Esteri 2 – YCB & CARSA

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esteri 2:1-23

Esteri di ayaba

1Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Ahaswerusi ọba sì dáwọ́ ìbínú un rẹ̀ dúró, ó rántí i Faṣti àti ohun tí ó ti ṣe àti àṣẹ tí ó pa nípa tirẹ̀. 2Nígbà náà ni ìránṣẹ́ ọba tí ó wà ní ọ̀dọ̀ ọ rẹ̀ wí pé, “Jẹ́ kí a wá ọmọbìnrin arẹwà tí kò ì ti mọ ọkùnrin rí fún ọba. 3Àti pé kí ọba kí ó yan àwọn aláṣẹ ní gbogbo agbègbè ilẹ̀ ọba láti kó gbogbo àwọn arẹwà ọmọbìnrin wọ̀nyí jọ sí ilé àwọn obìnrin ní ilé ìṣọ́ Susa. Kí a kó wọn fún ìtọ́jú Hegai, ìwẹ̀fà ọba, ẹni tí ó ṣe olùtọ́jú àwọn obìnrin; kí a ṣe ìtọ́jú u wọn dáradára. 4Nígbà náà kí ọmọbìnrin tí ó bá tẹ́ ọba lọ́rùn kí ó jẹ́ ayaba dípò Faṣti.” Ìmọ̀ràn yìí tẹ́ ọba lọ́rùn, ó sì tẹ̀lé e.

5Ó sì ṣe ní ìgbà náà ará a Júù kan wà ní ilé ìṣọ́ ti Susa, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Mordekai ọmọ Jairi, ọmọ Ṣimei, ọmọ Kiṣi, ẹ̀yà Benjamini, 6ẹni tí Nebukadnessari ọba Babeli ti gbé lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu, lára àwọn tí wọ́n kó ní ìgbèkùn pẹ̀lú ọba Jekoniah ọba Juda. 7Mordekai ní arákùnrin kan ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hadassa, ẹni tí ó tọ́ dàgbà nítorí tí kò ní baba bẹ́ẹ̀ sì ni kò ní ìyá. Obìnrin yìí, ẹni tí a tún mọ̀ sí Esteri, ó dára ó sì lẹ́wà, Mordekai mú u gẹ́gẹ́ bí ọmọ rẹ̀ nígbà tí baba àti ìyá rẹ̀ ti kú.

8Nígbà tí a ti kéde òfin àti àṣẹ ọba, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọbìnrin ni a kó wá sí ilé ti ìṣọ́ Susa, sí abẹ́ ìtọ́jú Hegai. A sì mú Esteri náà wá sí ààfin ọba pẹ̀lú, a fà á lé Hegai lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ alábojútó ilé àwọn obìnrin. 9Ọmọbìnrin náà sì wù ú, ó sì rí ojúrere rẹ̀, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó pèsè àwọn ohun tí ó dára àti oúnjẹ pàtàkì fún un. Ó sì yan àwọn ìránṣẹ́bìnrin wúńdíá méje láti ààfin ọba òun àti àwọn ìránṣẹ́bìnrin náà lọ sí ibi tí ó dára jù nínú ilé àwọn obìnrin.

10Esteri kò tí ì sọ nípa àwọn ènìyàn àti ìdílé e rẹ̀, nítorí Mordekai ti pàṣẹ fún un pé kí ó má ṣe sọ ọ́. 11Ní ojoojúmọ́ ni Mordekai máa ń rìn ní iwájú ilé àwọn obìnrin láti wo bí Esteri ṣe wà ní àlàáfíà àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.

12Kí àkókò tó tó fún obìnrin kọ̀ọ̀kan láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Ahaswerusi, ó ní láti lo ohun èlò tí ń mú ara lẹ́wà tí a yàn fún àwọn obìnrin fún oṣù méjìlá, yóò lo òróró òjìá fún oṣù mẹ́fà, yóò sì lo ohun èlò olóòórùn dídùn tùràrí àti ìpara fún oṣù mẹ́fà pẹ̀lú. 13Báyìí ni yóò ṣe lọ síwájú ọba: ohunkóhun tí ó bá béèrè ni wọ́n fi fún un láti inú ilé àwọn obìnrin lọ sí ààfin ọba. 14Ní alẹ́ ni yóò lọ síbẹ̀, tí ó bá sì di òwúrọ̀ yóò padà sí ilé kejì nínú ilé àwọn obìnrin ní abẹ́ ìtọ́jú Ṣaaṣigasi ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó máa ń ṣe ìtọ́jú àwọn àlè. Òun kò ní lọ sí ọ̀dọ̀ ọba mọ́ àyàfi tí inú ọba bá dùn sí i, tí ó sì ránṣẹ́ pé ó ní orúkọ obìnrin.

15Nígbà tí ó kan Esteri (ọmọbìnrin tí Mordekai gbà ṣe ọmọ, ọmọbìnrin arákùnrin rẹ̀ tí ó ń jẹ́ Abihaili) láti lọ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọn kò béèrè fún ohunkóhun ju èyí tí Hegai, ìwẹ̀fà ọba ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ilé àwọn obìnrin sọ pé kí ó ṣe lọ. Esteri sì rí ojúrere lọ́dọ̀ gbogbo àwọn tí ó rí i. 16A mú Esteri lọ síwájú ọba Ahaswerusi ní ibùgbé ọba ní oṣù kẹwàá, tí ó jẹ́ oṣù Tebeti, ní ọdún keje ìjọba rẹ̀.

17Esteri sì wu ọba ju àwọn obìnrin tókù lọ, Ó sì rí ojúrere àti oore-ọ̀fẹ́ gbà ju ti àwọn wúńdíá tókù lọ. Nítorí náà ó fi adé ọba dé e ní orí ó sì fi ṣe ayaba dípò Faṣti. 18Ọba sì ṣe àsè ńlá, àsè Esteri, fún gbogbo àwọn ọlọ́lá àti àwọn ìjòyè e rẹ̀. Ó sì kéde ìsinmi jákèjádò ìgbèríko ó sì pín ẹ̀bùn fún wọn pẹ̀lú bí ọba ṣe lawọ́ tó.

Mordekai Tú Àṣírí Ìṣọ̀tẹ̀

19Nígbà tí àwọn wúńdíá tún péjọ ní ìgbà kejì, Mordekai jókòó sí ẹnu-ọ̀nà ọba. 20Ṣùgbọ́n Esteri pa àṣírí ìdílé e rẹ̀ àti ibi tí ó ti wá mọ́ gẹ́gẹ́ bí Mordekai ṣe sọ fún un pé kí ó ṣe, nítorí tí ó ń tẹ̀lé àṣẹ tí Mordekai fún un gẹ́gẹ́ bí ó ṣe máa ń ṣe nígbà tí ó wà ní ọ̀dọ̀ Mordekai.

21Ní àsìkò tí Mordekai jókòó sí ẹnu-ọ̀nà ọba, Bigitana àti Tereṣi, àwọn ìjòyè ọba méjì tí wọ́n máa ń ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà, wọ́n bínú, wọ́n sì ń wá ọ̀nà láti pa ọba Ahaswerusi. 22Ṣùgbọ́n Mordekai sì mọ̀ nípa ọ̀tẹ̀ náà, ó sọ̀ fún ayaba Esteri, Esteri sì sọ fún ọba, wọ́n sì fi ọlá fún Mordekai. 23Nígbà tí wọ́n sì wádìí ọ̀rọ̀ náà tí ó sì jásí òtítọ́, a sì so àwọn ìjòyè méjèèjì náà kọ́. Gbogbo nǹkan wọ̀nyí ni a kọ sínú ìwé ìtàn ní iwájú ọba.

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Есфирь 2:1-23

Есфирь становится царицей

1Спустя некоторое время, когда гнев царя Ксеркса остыл, он вспомнил Астинь, то, что она сделала, и то, что он приказал сделать по отношению к ней. 2Тогда царские слуги, которые прислуживали ему, предложили:

– Пусть для царя поищут красивых молодых девушек. 3Пусть царь назначит особых людей в каждую из провинций своего царства. И пусть они соберут всех красивых молодых девушек в гарем крепости Сузы под надзор царского евнуха Егая, который смотрит за женщинами, и пусть им выдают косметические масла для ухода за телом. 4И пусть девушка, которая понравится царю, станет царицей вместо Астинь.

Этот совет понравился царю, и он воспользовался им. 5В крепости Сузы был иудей из рода Вениамина по имени Мардохей, сын Иаира, сына Шимея, сына Киша, 6который был уведён в плен из Иерусалима царём Вавилона Навуходоносором2:6 Навуходоносор II, самый великий царь Нововавилонской империи, правил с 605 по 562 гг. до н. э. вместе с теми, кто был пленён с царём Иудеи Иехонией. 7Мардохей вырастил Гадассу, она же Есфирь, – свою двоюродную сестру, потому что у неё не было ни отца, ни матери. Девушка была пригожа и красива, и когда её отец и мать умерли, Мардохей взял её к себе вместо дочери.

8После того как царская воля и указ были объявлены во всеуслышание, в крепость Сузы привели и отдали под надзор Егая множество девушек. Есфирь тоже была взята в царский дворец и отдана под надзор Егая, смотрителя гарема. 9Девушка понравилась ему и приобрела его расположение. Он сразу же выдал ей пропитание и косметические масла для ухода за телом. Он приставил к ней семь служанок, выбранных для неё из царского дворца, и переселил её вместе со служанками в лучшее помещение гарема. 10Есфирь не рассказывала ни о своём народе, ни о сородичах, потому что Мардохей запретил ей. 11Мардохей каждый день прогуливался перед двором гарема, чтобы узнать, как поживает Есфирь и что делается с ней.

12Прежде чем в свой черёд войти к царю Ксерксу, каждая девушка должна была двенадцать месяцев ухаживать за собой, как было предписано женщинам: шесть месяцев притираний мирровым маслом и шесть месяцев благовониями и другими средствами. 13Когда девушка входила к царю, ей давали всё, чего бы она ни захотела взять с собой из гарема в царский дворец. 14Вечером она уходила туда, а на утро возвращалась в другую часть гарема под надзор Шаашгаза, царского евнуха, который смотрел за наложницами. Она уже не возвращалась к царю, если он не оставался ею доволен и не призывал её по имени. 15Когда пришёл черёд Есфири, дочери Авихаила, дяди Мардохея, который взял её к себе вместо дочери, она не попросила ничего, кроме того, что посоветовал царский евнух, смотритель гарема Егай. А Есфирь приобрела расположение у всех, кто её видел. 16Её отвели к царю Ксерксу в его дворец в десятом месяце, в месяце тевете (в начале зимы 479 г. до н. э.), в седьмой год его царствования.

17Есфирь понравилась царю больше всех прочих женщин, она приобрела его расположение и привязанность больше, чем все остальные девушки. Он возложил ей на голову царский венец и сделал её царицей вместо Астинь. 18И царь устроил великий пир в честь Есфири для всех своих сановников и знати. Он объявил по всем провинциям праздник2:18 Или: «освобождение от налогов». и с царской щедростью раздал дары.

Мардохей раскрывает заговор

19Когда девушек собирали во второй раз, Мардохей сидел у царских ворот. 20А Есфирь ничего не говорила о своих родственниках и о народе, как сказал ей Мардохей, потому что она слушалась наставлений Мардохея, как в те времена, когда он её растил.

21В то время как Мардохей сидел у царских ворот, Бигтан и Тереш, двое царских евнухов, охранявших порог, разгневались и составили заговор, чтобы убить царя Ксеркса. 22Но Мардохей узнал о заговоре и рассказал царице Есфири, а она рассказала об этом царю от имени Мардохея. 23Дело было расследовано и доказано, и обоих евнухов повесили на виселице2:23 Или: «посадили на кол»; так же в 5:14; 6:4; 7:9; 8:7; 9:13, 14, 25.. Обо всём этом было записано в летописи в присутствии царя.