Esekiẹli 28 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 28:1-26

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí ọba Tire

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 228.2: Da 11.36; 2Tẹ 2.4; If 13.5.“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ọmọ-aládé Tire pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Nítorí tí ọkàn rẹ gbé sókè sí mi,

ìwọ wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run;

Èmi jókòó sí orí ìtẹ́ òrìṣà,

ní àárín gbùngbùn Òkun.”

Ṣùgbọ́n ènìyàn ni ọ́, kì i ṣe òrìṣà,

bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ rò pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.

3Ìwọ gbọ́n ju Daniẹli lọ bí?

Ṣé kò sí àṣírí kan tí ó pamọ́ fún ọ?

4Pẹ̀lú ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ,

ìwọ tí jèrè ọrọ̀ fún ara rẹ,

àti àkójọpọ̀ wúrà àti fàdákà,

nínú àwọn ilé ìṣúra rẹ.

5Nípa ọgbọ́n rẹ ńlá àti nípa òwò rẹ,

ìwọ ti sọ ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,

àti nítorí ọrọ̀ rẹ di púpọ̀,

ọkàn rẹ gbé sókè,

nítorí ọrọ̀ rẹ.

6“ ‘Nítorí náà èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Nítorí pé ìwọ rò pé o gbọ́n,

pé ìwọ gbọ́n bí Ọlọ́run.

7Èmi yóò mú kí àwọn àjèjì dìde sí ọ,

ẹlẹ́rù nínú àwọn orílẹ̀-èdè;

wọn yóò yọ idà wọn sí ọ,

ẹwà rẹ àti ọgbọ́n rẹ,

wọn yóò sì ba dídán rẹ̀ jẹ́.

8Wọn yóò mú ọ sọ̀kalẹ̀ wá sínú ihò,

ìwọ yóò sì kú ikú gbígbóná,

àwọn tí a pa ní àárín Òkun.

9Ṣé ìwọ yóò wá wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run,”

ní ojú àwọn tí ó pa ọ́?

Ìwọ yóò jẹ́ ènìyàn, kì í ṣe Ọlọ́run,

ní ọwọ́ àwọn ti yóò pa ọ́.

10Ìwọ yóò kú ikú aláìkọlà,

ní ọwọ́ àwọn àjèjì.

Èmi ni ó ti sọ ọ́, ní Olúwa Olódùmarè wí.’ ”

11Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 12“Ọmọ ènìyàn, pohùnréré ẹkún sórí ọba Tire kí ó sì sọ fún un pé: ‘Èyí yìí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ ìjẹ́pípé náà,

o kún fún ọgbọ́n,

o sì pé ní ẹwà.

13Ìwọ ti wà ní Edeni, ọgbà Ọlọ́run;

onírúurú òkúta oníyebíye ni ìbora rẹ;

sardiu, topasi àti diamọndi, berili, óníkìsì,

àti jasperi, safire, emeradi,

turikuose, àti karbunkili, àti wúrà,

ìpilẹ̀ṣẹ̀ rẹ àti àwọn òkè rẹ ní a dà,

láti ara wúrà,

ní ọjọ́ tí á dá ọ ní a pèsè wọn.

14A fi àmì òróró yàn ọ́ gẹ́gẹ́ bí olùtọ́jú kérúbù,

torí èyí ni mo fi yàn ọ́.

Ìwọ wà lórí òkè mímọ́ Ọlọ́run;

ìwọ rìn ni àárín òkúta a mú bí iná.

15Ìwọ pé ní ọ̀nà rẹ,

láti ọjọ́ tí a ti dá ọ,

títí a fi rí àìṣedéédéé ní inú rẹ.

16Nípa ìtànkálẹ̀ òwò rẹ,

ìwọ kún fún ìwà ipá;

ìwọ sì dẹ́ṣẹ̀.

Nítorí náà ni mo ṣe sọ ọ nù,

bí ohun àìlọ́wọ̀ kúrò lórí òkè Ọlọ́run.

Èmi sì pa ọ run,

ìwọ kérúbù, tí ó bọ́ kúrò ní àárín òkúta a mú bí iná.

17Ọkàn rẹ gbéraga,

nítorí ẹwà rẹ.

Ìwọ sì ba ọgbọ́n rẹ jẹ́,

nítorí dídára rẹ.

Nítorí náà mo le ọ sórí ayé;

mo sọ ọ di awòojú níwájú àwọn ọba.

18Nípa ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ rẹ àti òwò àìṣòótọ́ rẹ,

ìwọ ti ba àwọn ibi mímọ́ rẹ jẹ́.

Nítorí náà mo mú kí iná jáde wá,

láti inú rẹ, yóò sì jó ọ run,

èmi yóò sì sọ ọ́ di eérú lórí ilẹ̀,

lójú gbogbo àwọn tí ó ń wò ọ́.

19Gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó mọ̀ ọ́n,

ní ẹnu ń yà sí ọ;

ìwọ yóò sì jẹ́ ẹ̀rù,

ìwọ kì yóò sì ṣí mọ́ láéláé.’ ”

Àsọtẹ́lẹ̀ òdì sí Sidoni

2028.20-26: Jl 3.4-8; Sk 9.2.Ọ̀rọ̀ Olúwa tún tọ̀ mí wá wí pé: 21“Ọmọ ènìyàn, kọ ojú sí Sidoni; kí o sì sọtẹ́lẹ̀ sí i, 22kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí:

“ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni,

a ó sì ṣe mí lógo láàrín rẹ.

Wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa,

nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ,

tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ.

23Èmi yóò sì rán àjàkálẹ̀-ààrùn sínú rẹ,

èmi yóò sì mú kí ẹ̀jẹ̀ sàn ní ìgboro rẹ,

ẹni ti á pa yóò ṣubú ní àárín rẹ,

pẹ̀lú idà lára rẹ ní gbogbo ẹ̀gbẹ́,

nígbà náà wọn yóò mọ̀ wí pé èmi ni Olúwa.

24“ ‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.

25“ ‘Èyí yìí ní Olúwa Olódùmarè wí: Nígbà tí èmi yóò bá sa àwọn ènìyàn Israẹli jọ kúrò ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fọ́nká sí, tí a ó sì yà mí sí mímọ́ láàrín wọn lójú àwọn aláìkọlà. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ní ilẹ̀ àwọn tìkálára wọn, èyí tí mo fún ìránṣẹ́ mi Jakọbu. 26Wọn yóò sì máa gbé ní inú rẹ̀ ní àìléwu, wọn yóò sì kọ́lé, wọn yóò sì gbin ọgbà àjàrà; nítòótọ́ wọn yóò wà ní ìbàlẹ̀ àyà, nígbà tí èmi bá ti mú ìdájọ́ mi ṣẹ̀ sí ara àwọn tí ń ṣátá wọn ní gbogbo àyíká wọn. Nígbà náà ni wọn yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.’ ”

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

以西结书 28:1-26

预言审判泰尔王

1耶和华对我说: 2“人子啊,你去告诉泰尔王,主耶和华这样说,

“‘你心里高傲,说,我是神,

我坐在海中神的宝座上。

你虽然自以为像神,

但事实上你不是神,不过是人。

3看啊,你比但以理更有智慧,

什么秘密都瞒不过你。

4你凭智慧和头脑发了财,

金银装满了你的库房。

5你靠高超的经商本领使财富大增,

因而变得心高气傲。

6因此,主耶和华说,

因为你自以为像神,

7我要使列国中最残暴的外族人来攻打你,

拔刀毁坏你凭智慧得来的美物,

玷污你的荣美,

8使你坠入坟墓,

你必惨死在大海中。

9在杀戮你的人面前,

你还能自称为神吗?

在杀你的人手中,

你不过是人,不是神。

10你要像未受割礼的人那样死在外族人手中。’

这是主耶和华说的。”

泰尔王的终局

11耶和华对我说: 12“人子啊,你要为泰尔王唱哀歌,告诉他,主耶和华这样说,

“‘你曾经是完美的典范,

充满智慧,美丽无瑕。

13你曾在上帝的伊甸园中,

你曾佩戴各种宝石,

有红宝石、黄玉、钻石、

绿宝石、红玛瑙、碧玉、

蓝宝石、绿松石、翡翠,

还镶嵌着精美的黄金,

这些在你受造的那天都已经预备妥当。

14我膏立你为看守约柜的基路伯天使。

你在上帝的圣山上,

在闪闪发光的宝石中行走。

15你从受造那天开始所行的纯全无过,

但后来在你那里查出不义。

16因为贸易发达,

你便充满暴力,犯罪作恶。

因此,看守约柜的基路伯天使啊,

我把你当作污秽之物逐出我的山,

从闪闪发光的宝石中除掉你。

17你因俊美而心高气傲,

因辉煌而心智败坏,

所以我把你扔到地上,

让你在列国的君王面前出丑。

18你多行不义,

交易不公,

亵渎了你的圣所,

因此我要用火烧你,

在众目睽睽之下把你烧成灰烬。

19所有认识你的民族都因你而惊骇,

你那可怕的末日来临了,

你将永远不复存在。’”

预言审判西顿

20耶和华对我说: 21“人子啊,你要说预言斥责西顿22告诉她,主耶和华这样说,

“‘西顿啊,我要与你为敌,

我要在你身上得到荣耀。

我要审判你,彰显我的圣洁,

人们就知道我是耶和华。

23我要使瘟疫进入你境内,

刀剑从四面八方临到你,

被杀的人横尸城中,血流街头,

这样人们就知道我是耶和华。

24“‘藐视以色列人的邻邦必不再作刺他们的荆棘,伤他们的蒺藜,这样人们就知道我是主耶和华。’

25“主耶和华说,‘我要把分散到列国的以色列人招聚起来,当着列国的面在他们身上彰显我的圣洁,那时他们要回到我赐给我仆人雅各的地方居住。 26他们将在那里安然居住,兴建房屋,栽种葡萄园。我审判鄙视他们的四邻后,他们必安然居住。这样,他们便知道我是他们的上帝耶和华。’”