Efesu 1 – YCB & NUB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Efesu 1:1-23

1Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run,

Sí àwọn ènìyàn mímọ́ tí ó wà ní Efesu, àti sí àwọn olóòtítọ́ nínú Kristi Jesu:

2Oore-ọ̀fẹ́ sí yín àti àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wá àti Jesu Kristi Olúwa.

Ìbùkún ti Ẹ̀mí Mímọ́ nínú Kristi

31.3: 2Kọ 1.3.Ògo ni fún Ọlọ́run àti Baba Jesu Kristi Olúwa wa, ẹni tí ó ti bùkún wa láti inú ọ̀run wá pẹ̀lú àwọn ìbùkún ẹ̀mí gbogbo nínú Kristi. 4Àní, gẹ́gẹ́ bí o ti yàn wá nínú rẹ̀ ṣáájú ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, láti jẹ́ mímọ́ àti aláìlábùkù níwájú rẹ̀ nínú ìfẹ́ 5ẹni tí ò ti yàn wá tẹ́lẹ̀ sí ìsọdọmọ nípa Jesu Kristi fún ara rẹ̀, ní ìbámu ìdùnnú ìfẹ́ rẹ̀, 61.6: Kl 1.13.fún ìyìn ògo oore-ọ̀fẹ́ rẹ̀, èyí tí ò ti fi fún wa nínú Àyànfẹ́ rẹ̀. 71.7: Kl 1.14.Nínú rẹ̀ ni àwa rí ìràpadà gba nípa ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ àti ìdáríjì àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, ní ìbámu pẹ̀lú ọrọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run 8èyí tí ó fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ pẹ̀lú gbogbo ọgbọ́n àti ìmòye, 9Ó ti sọ ohun ìjìnlẹ̀ ìfẹ́ rẹ̀ di mí mọ̀ fún wa gẹ́gẹ́ bí ìdùnnú rere rẹ̀, èyí ti o pinnu nínú Kristi, 101.10: Ga 4.4.èyí tí yóò jẹ jáde ní kíkún àkókò, láti ṣe àkójọpọ̀ àwọn ohun tí ọ̀run àti ti ayé lábẹ́ Kristi.

11Nínú rẹ̀ ni a yàn wá fẹ́ lẹ́yìn tí ó ti yàn wá tẹ́lẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu ẹni tí ń ṣiṣẹ́ ohun gbogbo ní ìbámu ìfẹ́ rẹ̀, 12kí àwa kí ó le wà fún ìyìn ògo rẹ̀, àwa tí a ti ni ìrètí ṣáájú nínú Kristi. 13Àti ẹ̀yin pẹ̀lú darapọ̀ nínú Kristi nígbà tí ẹ̀yin gbọ́ ọ̀rọ̀ òtítọ́ náà àní ìyìnrere ìgbàlà yin. Nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́, a fi Ẹ̀mí Mímọ́ ṣe èdìdì ayé yin nínú rẹ, èyí tí a ti ṣe ìlérí rẹ̀ tẹ́lẹ̀, 141.14: 2Kọ 1.22.èyí tí ó jẹ́ ìdánilójú àṣansílẹ̀ ogún wa títí yóò fi di àkókò ìràpadà àwọn tí í ṣe ti Ọlọ́run sí ìyìn ògo rẹ̀.

Ìdúpẹ́ àti àdúrà

151.15: Kl 1.9.Nítorí ìdí èyí, nígbà tí mo ti gbúròó ìgbàgbọ́ ti ń bẹ láàrín yín nínú Jesu Olúwa, àti ìfẹ́ yín sí gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. 161.16: Kl 1.3.Èmi kò sì sinmi láti máa dúpẹ́ nítorí yín, àti láti máa rántí yín nínú àdúrà mi. 17Mo sì ń béèrè nígbà gbogbo pé kí Ọlọ́run Jesu Kristi Olúwa wa, Baba ògo, lè fún yín ni Ẹ̀mí nípa ti ọgbọ́n àti ti ìfihàn kí ẹ̀yin kí ó tún lè mọ̀ ọ́n sí i. 181.18: De 33.3.Mo tún ń gbàdúrà bákan náà wí pé kí ojú ọkàn yín lè mọ́lẹ̀; kí ẹ̀yin lè mọ ohun tí ìrètí ìpè rẹ̀ jẹ́, àti ọrọ̀ ògo rẹ̀ èyí tí í ṣe ogún àwọn ènìyàn mímọ́, 19àti aláìlẹ́gbẹ́ títóbi agbára rẹ̀ fún àwa tí a gbàgbọ́. Gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ agbára rẹ̀, 201.20: Sm 110.1.èyí tí ó fi sínú Kristi, nígbà tí o ti jí dìde kúrò nínú òkú, tí ó sì mú un jókòó lọ́wọ́ ọ̀tún nínú àwọn ọ̀run. 211.21: Kl 1.6; 2.10,15.Ó gbéga ju gbogbo ìjọba, àti àṣẹ, àti agbára, àti òye àti gbogbo orúkọ tí a ń dá, kì í ṣe ni ayé yìí nìkan, ṣùgbọ́n ni èyí tí ń bọ̀ pẹ̀lú. 221.22: Sm 8.6; Kl 1.18.Ọlọ́run sì ti fi ohun gbogbo sábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, ó sì fi í ṣe orí lórí ohun gbogbo fún ìjọ, 231.23: Ro 12.5; Kl 2.17.èyí tí i ṣe ara rẹ̀, ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ẹni tí ó kún ohun gbogbo ní gbogbo ọ̀nà.

Swedish Contemporary Bible

Efesierbrevet 1:1-23

Hälsning

1Från Paulus, som genom Guds vilja är apostel1:1 Eller sändebud. åt Kristus1:1 Se not till Matt 1:1. Jesus.

Till de heliga i Efesos som är trogna i Kristus Jesus.

2Nåd och frid från Gud, vår Fader, och Herren Jesus Kristus.

Inledande hyllning till Gud

3Välsignad är vår Herre Jesus Kristus Gud och Fader, som i Kristus har välsignat oss med all andlig välsignelse från den himmelska världen i Kristus, 4liksom han, innan världen skapades, utvalde oss att vara heliga och fläckfria inför sig i kärlek. 5Han har genom Jesus Kristus förutbestämt oss till att bli hans barn. Detta var hans vilja och beslut 6till pris och ära för den nåd han har skänkt oss i den Älskade. 7I honom är vi friköpta genom hans blod, och vi har fått förlåtelse för våra överträdelser på grund av den rika nåd 8som han lät flöda över oss, med vishet och insikt. 9Han avslöjade nämligen sin hemliga1:9 Paulus använde ordet hemlig för att gå emot den religionsblandning som förekom i området och för vilken detta var en viktig term. plan för oss – det beslut om Kristus som han från början hade fattat. 10Det skulle genomföras när tiden var inne: att sammanfatta allting i Kristus, både i himlen och på jorden.

11I honom har vi också fått vårt arv, eftersom vi är förutbestämda till det av honom som genomför allting efter sin vilja och sitt beslut. 12Detta var för att vi som var de första att börja hoppas på Kristus, skulle hylla och ära Gud. 13Men i honom har också ni fått höra det sanna budskapet, evangeliet som kan rädda er. Och i honom har också ni, efter att ha kommit till tro, fått den heliga Anden som ett sigill. 14Anden är garantin för vårt arv, att Guds eget folk ska friköpas och Gud hyllas och äras.

Paulus tackar för församlingen och ber om andlig vishet

15Ända sedan jag fick höra om er tro på Herren Jesus och om er kärlek till alla de heliga 16har jag ständigt tackat Gud när jag har bett för er. 17Jag ber att vår Herre Jesus Kristus Gud, härlighetens Fader, ska ge er vishetens och uppenbarelsens Ande, så att ni lär känna honom mer. 18Jag ber att era hjärtan ska upplysas, så att ni inser vad det är för hopp han har kallat er till och vilka härliga rikedomar som han låter de heliga få ärva, 19och hur otroligt stark hans kraft är för oss som tror. Det är samma mäktiga kraft 20som han lät verka i Kristus, när han uppväckte honom från de döda och satte honom på sin högra sida i himlen,1:20 Jfr Ps 110:1. 21högt över alla härskare, makter, krafter och auktoriteter,1:21 Området där Efesos låg var känt för sin ängladyrkan, som benämningarna kan tänkas syfta på, och Paulus ville visa att änglarna står under Jesus. över alla namn som kan nämnas, såväl i den här tidsåldern som i den kommande. 22Allt lade han under hans fötter1:22 Se Ps 8:7., och honom som är huvud över allting gjorde han också till huvud för församlingen. 23Församlingen är hans kropp, fullheten av honom som uppfyller allt i allting.1:23 Jfr Jer 23:24.