Esekiẹli 48 – YCB & HLGN

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Esekiẹli 48:1-35

Pínpín ilẹ̀ náà

1“Ìwọ̀nyí ni àwọn ẹ̀yà tí a kọ sílẹ̀ pẹ̀lú orúkọ wọn:

“Ní òpin àríwá, Dani yóò ni ìpín kan; èyí yóò tẹ̀lé ọ̀nà Hetiloni lọ sí Lebo-Hamati; Hasari-Enani àti ààlà àríwá tí Damasku tí ó kángun sí Hamati yóò jẹ́ ara ààlà rẹ̀ láti ìhà ìlà-oòrùn títí lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn.

2Aṣeri yóò ní ìpín kan; yóò jẹ́ ààlà agbègbè Dani láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

3Naftali yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Aṣeri láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

4Manase yóò ní ìpín; èyí yóò jẹ́ ààlà ti agbègbè Naftali láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.

5Efraimu yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Manase láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

6Reubeni yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Efraimu láti ìlà-oòrùn títí dé ìwọ̀-oòrùn.

7Juda yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Reubeni láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

8“Ní agbègbè Juda, láti ìhà ìlà-oòrùn dé ìhà ìwọ̀-oòrùn ni yóò jẹ́ ìpín tí ìwọ yóò gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì. Èyí tí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ìgbọ̀nwọ́ (25,000) ní ìbú, gígùn rẹ̀ láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn yóò jẹ́ bákan náà bí ọ̀kan nínú àwọn ìpín ìyókù; láti ìhà ìlà-oòrùn dé ìhà ìwọ̀-oòrùn, ibi mímọ́ yóò sì wà ní àárín gbùngbùn rẹ̀.

9“Ìpín pàtàkì tí ìwọ yóò fi fún Olúwa yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú. 10Èyí yóò jẹ́ ìpín ibi mímọ́ fún àwọn àlùfáà. Èyí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn ní ìhà àríwá, ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn, ó sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn ní ìhà gúúsù. Ní àárín gbùngbùn rẹ̀ ní ilé fún Olúwa yóò wà. 11Èyí yóò wà fún àwọn àlùfáà tí a yà sí mímọ́, àwọn ọmọ Sadoku tí wọn jẹ́ olóòtítọ́ nínú sí sìn mí, tiwọn kò sì ṣáko lọ bí ti àwọn Lefi ṣe ṣe nígbà tí àwọn Israẹli ṣáko lọ. 12Èyí yóò jẹ́ ọrẹ pàtàkì fún wọn láti ara ìpín ibi mímọ́ ilẹ̀ náà, ìpín tí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ, tí ó jẹ́ ààlà agbègbè àwọn Lefi.

13“Ní àkọjúsí agbègbè àwọn àlùfáà, àwọn Lefi yóò pín ìpín kan tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ìbú. Gígùn rẹ̀ ní àpapọ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́, àti inú rẹ̀ yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́. 14Wọn kò gbọdọ̀ tà tàbí pààrọ̀ ọ̀kankan nínú rẹ̀. Èyí yìí ni ó dára jùlọ lára ilẹ̀ náà, a kò sì gbọdọ̀ fi fún ẹlòmíràn nítorí pé ó jẹ́ mímọ́ fún Olúwa.

15“Agbègbè tí o ṣẹ́kù, tí ń ṣe ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìbú àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, yóò jẹ́ ibi àìmọ́ fun ìlú ńlá náà fún ilé gbígbé àti fún agbègbè. Ìlú ńlá náà yóò wà ní àárín rẹ̀, 1648.16: If 21.16.ìwọ̀nyí sì níbi a ṣe wọ́n ọ́n: ní ìhà àríwá ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ni ìhà gúúsù ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́, ní ìhà ìlà-oòrùn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ àti ní ìhà ìwọ̀-oòrùn ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́. 17Ilẹ̀ ìjẹ fún àwọn ẹran ọ̀sìn fún ìlú ńlá náà yóò jẹ igba àti àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà gúúsù, ìgbà àti ìgbà pẹ̀lú àádọ́ta (250) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀-oòrùn. 18Èyí tí ó kù ní agbègbè náà, tí ó jẹ́ àkọjúsí ìpín ibi mímọ́, gígùn rẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ni ìhà ìlà-oòrùn àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá (10,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ìhà ìwọ̀-oòrùn. Ìpèsè rẹ̀ yóò fi kún oúnjẹ fún àwọn òṣìṣẹ́ ìlú ńlá náà. 19Àwọn òṣìṣẹ́ láti ìlú ńlá náà, tí ó ń dá oko níbẹ̀ yóò wá láti gbogbo àwọn ẹ̀yà Israẹli. 20Gbogbo ìpín náà yóò rí bákan náà ní ẹ̀gbẹ́ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, èyí yóò jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn pàtàkì ìwọ yóò fi ìpín ibi mímọ́ sí ẹ̀gbẹ́ kan, papọ̀ mọ́ ohun ìní ìlú ńlá náà.

21“Èyí tí ó ṣẹ́kù ni ẹ̀gbẹ́ méjèèjì agbègbè tí ó jẹ́ ìpín ibi mímọ́ àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé. Èyí yóò lọ títí dé ìhà ìlà-oòrùn láti ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25,000) ìgbọ̀nwọ́ ti ìpín ibi mímọ́ títí dé ààlà ìlà-oòrùn. Agbègbè méjèèjì wọ̀nyí ni gígùn àwọn ìpín ẹlẹ́yàmẹ́yà yóò jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé, àti ìpín ibi mímọ́ pẹ̀lú tẹmpili yóò wa ní àárín wọn. 22Ilẹ̀ ìní àwọn Lefi àti ohun ìní ìlú ńlá náà yóò wà ni àárín agbègbè tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé. Agbègbè tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ-aládé yóò wà ní àárín ààlà tí Juda àti ààlà tí Benjamini.

23“Ní ti àwọn ẹ̀yà tí ó kù:

“Benjamini yóò ní ìpín kan; èyí yóò wà láti ìhà ìlà-oòrùn títí dé ìhà ìwọ̀-oòrùn.

24Simeoni yóò ní ìpín kan: èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Benjamini láti ìlà-oòrùn lọ sí ìwọ̀-oòrùn.

25Isakari yóò ní ìpín kan: èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Simeoni láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.

26Sebuluni yóò ní ìpín kan; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Isakari láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.

27Gadi yóò ní ìpín; èyí yóò jẹ́ ààlà agbègbè Sebuluni láti ìlà-oòrùn sí ìwọ̀-oòrùn.

28Ààlà tí gúúsù Gadi yóò dé gúúsù láti Tamari lọ sí odò Meriba Kadeṣi lẹ́yìn náà títí dé odo ti Ejibiti lọ sí Òkun ńlá.

29“Èyí ni ilẹ̀ tí ẹ̀yin yóò fi ìbò pín ní ogún fún àwọn ẹ̀yà Israẹli, wọ̀nyí sì ni ìpín wọn,” ní Olúwa Olódùmarè wí.

Àwọn ẹnu-ọ̀nà ìlú ńlá náà

30“Ìwọ̀nyí ní yóò jẹ́ ẹnu-ọ̀nà àbájáde ìlú ńlá náà:

“Bẹ̀rẹ̀ láti ìhà àríwá, ti ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, 3148.31-35: If 21.12-13.ẹnu-ọ̀nà ìlú ńlá náà ní àwa yóò fi orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli pè. Àwọn ọ̀nà mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ní ìhà àríwá ní yóò jẹ́ ọ̀nà tí Reubeni, ọ̀nà tí Juda ọ̀nà tí Lefi.

32Ní ìhà ìlà-oòrùn, èyí tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ni ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ọ̀nà Josẹfu, ọ̀nà tí Benjamini àti ọ̀nà tí Dani.

33Ní ìhà gúúsù, èyí tí wíwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lè ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ní ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ojú ọ̀nà Simeoni, ojú ọ̀nà Isakari àti ojú ọ̀nà Sebuluni.

34Ní ìhà ìwọ̀-oòrùn, èyí tí ó jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta (4,500) ìgbọ̀nwọ́ ni gígùn, ní ojú ọ̀nà mẹ́ta yóò wà: ojú ọ̀nà Gadi, ojú ọ̀nà Aṣeri àti ojú ọ̀nà Naftali.

35“Jíjìnnà rẹ̀ yípo yóò jẹ́ ẹgbàá mẹ́sàn (18,000) ìgbọ̀nwọ́.

“Orúkọ ìlú náà láti ìgbà náà yóò jẹ́: ‘Olúwa wà níbẹ̀.’ ”

Ang Pulong Sang Dios

Ezekiel 48:1-35

Ang Pagpartida sang Duta sa mga Tribo

1Amo ini ang lista sang mga tribo sang Israel kag ang mga duta nga ila batunon:

Ang duta sang tribo ni Dan ara sa aminhan. Ang dulunan sini magasugod sa Hetlon pakadto sa Lebo Hamat hasta sa Hazar Enan nga ara sa dulunan sang Damascus kag sang Hamat sa aminhan. Ang kasangkaron sang duta sang tribo ni Dan halin sa sidlangan hasta sa nakatundan sang Israel.

2Ang duta sang tribo ni Asher ara sa bagatnan sang duta sang tribo ni Dan, kag ang kasangkaron sini halin man sa sidlangan hasta sa nakatundan sang Israel.

3Ang duta sang tribo ni Naftali ara sa aminhan sang duta sang tribo ni Asher, kag ang kasangkaron sini halin man sa sidlangan hasta sa nakatundan sang Israel.

4Ang duta sang tribo ni Manase ara sa bagatnan sang duta sang tribo ni Naftali, kag ang kasangkaron sini halin man sa sidlangan hasta sa nakatundan sang Israel.

5-7Ang masunod pa nga mga duta amo ang iya sang tribo ni Efraim, ni Reuben, kag ni Juda, nga ang ila mga kasangkaron halin man sa sidlangan hasta sa nakatundan sang Israel.

8Ang duta sa aminhan sang Juda ihatag ninyo sa Ginoo bilang espesyal nga regalo. Dose ka kilometro ang kalabaon sini, kag ang kasangkaron halin man sa sidlangan hasta sa nakatundan sang Israel pareho sa mga tribo sang Israel. Ang templo patindugon sa tunga sang sini nga duta. 9Ang parte sang duta nga inyo ihatag sa Ginoo agod patindugan sang templo dose ka kilometro ang kalabaon kag lima ka kilometro ang kasangkaron. 10Ang katunga sang sini nga duta ihatag sa mga pari. Ang kalabaon sini halin sa sidlangan pakadto sa nakatundan dose ka kilometro, kag ang kasangkaron sini halin sa aminhan pakadto sa bagatnan lima ka kilometro. Sa tunga sini amo ang templo sang Ginoo. 11Ini nga duta para sa pinili nga mga pari, nga amo ang mga kaliwat ni Zadok, nga matinumanon nga nag-alagad sa akon kag wala nagbiya sa akon pareho sa ginhimo sang iban nga mga kaliwat ni Levi nga nag-upod sa mga Israelinhon nga nagbiya sa akon. 12-13Ini nga duta espesyal nga regalo para sa mga pari, kag ini ang pinakabalaan nga duta. Sa tupad sini amo ang duta nga para sa iban nga mga kaliwat ni Levi, nga dose ka kilometro ang kalabaon kag lima ka kilometro ang kasangkaron. 14Kinahanglan nga indi gid nila ini pag-ibaligya ukon pag-ibaylo bisan gamay lang nga parte sini, kay amo ini ang labing maayo nga duta kag balaan ini para sa Ginoo.

15Ang nabilin nga duta nga ang kalabaon dose ka kilometro kag ang kasangkaron duha kag tunga ka kilometro para sa publiko. Puwede ini estaran sang mga tawo kag pahalban sang ila mga sapat. Sa tunga sini amo ang banwa 16nga duha ka kilometro kuwadrado. 17Napalibutan ini sang mahawan nga lugar nga 125 ka metros kuwadrado. 18Sa guwa sang banwa may ara nga uma nga ang kalabaon lima ka kilometro pasidlangan kag lima man ka kilometro pakatundan. Ara ini sa dulunan sang balaan nga duta. Ang mga patubas sa sini nga duta para pagkaon sang mga nagaobra sa banwa. 19Ang bisan sin-o nga magaobra sa banwa halin sa nagkalain-lain nga tribo sang Israel puwede makapanguma sa sini nga duta. 20Gani ang bug-os nga duta nga inyo ihatag sa Ginoo bilang espesyal nga regalo, lakip na ang balaan nga duta kag ang banwa, dose ka kilometro kuwadrado.

21-22Ang nabilin nga mga duta, sa sidlangan kag sa nakatundan sang balaan nga duta kag sang banwa, mangin iya sang pangulo. Ini nga mga duta may kasangkaron nga dose ka kilometro kag nagalambot ini hasta sa dulunan sang Israel sa sidlangan kag sa nakatundan. Gani sa tunga sang duta nga para sa pangulo amo ang akon balaan nga duta, ang templo, ang duta sang mga kaliwat ni Levi, kag ang banwa. Ang duta nga para sa pangulo ara sa tunga sang duta nga para sa tribo ni Juda kag sang duta nga para sa tribo ni Benjamin.

23Amo ini ang mga duta nga batunon sang nabilin nga mga tribo:

Ang duta sang tribo ni Benjamin ara sa bagatnan sang duta sang pangulo, kag ang kasangkaron sini halin sa sidlangan hasta sa nakatundan sang Israel.

24Ang duta sang tribo ni Simeon ara sa bagatnan sang duta sang tribo ni Benjamin, kag ang kasangkaron sini halin man sa sidlangan hasta sa nakatundan sang Israel.

25-27Ang masunod pa nga mga duta amo ang iya sang mga tribo ni Isacar, ni Zebulun, kag ni Gad, nga ang ila mga kasangkaron halin man sa sidlangan hasta sa nakatundan sang Israel. 28Ang bagatnan nga dulunan sang tribo ni Gad magasugod sa Tamar pakadto sa tuburan sang Meriba Kadesh48:28 Meriba Kadesh: ukon, Meriba sa Kadesh. deretso sa ililigan sang tubig sang Egipto hasta sa Dagat sang Mediteraneo.

29Amo ato ang mga duta nga batunon sang mga tribo sang Israel bilang ila nga palanublion. Ako, ang Ginoong Dios, ang nagasiling sini.

Ang mga Puwertahan sang Siyudad sang Jerusalem

30-34Ang apat ka pader nga nagapalibot sa siyudad sang Jerusalem may ara sing tig-tatlo ka puwertahan. Ang mga puwertahan sa aminhan nga pader pagatawgon nga Reuben, Juda, kag Levi. Ang mga puwertahan sa sidlangan nga pader pagatawgon nga Jose, Benjamin, kag Dan. Ang mga puwertahan sa bagatnan nga pader pagatawgon nga Simeon, Isacar, kag Zebulun. Kag ang mga puwertahan sa nakatundan nga pader pagatawgon nga Gad, Asher, kag Naftali. Ang tagsa ka pader may kalabaon nga 2,250 ka metros, 35gani ang bug-os nga kalabaon sang pader 9,000 ka metros. Kag halin sa sina nga tion ang siyudad pagatawgon, “Ang Ginoo Ari Diri!”