Esekiẹli 4 – YCB & NRT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 4:1-17

A ya àwòrán ìgbógunti Jerusalẹmu

1“Nísinsin yìí, ìwọ ọmọ ènìyàn, mú amọ̀ ṣíṣù kan, gbé e sí iwájú rẹ, kí o sì ya àwòrán ìlú Jerusalẹmu sí orí rẹ̀. 2Kí o sì dó tì í, kí o sì mọ ilé ìṣọ́ tì í, kí o sì mọ odi tì í, kí o sì gbé ogun sí i, kí o sì to òòlù yí i ká. 3Kí o sì fi àwo irin kan ṣe ògiri láàrín rẹ̀ àti ìlú yìí, kí o sì kọjú sí i, a ó sì dó tì í, ìwọ yóò sì dó tì í. Èyí yóò jẹ́ àmì fún ilé Israẹli.

4“Lẹ́yìn èyí, lọ fi ẹ̀gbẹ́ òsì dùbúlẹ̀, kí o sì gbé ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli lé orí ara rẹ. Iye ọjọ́ tí ìwọ bá fi sùn náà ni ìwọ yóò fi ru ẹ̀ṣẹ̀ wọn. 5Nítorí mo fi iye ọdún tí wọ́n fi ṣẹ̀ fún ọ gẹ́gẹ́ bí iye ọjọ́ tí ìwọ yóò lò. Nítorí náà, ìwọ yóò ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Israẹli fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390).

6“Tí o bá parí èyí, tún fi ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún dùbúlẹ̀ kí o sì ru ẹ̀ṣẹ̀ ilé Juda fún ogójì ọjọ́, nítorí pé ọjọ́ kan ló dúró fún ọdún kan. 7Ìwọ dojúkọ ìgbógunti Jerusalẹmu, na ọwọ́ rẹ sí i, kí o sì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa ìlú náà. 8Èmi yóò dè ọ́ ní okùn dé bi pé ìwọ kò ní í le yírapadà láti ìhà ọ̀tún sí ìhà òsì títí tí ọjọ́ ìgbóguntì rẹ yóò fi pé.

9“Mú alikama, ọkà bàbà àti barle, erèé àti lẹntili, jéró àti ẹwẹ; fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe àkàrà tí ìwọ yóò máa jẹ nígbà tí ìwọ bá dùbúlẹ̀ fún irinwó ọjọ́ ó dín mẹ́wàá (390). 10Wọn òsùwọ̀n ogún ṣékélì oúnjẹ tí ìwọ yóò máa jẹ lójoojúmọ́ kí o sì máa jẹ ẹ́ ní àkókò tí a ti yà sọ́tọ̀. 11Bákan náà, wọn ìdámẹ́fà omi, kí ìwọ ó sì máa mú ní àkókò tí a yà sọ́tọ̀. 12Ìwọ yóò sì jẹ ẹ́ bí àkàrà barle; dín in ní ojú àwọn ènìyàn, ìgbẹ́ ènìyàn ni kí o fi dáná rẹ.” 13Olúwa sọ pé, “Báyìí ni àwọn ọmọ Israẹli yóò jẹ oúnjẹ àìmọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè tí èmi yóò lé wọn lọ.”

14Nígbà náà ni mo wí pé, “Háà! Kò rí bẹ́ẹ̀ Olúwa Olódùmarè! Láti ìgbà èwe mi di ìsinsin yìí èmi kò tí ì sọ ara mi di aláìmọ́ rí. Èmi kò tí ì jẹ ohun tó kú fúnra rẹ̀ tàbí èyí tí ẹranko búburú fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ. Bẹ́ẹ̀ ni ẹran àìmọ́ kan kò tí ì wọ ẹnu mi rí.”

15Nígbà náà ló wí fún mi pé, “Wò ó, Èmi ó fún ọ ní ìgbẹ́ màlúù dípò ìgbẹ́ ènìyàn. Èmi yóò mú ki ó dín àkàrà rẹ lórí ìgbẹ́ màlúù dípò ìgbẹ́ ènìyàn.”

16Ó sì tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, èmi yóò dáwọ́ ìpèsè oúnjẹ dúró ní Jerusalẹmu. Ní pípín ni àwọn ènìyàn yóò máa pín oúnjẹ jẹ pẹ̀lú ìfọkànsọ́nà bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni wọn yóò máa mu omi pẹ̀lú ìdààmú, 17nítorí pé oúnjẹ àti omi yóò wọ́n. Wọn yóò máa wo ara wọn pẹ̀lú ìyanu, èmi yóò sì jẹ́ kí wọ́n ṣọ̀fọ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

New Russian Translation

Иезекииль 4:1-17

Пророчество об осаде Иерусалима

1– А ты, сын человеческий, возьми кирпич, положи перед собой и нарисуй на нем город Иерусалим. 2Устрой против него осаду: сооруди укрепления, насыпь осадный вал, расположи под ним лагеря и окружи его стенобитными орудиями. 3Возьми железный противень, поставь его железной стеной между собой и городом и повернись к нему лицом. Он будет осажден, а ты осаждай его. Это будет знамением дому Израиля.

4Ты же ляг на левый бок и возложи на себя4:4 Или: «на него». грех4:4 Или: «наказание»; также в ст. 5, 6. дома Израиля. Неси их грех столько дней, сколько будешь лежать на боку. 5Я определил тебе столько дней, сколько лет они грешили: триста девяносто дней ты будешь нести грех дома Израиля. 6Когда исполнишь это, ляг снова, но теперь на правый бок, и неси грех дома Иуды. Я определил тебе сорок дней, по дню за каждый год4:6 Нет точных данных о том, к какому историческому периоду относятся упомянутые числа и годы. Они могут относиться к периоду завоевания Ассирией или Вавилоном, к периоду завоевания израильтян другими народами, либо к другим периодам.. 7Обрати лицо и обнаженную руку к осажденному Иерусалиму и пророчествуй против него. 8Смотри, Я налагаю на тебя путы, чтобы ты не мог перевернуться с одного бока на другой, пока не окончишь дней осады.

9Возьми пшеницу и ячмень, фасоль и чечевицу, просо и полбу, положи в один сосуд и сделай себе хлеб. Ты будешь есть его те триста девяносто дней, что будешь лежать на боку. 10Отвесь двадцать шекелей4:10 Около 0,2 кг. пищи, чтобы съедать каждый день, и ешь ее в установленное время. 11Также отмерь шестую часть гина4:11 Около 0,6 л. воды и пей в установленное время. 12Ешь пищу, как ячменные лепешки; пеки их на глазах у людей на человеческом кале, – 13сказал Господь. – Вот так народ Израиля будет есть оскверненную пищу среди тех народов, к которым Я их изгоню.

14Тогда я сказал:

– О нет, Владыка Господи! Я никогда не осквернялся4:14 См. Втор. 23:12-14. Израильтяне должны были закапывать человеческий кал за городом или лагерем, им было запрещено использовать его как топливо.. С юности и до сегодняшнего дня я никогда не ел ни мертвечины, ни растерзанного диким зверем. Нечистое мясо не входило в мои уста.

15– Хорошо, – сказал Он, – Я позволяю тебе печь твой хлеб на коровьем навозе, вместо человеческого кала.

16Потом Он сказал мне:

– Сын человеческий, Я уничтожу запасы пищи в Иерусалиме. Народ будет есть свою часть еды в тревоге и пить свою часть воды в ужасе, 17потому что пищи и воды не будет хватать. Они будут ужасаться при виде друг друга, и угасать из-за своего греха4:17 Или: «в своем грехе»..