí o le è túmọ̀ rẹ̀. Ṣùgbọ́n mo ti gbọ́ nípa rẹ pé bí o bá ti gbọ́ àlá, o le è túmọ̀ rẹ̀.”

16Josẹfu dá Farao ní ohùn pé, “Kì í ṣe agbára mi, ṣùgbọ́n, Ọlọ́run ni yóò fi ìdáhùn àlàáfíà fún Farao ní ìtumọ̀ àlá náà.”

17Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Ní inú àlá mi, mo dúró ni etí bèbè odò Naili, 18sì kíyèsi i, màlúù méje tí ó sanra tí o sì lẹ́wà jáde wá, wọ́n sì ń jẹ koríko ní tòsí ibẹ̀. 19Lẹ́yìn wọn, màlúù méje mìíràn jáde wá, wọ́n rù hángógó, wọn kò sì lẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ tí n kò tí ì rí irú màlúù tí ó ṣe àìlẹ́wà tó bẹ́ẹ̀ rí ní ilẹ̀ Ejibiti. 20Àwọn màlúù tí ó rù tí kò sì lẹ́wà sì jẹ àwọn màlúù tí ó sanra tí ó kọ́ jáde nínú odò. 21Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jẹ́ wọ́n tan, kò sì ẹni tí ó le mọ̀ pé wọ́n jẹ ohunkóhun, nítorí wọn kò sanra sí i, wọn sì bùrẹ́wà síbẹ̀. Nígbà náà ni mo tají.

22“Ní ojú àlá mi, mo tún rí síírí ọkà méje tí ó yó ọmọ tí ó sì dára, wọ́n jáde láti ara igi ọkà kan. 23Lẹ́yìn wọn, àwọn méje mìíràn yọ jáde, tí kò yó ọmọ bẹ́ẹ̀ ni afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ ẹ́ dànù tán. 24Àwọn síírí ọkà méje tí kò yómọ sì gbé àwọn méje tí ó dára wọ̀nyí mì. Mo sọ àlá yìí fún àwọn onídán mi, ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí ó le túmọ̀ rẹ̀ fún mi.”

25Nígbà náà ni Josẹfu wí fún Farao, “Ìtumọ̀ kan náà ni àwọn àlá méjèèjì ní. Ọlọ́run fi ohun tí ó fẹ́ ṣe hàn fún Farao. 26Àwọn màlúù méje ti ó dára jẹ́ ọdún méje, síírí ọkà méje tí ó dára náà sì jẹ́ ọdún méje: ọ̀kan ṣoṣo ni wọn, àlá kan náà ni. 27Àwọn màlúù méje tí kò sanra, tí kò sì rẹwà tí ó jáde gbẹ̀yìn jẹ́ ọdún méje, bẹ́ẹ̀ náà ni síírí ọkà méje tí kò dára, tí afẹ́fẹ́ ìlà-oòrùn ti rẹ̀ dànù tan: Wọn jẹ́ ọdún méje tí ìyàn yóò fi mú.

28“Bí mo ti wí fún Farao ní ìṣáájú náà ni: Ọlọ́run fi ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ han Farao. 29Ọdún méje tí oúnjẹ yóò pọ̀ yanturu ń bọ̀ wà ní Ejibiti. 30Ṣùgbọ́n ọdún méje mìíràn tí ìyàn yóò mú ń bọ̀, nígbà náà ni a ó tilẹ̀ gbàgbé gbogbo ọ̀pọ̀ ní ilẹ̀ Ejibiti, ìyàn yóò sì run gbogbo ilẹ̀ náà, 31A kò ní rántí àsìkò ọ̀pọ̀ oúnjẹ yanturu náà mọ́ nítorí pé ìyàn tí yóò tẹ̀lé e yóò pọ̀ púpọ̀. 32Ìdí tí Ọlọ́run fi fi àlá náà han fún Farao ní ọ̀nà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni pé, Ọlọ́run ti pinnu pé yóò ṣẹlẹ̀ bẹ́ẹ̀ dandan, àti pé kò ni pẹ́ tí Ọlọ́run yóò fi ṣe é.

33“Ìmọ̀ràn mi ni wí pé, jẹ́ kí Farao wá ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ó sì fi ṣe alákòóso iṣẹ́ àgbẹ̀ ilẹ̀ Ejibiti. 34Kí Farao sì yan àwọn alábojútó láti máa gba ìdámárùn-ún ìkórè oko ilẹ̀ Ejibiti ní àsìkò ọdún méje ọ̀pọ̀. 35Kí wọn kó gbogbo oúnjẹ ilẹ̀ náà ni àwọn ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, kí wọn sì kó àwọn ọkà tí wọn jẹ ṣẹ́kù pamọ́ lábẹ́ àṣẹ Farao. Kí a kó wọn pamọ́ ni àwọn ìlú fún jíjẹ. 36Kí wọn kó oúnjẹ náà pamọ́ fún orílẹ̀-èdè yìí, kí a ba à le lò ó ni ọdún méje tí ìyàn yóò fi jà ní ilẹ̀ Ejibiti, kí ìyàn náà má ba à pa orílẹ̀-èdè yìí run.”

37Èrò náà sì dára lójú Farao àti àwọn ìjòyè rẹ̀. 38Farao sì bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ a le rí ẹnikẹ́ni bi ọkùnrin yìí, nínú ẹni tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń gbé?”

39Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu, “Níwọ́n bí Ọlọ́run ti fi gbogbo èyí hàn ọ́, kò sí ẹni náà tí ó gbọ́n tí ó sì mọ̀ràn bí i tìrẹ ní ilẹ̀ Ejibiti yìí, 40ìwọ yóò ṣe àkóso ààfin mi gbogbo àwọn ènìyàn gbọdọ̀ tẹríba fún àṣẹ ẹ̀ rẹ. Ìtẹ́ mi nìkan ni èmi yóò fi jù ọ́ lọ.”

Josẹfu di alábojútó ilẹ̀ Ejibiti

41Farao wí fún Josẹfu pé, “Mo fi ọ́ ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.” 4241.42: Da 5.29.Farao sì bọ́ òrùka èdìdì ọwọ́ rẹ̀, ó sì fi wọ Josẹfu ó wọ̀ ọ́ ní aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára, ó sì fi ẹ̀gbà tí ó dára sí i lọ́rùn. 43Ó sì mú un kí ó gun kẹ̀kẹ́-ẹṣin bí igbákejì ara rẹ̀, àwọn ènìyàn sì ń pariwo níwájú rẹ̀ pé, “Ẹ yàgò lọ́nà.” Báyìí ni ó sì fi ṣe alábojútó gbogbo ilẹ̀ Ejibiti.

44Nígbà náà ni Farao wí fún Josẹfu pé, “Èmi ni Farao. Ṣùgbọ́n láìsí àṣẹ rẹ, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun ní ilẹ̀ Ejibiti.” 45Farao sì sọ Josẹfu ní orúkọ yìí: Safenati-Panea èyí tí ó túmọ̀ sí, (ẹni tí ó ni agbára ikú àti ìyè ní ìkáwọ́ bí òrìṣà), Ó sì fun un ní Asenati ọmọ Potifẹra, alábojútó òrìṣà Oni, gẹ́gẹ́ bí aya. Josẹfu sì rin gbogbo ilẹ̀ Ejibiti já.

46Ọmọ ọgbọ̀n ọdún (30) ni Josẹfu nígbà tí ó wọ iṣẹ́ Farao ọba Ejibiti. Josẹfu sì jáde kúrò níwájú Farao, ó sì ṣe ìbẹ̀wò káàkiri gbogbo ilẹ̀ Ejibiti 47Ní ọdún méje ọ̀pọ̀, ilẹ̀ náà so èso lọ́pọ̀lọpọ̀. 48Josẹfu kó gbogbo oúnjẹ tí a pèsè ni ilẹ̀ Ejibiti ní ọdún méje ọ̀pọ̀ yìí, ó sì pa wọ́n mọ́ sí àwọn ìlú. Ní ìlú kọ̀ọ̀kan ni ó kó gbogbo oúnjẹ tí wọ́n gbìn ní àyíká ìlú wọn sí. 49Josẹfu pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkà mọ́ bí iyanrìn Òkun; ó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí kò ṣe àkọsílẹ̀ mọ́ nítorí, ó tayọ kíkà.

50Kí ó tó di pé ọdún ìyàn dé, Asenati ọmọ Potifẹra alábojútó Oni bí ọmọkùnrin méjì fún Josẹfu. 51Josẹfu sọ orúkọ àkọ́bí rẹ̀ ni Manase, ó sì wí pé, “Nítorí tí Ọlọ́run ti mú mi gbàgbé gbogbo ìdààmú mi àti gbogbo ilé baba mi.” 52Ó sì sọ orúkọ èkejì ní Efraimu, ó sì wí pé, “Nítorí pé Ọlọ́run fún mi ní ọmọ ní ilẹ̀ ìpọ́njú mi.”

53Ọdún méje ọ̀pọ̀ oúnjẹ sì wá sí òpin ní ilẹ̀ Ejibiti, 5441.54: Ap 7.11.Ọdún méje ìyàn sì bẹ̀rẹ̀, bí Josẹfu ti wí gan an. Ìyàn sì mú ní gbogbo ilẹ̀ tókù, ṣùgbọ́n oúnjẹ wà ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. 5541.55: Jh 2.5.Nígbà tí àwọn ará Ejibiti bẹ̀rẹ̀ sí ní rí ipá ìyàn náà, wọ́n kígbe sí Farao. Nígbà náà ni Farao wí fún wọn pé, “Ẹ lọ bá Josẹfu, ẹ ṣe ohun tí ó bá wí fún un yín.”

56Nígbà tí ìyàn sì ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ náà, Josẹfu ṣí inú àká, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ta ọkà fún àwọn ènìyàn, nítorí ìyàn náà mú gan an ní gbogbo ilẹ̀ Ejibiti. 57Gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè sì ń wá sí Ejibiti láti ra oúnjẹ lọ́wọ́ Josẹfu, nítorí ìyàn náà pọ̀ gidigidi káàkiri gbogbo ayé.

Swedish Contemporary Bible

1 Moseboken 41:1-57

Faraos dröm

1En natt två år senare drömde farao att han stod på Nilens strand, 2när sju välmående, feta kor kom upp ur floden och började beta i vassen. 3Efter dem kom sju andra kor upp ur floden, fula och magra. De gick fram och ställde sig på stranden bredvid de feta korna. 4Sedan åt de magra korna upp de sju välmående och feta. Då vaknade farao.

5Snart somnade han om igen och hade ännu en dröm. Han såg sju sädesax på samma strå, välformade och fylliga. 6Sedan visade sig ytterligare sju ax komma fram, men dessa var tunna och svedda av den östliga vinden. 7De tunna axen svalde de fylliga, välformade axen. Då vaknade farao igen och förstod att det var en dröm.

8Följande morgon var han mycket orolig. Han kallade på alla trollkarlar och vise män i Egypten och berättade drömmarna för dem men ingen kunde uttyda dem för farao. 9Då yttrade sig kungens vinsmakare:

”Idag måste jag påminna om mina brott. 10För en tid sedan då farao var arg på oss tjänare satte farao mig och mästerbagaren i fängelse hos befälhavaren för livgardet. 11En natt fick bagaren och jag var sin dröm och varje dröm hade sin särskilda betydelse. 12Vi berättade drömmarna för en ung hebré som var där med oss och var slav hos befälhavaren för livgardet och han berättade för oss vad drömmarna betydde.

13Allt inträffade precis som han hade sagt: jag återupprättades och fick tillbaka min ställning och den andre blev hängd.”

14Farao lät genast skicka efter Josef. Han fördes omedelbart från fängelsehålan och efter att ha rakat sig och bytt kläder, kom han inför farao.

15”Jag hade en dröm i natt”, berättade farao för honom. ”Ingen kan berätta för mig vad den betyder. Men jag har hört att du kan tolka drömmar du får höra.” 16”Inte jag själv”, svarade Josef. ”Men Gud kan ge farao det önskade svaret.”

17Då berättade farao drömmen för honom: ”Jag stod på Nilflodens strand, 18när sju feta, välmående kor kom upp ur floden och började beta i vassen. 19Men sedan kom sju andra kor upp ur floden, eländiga, mycket magra och fula, ja, så eländiga djur har jag aldrig sett i hela Egyptens land. 20Dessa magra kor åt upp de sju feta, som hade kommit först, 21men efteråt kunde man inte se att de gjort det, för de var lika magra som förut. Sedan vaknade jag.

22Därefter hade jag ännu en dröm och såg sju ax på ett strå, fylliga och vackra. 23Efter dem växte det fram sju torra ax, tunna och förtorkade i östanvinden, 24och de tunna axen svalde de sju fylliga. Jag berättade allt detta för mina trollkarlar men ingen av dem kunde säga vad det betydde.”

25”Båda drömmarna betyder samma sak”, sa Josef till farao. ”Gud har talat om för farao vad han tänker göra. 26De sju feta korna och de sju fylliga, välformade axen betyder sju år. Båda drömmarna har samma betydelse. 27De sju magra korna som kom upp efter dem, likaså de sju tunna och av östanvinden förtorkade axen, betyder att det kommer att bli sju års hungersnöd.

28Gud har precis som jag sa till farao visat farao vad han tänker göra. 29De kommande sju åren ska bli en period av stort välstånd i hela Egyptens land. 30Men efteråt kommer det att bli sju år av svält. Svälten blir så svår att man kommer att glömma bort välståndet som rådde i Egypten. Svälten kommer att ödelägga landet. 31Till och med minnet av de goda åren kommer att utplånas helt eftersom hungersnöden blir så fruktansvärd. 32Att farao fick två drömmar betyder att Gud har bestämt det och det kommer att ske snart.

33Farao bör nu söka reda på en förståndig och vis man och sätta honom över Egyptens land. 34Farao bör också utse tillsyningsmän över landet för att samla in en femtedel av all säd under de kommande sju välfärdsåren. 35Låt dem samla in livsmedel under de kommande goda åren och lagra och förvara spannmål i städerna under faraos tillsyn. 36Då kommer det att finnas tillräckligt att äta i Egyptens land när de sju årens svält kommer, så att landet inte går under genom hungersnöden.”

Josef härskar i Egypten

37Josefs förslag togs väl emot av farao och hans tjänare.

38Farao sa då till sina tjänare: ”Finns det någon som har Guds Ande41:38 Eller gudars ande – en möjlig översättning inte minst med tanke på att faraos religiösa föreställningar troligen var polyteistiska. Men han kan också ha syftat på Josefs Gud. såsom denne man?” 39Farao sa sedan till Josef: ”Eftersom Gud har uppenbarat allt detta för dig, finns det ingen som är förståndigare och visare än du. 40Därför utser jag dig som ansvarig för hela mitt hov och hela mitt folk ska rätta sig efter dig. Bara tronen ska vara förbehållen mig.”

41Farao sa till Josef: ”Jag ger dig ansvaret för hela Egypten.” 42Sedan tog farao av sig sin egen sigillring och satte den på Josefs finger, klädde honom i fina linnekläder och satte en guldkedja runt halsen på honom.

43Han lät också Josef åka i vagnen närmast hans egen41:43 Eller den näst förnämsta vagnen., och framför Josef ropade man ”Böj knä!”41:43 Grundtextens ord avrek kan möjligen också betyda lämna plats. Dess betydelse är inte säker. Farao satte honom så över hela Egypten. 44Farao sa till Josef: ”Jag är visserligen farao, men ingen ska lyfta vare sig hand eller fot i hela Egypten om inte du har befallt det.”

45Farao gav Josef namnet Safenat Paneach41:45 Den exakta betydelsen av namnet är osäker. Det kan möjligen betyda Gud talar och lever.. Han gav honom också Asenat till hustru, en dotter till Poti Fera, prästen41:45 Poti Fera, Josefs svärfar, var möjligen präst åt solguden Ra. i On41:45 Heliopolis.. Josef reste sedan omkring i Egypten.

46Josef var trettio år gammal när han började sin tjänst hos farao. Han började då resa genom hela landet.

47Under de följande sju välfärdsåren blev det rika skördar överallt. 48Under dessa sju år av överflöd samlade Josef in en del av skörden i Egypten och lagrade den i städerna. I varje stad samlades jordbruksprodukter från omgivningen. 49Josef samlade in så mycket säd att den var som sanden i havet. Man kunde till slut inte hålla räkning på den eftersom det var omöjligt.

50Innan det första svältåret började fick Josef två söner med Asenat, dotter till Poti Fera, prästen i On. 51Josef kallade sin äldste son Manasse41:51 Manasse låter som ”fått mig att glömma” på hebreiska., för han sa: ”Gud har fått mig att glömma allt mitt elände och förlusten av min familj.” 52Den andre sonen kallade han Efraim41:52 Efraim låter som två gånger fruktsam på hebreiska., för han sa: ”Gud har gjort mig fruktsam i mina lidandens land.”

53Slutligen hade de sju goda åren gått. 54Då började sju års svält, precis som Josef hade förutsagt. Det blev svält även i grannländerna, men i Egypten fanns det tillräckligt med bröd överallt.

55När folket i Egypten började känna av svälten bad de farao om mat och han skickade dem till Josef. ”Lyd honom vad han än säger”, sa han till dem.

56När hungersnöden gick fram över hela landet, öppnade Josef sädesförråden och sålde säd till egypterna eftersom hungersnöden var så svår i Egypten. 57Från hela världen kom man till Egypten för att köpa säd av Josef, för hungersnöden var svår överallt.