Eksodu 37 – YCB & NIRV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 37:1-29

Àpótí náà

137.1-9: Ek 25.10-22.Besaleli sì fi igi ṣittimu ṣe àpótí náà, ìgbọ̀nwọ́ méjì ààbọ̀ ni gígùn rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni fífẹ̀ rẹ̀, ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ni gíga rẹ̀. 2Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó ní inú àti ní òde, ó sì fi wúrà gbá etí rẹ̀ yíká. 3Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún, láti fi wọ́n sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ẹsẹ̀ rẹ̀, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní, òrùka wúrà méjì yóò wà ní ẹgbẹ́ kejì. 4Ó sì fi igi kasia ṣe ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n. 5Ó sì fi ọ̀pá náà bọ òrùka ní ẹ̀gbẹ́ kọ̀ọ̀kan àpótí ẹ̀rí náà láti fi gbé e.

6Ó fi ojúlówó wúrà ṣe ìtẹ́ àánú; ìgbọ̀nwọ́ méjì àti ààbọ̀ ní gígùn àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní fífẹ̀. 7Ó sì ṣe kérúbù méjì láti inú wúrà tí a fi òòlù sí igun ìtẹ́ àánú náà. 8Ó ṣe kérúbù kan ní igun kìn-ín-ní, àti kérúbù kejì sí igun kejì; kí kérúbù náà jẹ́ irú kan náà ní igun méjèèjì pẹ̀lú ìbòrí wọn. 9Àwọn kérúbù sì na ìyẹ́ apá wọn sókè, tí wọn yóò sì fi ìyẹ́ apá wọn ṣe ibòòji sí orí ìtẹ́ àánú. Àwọn kérúbù náà yóò kọ ojú sí ara wọn, wọn yóò máa wo ọ̀kánkán ìtẹ́.

Tábìlì náà

1037.10-16: Ek 25.23-29.Ó ṣe tábìlì igi ṣittimu ìgbọ̀nwọ́ méjì ní gígùn, ìgbọ̀nwọ́ kan ní fífẹ̀, àti ìgbọ̀nwọ́ kan ààbọ̀ ní gíga. 11Ó sì fi ojúlówó wúrà bò ó, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí i ká. 12Ó sì ṣe etí kan ní ìbú àtẹ́lẹwọ́ sí i yíká, ó sì ṣe ìgbátí wúrà yí etí rẹ̀ ká. 13Ó sì da òrùka wúrà mẹ́rin fún tábìlì náà, ìwọ ó sì fi òrùka kọ̀ọ̀kan sí igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tí ó wà ní ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin. 14Ní abẹ́ ìgbátí náà ni àwọn òrùka náà yóò wà, ààyè láti máa fi gbé tábìlì náà. 15Ó sì fi igi kasia ṣe àwọn ọ̀pá, ó sì fi wúrà bò wọ́n, láti máa fi wọ́n gbé tábìlì náà. 16Ó sì ṣe àwọn ohun èlò tí ó wà lórí tábìlì náà ní ojúlówó wúrà, abọ́ rẹ̀, àwo rẹ, àwokòtò rẹ̀ àti ìgò rẹ̀ fún dída ọrẹ mímu jáde.

Ọ̀pá fìtílà náà

1737.17-24: Ek 25.31-39.Ó sì ṣe ọ̀pá fìtílà náà ní ojúlówó wúrà, ó sì lù ú jáde, ọ̀pá rẹ̀, ìtànná ìfẹ́ rẹ̀, ìrudí rẹ àti agogo rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọ̀kan náà. 18Ẹ̀ka mẹ́fà ni yóò yọ ní ẹ̀gbẹ́ ọ̀pá fìtílà: mẹ́ta ní ẹ̀gbẹ́ kìn-ín-ní mẹ́ta ni ẹ̀gbẹ́ kejì. 19Àwo mẹ́ta ni a ṣe bí ìtànná almondi pẹ̀lú ìrudí àti ìtànná wà ni ẹ̀ka kan, mẹ́ta sì tún wà ní ẹ̀ka mìíràn, bẹ́ẹ̀ ni ní ẹ̀ka mẹ́fẹ̀ẹ̀fà jáde lára ọ̀pá fìtílà. 20Ní ara ọ̀pá fìtílà ni àwo mẹ́rin ti a ṣe gẹ́gẹ́ bí òdòdó almondi ti ó ni ìṣọ àti ìtànná yóò wà. 21Irúdì kan yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì àkọ́kọ́ tí ó yọ lára ọ̀pá fìtílà, irúdì kejì ó sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kejì, irúdì kẹta yóò sì wà ní abẹ́ ẹ̀ka rẹ̀ méjì kẹta: ẹ̀ka mẹ́fà ní àpapọ̀. 22Irúdì wọn àti ẹ̀ka wọn kí ó rí bákan náà, kí gbogbo rẹ̀ kí ó jẹ́ lílù ojúlówó wúrà.

23Ó ṣe fìtílà rẹ̀, méje, àti alumagaji rẹ̀, àti àwo rẹ̀, kìkì wúrà ni. 24Ó sì ṣe ọ̀pá fìtílà náà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀ láti ara tálẹ́ǹtì kan tí ó jẹ́ kìkì wúrà.

Pẹpẹ tùràrí

2537.25-29: Ek 30.1-5.Igi kasia ní ó fi ṣe pẹpẹ tùràrí náà. Igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin rẹ̀ jẹ́ déédé, gígùn rẹ̀ jẹ ìgbọ̀nwọ́ kan, fífẹ̀ rẹ̀ náà jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ kan àti gíga rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ méjì, ìwo rẹ̀ sì jẹ́ bákan náà. 26Kìkì wúrà ni ó fi bo orí rẹ̀, gbogbo ìhà rẹ̀ àti ìwo rẹ̀, ó sì fi ìgbátí wúrà yìí ká. 27Ó ṣe òrùka wúrà méjì sí ìsàlẹ̀ ìgbátí náà méjì ní òdìkejì ara wọn láti gbá òpó náà mú láti máa fi gbé e. 28Ó ṣe òpó igi ṣittimu, ó sì bò wọ́n pẹ̀lú u wúrà.

29Ó sì túnṣe òróró mímọ́ ìtasórí àti kìkì òórùn dídùn tùràrí—iṣẹ́ àwọn tí ń ṣe nǹkan olóòórùn.

New International Reader’s Version

Exodus 37:1-29

The Ark of the Covenant Law

1Bezalel made the ark of the covenant law out of acacia wood. It was three feet nine inches long and two feet three inches wide and high. 2He covered it inside and outside with pure gold. He put a strip of gold around it. 3He made four gold rings for it. He joined them to its four bottom corners. He put two rings on one side and two rings on the other. 4Then he made poles out of acacia wood. He covered them with gold. 5He put the poles through the rings on the sides of the ark to carry it.

6He made its cover out of pure gold. It was three feet nine inches long and two feet three inches wide. The cover is the place where sin is paid for. 7Then he made two cherubim out of hammered gold at the ends of the cover. 8He put one of the cherubim on each end of it. 9He made them as part of the cover itself. Their wings spread up over the cover. The cherubim faced each other and looked toward the cover.

The Table for the Holy Bread

10The workers made the table out of acacia wood. It was three feet long, one foot six inches wide and two feet three inches high. 11Then they covered it with pure gold. They put a strip of gold around it. 12They also made a rim around it three inches wide. They put a strip of gold around the rim. 13They made four gold rings for the table. They joined them to the four corners, where the four legs were. 14The rings were close to the rim. The rings held the poles used to carry the table. 15The workers made the poles out of acacia wood. They covered them with gold. 16They made plates, dishes and bowls out of pure gold for the table. They also made pure gold pitchers to pour out drink offerings.

The Gold Lampstand

17The workers made the lampstand out of pure gold. They hammered out its base and stem. Its buds, blossoms and cups branched out from it. 18Six branches came out from the sides of the lampstand. There were three on one side and three on the other. 19On one branch there were three cups shaped like almond flowers with buds and blossoms. There were three on the next branch. In fact, there were three on each of the six branches that came out from the lampstand. 20On the lampstand there were four cups shaped like almond flowers with buds and blossoms. 21One bud was under the first pair of branches that came out from the lampstand. A second bud was under the second pair. And a third bud was under the third pair. There was a total of six branches. 22The buds and branches came out from the lampstand. The whole lampstand was one piece hammered out of pure gold.

23The workers made its seven lamps out of pure gold. They also made its trays and wick cutters out of pure gold. 24They used 75 pounds of pure gold to make the lampstand and everything used with it.

The Altar for Burning Incense

25The workers made the altar for burning incense. They made it out of acacia wood. It was about one foot six inches square and three feet high. A horn stuck out from each of its upper four corners. 26The workers covered the top, sides and horns with pure gold. They put a strip of gold around it. 27They made two gold rings below the strip. They put the rings on the sides across from each other. The rings held the poles used to carry it. 28The workers made the poles out of acacia wood. They covered them with gold.

29They also made the sacred anointing oil and the pure, sweet-smelling incense. A person who makes perfume made them.