Eksodu 32 – YCB & CARST

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 32:1-35

Ère òrìṣà wúrà

132.1-6: Ap 7.40,41.Nígbà tí àwọn ènìyàn rí i pé Mose pẹ́ kí ó tó sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè wá, wọn péjọ yí Aaroni ká, wọ́n sì wí pé, “Wá, dá òrìṣà tí yóò máa ṣáájú wa fún wa. Bí ó ṣe ti Mose tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá, àwa kò mọ́ ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí i.”

2Aaroni dá wọn lóhùn pé, “Ẹ bọ́ òrùka wúrà tí ó wà ní etí àwọn ìyàwó yín, tí àwọn ọmọkùnrin yín, àti tí àwọn ọmọbìnrin yín, kí ẹ sì mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi.” 3Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ènìyàn bọ́ òrùka etí wọn, wọn sì kó wọn wá fún Aaroni. 4Ó sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ó sì fi ṣe ohun ọnà fínfín, ó sì dà á ní àwòrán ẹgbọrọ màlúù. Nígbà náà ni wọn wí pé, “Israẹli, wọ̀nyí ni òrìṣà, ti ó mú un yín jáde wá láti Ejibiti.”

5Nígbà ti Aaroni rí èyí, ó kọ́ pẹpẹ kan níwájú ẹgbọrọ màlúù náà, ó sì kéde pé, “Lọ́la ni àjọyọ̀ sí Olúwa.” 632.6: 1Kọ 10.7.Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn dìde ní kùtùkùtù ọjọ́ kejì, wọ́n sì rú ẹbọ sísun, wọ́n sì mú ẹbọ àlàáfíà wá. Lẹ́yìn náà wọ́n jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde láti ṣeré.

7Olúwa sì wí fún Mose pé, “Sọ̀kalẹ̀ lọ, nítorí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú gòkè wá láti Ejibiti, wọ́n ti dẹ́ṣẹ̀. 8Wọ́n ti yí kánkán kúrò nípa ọ̀nà tí mo ti mo pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì ti dá ère ẹgbọrọ màlúù fún ara wọn. Wọ́n ti foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì ti rú ẹbọ sí i, wọ́n sì ti sọ pé, ‘Israẹli wọ̀nyí ní òrìṣà tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá.’ ”

932.9-14: Ek 32.31-35; Nu 14.11-25.Olúwa wí fún Mose pé, “Èmi ti rí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, wọ́n sì jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn. 10Ǹjẹ́ nísinsin yìí fi mí sílẹ̀, nítorí kí ìbínú mi lè gbóná sí wọn, kí Èmi sì lè pa wọ́n run. Nígbà náà ni Èmi yóò sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.”

11Ṣùgbọ́n Mose kígbe fún ojúrere Olúwa Ọlọ́run rẹ̀, ó wí pé, “Olúwa, èéṣe tí ìbínú rẹ yóò ṣe gbóná sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ìwọ mú jáde láti Ejibiti wá pẹ̀lú agbára ńlá àti ọwọ́ agbára? 12Èéṣe tí àwọn ará Ejibiti yóò ṣe wí pé, ‘Nítorí ibi ni ó ṣe mọ̀ ọ́n mọ̀ mú wọn jáde, láti pa wọ́n ní orí òkè àti láti gbá wọn kúrò lórí ayé’? Yípadà kúrò nínú ìbínú rẹ tí ó múná, yí ọkàn padà, kí o má sì ṣe mú ìparun wá sórí àwọn ènìyàn rẹ. 13Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, ẹni tí ìwọ búra fún fúnra rẹ̀, ‘Tí o wí fún wọn pé, Èmi yóò mú irú-ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, Èmi yóò sì fún irú-ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ” 14Nígbà náà ni Olúwa dáwọ́ ìbínú rẹ̀ dúró, kò sì mú ìparun náà tí ó sọ wá sórí àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́.

15Mose sì yípadà, ó sì sọ̀kalẹ̀ láti orí òkè náà pẹ̀lú òkúta wàláà ẹ̀rí méjì ní ọwọ́ rẹ̀. Wọ́n kọ ìwé síhà méjèèjì, iwájú àti ẹ̀yin. 16Iṣẹ́ Ọlọ́run sì ni wàláà náà; ìkọ̀wé náà jẹ́ ìkọ̀wé Ọlọ́run, a fín in sára àwọn òkúta wàláà náà.

17Nígbà tí Joṣua gbọ́ ariwo àwọn ènìyàn tí wọ́n ń kígbe, ó sọ fún Mose pé, “Ariwo ogun wà nínú àgọ́.”

18Mose dáhùn pé,

“Kì í ṣe ariwo fún ìṣẹ́gun,

kì í ṣe ariwo fún aṣẹ́gun;

ohùn àwọn tí ń kọrin ni mo gbọ́.”

19Nígbà tí Mose dé àgọ́, ó sì rí ẹgbọrọ màlúù náà àti ijó, ìbínú rẹ gbóná, ó sì sọ wàláà ọwọ́ rẹ̀ sílẹ̀, ó sì fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́ ní ìsàlẹ̀ òkè náà. 20Ó sì gbé ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó sì fi iná jó wọn; ó sì lọ̀ wọ́n kúnná, ó dà á sínú omi, ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli mu ún.

21Mose sọ fún Aaroni pé, “Kí ni àwọn ènìyàn wọ̀nyí ṣe sí ọ, tí ìwọ ṣe mú wọn dá ẹ̀ṣẹ̀ ńlá yìí?”

22Aaroni dáhùn wí pé, “Má ṣe bínú olúwa mi. Ìwọ mọ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe burú tó. 2332.23: Ap 7.40.Wọ́n sọ fún mi pé, ‘Ṣe òrìṣà fún wa, tí yóò máa ṣáájú wa. Bí ó ṣe ti Mose ẹni tí ó mú wa jáde láti Ejibiti wá àwa kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí i.’ 24Bẹ́ẹ̀ ni mo sọ fún wọn pé, ‘Ẹnikẹ́ni tí ó ní òrùka wúrà, kí ó bọ́ ọ wá.’ Nígbà náà ni wọ́n fún mi ní wúrà, mo sì jù ú sínú iná, a sì fi ṣe ẹgbọrọ màlúù yìí!”

25Mose rí pé àwọn ènìyàn náà kò ṣe ṣàkóso àti pé Aaroni ti sọ wọ́n di aláìlákóṣo láàrín àwọn ọ̀tá tí ó dìde sí wọn. 26Bẹ́ẹ̀ ni Mose dúró ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́, ó sì wí pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá wà fún Olúwa, kí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.” Gbogbo àwọn ará Lefi sì péjọ yí i ká.

27Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, wí pé, ‘Kí olúkúlùkù ọkùnrin kí ó kọ idà rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ẹ lọ padà, kí ẹ jà láti àgọ́ kan dé òmíràn, olúkúlùkù kí ó pa arákùnrin rẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti aládùúgbò rẹ.’ ” 28Àwọn ará Lefi ṣe gẹ́gẹ́ bí Mose ṣe pàṣẹ, àti ní ọjọ́ náà àwọn tí ó kú tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) ènìyàn. 29Nígbà náà ni Mose wí pé, “Ẹ ti ya ara yín sọ́tọ̀ fún Olúwa lónìí, nítorí ìwọ ti dìde sí àwọn ọmọ rẹ àti arákùnrin rẹ, ó sì ti bùkún fún ọ lónìí.”

30Ní ọjọ́ kejì Mose sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ̀yin ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tí ó pọ̀. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí èmi yóò gòkè lọ bá Olúwa; bóyá èmi lè ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ yín.”

31Bẹ́ẹ̀ ni Mose padà tọ Olúwa lọ, ó sì wí pé, “Yé, kí ni ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí àwọn ènìyàn ti dá yìí! Wọ́n ti ṣe òrìṣà wúrà fún ara wọn. 3232.32,33: If 3.5.Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, jọ̀wọ́ dárí ẹ̀ṣẹ̀ wọn jì wọ́n ṣùgbọ́n tí kò bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, pa orúkọ mi rẹ́ kúrò nínú ìwé tí ìwọ ti kọ.”

33Olúwa dá Mose lóhùn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá dẹ́ṣẹ̀ sí mi, Èmi yóò pa á rẹ́ kúrò nínú ìwé mi. 34Ǹjẹ́ nísinsin yìí lọ, máa darí àwọn ènìyàn yìí lọ sí ibi ti mo sọ, angẹli mi yóò sì máa lọ ṣáájú yín. Ìgbà ń bọ̀ fún mi tì Èmi yóò ṣe ìbẹ̀wò, Èmi yóò fi yà jẹ wọ́n fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn.”

35Olúwa sì yọ àwọn ènìyàn náà lẹ́nu, pẹ̀lú ààrùn nítorí ohun tí wọ́n ṣe ní ti ẹgbọrọ màlúù tí Aaroni ṣe.

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

Исход 32:1-35

Золотой телец

(Втор. 9:7-21, 25-29)

1Увидев, что Мусо медлит спускаться с горы, народ собрался вокруг Хоруна и сказал:

– Послушай, сделай нам бога, который бы вёл нас, потому что мы не знаем, что приключилось с этим Мусо, выведшим нас из Египта.

2Хорун ответил им:

– Снимите золотые серьги с ваших жён, сыновей и дочерей и принесите их мне.

3Народ снял золотые серьги и принёс их Хоруну. 4Он взял то, что они принесли ему, и сделал из этого золота литого тельца, придав ему вид резцом. Тогда они сказали:

– Вот твой бог, Исроил, который вывел тебя из Египта!

5Увидев это, Хорун поставил перед тельцом жертвенник и возвестил:

– Завтра – праздник Вечному.

6Встав на следующий день рано утром, они принесли всесожжения и жертвы примирения. Народ сел есть и пить, а потом встал и начал веселиться.

7Тогда Вечный сказал Мусо:

– Спускайся с горы. Твой народ, который ты вывел из Египта, развратился. 8Как скоро они уклонились от того, что Я повелел им! Они сделали себе литого тельца, поклонились ему и принесли ему жертвы, говоря: «Вот твой бог, Исроил, который вывел тебя из Египта».

9– Я вижу этот народ, – сказал Вечный Мусо, – он упрям. 10Итак, оставь Меня. Я обращу Свой гнев на них и погублю их. Потом Я произведу великий народ от тебя.

11Но Мусо принялся умолять Вечного, своего Бога:

– О Вечный, – сказал он, – зачем Тебе гневаться на Свой народ, который Ты вывел из Египта великой силой и могучей рукой? 12Зачем египтянам давать повод говорить: «Он вывел их со злым умыслом, чтобы убить в горах и стереть с лица земли?» Оставь Свой пылающий гнев; смягчись, не наводи на Свой народ беду. 13Вспомни Твоих рабов Иброхима, Исхока и Якуба32:13 Букв.: «Исроила». Всевышний дал Якубу новое имя – Исроил (см. Нач. 32:27-28)., которым Ты клялся Собой: «Я дам вам столько потомков, сколько звёзд на небе. Весь этот край, который Я обещал отдать вам, будет достоянием ваших потомков навеки».

14Вечный смягчился и не навёл на Свой народ беду, которой грозил.

15Мусо повернулся и сошёл с горы с двумя каменными плитками священного соглашения в руках. Они были исписаны с обеих сторон, спереди и сзади. 16Всевышний сделал эти плитки; Он высек на них Свои письмена.

17Когда Иешуа услышал гул кричащего народа, он сказал Мусо:

– В лагере шум битвы.

18Но Мусо ответил:

– Это не клич победителей,

не плач побеждённых:

я слышу голос поющих.

19Подойдя к лагерю и увидев тельца и пляски, Мусо разгневался. Он бросил каменные плитки, которые нёс, разбив их на куски у подножия горы. 20Он взял сделанного ими тельца и расплавил его в огне. Он стёр его в порошок, рассыпал по воде и заставил исроильтян пить эту воду.

21Мусо сказал Хоруну:

– Что сделали тебе эти люди, что ты ввёл их в такой страшный грех?

22– Не гневайся, мой господин, – ответил Хорун. – Ты знаешь, как склонны эти люди к злу. 23Они сказали мне: «Сделай нам бога, который бы вёл нас, потому что мы не знаем, что приключилось с этим Мусо, выведшим нас из Египта». 24Тогда я сказал им: «У кого есть золотые украшения, пусть снимет их». Они дали мне золото, я бросил его в огонь, и получился этот телец!

25Мусо увидел, что люди необузданны, потому что Хорун позволил им это на посмешище врагам; 26он встал у входа в лагерь и сказал:

– Кто за Вечного – ко мне, – и вокруг него собрались все левиты.

27Он сказал им:

– Так говорит Вечный, Бог Исроила: «Все опояшьтесь мечом! Идите через лагерь от одного края к другому и обратно, убивая братьев, друзей и ближних».

28Левиты сделали, как повелел Мусо, и в тот день погибло около трёх тысяч человек. 29Мусо сказал:

– Сегодня вы посвятили себя служению Вечному ценой сыновей и братьев, и Он благословил вас.

30На другой день Мусо сказал народу:

– Вы совершили страшный грех. Но сейчас я поднимусь к Вечному; может быть, я смогу загладить ваш грех.

31Мусо вернулся к Вечному и сказал:

– Да, эти люди совершили страшный грех, сделав себе золотого бога. 32Но теперь, молю, прости их, а если не простишь, так сотри и моё имя из книги, которую Ты написал32:32 Здесь имеется в виду книга жизни, в которой записаны имена тех, кто принадлежит к Его народу (см. Заб. 68:29; Отк. 20:15; 21:27)..

33Вечный ответил Мусо:

– Я сотру из Своей книги имя того, кто согрешит против Меня. 34А теперь ступай, веди народ туда, куда Я тебе сказал, и Мой Ангел пойдёт перед тобой. Но когда придёт срок, Я накажу их за грех.

35Вечный поразил народ мором за то, что они сделали тельца – того, которого изготовил Хорун.