Eksodu 31 – YCB & BDS

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 31:1-18

Besaleli àti Oholiabu

131.1-6: Ek 35.30–36.1.Olúwa wí fún Mose pé, 2“Wò ó, Èmi ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda, 3Èmi sì ti fi Ẹ̀mí Ọlọ́run kún un pẹ̀lú ọgbọ́n, òye àti ìmọ̀ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 4Láti ṣe aláràbarà iṣẹ́ ní wúrà, fàdákà àti idẹ, 5láti gbẹ́ òkúta àti láti tò wọ́n, láti ṣiṣẹ́ ní igi, àti láti ṣiṣẹ́ ní gbogbo onírúurú iṣẹ́ ọnà. 6Síwájú sí i, èmi ti yan Oholiabu ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀yà Dani, láti ràn án lọ́wọ́.

“Bákan náà, Èmi ti fi ọgbọ́n fún gbogbo àwọn oníṣẹ́-ọnà láti ṣe ohun gbogbo tí mo pàṣẹ fún ọ:

7“àgọ́ àjọ náà,

àpótí ẹ̀rí pẹ̀lú ìtẹ́ àánú tí ó wà lórí rẹ̀,

àti gbogbo ohun èlò àgọ́ náà,

8tábìlì àti ohun èlò rẹ̀,

ọ̀pá fìtílà tí ó jẹ́ kìkì wúrà àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,

pẹpẹ tùràrí,

9pẹpẹ ẹbọ sísun àti gbogbo ohun èlò rẹ̀,

agbada pẹ̀lú ẹsẹ̀ rẹ̀,

10àti aṣọ híhun pẹ̀lú,

papọ̀ pẹ̀lú aṣọ mímọ́ fún Aaroni àlùfáà

àti aṣọ fún àwọn ọmọ rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ bí àlùfáà,

11òróró ìtasórí àti tùràrí olóòórùn dídùn fún Ibi Mímọ́.

“Kí wọ́n ṣe wọ́n gẹ́gẹ́ bí mo ṣe pàṣẹ fún ọ.”

Ọjọ́ ìsinmi

1231.12-17: Ek 20.8; 23.12; 35.2; De 5.12-15.Olúwa wí fún Mose pé, 13“Kí ìwọ kí ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ẹ̀yin gbọdọ̀ máa pa ọjọ́ ìsinmi mi mọ́. Èyí ni yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti ẹ̀yin fún ìrandíran tó ń bọ̀, nítorí kí ẹ̀yin lè mọ̀ pé Èmi ni Olúwa, ẹni tí ó yà yín sí mímọ́.

14“ ‘Nítorí náà, kí ẹ̀yin kí ó máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, nítorí mímọ́ ni fún un yín. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bà á jẹ́, ni a yóò pa; ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe iṣẹ́ kankan ní ọjọ́ náà ni a yóò gé kúrò nínú àwọn ènìyàn rẹ. 15Ọjọ́ mẹ́fà ni kí ẹ fi ṣiṣẹ́, ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ní ọjọ́ ìsinmi tí ẹ̀yin yóò fi sinmi, mímọ́ ni fún Olúwa. Ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣiṣẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ni a ó pa nítòótọ́. 16Nítorí náà ni àwọn ọmọ Israẹli yóò ṣe máa pa ọjọ́ ìsinmi mọ́, ẹ máa ṣe àkíyèsí rẹ̀ dé ìrandíran tó ń bọ̀ bí i májẹ̀mú títí láé. 17Yóò jẹ́ àmì láàrín Èmi àti àwọn ọmọ Israẹli títí láé, nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, àti ní ọjọ́ keje ni ó fi iṣẹ́ sílẹ̀, ó sì sinmi.’ ”

18Nígbà tí Olúwa parí ọ̀rọ̀ sísọ fún Mose lórí òkè Sinai, ó fún un ní òkúta wàláà ẹ̀rí méjì, òkúta wàláà òkúta tí a fi ìka Ọlọ́run kọ.

La Bible du Semeur

Exode 31:1-18

Les artisans du sanctuaire

1L’Eternel parla à Moïse en ces termes : 2Vois, je désigne Betsaléel, fils d’Ouri, descendant de Hour, de la tribu de Juda, 3et je l’ai rempli de l’Esprit de Dieu qui lui confère de l’habileté, de l’intelligence et de la compétence pour exécuter toutes sortes d’ouvrages, 4pour concevoir des projets, pour travailler l’or, l’argent et le bronze, 5pour tailler des pierres à enchâsser, pour sculpter le bois et pour réaliser toutes sortes d’ouvrages. 6Je lui ai donné pour aide Oholiab, fils d’Ahisamak, de la tribu de Dan et, de plus, j’ai accordé un surcroît d’habileté à tous les artisans experts, afin qu’ils exécutent tout ce que je t’ai ordonné : 7la tente de la Rencontre, le coffre de l’acte de l’alliance, le propitiatoire qui doit lui servir de couvercle, et tous les objets de la tente, 8la table et ses ustensiles, le chandelier d’or pur et tous ses accessoires, l’autel des parfums, 9l’autel des holocaustes et tous ses accessoires, la cuve et son socle, 10les vêtements de cérémonie et les vêtements sacrés pour Aaron le prêtre, ainsi que ceux de ses fils, ceux qu’ils endosseront pour exercer les fonctions du sacerdoce, 11l’huile d’onction et le parfum aromatique pour le sanctuaire. Les artisans se conformeront à tous les ordres que je t’ai donnés.

Le jour du sabbat

12L’Eternel parla à Moïse en ces termes31.12 Pour les v. 12-17, voir 20.8-11 ; 23.12 ; 34.21 ; 35.2 ; Gn 2.1-3 ; Lv 23.3 ; Dt 5.13-14. : 13Et toi, dis ceci aux Israélites : « Surtout, observez bien mes sabbats ; car c’est là un signe entre moi et vous, de génération en génération, le signe que moi, l’Eternel, je vous rends saints. 14Vous observerez donc le jour du repos, car il est saint pour vous. Celui qui le profanera devra mourir ; car quiconque fera un travail quelconque ce jour-là, sera retranché de son peuple. 15On travaillera six jours, et le septième jour sera un jour de repos consacré à l’Eternel. Quiconque fera un travail le jour du sabbat devra mourir. 16Les Israélites observeront le jour du sabbat en le célébrant de génération en génération ; c’est une alliance éternelle. 17Il sera un signe à perpétuité entre moi et les Israélites, car en six jours l’Eternel a fait le ciel et la terre, et le septième jour il a cessé de travailler pour reprendre son souffle. »

La remise des deux tablettes de l’acte de l’alliance

18Quand il eut terminé de s’entretenir avec Moïse sur le mont Sinaï, l’Eternel lui remit les deux tablettes de l’acte de l’alliance ; c’étaient des tablettes de pierre gravées par le doigt de Dieu.