Eksodu 29 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 29:1-46

Ìyàsímímọ́ Àwọn Àlùfáà

129.1-37: Le 8.1-34.“Èyí ni ohun tí ìwọ yóò ṣe láti yà wọ́n sí mímọ́, kí wọn lè máa ṣe àlùfáà fún mi. Mú ọ̀dọ́ akọ màlúù kan àti àgbò méjì tí kò ní àbùkù. 2Láti ara ìyẹ̀fun aláìwú dídùn, ṣe àkàrà àti àkàrà tí a pò pẹ̀lú òróró, àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ aláìwú tí a da òróró sí. 3Ìwọ yóò sì kó wọn sínú apẹ̀rẹ̀ kan, ìwọ yóò sì mú wọn wà nínú apẹ̀rẹ̀ náà papọ̀ pẹ̀lú akọ màlúù àti àgbò méjì náà. 4Nígbà náà ni ìwọ yóò mú Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, ìwọ yóò sì fi omi wẹ̀ wọ́n. 5Ìwọ yóò sì fi ẹ̀wù àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ Aaroni, àti aṣọ ìgúnwà efodu, àti efodu, àti ìgbàyà, kí ó sì fi onírúurú ọnà ọ̀já ẹ̀wù efodu dì í. 6Ìwọ yóò sì fi fìlà dé e ní orí, ìwọ yóò sì ṣe adé mímọ́ sára fìlà náà. 7Nígbà náà ni ìwọ yóò sì mú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì yà á sí mímọ́ nípa dída òróró sí i ní orí. 8Ìwọ yóò sì mú àwọn ọmọ rẹ̀ ìwọ yóò sì fi aṣọ àwọ̀tẹ́lẹ̀ wọ̀ wọ́n 9ìwọ yóò sì fi fìlà dé wọn ni orí. Nígbà náà fi ọ̀já àmùrè di Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀. Iṣẹ́ àlùfáà yóò máa jẹ́ tiwọn ní ìlànà títí ayé.

“Báyìí ni ìwọ yóò sì ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́.

10“Ìwọ yóò sì mú akọ màlúù wá síwájú àgọ́ àjọ, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì fi ọwọ́ wọn lé akọ màlúù ní orí. 11Ìwọ yóò sì pa àwọn akọ màlúù náà níwájú Olúwa ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ. 12Ìwọ yóò sì mú nínú ẹ̀jẹ̀ akọ màlúù náà, ìwọ yóò sì fi ìka rẹ tọ́ ọ sára ìwo pẹpẹ náà, kí o sì da gbogbo ẹ̀jẹ̀ tókù sí ìsàlẹ̀ pẹpẹ náà. 13Kí o mú gbogbo ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí tí ó bo ẹ̀dọ̀ àti ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ. 14Ṣùgbọ́n fi iná sun ẹran akọ màlúù, awọ rẹ̀ àti ìgbẹ́ rẹ̀ lẹ́yìn òde. Ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni.

15“Ìwọ yóò sì mú àgbò kan, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò sì gbọ́wọ́ lé orí àgbò náà. 16Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò sì mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì fi wọ́n pẹpẹ náà yíká. 17Ìwọ yóò sì gé àgbò náà sí wẹ́wẹ́, ìwọ yóò sì fọ inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tò wọ́n pẹ̀lú orí rẹ̀ lé ara wọn. 1829.18: Ef 5.2; Fp 4.18.Nígbà náà ni ìwọ yóò sun àgbò náà lórí pẹpẹ. Ẹbọ sísun ni sí Olúwa, olóòórùn dídùn ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe sí Olúwa ni.

19“Ìwọ yóò mú àgbò kejì, Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò fi ọwọ́ wọn lé àgbò náà lórí. 20Ìwọ yóò sì pa àgbò náà, ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ìwọ yóò sì tọ́ ọ sí etí ọ̀tún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, sí àtàǹpàkò ọwọ́ ọ̀tún wọn, àti sí àtàǹpàkò ẹsẹ̀ ọ̀tún wọn. Ìwọ yóò sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n pẹpẹ náà yíká. 21Ìwọ yóò mú nínú ẹ̀jẹ̀ tí ó wà lórí pẹpẹ àti nínú òróró ìtasórí, ìwọ yóò sì wọ́n ọn sára Aaroni àti sára aṣọ rẹ̀, sára àwọn ọmọ rẹ àti sára aṣọ wọn. Nígbà náà ni òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti aṣọ wọn yóò di mímọ́.

22“Ìwọ yóò mú lára ọ̀rá àgbò náà, ìrù tí ó lọ́ràá, ọ̀rá tí ó yí inú ká, èyí ti ó bo ẹ̀dọ̀, ìwé méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tí ó wà lára wọn àti itan ọ̀tún. (Èyí ni àgbò fún ìyàsímímọ́.) 23Láti inú apẹ̀rẹ̀ ìṣù àkàrà aláìwú, èyí tí ó wà níwájú Olúwa, mú ìṣù kan, àkàrà tí a fi òróró dín àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ kan. 24Ìwọ yóò fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì fì wọ́n gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fífì níwájú Olúwa. 25Nígbà náà ni ìwọ yóò sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ìwọ yóò sì sun wọ́n lórí pẹpẹ pẹ̀lú ẹbọ sísun fún òórùn dídùn níwájú Olúwa, ẹbọ ti a fi iná sun sí Olúwa. 26Ìwọ yóò sì mú igẹ̀ àgbò ìyàsímímọ́ Aaroni, ìwọ yóò si fí ì ni ẹbọ fífì níwájú Olúwa; ìpín tìrẹ ni èyí.

27“Ìwọ yóò sì ya igẹ̀ ẹbọ fífì náà sí mímọ́, àti ìtàn ẹbọ à gbé sọ sókè tí a fì, tí a sì gbé sọ sókè nínú àgbò ìyàsímímọ́ náà, àní nínú èyí tí í ṣe Aaroni àti nínú èyí tí ì ṣe tí àwọn ọmọ rẹ̀. 28Èyí ni yóò sì máa ṣe ìpín ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ láti ọwọ́ àwọn ọmọ Israẹli nígbà gbogbo. Nítorí ẹbọ à gbé sọ sókè ni ẹbọ tí yóò ṣì ṣe èyí ni ẹbọ tí àwọn ọmọ Israẹli yóò máa ṣe sí Olúwa láti inú ẹbọ àlàáfíà wọn.

29“Aṣọ mímọ́ Aaroni yóò jẹ́ ti irú àwọn ọmọ rẹ̀, nítorí kí a lè máa fi òróró yàn wọ́n kí a sì lè máa yà wọ́n sì mímọ́. 30Ọmọ rẹ̀ tí ó bá jẹ àlùfáà ní ipò rẹ̀, tí ó bá wọ̀ yóò máa sì wá sí àgọ́ àjọ láti ṣiṣẹ́ ní Ibi Mímọ́, yóò sì máa wọ̀ wọ́n ní ọjọ́ méje.

31“Ìwọ yóò sì mú àgbò fún ìyàsímímọ́, ìwọ yóò sì bọ ẹran rẹ̀ ní ibi mímọ́ kan. 32Ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ ni Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ yóò ti jẹ ẹran àgbò náà àti àkàrà náà tí ó wà nínú apẹ̀rẹ̀. 33Wọn yóò sì jẹ nǹkan wọ̀nyí èyí tí a fi ṣe ètùtù náà fún ìyàsímímọ́ àti ìsọdimímọ́ wọn. Ṣùgbọ́n àlejò ni kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀, nítorí pé mímọ́ ni. 34Bí ohun kan nínú ẹran àgbò ìyàsímímọ́ tàbí nínú àkàrà náà bá kù di òwúrọ̀, nígbà náà ni kí ìwọ fi iná sun wọn. A kò gbọdọ̀ jẹ ẹ́, nítorí mímọ́ ni.

35“Báyìí ni ìwọ yóò ṣì ṣe fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ bí ohun gbogbo ti mo paláṣẹ fún ọ, ọjọ́ méje ni ìwọ yóò fi yà wọ́n sí mímọ́. 36Ìwọ yóò sì máa pa akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ní ojoojúmọ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù. Ìwọ yóò sì wẹ pẹpẹ mọ́ nípa ṣíṣe ètùtù fún un, ìwọ yóò sì ta òróró sí i láti sọ ọ́ dí mímọ́. 37Ní ọjọ́ méje ni ìwọ yóò ṣe ètùtù sí pẹpẹ náà, ìwọ yóò sì sọ ọ́ di mímọ́. Nígbà náà ni pẹpẹ náà yóò jẹ́ mímọ́ jùlọ, àti ohunkóhun tí ó bá fi ọwọ́ kàn án yóò jẹ́ mímọ́.

3829.38-42: Nu 28.3-10.“Èyí ni ìwọ yóò máa fi rú ẹbọ ní orí pẹpẹ náà: Ọ̀dọ́-àgùntàn méjì ọlọ́dún kan ni ojoojúmọ́ láéláé. 39Ọ̀dọ́-àgùntàn kan ni ìwọ yóò fi rú ẹbọ ní òwúrọ̀ àti ọ̀dọ́-àgùntàn èkejì ní àṣálẹ́. 40Pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn ti àkọ́kọ́ rú ẹbọ ìdámẹ́wàá òsùwọ̀n ìyẹ̀fun dídára tí a fi ìdámẹ́rin hínì òróró lára olifi tí a gún, àti ìdámẹ́rin hínì wáìnì bí ẹbọ mímu. 41Ọ̀dọ́-àgùntàn kejì ni kí ìwọ kí ó pa rú ẹbọ ní àṣálẹ́ ìwọ yóò sì ṣe sí í gẹ́gẹ́ bí ẹbọ jíjẹ àti ẹbọ mímu bí ti òwúrọ̀ fún òórùn dídùn, ẹbọ tí a fi iná ṣe ni sí Olúwa.

42“Fún ìrandíran tó ń bọ̀, ni ẹ ó máa ṣe ẹbọ sísun nígbà gbogbo ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ níwájú Olúwa. Níbẹ̀ èmi yóò pàdé yín, èmi yóò sì bá a yín sọ̀rọ̀; 43níbẹ̀ sì tún ni èmi yóò pàdé àwọn ọmọ Israẹli, a ó sì fi ògo mi ya àgọ́ náà sí mímọ́.

44“Bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò ya àgọ́ àjọ náà sí mímọ́ àti pẹpẹ náà, èmi yóò sì ya Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀ sí mímọ́ láti máa ṣe iṣẹ́ bí àlùfáà fún mi. 45Nígbà náà ni èmi yóò máa gbé láàrín àwọn ọmọ Israẹli, èmi yóò sì máa ṣe Ọlọ́run wọn. 46Wọn yóò sì mọ̀ pé Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn, ẹni tí ó mú wọn jáde láti ilẹ̀ Ejibiti wá, nítorí kí èmi lè máa gbé àárín wọn. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

出埃及記 29:1-46

立祭司的條例

1「你要使亞倫父子們分別出來,做聖潔的祭司事奉我。你要選一頭公牛犢和兩隻毫無殘疾的公綿羊, 2用細麵粉預備無酵餅、調上油的無酵餅和塗上油的無酵薄餅。 3所有的餅都要用一個籃子盛,連同公牛和綿羊一起帶到會幕那裡。 4你要先讓亞倫父子們在會幕門前沐浴, 5然後給亞倫穿上內袍、以弗得和以弗得的外袍,戴上胸牌,束上精緻的以弗得帶子, 6戴上禮冠,把聖冠29·6 聖冠」應指28提到的金牌。繫在禮冠上。 7之後,把膏油倒在他的頭上,立他為祭司。 8接著輪到亞倫的兒子們,要給他們穿上內袍, 9為他們束上腰帶,戴上帽子,他們就按永遠的條例得到祭司的職分。你要這樣把聖職授予他們。

10「要把公牛牽到會幕前面,亞倫父子們要把手按在公牛頭上, 11在會幕門前,在耶和華面前宰牛。 12然後,把血帶到祭壇那裡,用手指把血塗在壇的四個角上,剩下的血倒在壇腳。 13再把遮蓋內臟的脂肪、肝、兩個腎臟和附在上面的脂肪都放在祭壇上燒掉。 14但牛皮、肉和糞要拿到營外焚燒。這是贖罪祭。

15「要把一隻公綿羊牽來,亞倫父子們要把手按在羊頭上, 16然後宰羊,把血灑在祭壇的四周。 17再把羊切成塊狀,用水洗淨所有的內臟和腿,跟肉塊和頭放在一起。 18然後,把整隻羊放在祭壇上焚燒,這是獻給耶和華的燔祭,是蒙耶和華悅納的馨香火祭。

19「你要把另一隻公綿羊牽來,亞倫父子們要把手按在羊頭上, 20然後宰羊,取一點血塗在亞倫和他兒子們的右耳垂、右手的大拇指和右腳的大腳趾上,餘下的血就灑在祭壇的四周。 21再從祭壇上取一點血,與膏油一起灑在亞倫父子及其衣服上。這樣,他們和他們的衣服就被分別出來,變得聖潔。

22「你要取出羊的脂肪、肥尾巴、遮蓋內臟的脂肪、肝葉、兩個腎臟和附在上面的脂肪以及右腿,因為這是授聖職時所獻的羊。 23再從耶和華面前的籃子裡取一個無酵餅、一個調油的無酵餅和一個薄餅。 24把這些祭物都放在亞倫和他兒子的手中,作為搖祭在耶和華面前搖一搖。 25然後,你要把這些祭物接過來,放在祭壇上焚燒獻給耶和華,成為蒙耶和華悅納的馨香火祭。 26你要拿起亞倫承受聖職時所獻的那頭公羊的胸肉,作為搖祭在耶和華面前搖一搖。之後,這份祭肉就歸你。

27「要將屬於亞倫父子們、授聖職時所獻的搖祭胸肉和舉祭腿肉分別出來,使之聖潔。 28這些祭物要從以色列人所獻的平安祭中取出來,歸給亞倫父子們,作為永遠的定例。這是以色列人當向耶和華獻的祭物。

29亞倫的聖衣要留給他的子孫,他們可以穿上這聖衣受膏,承受聖職。 30接替亞倫做祭司的那位後裔,每次進會幕的聖所供職時,都要一連七天穿著聖衣。

31「要在聖潔的地方煮授聖職時所用的公綿羊肉。 32亞倫父子們可以在會幕的門前吃這些祭肉和籃內的餅。 33他們要吃這些在授聖職時用來贖罪、使他們聖潔的祭物。但普通人不能吃,因為這些是聖物。 34若有授聖職時的肉或餅留到早上,就要燒掉,不可再吃,因為這些都是聖物。

35「你要照我的吩咐,為亞倫父子們舉行授聖職禮,歷時七天。 36每天要獻一頭公牛作贖罪祭潔淨祭壇,然後用膏油抹祭壇,使祭壇聖潔。 37你們連續七天都要這樣做,這樣祭壇便完全聖潔,凡是碰到祭壇的都變得聖潔。

38「你們每天要獻上兩隻一歲的羊羔作燔祭。 39一隻在早晨獻上,另一隻在黃昏獻上。 40要用一公斤細麵粉調一升橄欖油做成素祭,與早晨獻的羊羔一同獻上,再獻上一升酒作奠祭。 41另一隻羊要在黃昏的時候獻上,所獻的素祭和奠祭要跟早晨的一樣,作為蒙耶和華悅納的馨香火祭。

42「你們世世代代要不斷地在我面前獻上燔祭,祭禮要在會幕門前舉行,這會幕就是我跟你們會面和交談的地方。 43我要在那裡和以色列人相會,我的榮耀將使整座會幕聖潔。

44「我要使會幕和祭壇聖潔,也要使亞倫父子們聖潔,做祭司事奉我。 45我要住在以色列人中間,做他們的上帝。 46他們必知道我是他們的上帝耶和華。我帶領他們離開埃及,就是為了要住在他們中間。我是他們的上帝耶和華。