Eksodu 20 – YCB & PCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Eksodu 20:1-26

Òfin mẹ́wàá

1Ọlọ́run sì sọ gbogbo ọ̀rọ̀ yìí pé,

220.2-17: De 5.6-21.“Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó mú un yín jáde láti ilẹ̀ Ejibiti, láti oko ẹrú jáde wá.

320.3: Ek 20.23; De 5.7.“Ìwọ kò gbọdọ̀ ní ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi.

420.4: Ek 20.23; 34.17; Le 19.4; 26.1; De 4.15-19; 5.8; 27.15.Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ère fún ara yín, tàbí àwòrán ohun kan tí ń bẹ ní òkè ọ̀run, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀, tàbí ti ohun kan tí ń bẹ nínú omi ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀. 520.5,6: Ek 23.24; 34.6,7,14; De 4.24; 5.9,10; 7.9.Ìwọ kò gbọdọ̀ tẹ orí ara rẹ ba fún wọn, bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kò gbọdọ̀ sìn wọ́n; nítorí Èmi Olúwa Ọlọ́run rẹ, Ọlọ́run owú ni mí, tí ń bẹ ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba wò lára àwọn ọmọ, láti ìran kẹta títí dé ẹ̀kẹrin nínú àwọn tí ó kórìíra mi. 6Èmi a sì máa fi àánú hàn sí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn tí ó fẹ́ mi, tí wọ́n sì ń pa òfin mi mọ́.

720.7: Le 19.12; De 5.11.Ẹ má ṣe ṣi orúkọ Olúwa Ọlọ́run yín lò, torí pé ẹnikẹ́ni tí o bá ṣi orúkọ rẹ̀ lò kì yóò lọ láìjẹ̀bi.

820.8: Ek 23.12; 31.12-17; 34.21; 35.2,3; Le 19.3; De 5.12-15.Rántí ọjọ́ ìsinmi láti yà á sí mímọ́. 9Ọjọ́ mẹ́fà ni ìwọ yóò fi ṣiṣẹ́, kí ìwọ kí ó ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ, 10ṣùgbọ́n ọjọ́ keje ni ọjọ́ ìsinmi Olúwa Ọlọ́run rẹ: nínú rẹ̀ ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́kíṣẹ́ kan: ìwọ, àti ọmọ rẹ ọkùnrin àti ọmọ rẹ obìnrin, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ obìnrin, àti ẹran ọ̀sìn rẹ, àti àlejò rẹ, tí ń bẹ nínú ibodè rẹ. 11Nítorí ní ọjọ́ mẹ́fà ni Olúwa dá ọ̀run àti ayé, òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn, ó sì sinmi ní ọjọ́ keje: nítorí náà ni Olúwa ṣe bùkún ọjọ́ ìsinmi tí ó sì yà á sí mímọ́.

1220.12-16: Mt 19.18,19; Mk 10.19; Lk 18.20.20.12: Le 19.3; De 5.16; Mt 15.4; Mk 7.10; Ef 6.2.Bọ̀wọ̀ fún baba òun ìyá rẹ, kí ọjọ́ rẹ kí ó lè pẹ́ ní orí ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ.

1320.13: Gẹ 9.6; Ek 21.12; Le 24.17; De 5.17; Mt 5.21; Jk 2.11.20.13-17: Ro 13.9.Ìwọ kò gbọdọ̀ pànìyàn.

1420.14: Le 20.10; De 5.18; Mt 5.27; Ro 7.7.Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe panṣágà.

1520.15: Le 19.11; De 5.19.Ìwọ kò gbọdọ̀ jalè.

1620.16: Ek 23.1; De 5.20.Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́rìí èké sí ẹnìkejì rẹ.

1720.17: De 5.21; Ro 7.7.Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí ilé ẹnìkéjì rẹ. Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ojúkòkòrò sí aya ẹnìkéjì rẹ, ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ ọkùnrin àti ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ obìnrin, akọ màlúù rẹ̀ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀ àti ohun gbogbo tí í ṣe ti ẹnìkéjì rẹ.”

18Nígbà tí àwọn ènìyàn náà rí mọ̀nàmọ́ná tí wọ́n sí gbọ́ ohùn ìpè àti èéfín tí ń rú láti orí òkè, tí wọ́n sì gbọ́ sísán àrá, dídún ìpè kíkankíkan; wọ́n dúró ní òkèrè wọ́n sì ń gbọ̀n ṣìgàṣìgà fún ìbẹ̀rù. 19Wọ́n wí fún Mose pé, “Ìwọ fúnra rẹ̀ máa bá wa sọ̀rọ̀, àwa yóò sì gbọ́. Má ṣe jẹ́ kí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ kí ó bá wa sọ̀rọ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, àwa yóò kú.”

20Mose sì sọ fún àwọn ènìyàn náà pé, “Ẹ má bẹ̀rù. Ọlọ́run wá láti dán an yín wò, kí ẹ̀rù Ọlọ́run kí ó lè máa wà ní ara yín, kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣẹ̀.”

21Àwọn ènìyàn sì dúró ní òkèèrè nígbà tí Mose súnmọ́ ibi òkùnkùn biribiri níbi tí Ọlọ́run wà.

22Olúwa sì sọ fún Mose pé, “Sọ àwọn nǹkan wọ̀nyí fún àwọn ará Israẹli, ‘Ẹ̀yin ti rí i fúnra yín bí èmi ti bá a yín sọ̀rọ̀ láti ọ̀run wá. 2320.23: Ek 20.3,4; 34.17; De 27.15.Ẹ̀yin kò gbọdọ̀ sin ọlọ́run mìíràn pẹ̀lú mi: ẹ̀yin kò gbọdọ̀ rọ ọlọ́run fàdákà tàbí ọlọ́run wúrà fún ara yín.

2420.24: Ek 27.1-8; De 12.5; 26.2.“ ‘Pẹpẹ erùpẹ̀ ni kí ìwọ mọ fún mi. Ní orí pẹpẹ yìí ni kí ìwọ ti máa rú ẹbọ sísun rẹ sí mi àti ẹbọ àlàáfíà rẹ, àgùntàn rẹ, ewúrẹ́ àti akọ màlúù rẹ. Ní ibi gbogbo tí mo gbé fi ìrántí orúkọ mi sí, èmi yóò sì máa tọ̀ ọ́ wá, èmi yóò sì máa bùkún ọ níbẹ̀. 2520.25: De 27.5-7; Jo 8.31.Bí ìwọ bá ṣe pẹpẹ òkúta fún mi, má ṣe fi òkúta tí a ṣe lọ́ṣọ̀ọ́ kọ́ ọ, nítorí bí ìwọ bá lo ohun ọnà rẹ lórí rẹ̀, ìwọ sọ ọ di àìmọ́. 26Ìwọ kò gbọdọ̀ gun àkàsọ̀ lọ sí ibi pẹpẹ mi, kí àwọn ènìyàn má ba à máa wo ìhòhò rẹ láti abẹ́ aṣọ tí ìwọ wọ̀ nígbà tí ìwọ bá ń gòkè lọ sí ibi pẹpẹ.’

Persian Contemporary Bible

خروج 20:1-26

ده فرمان

(تثنيه 5‏:1‏-21)

1خدا با موسی سخن گفت و اين احكام را صادر كرد:

2«من خداوند، خدای تو هستم، همان خدايی كه تو را از اسارت و بندگی مصر آزاد كرد.

3«تو را خدايان ديگر غير از من نباشد.

4«هيچگونه بتی به شكل حيوان يا پرنده يا ماهی برای خود درست نكن. 5در برابر آنها زانو نزن و آنها را پرستش نكن، زيرا من كه خداوند، خدای تو می‌باشم، خدای غيوری هستم و كسانی را كه با من دشمنی كنند، مجازات می‌كنم. اين مجازات، شامل حال فرزندان آنها تا نسل سوم و چهارم نيز می‌گردد. 6اما بر كسانی كه مرا دوست داشته باشند و دستورات مرا پيروی كنند، تا هزار پشت رحمت می‌كنم.

7«از نام من كه خداوند، خدای تو هستم سوءاستفاده نكن. اگر نام مرا با بی‌احترامی به زبان بياوری يا به آن قسم دروغ بخوری، تو را مجازات می‌كنم.

8«روز سبت را به ياد داشته باش و آن را مقدس بدار. 9در هفته شش روز كار كن، 10ولی در روز هفتم كه ”سبت خداوند“ است هيچ كار نكن، نه خودت، نه پسرت، نه دخترت، نه غلامت، نه كنيزت، نه مهمانانت و نه چارپايانت. 11چون خداوند در شش روز، آسمان و زمين و دريا و هر چه را كه در آنهاست آفريد و روز هفتم دست از كار كشيد. پس او روز سبت را مبارک خواند و آن را روز استراحت تعيين نمود.

12«پدر و مادرت را احترام كن تا در سرزمينی كه خداوند، خدای تو به تو خواهد بخشيد، عمر طولانی داشته باشی.

13«قتل نكن.

14«زنا نكن.

15«دزدی نكن.

16«دروغ نگو.

17«چشم طمع به مال و ناموس ديگران نداشته باش. به فكر تصاحب غلام و كنيز، گاو و الاغ، و اموال همسايه‌ات نباش.»

18وقتی قوم اسرائيل رعد و برق و بالا رفتن دود را از كوه ديدند و صدای شيپور را شنيدند، از ترس لرزيدند. آنها در فاصله‌ای دور از كوه ايستادند و 19به موسی گفتند:

«تو پيام خدا را بگير و به ما برسان و ما اطاعت می‌كنيم. خدا مستقيماً با ما صحبت نكند، چون می‌ترسيم بميريم.»

20موسی گفت: «نترسيد، چون خدا برای اين نزول كرده، كه قدرت خود را بر شما ظاهر سازد تا از اين پس از او بترسيد و گناه نكنيد.»

21در حالی که همهٔ قوم آنجا ايستاده بودند، ديدند كه موسی به ظلمت غليظی كه خدا در آن بود، نزديک شد.

مقررات قربانگاه

22آنگاه خداوند از موسی خواست تا به قوم اسرائيل چنين بگويد:

«شما خود ديديد چگونه از آسمان با شما صحبت كردم، 23پس ديگر برای خود خدايانی از طلا و نقره نسازيد و آنها را پرستش نكنيد. 24قربانگاهی كه برای من می‌سازيد بايد از خاک زمين باشد. از گله و رمهٔ خود قربانیهای سوختنی و هدايای سلامتی روی اين قربانگاه قربانی كنيد. در جايی كه من برای عبادت تعيين می‌كنم قربانگاه بسازيد تا من آمده، شما را در آنجا بركت دهم. 25اگر خواستيد قربانگاه را از سنگ بنا كنيد، سنگها را با ابزار نشكنيد و نتراشيد، چون سنگهايی كه روی آنها ابزار به کار رفته باشد مناسب قربانگاه من نيستند. 26برای قربانگاه، پله نگذاريد مبادا وقتی از پله‌ها بالا می‌رويد عورت شما ديده شود.