Eksodu 40 – YCB & KLB

Yoruba Contemporary Bible

Eksodu 40:1-38

Gbígbé àgọ́ ró

1Olúwa sì wí fún Mose pé: 2Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù kìn-ín-ní ni kí ó gbé àgọ́ náà, àgọ́ àjọ náà ró. 3Gbé àpótí ẹ̀rí sí inú rẹ̀, kí ó sì bo àpótí náà pẹ̀lú aṣọ títa. 4Gbé tábìlì náà wọ ilé, kí o sì to àwọn ohun tí ó jẹ́ tirẹ̀ lé e lórí. Nígbà náà gbé ọ̀pá fìtílà wọlé, kí o sì to àwọn fìtílà rẹ̀. 5Gbé pẹpẹ wúrà ti tùràrí sí iwájú àpótí ẹ̀rí, kí o sì fi aṣọ títa ẹnu-ọ̀nà sí ara àgọ́ náà.

6“Gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí iwájú ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà, àgọ́ àjọ; 7gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, kí o sì fi omi sí inú rẹ̀. 8Gbé àgbàlá ró yìí ka, kí ó sì fi aṣọ títa sí ẹnu-ọ̀nà àgbàlá náà.

9“Mú òróró ìtasórí, kí ó sì ta á sára àgọ́ náà àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀: yà pẹpẹ sí mímọ́ àti gbogbo ọ̀ṣọ́ rẹ̀, yóò sì jẹ́ mímọ́. 10Ta òróró sára pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀, ya pẹpẹ náà sí mímọ́, yóò sì jẹ́ mímọ́ jùlọ. 11Ta òróró sára agbada náà àti ẹsẹ̀ rẹ, kí o sì yà wọ́n sí mímọ́.

12“Mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, kí o sì wẹ̀ wọ́n pẹ̀lú omi. 13Nígbà náà wọ Aaroni ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà. 14Mú àwọn ọmọ rẹ̀ kí o sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n. 15Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ní orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.” 16Mose ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

17Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gbé àgọ́ náà ró ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní ní ọdún kejì. 18Nígbà tí Mose gbé àgọ́ náà ró ó fi ihò ìtẹ̀bọ̀ sí ààyè rẹ̀, ó to pákó rẹ̀, ó fi ọ̀pá rẹ̀ bọ̀ ọ́, ó sì gbé àwọn òpó rẹ̀ ró. 19Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

20Ó mu ẹ̀rí, ó sì fi sínú àpótí, ó so àwọn òpó mọ́ àpótí náà, ó sì fi àánú bo orí rẹ. 21Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

22Mose gbé tábìlì sínú àgọ́ àjọ sí ìhà àríwá àgọ́ náà lẹ́yìn aṣọ títa, 2340.23: Ek 25.30; 39.36; Le 24.5-9.ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

24Ó gbé ọ̀pá fìtílà sínú àgọ́ àjọ ní òdìkejì tábìlì ní ìhà gúúsù àgọ́ náà. 25Ó sì tan àwọn fìtílà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

26Mose gbé pẹpẹ wúrà sínú àgọ́ àjọ níwájú aṣọ títa 27ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

28Ó sì ta aṣọ títa sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ náà. 29Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́, àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ (ọkà), gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

3040.30-32: Ek 30.18-21.Ó gbé agbada sí àárín àgọ́ àjọ àti pẹpẹ, ó sì pọn omi sínú rẹ̀ fún wíwẹ̀, 31Mose, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lò ó láti fi wẹ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn. 32Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkúgbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

33Mose sì gbé àgbàlá tí ó yí àgọ́ náà kà ró àti pẹpẹ, ó sì ta aṣọ títa ti ẹnu-ọ̀nà sí àgbàlá náà. Bẹ́ẹ̀ ni Mose ṣe parí iṣẹ́ náà.

Ògo Olúwa

3440.34: If 15.8.Nígbà náà ni àwọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo Olúwa bo àgọ́ náà. 35Mose kò sì lè wọ inú àgọ́ àjọ, nítorí àwọsánmọ̀ wà ní orí àgọ́, ògo Olúwa sì ti kún inú àgọ́ náà.

36Ní gbogbo ìrìnàjò àwọn ọmọ Israẹli nígbàkúgbà tí a bá ti fa ìkùùkuu àwọsánmọ̀ náà sókè kúrò lórí àgọ́, wọ́n máa ń jáde lọ; 37ṣùgbọ́n tí àwọsánmọ̀ kò bá gòkè wọn kò ní jáde títí di ọjọ́ tí ó bá gòkè. 38Nítorí náà àwọsánmọ̀ Olúwa wà lórí àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọsánmọ̀ ní alẹ́, ní ojú gbogbo ilé Israẹli ní gbogbo ìrìnàjò wọn.

Korean Living Bible

출애굽기 40:1-38

성막을 세움

1여호와께서 모세에게 말씀하셨다.

2“너는 정월 초하룻날에 성막을 세우고

3그 안에 법궤를 들여놓은 다음 휘장을 쳐서 그 궤를 가려라.

4그리고 상을 들여놓고 그 위에 얹을 것을 차려 놓고 또 등대를 들여놓아 불을 켜고

5향단을 법궤 앞에 놓고 성막 출입구 휘장을 달아라.

6“너는 제물을 태워 바칠 번제단을 성막 출입구 앞에 놓고

7넓적한 물통을 성막과 번제단 사이에 놓은 후 그 속에 물을 채워라.

8그런 다음 포장을 쳐서 뜰을 만들고 뜰 출입구 막을 달아라.

9“그리고 너는 거룩한 기름을 가져다가 성막과 그 안에 있는 모든 것에 발라 성막과 그 모든 기구를 신성하게 하라. 그러면 그것이 거룩해질 것이다.

10너는 또 그 기름을 번제단과 그 모든 기구에 발라 그 제단을 신성하게 하라. 그 단이 아주 거룩해질 것이다.

11그리고 넓적한 물통과 그 받침에도 기름을 발라 그것들을 거룩하게 하라.

12“너는 또 아론과 그의 아들들을 성막 입구로 데려다가 그들을 물로 씻긴 다음

13아론에게 거룩한 옷을 입히고 그에게 기름을 붓고 거룩하게 하여 제사장으로서 나를 섬기게 하라.

14그리고 너는 그의 아들들에게 속옷을 입히고

15또 아론에게 기름을 부은 것처럼 그들에게도 기름을 부어 제사장으로서 나를 섬기게 하라. 그들이 기름 부음을 받음으로써 그들의 제사장직은 영구히 계승되어 그 후손들이 대대로 제사장이 될 것이다.”

16그래서 모세는 모든 일을 여호와께서 자기에게 명령하신 대로 하였는데

17그들이 이집트를 떠나온 지 2년째가 되는 해 정월 초하룻날에 성막이 세워졌다.

18모세는 성막을 세울 때 받침들을 놓고 널빤지를 세웠으며 그 가로대를 끼우고 또 기둥을 세웠다.

19그런 다음 그는 성막 위에 막을 펴고 그 위에 덮개를 덮어 여호와께서 자기에게 명령하신 대로 하였다.

20그는 또 십계명이 기록된 두 돌판을 궤 속에 넣고 운반채를 궤의 고리에 꿰고 그 궤의 뚜껑인 속죄소를 궤 위에 얹었다.

21그러고서 그는 궤를 성막 안에 들여놓고 여호와께서 자기에게 명령하신 대로 휘장을 쳐서 그 40:21 또는 ‘증거궤’법궤를 가렸다.

22모세는 또 성막의 그 휘장 밖에 북쪽으로 상을 놓고

23여호와께서 자기에게 명령하신 대로 여호와께 바친 빵을 그 상 위에 차려 놓았다.

24그리고 그는 성막 안의 남쪽인 상 맞은편에 등대를 놓고

25여호와 앞에서 등잔에 불을 켜 여호와께서 명령하신 대로 하였다.

26그는 또 향단을 성막 안의 휘장 앞에 두고

27그 위에 향을 피워 여호와께서 명령하신 대로 하였다.

28그리고 그는 성막 입구에 휘장을 달고

29성막 출입구 앞에 제물을 태워 바칠 번제단을 놓았으며 그 위에 짐승을 불에 태워 바치는 번제와 곡식으로 드리는 소제를 드려 여호와께서 자기에게 말씀하신 대로 하였다.

30그는 또 물통을 성막과 제단 사이에 두고 거기에 물을 채웠으며

31모세와 아론과 그의 아들들은 그 물로

32성막에 들어갈 때나 단에 가까이 갈 때 손발을 씻어 여호와께서 모세에게 명령하신 대로 하였다.

33그리고 모세는 성막과 제단 주위에 포장을 쳐서 뜰을 만들고 뜰의 출입구 막을 달아 모든 일을 끝마쳤다.

여호와의 영광

34그러자 구름이 성막에 덮이고 여호와의 영광의 광채가 성막을 가득 채웠다.

35모세는 성막 위에 덮인 그 구름과 성막 안에 가득한 그 영광의 광채 때문에 성막에 들어갈 수가 없었다.

36이스라엘 백성은 구름이 성막 위에서 떠오를 때마다 계속 행진하였으나

37구름이 떠오르지 않을 때에는 그 구름이 떠오를 때까지 떠나지 않았다.

38이와 같이 이스라엘 백성이 다 보는 가운데 낮에는 여호와의 구름이 성막 위에 있고 밤에는 구름 가운데 불이 있었다. 이것은 그들이 길을 가는 동안 줄곧 계속되었다.