Esekiẹli 13 – YCB & NIRV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 13:1-23

Wòlíì èké gba ìdálẹ́bi

1Ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ mí wá wí pé: 2“Ọmọ ènìyàn sọtẹ́lẹ̀ lòdì sí àwọn wòlíì Israẹli tó ń sọtẹ́lẹ̀, kí o sì sọ fún àwọn tí ń sọtẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn, ‘Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa! 3Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: Ègbé ni fún àwọn aṣiwèrè wòlíì tó ń tẹ̀lé ẹ̀mí ara wọn tí wọn kò sì rí nǹkan kan! 4Israẹli àwọn wòlíì rẹ dàbí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ nínú pápá. 5Ẹ̀yin kò gòkè láti mọ odi tí ó ya ní ilé Israẹli kí wọ́n ba lè dúró gbọin ní ojú ogun ní ọjọ́ Olúwa. 6Ìran àti àfọ̀ṣẹ wọn jẹ́ èké. Wọ́n wí pé, “Olúwa wí,” nígbà tí Olúwa kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n fẹ́ kí Olúwa mú ọ̀rọ̀ wọn ṣẹ. 7Ẹ̀yin kò ha ti rí ìran asán, ẹ̀yin kò ha ti fọ àfọ̀ṣẹ èké, nígbà tí ẹ̀yin sọ pé, “Olúwa wí,” bẹ́ẹ̀ sì ni Èmi kò sọ̀rọ̀?

8“ ‘Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, Nítorí ọ̀rọ̀ asán àti ìran èké yín, mo lòdì sí yín: ni Olúwa Olódùmarè wí. 9Ọwọ́ mi yóò sì wà lórí àwọn wòlíì tó ń ríran asán, tó sì ń sọ àfọ̀ṣẹ èké. Wọn kò ní sí nínú ìjọ àwọn ènìyàn mi, a ó sì yọ orúkọ wọn kúrò nínú àkọsílẹ̀ ilé Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì ní wọ ilẹ̀ Israẹli mọ́. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa Olódùmarè.

10“ ‘Wọ́n ti mú àwọn ènìyàn mi ṣìnà, wọ́n ní, “Àlàáfíà,” nígbà tí kò sí àlàáfíà, nítorí pé bí àwọn ènìyàn bá mọ odi fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́, wọn a fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, wọn ó sì fi ẹfun kùn ún, 11nítorí náà, sọ fún àwọn tí ń fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ àti àwọn tó fi ẹfun kùn ún pé, odi náà yóò wó, ìkún omi òjò yóò dé, Èmi yóò sì rán òkúta yìnyín sọ̀kalẹ̀, ìjì líle yóò ya á lulẹ̀. 12Nígbà tí odi náà bá sì wó, ǹjẹ́ àwọn ènìyàn wọn kò níbi yín pé, “Rírẹ́ tí ẹ rẹ́ ẹ dà, ibo sì ni ẹfun tí ẹ fi kùn ún wà?”

13“ ‘Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí, Nínú ìbínú gbígbóná mi, èmi yóò tu afẹ́fẹ́ líle lé e lórí nínú ìrunú mi, àti nínú ìbínú mi, òjò yóò sì rọ̀ púpọ̀ nínú ìbínú mi, àti yìnyín ńlá nínú ìrunú mi láti pa wọ́n run. 14Èmi yóò wó ògiri tí ẹ fi amọ̀ àìpò rẹ́, èyí tí ẹ fi ẹfun kùn lulẹ̀ dé bi pé ìpìlẹ̀ rẹ yóò hàn jáde. Nígbà ti odi náà wó palẹ̀, a ó sì run yín sínú rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa. 15Báyìí ni Èmi yóò ṣe lo ìbínú mi lórí odi yìí àti àwọn to fi amọ̀ àìpò rẹ́ ẹ, tí wọ́n sì fi ẹfun kùn ún. Èmi yóò sì sọ fún yín pé, “Kò sí odi mọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwọn tó rẹ́ ẹ náà kò sí mọ́. 16Àwọn wòlíì Israẹli tí ń sọtẹ́lẹ̀ sí Jerusalẹmu, tí wọn ríran àlàáfíà sí i nígbà ti kò sì àlàáfíà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí.” ’

17“Nísinsin yìí, ọmọ ènìyàn, dojúkọ àwọn ọmọbìnrin ènìyàn rẹ tí wọ́n ń sọtẹ́lẹ̀ láti inú èrò ọkàn wọn, sọtẹ́lẹ̀ sí wọn 18wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí. Ègbé ni fún ẹ̀yin obìnrin tí ẹ ń rán ìfúnpá òògùn sí ìgbọ̀nwọ́ àwọn ènìyàn, tí ẹ ń ṣe ìbòjú oríṣìíríṣìí fún orí oníkálùkù ènìyàn láti ṣọdẹ ọkàn wọn. Ẹ̀yin yóò wa dẹkùn fún ọkàn àwọn ènìyàn mi bí? Ẹ̀yin yóò sì gba ọkàn ti ó tọ̀ yín wá là bí? 19Nítorí ẹ̀kúnwọ́ ọkà barle àti òkèlè oúnjẹ. Ẹ ti pa àwọn tí kò yẹ kí ẹ pa, ẹ sì fi àwọn tí kò yẹ kó wà láààyè sílẹ̀ nípa irọ́ tí ẹ ń pa fún àwọn ènìyàn mi, èyí tí àwọn náà ń fetí sí.

20“ ‘Nítorí náà, báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí. Mo lòdì sí ìfúnpá òògùn tí ẹ fi ń ṣọdẹ ọkàn ènìyàn káàkiri bí ẹyẹ, Èmi yóò ya á kúrò lápá yín, Èmi yóò sì dá ọkàn àwọn ènìyàn tí ẹ ń ṣọdẹ sílẹ̀. 21Èmi yóò ya àwọn ìbòjú yín, láti gba àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́ yín, wọn kò sì ní jẹ́ ìjẹ fún yín mọ́. Nígbà náà ni ẹ̀yin yóò mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa. 22Nítorí pé ẹ̀yin ti ba ọkàn àwọn olódodo jẹ́ pẹ̀lú irọ́ yín, nígbà tí Èmi kò mú ìbànújẹ́ bá wọn, àti nítorí ẹ̀yin ti mú ọkàn àwọn ènìyàn búburú le, kí wọ́n má ba à kúrò nínú ọ̀nà ibi wọn dé bi tí wọn yóò fi gba ẹ̀mí wọn là, 23nítorí èyí, ẹ̀yin kò ní í ríran èké, ẹ̀yin kò sì ní fọ àfọ̀ṣẹ mọ́. Èmi yóò gba àwọn ènìyàn mi lọ́wọ́ yín. Ẹ̀yin yóò sì mọ̀ pé, Èmi ni Olúwa.’ ”

New International Reader’s Version

Ezekiel 13:1-23

The Lord Punishes Those Who Pretend to Be True Prophets

1A message from the Lord came to me. The Lord said, 2“Son of man, prophesy against those who are now prophesying in Israel. What they prophesy comes out of their own minds. Tell them, ‘Listen to the Lord’s message! 3The Lord and King says, “How terrible it will be for you foolish prophets! You say what your own minds tell you to. Your visions do not come from me. 4Israel, your prophets are like wild dogs that live among broken-down buildings. 5You have not repaired the cracks in the city wall for the people of Israel. So it will not stand firm in the battle on the day I judge you. 6The visions of those prophets are false. They use magic to try to find out what is going to happen. But their magic tricks are lies. They say, ‘The Lord announces.’ But I have not sent them. In spite of that, they expect him to make their words come true. 7You prophets have seen false visions. You have used magic to try to find out what is going to happen. But your magic tricks are lies. So you lied when you said, ‘The Lord announces.’ I did not even speak to you at all.”

8“ ‘The Lord and King says, “I am against you prophets. Your messages are false. Your visions do not come true,” announces the Lord and King. 9“Israel, my power will be against the prophets who see false visions. Their magic tricks are lies. They will not be among the leaders of my people. They will not be listed in the records of Israel. In fact, they will not even enter the land. Then you will know that I am the Lord and King.

10“ ‘ “They lead my people away from me. They say, ‘Peace.’ But there isn’t any peace. They are like people who build a weak wall. They try to cover up the weakness by painting the wall white. 11Tell those who do this that their wall is going to fall. Heavy rains will come. I will send hailstones crashing down. Powerful winds will blow. 12The wall will fall down. Then people will ask them, ‘Now where is the paint you covered it with?’ ”

13“ ‘So the Lord and King speaks. He says, “When I am very angry, I will send a powerful wind. Hailstones and heavy rains will come. They will fall with great force. 14I will tear down the wall you prophets painted over. I will knock it down. The only thing left will be its foundation. When it falls, you will be destroyed along with it. Then you will know that I am the Lord. 15So I will pour out all my great anger on the wall. I will also send it against you prophets who painted it. I will say to you, ‘The wall is gone. You who painted it will be gone too. 16You prophets of Israel prophesied to Jerusalem. You saw visions of peace for its people. But there wasn’t any peace,’ announces the Lord and King.” ’

17“Son of man, turn your attention to the daughters of your people. What they prophesy comes out of their own minds. So prophesy against them. 18Tell them, ‘Here is what the Lord and King says. “How terrible it will be for you women who sew magic charms to put around your wrists! You make veils of different lengths to put on your heads. You do these things to trap people. You trap my people. But you will also be trapped. 19You have treated me as if I were not holy. You did it among my very own people. You did it for a few handfuls of barley and scraps of bread. You told lies to my people. They like to listen to lies. You killed those who should have lived. And you spared those who should have died.”

20“ ‘So the Lord and King says, “I am against your magic charms. You use them to trap people as if they were birds. I will tear them off your arms. I will set free the people you trap like birds. 21I will tear your veils off your heads. I will save my people from your power. They will no longer be under your control. Then you will know that I am the Lord. 22I had not made godly people sad. But when you told them lies, you made them lose all hope. You advised sinful people not to turn from their evil ways. You did not want them to save their lives. 23So you will never see false visions again. You will not use your magic tricks anymore. I will save my people from your power. Then you will know that I am the Lord.” ’ ”