Deuteronomi 27 – YCB & AKCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 27:1-26

Pẹpẹ ní orí òkè Ebali

1Mose àti àwọn àgbàgbà Israẹli pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé, “Pa gbogbo àṣẹ tí mo fún ọ lónìí mọ́. 2Nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani sí inú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, gbé kalẹ̀ lára àwọn òkúta ńlá àti aṣọ ìlekè rẹ pẹ̀lú ẹfun. 3Kí ìwọ kí ó kọ gbogbo ọ̀rọ̀ òfin yìí sára wọn nígbà tí ìwọ bá ti ń rékọjá láti wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fún ọ, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin, gẹ́gẹ́ bí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti ṣèlérí fún ọ. 4Àti nígbà tí o bá ti kọjá a Jordani, kí o gbé òkúta yìí kalẹ̀ sórí i Ebali, bí mo ti pa à láṣẹ fún ọ lónìí, kí o sì wọ̀ wọ́n pẹ̀lú ẹfun. 5Kọ́ pẹpẹ síbẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, pẹpẹ òkúta. Má ṣe lo ohun èlò irin lórí wọn. 6Kí ìwọ kí ó mọ pẹpẹ pẹ̀lú òkúta àìgbẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí ìwọ kí ó sì máa rú ẹbọ sísun ni orí rẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ. 7Rú ẹbọ àlàáfíà níbẹ̀ kí o jẹ wọ́n, kí o sì yọ̀ níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ. 8Kí o sì kọ gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ òfin yìí ketekete sórí òkúta tí ó ti gbé kalẹ̀.”

Ègún ní orí òkè Ebali

9Nígbà náà ni Mose àti àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, sọ fún Israẹli pé, “Ẹ dákẹ́ ẹ̀yin Israẹli, kí ẹ sì fetísílẹ̀! O ti wá di ènìyàn Olúwa Ọlọ́run rẹ báyìí. 10Gbọ́rọ̀ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ kí o sì tẹ̀lé àṣẹ àti òfin rẹ̀ tí mo ń fi fún ọ lónìí.”

11Ní ọjọ́ kan náà Mose pàṣẹ fún àwọn ènìyàn pé.

12Nígbà tí ìwọ bá ti kọjá a Jordani, àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Gerisimu láti súre fún àwọn ènìyàn: Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Josẹfu àti Benjamini. 13Àwọn ẹ̀yà yìí yóò dúró lórí òkè Ebali láti gé ègún: Reubeni, Gadi, àti Aṣeri, àti Sebuluni, Dani, àti Naftali.

14Àwọn ẹ̀yà Lefi yóò ké sí gbogbo ènìyàn Israẹli ní ohùn òkè:

1527.15: Ek 20.4,23; 34.17; Le 19.4; 26.1; De 4.16,23,25; 5.8; 7.25.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó fín ère tàbí gbẹ́ òrìṣà ohun tí ó jẹ́ ìríra níwájú Olúwa, iṣẹ́ ọwọ́ oníṣọ̀nà tí ó gbé kalẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

1627.16: Ek 20.12; 21.15,17; Le 20.9; De 5.16; 21.18-21.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dójútì baba tàbí ìyá rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

17“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí òkúta ààlà aládùúgbò o rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

1827.18: Le 19.14.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ṣi afọ́jú lọ́nà ní ojú ọ̀nà.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

1927.19: Ek 22.21-24; 23.9; Le 19.33,34; De 24.17,18.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó yí ìdájọ́ po fún àlejò, aláìní baba tàbí opó.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

2027.20: Le 18.8; 20.11; De 22.30.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyàwó baba rẹ̀, nítorí ó ti dójúti ibùsùn baba rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

2127.21: Ek 22.19; Le 18.23; 20.15.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ẹranko.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

22“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú arábìnrin rẹ̀, ọmọbìnrin baba rẹ̀ tàbí ọmọbìnrin ìyá rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

2327.23: Le 18.17; 20.14.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó dùbúlẹ̀ pẹ̀lú ìyá ìyàwó o rẹ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

24“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó pa aládùúgbò rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

25“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí ó gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀ láti pa ènìyàn láìjẹ̀bi.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

2627.26: Ga 3.10.“Ègún ni fún ọkùnrin náà tí kò gbé ọ̀rọ̀ òfin yìí ró nípa ṣíṣe wọ́n.”

Nígbà náà ni gbogbo ènìyàn wọ̀nyí yóò wí pé, “Àmín!”

Akuapem Twi Contemporary Bible

5 Mose 27:1-26

Bepɔw Ebal Afɔremuka

1Mose ne Israel mpanyimfo hyɛɛ ɔmanfo no se, “Munni mmara a mede rema mo nnɛ yi nyinaa so. 2Sɛ mutwa Yordan kodu asase a Awurade, mo Nyankopɔn no, de rema mo no so a, monhyehyɛ abo akɛse na momfa akaadoo nsra ho. 3Sɛ mutwa Yordan kɔ asase a Awurade, mo Nyankopɔn no, de rema mo no so, asase a ɛwo ne nufusu resen so no so a, monkyerɛw mmara no nyinaa ngu so sɛnea Awurade, mo agyanom Nyankopɔn, hyɛɛ mo bɔ no. 4Na sɛ mutwa Yordan a, monhyehyɛ abo yi wɔ Ebal bepɔw so sɛnea merehyɛ mo nnɛ yi na momfa akaadoo nsra ho. 5Munsi afɔremuka, abo afɔremuka wɔ hɔ mma Awurade, mo Nyankopɔn no. Mommfa dade biribiara nka. 6Momfa abo amuamu nsi Awurade, mo Nyankopɔn no, afɔremuka no na mommɔ ɔhyew afɔre wɔ so mma Awurade, mo Nyankopɔn no. 7Mommɔ asomdwoe afɔre nso wɔ so na momfa anigye nnidi wɔ hɔ wɔ Awurade, mo Nyankopɔn no, anim. 8Monkyerɛw mmara no mu nhyehyɛe nyinaa pɛpɛɛpɛ ngu abo a wɔde akaadoo asra ho no so.”

Nnome A Efi Bepɔw Ebal So

9Afei, Mose ne Lewifo asɔfo kasa kyerɛɛ Israelfo no se, “Israel, monyɛ komm na muntie! Nnɛ, moabɛyɛ Awurade, mo Nyankopɔn no, manfo. 10Monyɛ osetie mma Awurade, mo Nyankopɔn no, na munni ne mmara ne nʼahyɛde a mede rema mo nnɛ yi so.”

11Saa da no ara, Mose hyɛɛ ɔmanfo no se:

12Sɛ mutwa Asubɔnten Yordan a Simeon, Lewi, Yuda, Isakar, Yosef ne Benyamin mmusuakuw na wonnyina Gerisim bepɔw so nhyira ɔman no. 13Ruben, Gad, Aser, Sebulon, Dan ne Naftali mmusuakuw nso nnyina Ebal bepɔw so nnome.

14Lewifo nteɛteɛ mu nworo ngu nnipa a wɔwɔ Israel nyinaa so se:

15“Nnome nka onipa a ɔbɛyɛ ohoni a wɔasen anaa nea wɔagu de ahyɛ kokoa mu. Saa ahoni, adwumfo nsa ano nnwuma yi yɛ Awurade akyiwade.”

Na ɔman no nyinaa begye so se, “Amen!”

16“Nnome nka obiara a obebu nʼagya anaa ne na animtiaa.”

Na ɔman no nyinaa begye so se, “Amen!”

17“Nnome nka obiara a opia ɔhye nam so bɔ ne yɔnko korɔn.”

Na ɔman no nyinaa begye so se, “Amen!”

18“Nnome nka obiara a ɔma onifuraefo fom kwan.”

Na ɔman no nyinaa begye so se, “Amen!”

19“Nnome nka obiara a osisi ahɔho, nyisaa ne akunafo.”

Na ɔman no nyinaa begye so se, “Amen!”

20“Nnome nka obiara a ɔne nʼagya yere bɛda, efisɛ wagu nʼagya mpa ho fi.”

Na ɔman no nyinaa begye so se, “Amen!”

21“Nnome nka obiara a ɔne aboa bɛda.”

Na ɔman no nyinaa begye so se, “Amen!”

22“Nnome nka obiara a ɔne ne nuabea bɛda, sɛ ɔyɛ nʼagya babea anaa ne na babea.”

Na ɔman no nyinaa begye so se, “Amen!”

23“Nnome nka obiara a ɔne nʼasebea bɛda.”

Na ɔman no nyinaa begye so se, “Amen!”

24“Nnome nka obiara a obekum ɔfoforo wɔ kokoa mu.”

Na ɔman no nyinaa begye so se, “Amen!”

25“Nnome nka obiara a ogye apaade, kum onipa a ɔnyɛɛ bɔne biara.”

Na ɔman no nyinaa begye so se, “Amen!”

26“Nnome nka obiara a wanni mmara nsɛm yi so na wannye anto mu.”

Na ɔman no nyinaa begye so se, “Amen!”