Ìbí Isaaki
1Olúwa sì bẹ Sara wò bí ó ti wí, Olúwa sì ṣe fún Sara gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣèlérí. 221.2: Hb 11.11.Sara sì lóyún, ó sì bí ọmọkùnrin kan fún Abrahamu ní ọjọ́ ogbó rẹ̀, ní àkókò náà gan an tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún un. 3Abrahamu sì sọ orúkọ ọmọ náà tí Sara bí fun un ní Isaaki. 421.4: Gẹ 17.12; Ap 7.8.Nígbà tí Isaaki pé ọmọ ọjọ́ mẹ́jọ, Abrahamu sì kọ ọ́ ní ilà gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún un. 5Ẹni ọgọ́rùn-ún (100) ọdún ni Abrahamu nígbà tí ó bí Isaaki.
6Sara sì wí pé, “Ọlọ́run ti pa mí lẹ́rìn-ín. Gbogbo ẹni tí ó bá sì gbọ́ pé mo bímọ yóò rẹ́rìn-ín pẹ̀lú mi.” 7Ó sì fi kún un pé, “Ta ni ó le sọ fún Abrahamu pé, Sara yóò di ọlọ́mọ? Síbẹ̀síbẹ̀, mo sì tún bí ọmọ fún Abrahamu ní ìgbà ogbó rẹ.”
A lé Hagari àti Iṣmaeli jáde
8Nígbà tí ọmọ náà dàgbà, ó sì gbà á lẹ́nu ọmú, ní ọjọ́ tí a gba Isaaki lẹ́nu ọmú, Abrahamu ṣe àsè ńlá. 9Ṣùgbọ́n Sara rí ọmọ Hagari ará Ejibiti tí ó bí fún Abrahamu tí ó fi ṣe ẹlẹ́yà, 1021.10: Ga 4.30.ó sì wí fún Abrahamu pé, “Lé ẹrúbìnrin yìí àti ọmọ rẹ̀ jáde, nítorí ọmọ ẹrú yìí kò ní bá ọmọ mi Isaaki pín ogún.”
11Ọ̀rọ̀ náà sì ba Abrahamu lọ́kàn jẹ́ gidigidi nítorí ọmọ rẹ̀ náà sá à ni Iṣmaeli i ṣe. 1221.12: Ro 9.7; Hb 11.18.Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fun Abrahamu pé, “Má ṣe ba ọkàn jẹ́ nítorí ọmọ náà àti ẹrúbìnrin rẹ. Gbọ́ ohun tí Sara wí fún ọ, nítorí nínú Isaaki ni a ó ti pe irú-ọmọ rẹ̀. 13Èmi yóò sọ ọmọ ẹrúbìnrin náà di orílẹ̀-èdè pẹ̀lú, nítorí ọmọ rẹ ni.”
14Abrahamu sì dìde ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ó sì mú oúnjẹ àti ìgò omi kan, ó sì kó wọn fún Hagari, ó kó wọn lé e léjìká, ó sì lé e jáde pẹ̀lú ọmọ náà. Ó sì lọ lọ́nà rẹ, ó sì ń ṣe alárìnkiri ní ijù Beerṣeba.
15Nígbà tí omi inú ìgò náà tan, ó gbé ọmọ náà sí abẹ́ igbó. 16Ó sì lọ, ó sì jókòó nítòsí ibẹ̀, níwọ̀n bí ìtafà kan, nítorí, ó rò ó nínú ara rẹ̀ pé, “Èmi kò fẹ́ wo bí ọmọ náà yóò ṣe kú.” Bí ó sì ti jókòó sí tòsí ibẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí ní sọkún.
17Ọlọ́run gbọ́ ohun ẹkún náà, Angẹli Ọlọ́run sì pe Hagari láti ọ̀run, ó sì wí fun un pé, “Hagari, kín ni ó ṣe ọ́? Má bẹ̀rù nítorí Ọlọ́run ti gbọ́ ẹkún ọmọ náà níbi tí o tẹ́ ẹ sí. 18Dìde, gbé ọmọ náà sókè, kí o sì dìímú (tù ú nínú) nítorí èmi yóò sọ ọmọ náà di orílẹ̀-èdè ńlá.”
19Ọlọ́run sì ṣí ojú Hagari, ó sì rí kànga kan, ó lọ síbẹ̀, ó rọ omi kún inú ìgò náà, ó sì fún ọmọ náà mu.
20Ọlọ́run sì wà pẹ̀lú ọmọ náà bí ó ti ń dàgbà, ó ń gbé nínú ijù, ó sì di tafàtafà. 21Nígbà tí ó ń gbé ni aginjù ní Parani, ìyá rẹ̀ fẹ́ ìyàwó fún un láti ilẹ̀ Ejibiti wá.
Májẹ̀mú ní Beerṣeba
2221.22: Gẹ 26.26.Ní àkókò yìí ni ọba Abimeleki àti Fikoli, olórí ogun rẹ̀ wí fún Abrahamu pé, “Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú gbogbo ohun tí ó ń ṣe. 23Ǹjẹ́ nísinsin yìí, fi Ọlọ́run búra fún mi, ìwọ kì yóò tàn mí àti àwọn ọmọ mi àti àwọn ìran mi, ìwọ yóò fi inú rere hàn fún mi àti orílẹ̀-èdè tí ìwọ ti ṣe àtìpó, bí mo ti fihàn fún ọ pẹ̀lú.”
24Abrahamu sì wí pé, “Èmí búra.”
25Nígbà náà ni Abrahamu fi ẹ̀dùn ọkàn rẹ̀ hàn fún Abimeleki nípa kànga tí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ gbà lọ́wọ́ rẹ̀. 26Ṣùgbọ́n Abimeleki dáhùn pé, “Èmi kò mọ ẹni tí ó ṣe nǹkan yìí. Ìwọ kò sì sọ fún mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbọ́, bí kò ṣe lónìí.”
27Abrahamu sì mú àgùntàn àti màlúù wá, ó sì kó wọn fún Abimeleki. Àwọn méjèèjì sì dá májẹ̀mú. 28Abrahamu sì ya abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje nínú agbo àgùntàn rẹ̀ sọ́tọ̀. 29Abimeleki sì béèrè lọ́wọ́ Abrahamu pé, “Kín ni ìtumọ̀ yíyà tí ìwọ ya àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn méje wọ̀nyí sọ́tọ̀ sí.”
30Ó dalóhùn pé “Gba àwọn abo ọ̀dọ́-àgùntàn méje wọ̀nyí lọ́wọ́ mi gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí pé èmi ni mo gbẹ́ kànga yìí.”
3121.31: Gẹ 26.33.Nítorí náà ni a ṣe ń pe ibẹ̀ náà ni Beerṣeba nítorí níbẹ̀ ni àwọn méjèèjì gbé búra.
32Lẹ́yìn májẹ̀mú tí wọ́n dá ní Beerṣeba yìí, ni Abimeleki àti Fikoli olórí ogun rẹ̀ padà sí ilẹ̀ àwọn ará Filistini. 33Abrahamu lọ́ igi tamariski kan sí Beerṣeba, níbẹ̀ ni ó sì pe orúkọ Olúwa Ọlọ́run ayérayé. 34Abrahamu sì gbé ilẹ̀ àwọn ará Filistini fún ọjọ́ pípẹ́.
以撒出生
1耶和華按著自己說過的話眷顧撒拉,實現給她的應許。 2亞伯拉罕年老的時候,撒拉懷了孕,在上帝指定的日期為他生了一個兒子。 3亞伯拉罕為兒子取名叫以撒。 4以撒出生後第八天,亞伯拉罕就照著上帝的吩咐為他行了割禮。 5以撒出生時亞伯拉罕已經一百歲。 6撒拉說:「上帝使我歡笑,凡聽見這事的人也必跟我一同歡笑。 7誰曾料到我會為亞伯拉罕哺養孩子呢?我竟然在丈夫年老的時候給他生了兒子。」
夏甲和以實瑪利被逐
8以撒漸漸長大,亞伯拉罕在他斷奶的那天擺設宴席。 9撒拉見埃及人夏甲給亞伯拉罕生的兒子以實瑪利嘲笑以撒, 10就對亞伯拉罕說:「趕走這婢女和她的兒子,因為這婢女的兒子不可和我的兒子以撒一同承受產業。」 11亞伯拉罕因兒子以實瑪利的事非常煩惱。 12上帝對亞伯拉罕說:「你不要再為這孩子和你的婢女煩惱,只管照撒拉的意思去做,因為以撒生的才可算為你的後代。 13至於那婢女的兒子以實瑪利,我也會使他自成一國,因為他也是你的兒子。」
14第二天,亞伯拉罕清早起來,把食物和一皮袋水放在夏甲肩上,讓她和孩子離開。夏甲在別示巴的曠野流浪。 15皮袋的水喝光了,夏甲把兒子留在一叢灌木下, 16自己走到離孩子約一箭之遠的地方,對著孩子坐下,說:「我不忍心看著他死啊!」夏甲坐在那裡放聲大哭起來。 17上帝聽見孩子的哭聲,就差遣天使從天上安慰夏甲說:「夏甲,你怎麼了?不要害怕,上帝已經聽見孩子的哭聲了。 18你去扶他起來,安慰他,我必使他成為大國。」 19上帝使夏甲的眼睛明亮,讓她看見一口水井,她就上前把皮袋裝滿水拿給兒子喝。 20在上帝的看顧下,孩子在曠野漸漸長大,成為一個射箭能手。 21他住在巴蘭曠野,他母親為他娶了一個埃及女子。
亞伯拉罕與亞比米勒立約
22有一次,亞比米勒和他的將領非各對亞伯拉罕說:「你做的一切都有上帝保佑。 23現在請你在這裡當著上帝的面向我起誓,你不會欺騙我和我的子孫後代。我怎樣善待你,請你也同樣善待我以及你所寄居之地的百姓。」 24亞伯拉罕說:「我願起誓。」
25由於亞比米勒的僕人霸佔了一口水井,亞伯拉罕就指責亞比米勒。 26亞比米勒說:「我不知道是誰做的,你以前沒有告訴我,我今天才聽說這事。」 27亞伯拉罕把牛羊送給亞比米勒,他們二人立了約。 28亞伯拉罕又從羊群中分出七隻母羊羔。 29亞比米勒問亞伯拉罕:「你分出七隻母羊羔是什麼意思?」 30亞伯拉罕回答說:「你要從我手中接受這七隻母羊羔,表示你承認這口井是我挖的。」 31所以,那地方被稱為別示巴21·31 「別示巴」意思是「盟誓之井」。,因為他們二人在那裡起了誓。
32他們立約以後,亞比米勒和他的將領非各便回非利士去了。 33亞伯拉罕在別示巴栽了一棵紅柳,又在那裡呼求耶和華——永恆上帝的名。 34亞伯拉罕在非利士住了很長時間。