12.1-3: Ek 20.11.Báyìí ni Ọlọ́run parí dídá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.
22.2,3: Ek 20.11.2.2: Hb 4.4,10.Ní ọjọ́ keje Ọlọ́run sì parí iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ń ṣe; ó sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo tí ó ti ń ṣe. 3Ọlọ́run sì súre fún ọjọ́ keje, ó sì yà á sí mímọ́, nítorí pé ní ọjọ́ náà ni ó sinmi kúrò nínú iṣẹ́ dídá ayé tí ó ti ń ṣe.
Adamu àti Efa
4Èyí ni ìtàn bí Ọlọ́run ṣe dá àwọn ọ̀run àti ayé nígbà tí ó dá wọn. Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run dá ayé àti àwọn ọ̀run.
5Kò sí igi igbó kan ní orí ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ewéko igbó kan tí ó tí ì hù jáde ní ilẹ̀, nítorí Olúwa Ọlọ́run kò tí ì rọ̀jò sórí ilẹ̀, kò sì sí ènìyàn láti ro ilẹ̀. 6Ṣùgbọ́n ìsun omi ń jáde láti ilẹ̀, ó sì ń bu omi rin gbogbo ilẹ̀. 72.7: 1Kọ 15.45-47.Olúwa Ọlọ́run sì fi erùpẹ̀ ilẹ̀ mọ ènìyàn, ó si mí èémí ìyè sí ihò imú rẹ̀, ènìyàn sì di alààyè ọkàn.
8Olúwa Ọlọ́run sì gbin ọgbà kan sí Edeni ní ìhà ìlà-oòrùn, níbẹ̀ ni ó fi ọkùnrin náà tí ó ti dá sí. 92.9: If 2.7; 22.2,14,19.Olúwa Ọlọ́run sì mú kí onírúurú igi hù jáde láti inú ilẹ̀, àwọn igi tí ó dùn ún wò lójú, tí ó sì dára fún oúnjẹ. Ní àárín ọgbà náà ni igi ìyè àti igi tí ń mú ènìyàn mọ rere àti búburú wà.
10Odò kan sì ń ti Edeni sàn wá láti bu omi rin ọgbà náà, láti ibẹ̀ ni odò náà gbé ya sí ipa mẹ́rin. 11Orúkọ èkínní ni Pisoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Hafila ká, níbi tí wúrà gbé wà. 12(Wúrà ilẹ̀ náà dára, òjìá2.12 tí ó túmọ̀ sí, bedeliumu àti òkúta óníkìsì oníyebíye wà níbẹ̀ pẹ̀lú). 13Orúkọ odò kejì ni Gihoni, òun ni ó sàn yí gbogbo ilẹ̀ Kuṣi ká. 14Orúkọ odò kẹta ni Tigirisi, òun ni ó sàn ní apá ìlà-oòrùn ilẹ̀ Asiria. Odò kẹrin ni Eufurate.
15Olúwa Ọlọ́run mú ọkùnrin náà sínú ọgbà Edeni láti máa ṣe iṣẹ́ níbẹ̀, kí ó sì máa ṣe ìtọ́jú rẹ̀. 16Olúwa Ọlọ́run sì pàṣẹ fún ọkùnrin náà pé, “Ìwọ lè jẹ lára èyíkéyìí èso àwọn igi inú ọgbà; 17ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú èso igi ìmọ̀ rere àti èso igi ìmọ̀ búburú, nítorí ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ ẹ́ ni ìwọ yóò kùú.”
18Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.”
19Lẹ́yìn tí Olúwa Ọlọ́run ti dá àwọn ẹranko inú igbó àti gbogbo ẹyẹ ojú ọ̀run láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀. Ó sì kó wọn tọ ọkùnrin náà wá láti wo orúkọ tí yóò sọ wọ́n; orúkọ tí ó sì sọ gbogbo ẹ̀dá alààyè náà ni wọ́n ń jẹ́. 20Gbogbo ohun ọ̀sìn, ẹyẹ ojú ọ̀run àti gbogbo ẹranko igbó ni ọkùnrin náà sọ ní orúkọ.
Ṣùgbọ́n fún Adamu ni a kò rí olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀. 21Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run mú kí ọkùnrin náà sùn fọnfọn; nígbà tí ó sì ń sùn, Ọlọ́run yọ egungun ìhà rẹ̀ kan, ó sì fi ẹran-ara bò ó padà. 22Olúwa Ọlọ́run sì dá obìnrin láti inú egungun tí ó yọ ní ìhà ọkùnrin náà, Ó sì mu obìnrin náà tọ̀ ọ́ wá.
23Ọkùnrin náà sì wí pé,
“Èyí ni egungun láti inú egungun mi
àti ẹran-ara nínú ẹran-ara mi;
‘obìnrin’ ni a ó máa pè é,
nítorí a mú un jáde láti ara ọkùnrin.”
242.24: Mt 19.5; Mk 10.7; 1Kọ 6.16; Ef 5.31.Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.
25Ọkùnrin náà àti aya rẹ̀ sì wà ní ìhòhò, ojú kò sì tì wọ́n.
1Nahuman ug mugna sa Dios ang kalangitan, ang kalibotan, ug ang tanan nga anaa niini. 2Nahuman niya kini sulod sa unom ka adlaw, ug mipahulay siya sa ikapito nga adlaw. 3Gipanalanginan niya ang ikapito nga adlaw ug giisip niya kini nga usa ka pinasahi nga adlaw, tungod kay niining adlawa mipahulay siya human niya gimugna ang tanan. 4Mao kini ang sugilanon mahitungod sa pagmugna sa kalangitan ug sa kalibotan.
Si Adan ug si Eva
Sa pagmugna sa Ginoong Dios sa kalibotan ug sa kalangitan, 5wala pa sa kalibotan ang tanan nga klasi sa tanom nga nagaturok sa yuta,2:5 yuta: sa English, open field. kay wala pa niya kini paulani ug wala pay tawo nga moatiman niini. 6Apan bisan walay ulan, may mga tubod nga nagpabasa sa yuta.
7Unya gibuhat sa Ginoong Dios ang tawo gikan sa yuta. Gihuypan niya ang ilong sa tawo sa gininhawa nga nagahatag ug kinabuhi, ug ang tawo nahimong kalag nga may kinabuhi.
8Unya nagbuhat ang Ginoong Dios ug tanaman sa Eden, sa sidlakan, ug gipapuyo niya didto ang tawo nga iyang gibuhat. 9Gipatubo sa Ginoong Dios ang tanang matang sa mga kahoy nga nindot tan-awon ug ang ilang mga bunga maayong kan-on. Sa taliwala sa tanaman adunay kahoy nga nagahatag ug kinabuhi ug kahoy nga nagahatag sa kahibalo kon unsa ang maayo ug daotan.
10Adunay nagadagayday nga suba didto sa Eden nga nagahatag ug tubig sa tanaman. Kini nga suba nagasanga sa upat ka bahin. 11Ang ngalan sa unang suba mao ang Pishon. Nagadagayday kini sa tibuok nga yuta sa Havila diin adunay bulawan. 12Maayong klase ang bulawan niadtong dapita ug adunay usa ka mahalon nga pahumot nga bediliyum ug mahalon nga bato nga onix. 13Ang ngalan sa ikaduhang suba mao ang Gihon. Nagadagayday kini sa tibuok nga yuta sa Cush. 14Ang ngalan sa ikatulong suba mao ang Tigris. Nagadagayday kini sa sidlakang bahin sa Asiria. Ug ang ikaupat nga suba mao ang Eufrates.
15Gipapuyo sa Ginoong Dios sa tanaman sa Eden ang tawo nga iyang gibuhat aron pag-ugmad ug pag-atiman niini. 16Unya giingnan sa Dios ang tawo, “Mahimo mong kaonon ang bunga sa bisan unsa nga kahoy sa tanaman, 17gawas lang sa bunga sa kahoy nga nagahatag ug kahibalo kon unsay maayo ug daotan. Kay sa higayon nga kan-on mo kini, sigurado gayod nga mamatay ka.”
18Unya miingon ang Ginoong Dios, “Dili maayo nga mag-inusara ang tawo. Buhatan ko siya ug katabang nga angay kaniya.” 19Gibuhat sa Ginoong Dios gikan sa yuta ang tanang matang sa mga mananap nga nagapuyo sa yuta2:19 yuta: sa English, open field. ug ang tanang matang sa mga mananap nga nagalupad. Unya gidala niya sila ngadto sa tawo aron panganlan kini. Kon unsay gipangalan sa tawo kanila mao nay tawag kanila. 20Busa ginganlan sa tawo ang tanang mananap nga nagapuyo sa yuta apil ang mga mananap nga nagalupad. Apan walay usa niining mga mananap nga angay mahimong kaabag ni Adan. 21Busa gipakatulog sa Ginoong Dios ang tawo. Ug samtang nahinanok siya, gikuha sa Ginoong Dios ang usa sa iyang mga gusok, ug unya gibalik ug kipot ang bahin nga gikuhaan niini. 22Ang gusok nga gikuha gikan sa lalaki gibuhat sa Ginoong Dios nga usa ka babaye, ug gidala niya kini sa lalaki. 23Unya miingon ang lalaki,
“Ania na ang sama kanako!
Bukog nga gikuha sa akong bukog,
ug unod nga gikuha sa akong unod.
Pagatawgon siya nga babaye,
kay gikuha siya gikan sa lalaki.”2:23 Ang Hebreo nga “isha” (babaye) nagagikan sa pulong nga “ish” (lalaki).
24Busa mao kini ang hinungdan nga mobiya ang lalaki gikan sa iyang amahan ug inahan ug makighiusa sa iyang asawa, ug silang duha mahimong usa.
25Niadtong panahona, hubo ang lalaki ug ang iyang asawa, apan wala sila maulaw.