Filipi 1 – YCB & CCB

Yoruba Contemporary Bible

Filipi 1:1-30

11.1: Ap 16.1,12-40; Ro 1.1; 2Kọ 1.1; Ga 1.10; Kl 1.1; 1Tẹ 1.1; 2Tẹ 1.1; Fm 1.Paulu àti Timotiu, àwọn ìránṣẹ́ Jesu Kristi.

Sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́ nínú Kristi Jesu tí ó wà ní Filipi, pẹ̀lú àwọn alábojútó àti àwọn díákónì.

21.2: Ro 1.7.Oore-ọ̀fẹ́ sí yín, àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa, àti Olúwa wa Jesu Kristi.

Àdúrà àti Ọpẹ́

3Mo ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run mi ní gbogbo ìgbà tí mo bá rántí yín: 4Nínú gbogbo àdúrà mi fún un yín, èmi ń fi ayọ̀ gbàdúrà, 5nítorí ìdàpọ̀ yín nínú ìhìnrere láti ọjọ́ kìn-ín-ní wá títí di ìsinsin yìí. 61.6,10: 1Kọ 1.8.Ohun kan yìí sá à dá mi lójú pé, ẹni tí ó ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ rere nínú yín, yóò ṣe àṣepé rẹ̀ títí di ọjọ́ náà tí Jesu Kristi yóò dé:

71.7: Ap 21.33; 2Kọ 7.3; Ef 6.20.Gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi láti ro èyí nípa gbogbo yín, nítorí tí mo fi yín sọ́kàn, bí mo tilẹ̀ wà nínú ìdè tàbí ìdáhùn ẹjọ́, àti ìfẹsẹ̀múlẹ̀ ìhìnrere, gbogbo yín jẹ́ alábápín oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run pẹ̀lú mi. 8Nítorí Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí mi, bí mo ti ń ṣàfẹ́rí yín gidigidi nínú ìfẹ́ Jesu Kristi.

9Èyí sì ni àdúrà mi: pé kí ìfẹ́ yín lè máa pọ̀ síwájú àti síwájú sí i nínú ìfẹ́ àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, 10kí ẹ̀yin kí ó lè ní òye ohun tí ó dára jùlọ; kí ó sì jásí òdodo àti aláìjẹ́ ohun ìkọ̀sẹ̀ títí di ọjọ́ dídé Jesu Kristi: 11Lẹ́yìn ìgbà ti ẹ ti kún fún àwọn ìwà òdodo láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, fún ògo àti ìyìn Ọlọ́run.

Ìrírí Paulu nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́

121.12: Lk 21.13.Ǹjẹ́ èmi fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó mọ̀, ará, pé ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí mi jásí àtẹ̀gùn sí ìlọsíwájú ìhìnrere. 131.13: Ap 28.30; 2Tm 2.9.Nítorí ìdí èyí, ó ti hàn gbangba sí gbogbo àwọn ẹ̀ṣọ́ ààfin àti sí àwọn ẹlòmíràn wí pé mo wà nínú ìdè fún Kristi. 14Nítorí ìdè mi, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará nínú Olúwa ni a ti mú lọ́kàn le láti sọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí i pẹ̀lú ìgboyà àti láìbẹ̀rù.

15Òtítọ́ ni pé àwọn ẹlòmíràn tilẹ̀ ń fi ìjà àti ìlara wàásù Kristi, ṣùgbọ́n àwọn ẹlòmíràn sì ń fi inú rere ṣe é. 16Àwọn kan ń fi ìjà wàásù Kristi, kì í ṣe pẹ̀lú òtítọ́ inú, wọ́n ń gbèrò láti fi ìpọ́njú kún ìdè mi: 17Àwọn kan ẹ̀wẹ̀ si ń fi ìfẹ́ ṣe é, nítorí tí wọ́n mọ̀ pé a gbé mi dìde láti dá ààbò bo iṣẹ́ ìhìnrere. 18Kí ló tún kù? Kìkì í pé níbi gbogbo, ìbá à ní ìfẹ̀tànṣe tàbí ni ti òtítọ́ a sá à n wàásù Kristi, èmi sì ń yọ̀ nítorí èyí.

Nítòótọ́, èmi ó sì máa yọ̀, 191.19: Ap 16.7; 2Kọ 1.11.nítorí tí mo mọ̀ pé èyí ni yóò yọrí sí ìgbàlà fún mi láti inú àdúrà yín wá, àti ìfikún ẹ̀mí Jesu Kristi, 201.20: Ro 14.8. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ ọkàn àti ìrètí mi pé kí ojú kí ó má ṣe ti mi ní ohunkóhun, ṣùgbọ́n kí èmi kí ó le máa ni ìgboyà ní ìgbà gbogbo àti nísinsin yìí, kí a lè ti ipasẹ̀ mi gbé Kristi ga lára mi, ìbá à ṣe pé mo wà láààyè, tàbí mo kú. 211.21: Ga 2.20.Nítorí, ní ti èmi, láti wa láààyè jẹ́ Kristi, láti kú pẹ̀lú sì jẹ́ èrè fún mi. 22Ṣùgbọ́n bí èmi bá le è ṣe iṣẹ́ ti ó ni àpẹẹrẹ nípa wíwà láààyè nínú ara, ṣùgbọ́n ohun ti èmi ó yàn, èmi kò mọ̀. 23Ṣùgbọ́n èmi n ṣiyèméjì, nítorí ti èmi fẹ́ láti lọ kúrò nínú ayé yìí, láti wà lọ́dọ̀ Kristi; nítorí ó dára púpọ̀ jù: 24Síbẹ̀ láti wà láààyè jẹ́ àǹfààní nítorí tiyín. 25Bí èyí sì ti dá mi lójú, mo mọ̀ pé èmi ó dúró, èmi ó sì máa wà pẹ̀lú yín fún ìtẹ̀síwájú àti ayọ̀ yín nínú ìgbàgbọ́, 26kí ìṣògo yín kí ó lè di púpọ̀ gidigidi nínú Jesu Kristi, àti nínú mi nípa ìpadà wá mi sọ́dọ̀ yín.

27Ohun yówù kó ṣẹlẹ̀, ẹ jẹ́ kí ìgbé ayé yín ri gẹ́gẹ́ bí ìhìnrere Kristi: pé yálà bi mo tilẹ̀ wá wò yín, tàbí bí èmi kò wá, kí èmi kí ó lè máa gbúròó bí ẹ ti ń ṣe, pé ẹ̀yin dúró ṣinṣin nínú Ẹ̀mí kan, ẹ̀yin jùmọ̀ jìjàkadì nítorí ìgbàgbọ́ ìhìnrere, pẹ̀lú ọkàn kan; 281.28: 2Tẹ 1.5.Kí ẹ má sì jẹ́ ki àwọn ọ̀tá dẹ́rùbà yin ni ohunkóhun: èyí tí í ṣe ààmì tí ó dájú pé a ó pa wọ́n run, ṣùgbọ́n Ọlọ́run tìkára rẹ̀ ni yóò gbà yin là. 29Nítorí tí a ti fún yin ni àǹfààní, kì í ṣe láti gba Kristi gbọ́ nìkan, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú: 301.30: Ap 16.19-40; 1Tẹ 2.2.Ẹ sì máa ja ìjà kan náà, èyí ti ẹ̀yin ti ri, ti ẹ sì ti gbọ́ pé èmi n jà pẹ̀lú.

Chinese Contemporary Bible 2022 (Simplified)

腓立比书 1:1-30

1保罗提摩太是基督耶稣的奴仆,写信给腓立比在基督耶稣里的所有圣徒、诸位监督和执事。

2愿我们的父上帝和主耶稣基督赐给你们恩典和平安!

感恩和祷告

3我每逢想起你们,就感谢我的上帝; 4每次为你们众人祷告,心里都带着喜乐。 5因为你们从最初直到现在,始终和我同心合意地传扬福音。 6我深信,上帝既然在你们心里开始了这美好的工作,就必在耶稣基督再来的时候完成这工作。 7我对你们众人有这样的感受很自然,因为我常把你们放在心上1:7 “我常把你们放在心上”或译“你们常把我放在心上”。。不论我是身在狱中,还是为福音辩护和作证的时候,你们都与我同蒙恩典。 8上帝可以作证,我是怎样以基督耶稣的慈心想念你们的。

9我所祈求的就是:你们的爱心随着属灵知识和辨别力的提高而日益增长, 10使你们能够择善而从,做诚实无过的人,一直到基督再来的日子, 11并靠着耶稣基督结满仁义的果子,使上帝得到荣耀与颂赞。

为基督而活

12弟兄姊妹,我希望你们知道,我的遭遇反而会使福音传得更广, 13连所有的皇家卫兵和其他众人都知道我是为了基督的缘故而受囚禁。 14大多数主内的弟兄姊妹因我被囚的缘故,就信心坚定,更加放胆传扬上帝的道。 15当然,有些人宣讲基督是出于嫉妒和争强好胜,也有些人是出于善意。 16后者是出于爱心,知道我是上帝派来为福音辩护的。 17前者传讲基督是出于个人野心,动机不纯,以为可以增加我在狱中的痛苦。 18那又怎样呢?无论他们是出于真心还是假意,基督的福音毕竟被传开了,因此我很欢喜,而且欢喜不已。 19因为我知道,借着你们的祷告和耶稣基督之灵的帮助,我终必得到释放。

20我热切期待和盼望:我不会感到任何羞愧,而是放胆无惧,不管是生是死,都要照常使基督在我身上被尊崇。 21因为对我来说,活着是为了基督,死了也有益处。 22如果活在世上,我的工作肯定富有成果。我真不知道该怎么选择! 23我处在两难之间。我情愿离开世界,与基督在一起,那实在是再好不过了。 24可是为了你们,我更有必要活在世上。 25我既然对此深信不疑,就知道自己仍要活下去,继续跟你们在一起,好使你们在信仰上又长进又充满喜乐。 26这样,我再到你们那里的时候,你们可以因为我的缘故更加以基督耶稣为荣。

27最要紧的是:你们行事为人要与基督的福音相称。这样,不管是去看你们,还是只听到你们的消息,我都能知道你们同心合意,坚定不移地一起为福音信仰奋斗, 28毫不惧怕敌人的恐吓。这是出于上帝的记号,表明他们必灭亡,你们必得救。 29因为上帝为了基督的缘故,赐恩使你们不但信基督,而且为祂受苦, 30经历你们从前在我身上见过、现在又从我这里听到的同样争战。