Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 3:1-24

Ìṣubú ènìyàn

13.1: If 12.9; 20.2.Ejò sá à ṣe alárékérekè ju àwọn ẹranko igbó yòókù tí Olúwa Ọlọ́run dá lọ. Ó sọ fún obìnrin náà pé, “Ǹjẹ́ òtítọ́ ha ni Ọlọ́run wí pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ èso èyíkéyìí lára àwọn igi tí ó wà nínú ọgbà’?”

2Obìnrin náà dá ejò lóhùn pé, “Àwa lè jẹ lára àwọn èso igi tí ó wà nínú ọgbà, 3ṣùgbọ́n Ọlọ́run sọ pé, ‘Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ jẹ lára èso igi tí ó wà láàrín ọgbà, ẹ kò sì gbọdọ̀ fi ọwọ́ kàn án, bí ẹ̀yin bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin yóò kùú.’ ”

43.4: 2Kọ 11.3.Ejò wí fún obìnrin náà pé, “Ẹ̀yin kì yóò kú ikúkíkú kan.” 5“Nítorí Ọlọ́run mọ̀ wí pé, bí ẹ̀yin bá jẹ nínú rẹ̀, ojú yín yóò là, ẹ̀yin yóò sì dàbí Ọlọ́run, ẹ̀yin yóò sì mọ rere yàtọ̀ sí búburú.”

6Nígbà tí obìnrin náà rí i wí pé èso igi náà dára fún oúnjẹ àti pé, ó sì dùn ún wò, àti pé ó ń mú ni ní ọgbọ́n, ó mú díẹ̀ níbẹ̀, ó sì jẹ ẹ́. Ó sì mú díẹ̀ fún ọkọ rẹ̀, ẹni tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, òun náà sì jẹ ẹ́. 7Nígbà náà ni ojú àwọn méjèèjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn wà ní ìhòhò; wọ́n sì rán ewé ọ̀pọ̀tọ́ pọ̀, wọ́n sì fi bo ara wọn.

8Nígbà náà ni ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ gbọ́ ìró Olúwa Ọlọ́run bí ó ti ń rìn nínú ọgbà, nígbà tí ojú ọjọ́ tura, wọ́n sì fi ara pamọ́ kúrò níwájú Olúwa Ọlọ́run sí àárín àwọn igi inú ọgbà. 9Ṣùgbọ́n Olúwa Ọlọ́run ké pe ọkùnrin náà pé, “Níbo ni ìwọ wà?”

10Ó dáhùn pé, “Mo gbúròó rẹ̀ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí, nítorí pé, mo wà ní ìhòhò, mo sì fi ara pamọ́.”

11Ọlọ́run wí pé, “Ta ni ó wí fún ọ pé ìhòhò ni ìwọ wà? Ṣé ìwọ ti jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀ ni?”

12Ọkùnrin náà wí pé, “Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, ni ó fún mi nínú èso igi náà, mo sì jẹ ẹ́.”

133.13: 2Kọ 11.3; 1Tm 2.14.Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Èwo ni èyí tí ìwọ ṣe yìí?”

Obìnrin náà dáhùn pé, “Ejò ni ó tàn mí jẹ, mo sì jẹ ẹ́.”

143.14,15: If 12.9; 20.2.Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run wí fún ejò náà pé, “Nítorí tí ìwọ ti ṣe èyí,

“Ègún ni fún ọ ju gbogbo ohun ọ̀sìn

àti gbogbo ẹranko igbó tókù lọ!

Àyà rẹ ni ìwọ yóò fi máa wọ́,

ìwọ yóò sì máa jẹ erùpẹ̀ ilẹ̀

ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

153.15: If 12.17.Èmi yóò sì fi ọ̀tá

sí àárín ìwọ àti obìnrin náà,

àti sí àárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ obìnrin náà;

òun yóò fọ́ orí rẹ,

ìwọ yóò sì bù ú jẹ ní gìgísẹ̀.”

16Ọlọ́run wí fún obìnrin náà pé:

“Èmi yóò fi kún ìrora rẹ ní àkókò ìbímọ;

ni ìrora ni ìwọ yóò máa bí ọmọ.

Ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yóò máa fà sí,

òun ni yóò sì máa ṣe àkóso rẹ.”

173.17,18: Hb 6.8.Ọlọ́run sì wí fún Adamu pé, “Nítorí pé ìwọ fetí sí aya rẹ, ìwọ sì jẹ nínú èso igi tí mo pàṣẹ fún ọ pé ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀,’

“Ègún ni fún ilẹ̀ nítorí rẹ;

nínú ọ̀pọ̀ làálàá ni ìwọ yóò jẹ nínú rẹ̀,

ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ.

18Ilẹ̀ yóò sì hu ẹ̀gún àti èṣùṣú fún ọ,

ewéko igbó ni ìwọ yóò sì máa jẹ.

19Nínú òógùn ojú rẹ

ni ìwọ yóò máa jẹun

títí tí ìwọ yóò fi padà sí ilẹ̀,

nítorí inú ilẹ̀ ni a ti mú ọ jáde wá;

erùpẹ̀ ilẹ̀ sá à ni ìwọ,

ìwọ yóò sì padà di erùpẹ̀.”

20Adamu sì sọ aya rẹ̀ ní Efa nítorí òun ni yóò di ìyá gbogbo alààyè.

21Olúwa Ọlọ́run, sì dá ẹ̀wù awọ fún Adamu àti aya rẹ̀, ó sì fi wọ̀ wọ́n. 223.22,24: If 2.7; 22.2,14,19.Olúwa Ọlọ́run sì wí pé, “Ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan lára wa, ó mọ rere àti búburú. A kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ó na ọwọ́ rẹ̀ kí ó mú lára èso igi ìyè kí ó sì jẹ, kí ó sì wà láààyè títí láéláé.” 23Nítorí náà, Olúwa Ọlọ́run lé e kúrò nínú ọgbà Edeni láti lọ máa ro ilẹ̀ nínú èyí tí a ti mú un jáde wá. 24Lẹ́yìn tí ó ti lé ènìyàn jáde tán, ó fi àwọn Kérúbù àti idà iná tí ó ń kọ mọ̀nàmọ́ná síwájú àti sẹ́yìn láti ṣọ́ ọ̀nà tí ó lọ sí ibi igi ìyè, ní ìhà ìlà-oòrùn ọgbà Edeni.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

创世记 3:1-24

始祖犯罪

1在耶和华上帝所造的田野的各种动物中,蛇最狡猾。蛇对女人说:“上帝真的说过不许你们吃园中所有树上的果子吗?” 2女人回答说:“我们可以吃园中树上的果子, 3只是不可以吃园子中间那棵树的果子。上帝曾经吩咐说,‘你们不可吃那果子,也不可摸,否则你们就会死。’” 4蛇对女人说:“你们一定不会死! 5上帝那样说是因为祂知道你们吃了那树的果子以后,眼睛就会明亮,像上帝一样懂得分辨善恶。” 6女人见那棵树上的果子可口,赏心悦目,可以使人有智慧,就摘下来吃了。她也把果子给跟她在一起的丈夫,他也吃了。 7二人的眼睛果然明亮起来,这才发觉自己原来赤身露体,便把无花果树的叶子编起来遮体。

8傍晚天凉时,夫妇二人听见耶和华上帝在园中行走的声音,就藏在园子的树丛中,想躲开耶和华上帝。 9耶和华上帝呼唤那人说:“你在哪里?” 10那人说:“我听见你在园中行走的声音,就害怕得躲了起来,因为我赤身露体!” 11耶和华上帝问:“谁说你赤身露体?难道你吃了我吩咐你不可吃的果子吗?” 12那人说:“你赐给我作伴的女人摘了那树上的果子给我,我就吃了。” 13耶和华上帝对女人说:“你这做的是什么事?”女人说:“是蛇诱骗我,我才吃的。”

上帝的审判

14耶和华上帝对蛇说:

“你既然做了这事,

你要比一切的牲畜和野兽受更重的咒诅,

你要用肚子爬行,

一生都要吃尘土。

15我要使你和女人结仇,

你的后代和女人的后代也要彼此为仇,

女人的后代必伤你的头,

你必伤他的脚跟。”

16耶和华上帝对女人说:

“我必大大加重你怀孕的痛苦,

你分娩时必受痛苦。

你必恋慕3:16 恋慕”或译“想控制”。自己的丈夫,

你的丈夫必管辖你。”

17耶和华上帝又对亚当说:

“因为你听从妻子的话,

吃了我吩咐你不可吃的果子,

地必因你而受咒诅。

你必终生艰辛劳苦,

才能吃到地里出产的食物。

18地必给你长出荆棘和蒺藜,

你要吃田间长出来的菜蔬。

19你必汗流满面,才有饭吃,

一直到你归回尘土。

因为你是尘土造的,

也必归回尘土。”

20亚当给他的妻子取名叫夏娃,因为她是众生之母。 21耶和华上帝做了皮衣给他们夫妇穿。 22耶和华上帝说:“看啊,那人已经与我们相似,能分辨善恶。现在,恐怕他会伸手去摘生命树的果子吃,那样他就会永远活着。” 23因此,耶和华上帝就把亚当赶出伊甸园,让他去开垦土地——他的本源。 24上帝赶走了亚当以后,就派遣基路伯天使驻守在伊甸园东边,又用一把旋转的火剑守护在通往生命树的路上。