Eksodu 3 – YCB & JCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 3:1-22

Mose àti igbó tí ń jó

13.1–4.17: Ek 6.2-13.Ní ọjọ́ kan nígbà tí Mose ń ṣọ́ agbo ẹran Jetro baba ìyàwó rẹ̀, àlùfáà Midiani. Ó da agbo ẹran náà lọ sí ọ̀nà jíjìn nínú aginjù. Ó dé Horebu, òkè Ọlọ́run. 23.2: Ap 7.30.Níbẹ̀ ni angẹli Olúwa ti yọ sí i nínú ọ̀wọ́-iná tí ń jó láàrín igbó. Mose rí i pé iná ń jó nínú igbó ṣùgbọ́n igbó kò run. 3Nígbà náà ni Mose sọ pé, “Èmi yóò lọ wo ohun ìyanu yìí, ìdí tí iná kò fi jó igbó run.”

4Nígbà tí Olúwa rí i pe Mose ti lọ láti lọ wò ó, Ọlọ́run ké pè é láti àárín igbó náà, “Mose! Mose!”

Mose sì dáhùn ó wí pé, “Èmi nìyìí.”

53.5: Ap 7.33.Olúwa sì wí fún Mose pé, “Má ṣe súnmọ́ ìhín yìí, bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni.” 63.6: Mt 22.32; Mk 12.26; Lk 20.37; Ap 3.13; 7.32.Nígbà náà ní ó wí pé, “Èmi ni Ọlọ́run baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu.” Nítorí ìdí èyí, Mose sì pa ojú rẹ̀ mọ́, nítorí ó bẹ̀rù láti bojú wo Ọlọ́run.

7Olúwa si wí pé, “Èmí ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi ní ilẹ̀ Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ohùn igbe wọn nítorí àwọn akóniṣiṣẹ́ wọn. Ìyà tí ń jẹ wọ́n sì kan mi lára. 8Èmi sì ti sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Ejibiti, àti láti mú wọn gòkè kúrò ní ilẹ̀ náà lọ sí ilẹ̀ tí ó dára tí ó sì ní ààyè, àní ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; ibùgbé àwọn ará Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi. 9Ǹjẹ́ nísinsin yìí, wò ó, igbe àwọn ará Israẹli ti dé ọ̀dọ̀ mi, Èmi sì ti rí bí àwọn ará Ejibiti ti ṣe ń gbà ń jẹ wọ́n ní ìyà. 10Ǹjẹ́ nísinsin yìí, lọ, èmi yóò rán ọ sí Farao láti kó àwọn ènìyàn Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti.”

11Ṣùgbọ́n Mose wí fún Ọlọ́run pé, “Ta ni èmi, tí èmi yóò tọ Farao lọ, ti èmi yóò sì kó àwọn ará Israẹli jáde kúrò ni ilẹ̀ Ejibiti?”

12Nígbà náà ni Ọlọ́run wí fún Mose pé, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ. Èyí ni yóò jẹ́ àmì fún ọ, tí yóò fihàn pé, èmi ni ó rán ọ lọ, nígbà tí ìwọ bá kó àwọn ènìyàn náà jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti, ẹ̀yin yóò sin Ọlọ́run ni orí òkè yìí.”

13Mose sì wí fún Ọlọ́run pé, “Bí mo bá tọ àwọn ará Israẹli lọ tí mo sì sọ fún wọn pé, ‘Ọlọ́run àwọn baba yín ni ó rán mi sí i yín,’ tí wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Kí ni orúkọ rẹ̀?’ Kí ni èmi yóò sọ fún wọn ní ìgbà náà?”

14Ọlọ́run sì sọ fún Mose pé, “èmi ni ti ń jẹ́ èmi ni. Èyí ni ìwọ yóò sọ fún àwọn ará Israẹli: ‘èmi ni ni ó rán mi sí i yín.’ ”

15Ọlọ́run sì wí fún Mose pẹ̀lú pé, “Báyìí ni kí ìwọ sọ fún àwọn ọmọ Israẹli, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín; Ọlọ́run Abrahamu, Ọlọ́run Isaaki àti Ọlọ́run Jakọbu; ni ó rán mi sí i yín.’

“Èyí ni orúkọ mi títí ayérayé,

orúkọ ti ẹ ó fi máa rántí mi

láti ìran dé ìran.

16“Lọ, kó àwọn àgbàgbà Israẹli jọ, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín, Ọlọ́run Abrahamu, ti Isaaki, àti ti Jakọbu; ni ó farahàn mi, ó sì wí pé, lóòótọ́ èmi ti ń bojú wò yín, èmi sì ti rí ohun tí wọ́n ṣe sí i yín ni ilẹ̀ Ejibiti. 17Èmi sì ti ṣe ìlérí láti mú un yín jáde kúrò nínú ìpọ́njú yín ni ilẹ̀ Ejibiti wá sí ilẹ̀ Kenaani, ará Hiti, Amori, Peresi, Hifi àti Jebusi; ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin.’

18“Àwọn àgbàgbà Israẹli yóò fetísílẹ̀ sí ohùn rẹ. Nígbà náà ni ìwọ, àti àwọn àgbàgbà yóò jọ tọ ọba Ejibiti lọ, ẹ ó sì wí fún un pé, ‘Olúwa, Ọlọ́run àwọn ará Heberu ti pàdé wa. Jẹ́ kí a lọ ni ìrìn ọjọ́ mẹ́ta sí inú aginjù láti lọ rú ẹbọ sí Olúwa Ọlọ́run.’ 19Ṣùgbọ́n èmi mọ̀ pé ọba Ejibiti kò ní jẹ́ kí ẹ lọ bí kò ṣe pé ọwọ́ ńlá Ọlọ́run wà ni ara rẹ̀. 20Nítorí náà, èmi yóò na ọwọ́ mí láti lu àwọn ará Ejibiti pẹ̀lú gbogbo ohun ìyanu tí èmi yóò ṣe ni àárín wọn. Lẹ́yìn náà, òun yóò jẹ́ kí ẹ máa lọ.

21“Èmi yóò sì jẹ́ kí ẹ bá ojúrere àwọn ará Ejibiti pàdé. Tí yóò fi jẹ́ pé ti ẹ̀yin bá ń lọ, ẹ kò ní lọ ní ọwọ́ òfo. 22Gbogbo àwọn obìnrin ni ó ní láti béèrè lọ́wọ́ àwọn aládùúgbò wọn àti gbogbo àwọn obìnrin ti ń gbé nínú ilé rẹ fún ohun fàdákà àti wúrà àti fún aṣọ, èyí ti ẹ̀yin yóò wọ̀ sí ọrùn àwọn ọmọ yín ọkùnrin àti obìnrin. Báyìí ni ẹ̀yin yóò sì kó ẹrù àwọn ará Ejibiti.”

Japanese Contemporary Bible

出エジプト記 3:1-22

3

神に呼ばれたモーセ

1ある日モーセは、ミデヤンの祭司であるしゅうとイテロ〔別名レウエル〕の羊の群れの番をしていました。砂漠のはずれにある神の山ホレブ(シナイ山)に近い所です。 2と、突然、柴の燃える炎の中に、主の使いが現れました。よく見ると、柴には火がついているのに、いつまでも燃え尽きません。 3-4「いったい、どういうことだろう。」不思議に思いながら、そばに近寄りました。その時です。神が燃える柴の中からモーセに呼びかけました。「モーセ、モーセ。」

「は、はい。どなたでしょう。」

5「それ以上近寄ってはならない。くつを脱ぎなさい。あなたが立っている場所は聖なる地だ。 6わたしはあなたの先祖の神、アブラハム、イサク、ヤコブの神である。」モーセはあわてて顔を覆いました。

7主は続けて語りました。「わたしの民が、エジプトで非常な苦しみを受けているのを見た。無慈悲な監督のむちを取り除いてほしい、と叫んでいる声を聞いた。 8わたしは彼らをエジプト人の手から救い出す。エジプトから助け出し、乳とみつの流れる国、広々とした美しい国へ連れて行こう。今は、カナン人、ヘテ人、エモリ人、ペリジ人、ヒビ人、エブス人が住んでいる地である。 9今こそイスラエル人の嘆きがよくわかった。苦役に明け暮れ、エジプト人に酷使されている。 10そこで、あなたをエジプトの王ファラオのもとへ遣わそう。わたしの民をエジプトから助け出すのだ。」

11「そんな大それた仕事など、とても私にはできません。」モーセは思わず叫びました。

12「心配することはない。わたしがついている。あなたを遣わしたのがわたしだという証拠に、必ずあなたとともにいよう。人々を無事エジプトから助け出したら、この山で礼拝しなければならない。」

13「ですが神様、イスラエル人のところへ行って、先祖の神に遣わされて来たと言ったら、きっと聞かれます。『先祖の神様とは、いったい何という名の神様だ。』その時、私はどう説明したらよいのでしょう。」

14「わたしは『わたしはある』(「永遠に生ける神、創造者」の意で、イスラエルの神の名。「主」のもともとの意味)という者だ。『「わたしはある」という方から遣わされた』と言えばよい。 15そして、『あなたがたの先祖アブラハム、イサク、ヤコブの神、主が私を遣わした』と言いなさい。これが永遠に変わらないわたしの名だ。」

16神はまた、モーセに命じました。「イスラエルの長老全員を呼び集めなさい。そして神が燃える柴の中に現れ、こう語ったと伝えるのだ。『わたしの民イスラエルがエジプトでどんなに苦しんでいるかを、この目で見た。 17しかし、もうそんな屈辱を味わうことも、つらい労働をしいられることもない。わたしが必ず救い出す。そして、今、カナン人、ヘテ人、エモリ人、ペリジ人、ヒビ人、エブス人が住んでいる、「乳とみつの流れる」国へ連れて行く』と。 18長老たちはあなたの言うことを聞くだろうから、いっしょにエジプトの王のところへ行き、こう言うのだ。『ヘブル人の信じる神様からお告げがありました。砂漠を三日ほど行った所で、神様にいけにえをささげるようにとのことです。どうぞ出かける許可を下さい。』 19だが、王も一筋縄ではいかない。 20だからわたしが、いやおうなしに王が承知するようにしよう。奇跡を起こしてエジプトを懲らしめる。そのあとで、ようやく行かせることになるだろう。 21その時には、エジプト人からたくさんの贈り物をもらえるようにする。何も持たずにエジプトを出ることは決してない。 22女はみな、エジプト人の主人の妻や隣人から、金、銀、宝石、美しい服を求め、それらエジプトの最上のものを息子や娘たちに着させなさい。」