Esekiẹli 7 – YCB & NIVUK

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 7:1-27

Òpin ti dé

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 27.2: If 7.1; 20.8.“Ọmọ ènìyàn, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí sí ilé Israẹli:

“ ‘Òpin! Òpin ti dé

sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ náà!

3Òpin tí dé sí ọ báyìí,

èmi yóò sì tú ìbínú mi jáde sí ọ,

èmi yóò dájọ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwà rẹ,

èmi yóò sì san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ìwà ìríra rẹ.

4Ojú mi kò ní i dá ọ sì,

bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò ṣàánú;

ṣùgbọ́n èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ

àti gbogbo ìwà ìríra tó wà láàrín rẹ.

Nígbà náà ní ẹ̀yin yóò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.’

5“Èyí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Ibi! Ibi kan ṣoṣo.

Kíyèsi, ó bọ̀ ní orí rẹ!

6Òpin ti dé!

Òpin ti dé!

Ó ti dìde lòdì sí ọ.

Kíyèsi, ó ti dé!

7Ìparun ti dé sórí rẹ,

ìwọ tó ń gbé ní ilẹ̀ náà.

Àkókò náà dé! Ọjọ́ wàhálà ti súnmọ́ etílé!

Kì í ṣe ọjọ́ ariwo ayọ̀ lórí òkè.

8Mo ṣetán láti tú ìbínú gbígbóná mi lé ọ lórí

àti láti lo ìbínú mi lórí rẹ gẹ́gẹ́ bí gbogbo ọ̀nà rẹ,

èmi yóò sì dá ọ lẹ́jọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ

àti gẹ́gẹ́ bí ìwà ìríra rẹ ni èmi yóò sì san án fún ọ.

9Ojú mi kò ní i dá ọ sí,

Èmi kò sì ní wò ọ́ pẹ̀lú àánú;

èmi yóò san án fún ọ gẹ́gẹ́ bí ọ̀nà rẹ

àti fún gbogbo ìwà ìríra tí wà láàrín rẹ.

“ ‘Nígbà náà ní ẹ o mọ̀ pé Èmi Olúwa lo kọlù yín.

10“ ‘Ọjọ́ náà dé!

Kíyèsi ó ti dé!

Ìparun ti bú jáde,

ọ̀pá ti tanná,

ìgbéraga ti rúdí!

11Ìwà ipá ti di ọ̀pá ìwà búburú;

ọ̀pá láti jẹ ẹni búburú ní ìyà.

Kò sí nínú wọn tí yóò ṣẹ́kù,

tàbí nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn,

kò sí nínú ọrọ̀ wọn,

kò sí ohun tí ó ní iye.

12Àkókò náà dé!

Ọjọ́ náà ti dé!

Kí òǹrajà má ṣe yọ̀,

bẹ́ẹ̀ ni ki òǹtajà má ṣe ṣọ̀fọ̀;

nítorí, ìbínú gbígbóná wà lórí gbogbo ènìyàn.

13Nítorí pé òǹtajà kì yóò rí gbà padà

dúkìá èyí tó tà

níwọ̀n ìgbà ti àwọn méjèèjì bá wà láààyè.

Nítorí ìran tó kan gbogbo ènìyàn yìí

kò ní yí padà.

Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn, kò sí ọ̀kan nínú wọn

tí yóò gba ara rẹ̀ là.

14“ ‘Wọ́n ti fọn ìpè ogun,

tí wọ́n sì pèsè ohun gbogbo sílẹ̀,

ṣùgbọ́n kò sí ẹni tí yóò lọ ojú ogun,

nítorí ìbínú gbígbóná mi ti wà lórí gbogbo ènìyàn.

15Idà wà ní ìta,

àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn wà nílé,

idà yóò pa ẹni tó bá wà ní orílẹ̀-èdè,

àjàkálẹ̀-ààrùn àti ìyàn yóò pa ẹni tó bá wà ní ìlú.

16Gbogbo àwọn tí ó bọ́ nínú wọn yóò sálà,

wọn yóò sì wà lórí òkè.

Bí i àdàbà inú àfonífojì,

gbogbo wọn yóò máa ṣọ̀fọ̀,

olúkúlùkù nítorí àìṣedéédéé rẹ̀.

17Gbogbo ọwọ́ yóò rọ,

gbogbo orúnkún yóò di aláìlágbára bí omi.

18Wọn yóò wọ aṣọ ọ̀fọ̀,

ẹ̀rù yóò sì bò wọ́n mọ́lẹ̀,

ìtìjú yóò mù wọn,

wọn yóò sì fá irun wọn.

19“ ‘Wọn yóò dà fàdákà wọn sí ojú pópó,

wúrà wọn yóò sì dàbí èérí

fàdákà àti wúrà wọn

kò ní le gbà wọ́n

ní ọjọ́ ìbínú gbígbóná Olúwa.

Wọn kò ní le jẹun tẹ́ ra wọn lọ́rùn

tàbí kí wọn kún ikùn wọn pẹ̀lú oúnjẹ

nítorí pé ó ti di ohun ìkọ̀sẹ̀ fún wọn.

20Wọ́n ń ṣe ìgbéraga pẹ̀lú ohun ọ̀ṣọ́ wọn tí ó lẹ́wà,

wọn sì ti fi ṣe òrìṣà,

wọn sì tún ya àwòrán ìríra wọn níbẹ̀.

Nítorí náà, èmi yóò sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí di aláìmọ́ fún wọn.

21Èmi yóò sì fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe ìjẹ fún àjèjì

àti ìkógun fún àwọn ènìyàn búburú ayé,

wọn yóò sì sọ ọ́ di aláìmọ́.

22Èmi yóò gbójú mi kúrò lára wọn,

àwọn ọlọ́ṣà yóò sì sọ ibi ìṣúra mi di aláìmọ́;

àwọn ọlọ́ṣà yóò wọ inú rẹ̀,

wọn yóò sì bà á jẹ́.

23“ ‘Rọ ẹ̀wọ̀n irin!

Nítorí pé ilẹ̀ náà kún fún ẹ̀ṣẹ̀ ìtàjẹ̀ sílẹ̀,

ìlú náà sí kún fún ìwà ipá.

24Èmi yóò mú kí orílẹ̀-èdè ti ó búburú jùlọ

láti jogún ilé wọn.

Èmi yóò sì fi òpin sí ìgbéraga àwọn alágbára,

ibi mímọ́ wọn yóò sì di bíbàjẹ́.

25Nígbà tí ìpayà bá dé,

wọn yóò wá àlàáfíà, lórí asán.

26Wàhálà lórí wàhálà yóò dé,

ìdágìrì lórí ìdágìrì.

Nígbà náà ni wọn yóò wá ìran lọ́dọ̀ wòlíì,

ṣùgbọ́n ẹ̀kọ́ òfin yóò parun lọ́dọ̀ àlùfáà,

bẹ́ẹ̀ ni ìmọ̀ràn yóò ṣègbé lọ́dọ̀ àwọn àgbàgbà.

27Ọba yóò ṣọ̀fọ̀,

ọmọ-aládé yóò wà láìní ìrètí,

ọwọ́ àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà yóò wárìrì.

Èmi yóò ṣe é fún wọn gẹ́gẹ́ bí ìṣe wọn,

èmi yóò ṣe ìdájọ́ wọn gẹ́gẹ́ bí ìgbékalẹ̀ wọn.

Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa.’ ”

New International Version – UK

Ezekiel 7:1-27

The end has come

1The word of the Lord came to me: 2‘Son of man, this is what the Sovereign Lord says to the land of Israel:

‘ “The end! The end has come

upon the four corners of the land!

3The end is now upon you,

and I will unleash my anger against you.

I will judge you according to your conduct

and repay you for all your detestable practices.

4I will not look on you with pity;

I will not spare you.

I will surely repay you for your conduct

and for the detestable practices among you.

‘ “Then you will know that I am the Lord.”

5‘This is what the Sovereign Lord says:

‘ “Disaster! Unheard-of7:5 Most Hebrew manuscripts; some Hebrew manuscripts and Syriac Disaster after disaster!

See, it comes!

6The end has come!

The end has come!

It has roused itself against you.

See, it comes!

7Doom has come upon you,

upon you who dwell in the land.

The time has come! The day is near!

There is panic, not joy, on the mountains.

8I am about to pour out my wrath on you

and spend my anger against you.

I will judge you according to your conduct

and repay you for all your detestable practices.

9I will not look on you with pity;

I will not spare you.

I will repay you for your conduct

and for the detestable practices among you.

‘ “Then you will know that it is I the Lord who strikes you.

10‘ “See, the day!

See, it comes!

Doom has burst forth,

the rod has budded,

arrogance has blossomed!

11Violence has arisen,7:11 Or The violent one has become

a rod to punish the wicked.

None of the people will be left,

none of that crowd –

none of their wealth,

nothing of value.

12The time has come!

The day has arrived!

Let not the buyer rejoice

nor the seller grieve,

for my wrath is on the whole crowd.

13The seller will not recover

the property that was sold –

as long as both buyer and seller live.

For the vision concerning the whole crowd

will not be reversed.

Because of their sins, not one of them

will preserve their life.

14‘ “They have blown the trumpet,

they have made all things ready,

but no-one will go into battle,

for my wrath is on the whole crowd.

15Outside is the sword;

inside are plague and famine.

Those in the country

will die by the sword;

those in the city

will be devoured by famine and plague.

16The fugitives who escape

will flee to the mountains.

Like doves of the valleys,

they will all moan,

each for their own sins.

17Every hand will go limp;

every leg will be wet with urine.

18They will put on sackcloth

and be clothed with terror.

Every face will be covered with shame,

and every head will be shaved.

19‘ “They will throw their silver into the streets,

and their gold will be treated as a thing unclean.

Their silver and gold

will not be able to deliver them

in the day of the Lord’s wrath.

It will not satisfy their hunger

or fill their stomachs,

for it has caused them to stumble into sin.

20They took pride in their beautiful jewellery

and used it to make their detestable idols.

They made it into vile images;

therefore I will make it a thing unclean for them.

21I will give their wealth as plunder to foreigners

and as loot to the wicked of the earth,

who will defile it.

22I will turn my face away from the people,

and robbers will desecrate the place I treasure.

They will enter it

and will defile it.

23‘ “Prepare chains!

For the land is full of bloodshed,

and the city is full of violence.

24I will bring the most wicked of nations

to take possession of their houses.

I will put an end to the pride of the mighty,

and their sanctuaries will be desecrated.

25When terror comes,

they will seek peace in vain.

26Calamity upon calamity will come,

and rumour upon rumour.

They will go searching for a vision from the prophet,

priestly instruction in the law will cease,

the counsel of the elders will come to an end.

27The king will mourn,

the prince will be clothed with despair,

and the hands of the people of the land will tremble.

I will deal with them according to their conduct,

and by their own standards I will judge them.

‘ “Then they will know that I am the Lord.” ’