Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Gẹnẹsisi 22:1-24

Ọlọ́run dán Abrahamu wò

122.1-18: Hb 11.17-19.Nígbà tí ó ṣe, Ọlọ́run dán Abrahamu wò, ó pè é, ó sì wí pé, “Abrahamu.”

Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

222.2: 2Ki 3.1.Ọlọ́run sì wí pé, “Mú ọmọ rẹ, àní Isaaki ọmọ rẹ kan ṣoṣo nì, tí ìwọ fẹ́ràn, lọ sí ilẹ̀ Moriah, kí o sì fi rú ẹbọ sísun níbẹ̀ lórí ọ̀kan nínú àwọn òkè tí èmi yóò sọ fún ọ.”

3Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ ní gàárì, ó sì mú méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ àti Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì ṣẹ́ igi fún ẹbọ sísun, ó sì gbéra lọ sí ibi tí Ọlọ́run ti sọ fún un. 4Nígbà tí ó di ọjọ́ kẹta, Abrahamu gbé ojú sókè, ó sì rí ibi tí ó ń lọ ní òkèrè, 5Abrahamu sì wí fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Ẹ̀yin, ẹ dúró níhìn-ín pẹ̀lú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, èmi àti ọmọ yìí yóò lọ sí ohunkóhun láti sin Ọlọ́run, a ó sì tún padà wá bá a yín.”

6Abrahamu sì gbé igi ẹbọ sísun náà ru Isaaki, òun fúnrarẹ̀ sì mú iná àti ọ̀bẹ. Bí àwọn méjèèjì ti ń lọ, 7Isaaki sì sọ fún Abrahamu baba rẹ̀ wí pé, “Baba mi.”

Abrahamu sì dalóhùn pé, “Èmi nìyí ọmọ mi.”

Isaaki sì tún wí pé, “Wò ó iná àti igi nìyí, ṣùgbọ́n níbo ni ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà wà?”

8Abrahamu sì dáhùn pé, “Ọmọ mi, Ọlọ́run fúnrarẹ̀ ni yóò pèsè ọ̀dọ́-àgùntàn fún ẹbọ sísun náà.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì jùmọ̀ ń lọ.

922.9,10,12: Jk 2.21.Nígbà tí wọn sì dé ibi tí Ọlọ́run sọ fún Abrahamu, ó mọ pẹpẹ kan, ó sì to igi lé e lórí, ó sì di Isaaki ọmọ rẹ̀, ó sì da dùbúlẹ̀ lórí pẹpẹ náà. 10Abrahamu sì nawọ́ mú ọ̀bẹ, láti dúńbú ọmọ rẹ̀. 11Ṣùgbọ́n angẹli Olúwa ké sí i láti ọ̀run wá wí pé “Abrahamu! Abrahamu!”

Abrahamu sì dáhùn pé, “Èmi nìyí.”

12Angẹli Olúwa sì wí pé, “Má ṣe fọwọ́ kan ọmọ náà, ìwọ kò sì gbọdọ̀ ṣe é ni ohun kan. Nísinsin yìí ni mo mọ̀ pé o bẹ̀rù Ọlọ́run, nítorí pé ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí.”

13Abrahamu sì gbójú sókè, ó sì rí àgbò kan tí ó fi ìwo há pàǹtírí, ó sì lọ mú un, ó sì fi rú ẹbọ sísun dípò ọmọ rẹ̀. 14Abrahamu sì pe orúkọ ibẹ̀ ni, Olúwa yóò pèsè (Jehofah Jire). Bẹ́ẹ̀ ni a sì ń wí títí di òní olónìí pé, “Ní orí òkè Olúwa, ni a ó ti pèsè.”

15Angẹli Olúwa sì tún pe Abrahamu láti ọ̀run wá lẹ́ẹ̀kejì. 1622.16,17: Lk 1.73; Hb 6.13,14; 11.12.Ó sì wí pé, Olúwa wí pé, “Mo fi ara mi búra, níwọ̀n bí ìwọ ti ṣe èyí, tí ìwọ kò fi ọmọ rẹ, àní, ọmọ rẹ kan ṣoṣo dù mí, 1722.17: Hb 11.12.Nítòótọ́, ní bíbùkún èmi ó bùkún fún ọ, àti ní bíbísí èmi ó sì mú ọ bí sí i bí i ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti bí iyanrìn etí Òkun. Irú-ọmọ rẹ yóò sì gba ẹnu ibodè àwọn ọ̀tá wọn, 1822.18: Ap 3.25; Ga 3.16.àti nípasẹ̀ irú-ọmọ rẹ ni a ó ti bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè ayé nítorí tí ìwọ gbọ́rọ̀ sí mi lẹ́nu.”

19Nígbà náà ni Abrahamu padà tọ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ. Gbogbo wọn sì padà lọ sí Beerṣeba. Abrahamu sì jókòó ní Beerṣeba.

Àwọn ọmọ Nahori

20Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí ni a wí fún Abrahamu pé, “Milka aya Nahori bí àwọn ọmọkùnrin fún un.

21Usi, àkọ́bí rẹ̀, Busi arákùnrin rẹ̀,

Kemueli (Baba Aramu).

22Kesedi, Haso, Pildasi, Jidlafi, àti Betueli.”

23Betueli sì ni baba Rebeka.

Milka sì bí àwọn ọmọ mẹ́jọ wọ̀nyí fún Nahori arákùnrin Abrahamu.

24Àlè rẹ̀ tí ń jẹ́ Reuma náà bí àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí fun un:

Teba, Gahamu, Tahasi àti Maaka.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

創世記 22:1-24

上帝考驗亞伯拉罕

1這些事以後,上帝要考驗亞伯拉罕,就呼喚他:「亞伯拉罕!」他回答說:「我在這裡。」 2上帝說:「帶著你的兒子,你的獨生子,你疼愛的以撒前往摩利亞,在我指示你的山上把他獻為燔祭。」 3亞伯拉罕清早起來,準備好驢,劈好獻燔祭用的柴,帶著兩個僕人和兒子以撒動身前往上帝指示他的地方。 4到了第三天,亞伯拉罕遠遠看見那地方, 5就對僕人說:「你們和驢在這裡等著,我和孩子到那邊敬拜上帝,然後便回來。」

6於是,亞伯拉罕把獻燔祭用的柴放在兒子以撒肩上,自己手裡拿著火種和刀。父子二人一同向前走。 7以撒說:「父親。」亞伯拉罕說:「孩子,什麼事?」以撒說:「你看,火種和柴都有了,但獻燔祭用的羊羔在哪裡呢?」 8亞伯拉罕說:「孩子,上帝自己會預備獻燔祭的羊羔。」二人就繼續向前走。

9他們到了上帝指示的地方,亞伯拉罕就築起祭壇,把柴擺在上面,然後把以撒捆起來放在柴上。 10亞伯拉罕伸手拿起刀來,要殺他的兒子。 11耶和華的天使從天上呼喚他說:「亞伯拉罕亞伯拉罕!」他回答說:「我在這裡。」 12天使說:「不要動孩子,不可傷害他!現在我知道你敬畏上帝,因為你不惜獻上你的兒子——你的獨生子。」 13這時亞伯拉罕抬起頭來,突然看見有一隻公綿羊兩角卡在稠密的樹叢中,於是把羊取來代替他的兒子獻為燔祭。 14亞伯拉罕稱那地方為「耶和華以勒22·14 耶和華以勒」或譯「耶和華必預備」。。直到今天人們還說:「在耶和華的山上必有預備。」

15耶和華的天使再次從天上呼喚亞伯拉罕16對他說:「耶和華說,『你既然願意把你的兒子,你的獨生子獻給我,我憑自己向你起誓, 17我必賜福給你,使你的後裔多如天上的星和海邊的沙。你的後裔必佔領仇敵的城池, 18天下萬國必因你的後裔而蒙福,因為你聽從了我的話。』」 19於是,亞伯拉罕回到僕人等候的地方,他們一同返回亞伯拉罕居住的別示巴

拿鶴的後代

20後來,有人告訴亞伯拉罕:「密迦為你的兄弟拿鶴生了幾個兒子, 21長子烏斯烏斯的弟弟布斯亞蘭的父親基姆利22基薛哈瑣必達益拉利百加的父親彼土利。」 23密迦亞伯拉罕的兄弟拿鶴生了八個兒子。 24拿鶴的妾流瑪生了提八迦含他轄瑪迦