Esekiẹli 22 – YCB & CARSA

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 22:1-31

Àwọn ẹsẹ̀ Jerusalẹmu

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá:

2“Ọmọ ènìyàn ǹjẹ́ ìwọ yóò ha ṣe ìdájọ́ rẹ̀? Ǹjẹ́ ìwọ ha ṣe ìdájọ́ ìlú atàjẹ̀sílẹ̀? Tó bá rí bẹ́ẹ̀ dojúkọ wọn pẹ̀lú gbogbo ìwà ìríra wọn. 3Kí ó sì wí pé, ‘Èyí yìí ní ohun tí Olúwa Olódùmarè wí: Ìwọ ìlú ńlá tí ó mú ìparun wá sórí ara rẹ nípa títàjẹ̀sílẹ̀ ní àárín rẹ, tí ó sì ba ara rẹ̀ jẹ́ nípa ṣíṣe àwọn ère. 4Ìwọ ti jẹ̀bi nítorí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀, àti pé àwọn ère tí ó ṣe tí bà ọ́ jẹ́. Ìwọ tí mú ọjọ́ rẹ súnmọ́ tòsí, ìparí àwọn ọdún rẹ sì ti dé. Nítorí náà èmi yóò fi ọ ṣe ohun ẹ̀gàn lójú àwọn orílẹ̀-èdè àti ohun ẹ̀sín lójú gbogbo ìlú. 5Àwọn tí ó wà ní tòsí àti àwọn tí ó jìnnà sí ọ, yóò fi ọ ṣe ẹlẹ́yà, ìwọ ìlú ẹlẹ́gàn, tí ó kún fún làálàá.

6“ ‘Wo bí ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin ọba Israẹli tí ó wà nínú yín ti ń lo agbára rẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀. 7Nínú rẹ wọn ti hùwà sí baba àti ìyá pẹ̀lú ìfojú tínrín; nínú rẹ wọn ti ni àwọn àlejò lára, wọn sì hùwàkiwà sí aláìní baba àti opó. 8Ìwọ tí kọ àwọn ohun mímọ́ mi sílẹ̀, ìwọ sì ti lo ọjọ́ ìsinmi mi ní ìlòkulò. 9Nínú rẹ ni àwọn ayannijẹ ènìyàn pinnu láti tàjẹ̀ sílẹ̀; nínú rẹ ní àwọn tí ó ń jẹun ní orí òkè ojúbọ òrìṣà, wọn sì hùwà ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́. 10Nínú rẹ ní àwọn ti kò bu ọlá fún àwọn àkéte baba wọn; nínú rẹ ni àwọn tí o ń bá àwọn obìnrin lò nígbà tí wọ́n ń ṣe àkókò lọ́wọ́, ní àsìkò tí a ka wọn sì aláìmọ́. 11Nínú rẹ ọkùnrin kan ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ìríra pẹ̀lú aya aládùúgbò rẹ̀, òmíràn bá ìyàwó ọmọ rẹ̀ jẹ́, òmíràn sì bá arábìnrin rẹ̀ lòpọ̀ èyí tí í ṣe ọbàkan rẹ̀. 1222.12: Ek 23.8; De 16.19; Ek 22.25; Le 25.36,37; De 23.19.Nínú rẹ àwọn ènìyàn gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti tàjẹ̀ sílẹ̀; ìwọ gba èlé ìlọ́po láti mú aláìṣòótọ́ jèrè láti ara aládùúgbò rẹ nípa ìrẹ́jẹ. Ìwọ sì ti gbàgbé èmi; ni Olúwa Olódùmarè wí.

13“ ‘Èmi yóò kúkú pàtẹ́wọ́ lórí èrè àìmọ̀ tí ìwọ ti jẹ, àti lórí ẹ̀jẹ̀ tí ìwọ ti ta sílẹ̀ ní àárín yín. 14Ọkàn rẹ le gbà á, tàbí ọwọ́ rẹ lè le, ní ọjọ́ tí èmi yóò bá ọ ṣé? Èmi Olúwa ti sọ̀rọ̀, Èmi yóò sì ṣe é. 15Èmi yóò tú yin ká ní àárín àwọn orílẹ̀-èdè, èmi yóò fọ́n ọ ká sí àwọn ìlú; èmi yóò sì fi òpin sí àìmọ́ rẹ. 16Nígbà tí a ó bà ọ́ jẹ́ lójú àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”

17Nígbà náà ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá: 18“Ọmọ ènìyàn, ilé Israẹli ti di ìdàrọ́ sí mi; gbogbo wọn jẹ́ bàbà, idẹ, irin àti òjé ti a fi sínú iná ìléru. Wọn jẹ́ ìdàrọ́ ti fàdákà. 19Nítorí náà èyí yìí ni ohun ti Olúwa Olódùmarè wí: ‘Nítorí tí ìwọ ti di ìdàrọ́, èmi yóò kó yín jọ sí Jerusalẹmu. 20Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn ṣe ń kó fàdákà, bàbà, irin, òjé àti idẹ jọ sínú iná ìléru láti fi iná yọ́ ọ, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò kó ọ jọ ní ìbínú àti ìrunú mi, èmi yóò sì fi ọ sì àárín ìlú, èmi yóò sì yọ́ ọ. Níbẹ̀ ní ìwọ yóò sì ti yọ́. 21Èmi yóò kó yín jọ, èmi o sì fín iná ìbínú mi si yin lára, ẹ o si di yíyọ́ láàrín rẹ̀. 22Bí a ti ń yọ́ fàdákà nínú iná ìléru bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ní ìwọ yóò ṣe yọ́ nínú rẹ̀, ìwọ yóò sì mọ̀ wí pé, Èmi Olúwa ti tú ìbínú mi sórí rẹ.’ ”

23Lẹ́ẹ̀kan sí i ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé, 24“Ọmọ ènìyàn, sọ fún ilẹ̀ náà, ‘Ìwọ ní ilẹ̀ tí kò gbá mọ́, ti kò sì rọ òjò tàbí ìrì ní àkókò ìbínú.’ 25Ìdìtẹ̀ sì wà láàrín àwọn ọmọ-aládé inú rẹ̀, tó dàbí bíbú kìnnìún tó ń fà ẹran ya, wọ́n ń ba àwọn ènìyàn jẹ́, wọ́n ń kó ìṣúra àti àwọn ohun iyebíye wọ́n sì ń sọ púpọ̀ di opó nínú rẹ̀. 26Àwọn àlùfáà rẹ̀ ti rú òfin mi, wọn si ti sọ ohun mímọ́ mi di àìlọ́wọ̀: wọn kò fi ìyàtọ̀ sáàrín ohun mímọ́ àti àìlọ́wọ̀, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fi ìyàtọ̀ hàn láàrín ohun àìmọ́, àti mímọ́, wọn sì ti fi ojú wọn pamọ́ kúrò ní ọjọ́ ìsinmi mi, mó sì dí ẹni àìlọ́wọ̀ láàrín wọn. 27Àwọn ọmọ-aládé àárín rẹ̀ dàbí ìkookò ti ń ṣọdẹ, láti tàjẹ̀ sílẹ̀, láti pa ọkàn run, láti jèrè àìṣòótọ́. 28Àti àwọn wòlíì rẹ́ ti ṣẹ̀tàn sí wọn, wọn ń rì ìran asán, wọn sì ń fọ àfọ̀ṣẹ èké sí wọn, wí pé, ‘Báyìí ní Olúwa Olódùmarè wí,’ nígbà tí ó ṣépè Olúwa kò sọ̀rọ̀. 29Àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà, tí lo ìwà ìninilára, wọn sì já olè, wọn sì ni àwọn tálákà àti aláìní lára; nítòótọ́, wọn tí ní àlejò lára láìnídìí. Kò sì ṣí ìdájọ́ òdodo.

30“Èmi si wá ẹnìkan láàrín wọn, tí ìbá tún odi náà mọ́, tí ìbá dúró ní ibi tí ó ya náà níwájú mi fún ilẹ̀ náà, kí èmi má bá à parun: ṣùgbọ́n èmi kò rí ẹnìkan. 31Nítorí náà ni mo ṣe da ìbínú mi sí wọn lórí, mo ti fi iná ìbínú mi run wọn, mo si ti fi ọ̀nà wọn gbẹ̀san lórí ara wọn, ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

Езекиил 22:1-31

Грехи Иерусалима

1Было ко мне слово Вечного:

2– Смертный, будешь ли судить его? Будешь ли судить этот кровавый город? Тогда укажи ему на все его омерзительные обычаи 3и скажи: Так говорит Владыка Вечный: «О город, который, навлекая кару, проливает посреди себя кровь и оскверняется, делая идолов, 4ты стал виновен из-за крови, которую пролил, и осквернился идолами, которых сделал; ты приблизил свой день, и предел твоих лет настал. За это Я сделаю тебя поруганием для народов и посмешищем для всех стран. 5Те, кто далеко, и те, кто близко, будут глумиться над тобой, о бесславный город, объятый смутой.

6Вожди Исраила, что у тебя, – каждый по мере своих сил – проливали чужую кровь. 7У тебя они с презрением обходились с отцами и матерями, у тебя притесняли чужеземцев, у тебя творили зло сиротам и вдовам. 8Ты пренебрегал Моими святынями и осквернял Мои субботы. 9У тебя клеветники проливали чужую кровь; у тебя находились те, кто ел в горных капищах, и посреди тебя совершались непристойности. 10У тебя находились те, кто осквернял отцовское ложе; у тебя – те, кто принуждал женщину к совокуплению во время месячных, когда она ритуально нечиста. 11У тебя один совершал гнусное, спал с женой другого, второй бесстыдно осквернял сноху, а третий насиловал свою сестру по отцу. 12У тебя брали взятки, чтобы лить чужую кровь; ты занимался ростовщичеством, брал проценты и вымогательством наживался на ближнем. Ты оставил Меня, – возвещает Владыка Вечный.

13Гляди, Я всплесну руками о твоей неправедной наживе, которую ты приобрёл, и о крови, которую ты пролил посреди себя. 14Останешься ли ты храбрым и останутся ли сильными твои руки в те дни, когда Я буду наказывать тебя? Я, Вечный, сказал это и сделаю. 15Я рассею тебя между народами и раскидаю по странам; Я искореню в тебе твою нечистоту. 16Ты будешь осквернён в глазах других народов. Тогда ты узнаешь, что Я – Вечный».

17И было ко мне слово Вечного:

18– Смертный, исраильтяне стали у Меня бесполезной окалиной; все они – как медь, олово, железо и свинец, которые остаются в плавильном горне как изгарь серебра.

19Поэтому так говорит Владыка Вечный:

– Так как вы стали окалиной, Я соберу вас в Иерусалиме. 20Как собирают в плавильный горн серебро, медь, железо, свинец и олово, чтобы, раздув огонь, расплавить их, так и Я соберу вас в гневе и ярости, оставлю в городе и расплавлю. 21Я соберу вас, дохну на вас Моим огненным гневом, и вы расплавитесь в нём. 22Как серебро расплавляется в плавильном горне, так и вы расплавитесь в нём. Тогда вы узнаете, что Я, Вечный, излил на вас Свою ярость.

23Вновь было ко мне слово Вечного:

24– Смертный, скажи земле: «Ты – земля, неочищенная и неорошённая в день гнева». 25Её вожди подобны22:25 Или: «Заговор твоих пророков подобен». ревущему льву, что терзает добычу; они пожирают людей, отнимают сокровища и драгоценности и многих на ней делают вдовами. 26Её священнослужители преступают Мой Закон и оскверняют Мои святыни; они не делают различия между священным и несвященным; они учат, что нет разницы между нечистым и чистым; они закрывают глаза на соблюдение Моих суббот, так что Я оскверняюсь среди них. 27Её вельможи подобны волкам, терзающим добычу; они проливают кровь и убивают людей, чтобы приобрести неправедную поживу. 28Её пророки закрашивают для них такие дела белилами пустых видений и лживых прорицаний. Они говорят: «Так говорит Владыка Вечный», когда Вечный не говорил. 29Народ страны предан вымогательству и грабежу; они притесняют бедняков и нищих и угнетают чужеземцев, отказывая им в правосудии.

30Я искал среди них человека, который починил бы стену и встал бы предо Мною в бреши заступиться за страну, чтобы Мне её не погубить, но не нашёл. 31И вот Я изолью на них Мою ярость и истреблю их пламенем Моего негодования, обрушив им на головы то, что они натворили, – возвещает Владыка Вечный.