Deuteronomi 26 – YCB & KLB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 26:1-19

Àkọ́so àti ìdámẹ́wàá

126.1-11: El 22.29; 23.19; 34.26; Nu 18.12,13.Nígbà tí ìwọ bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ gẹ́gẹ́ bí ohun ìní tí ìwọ sì ti jogún, tí ìwọ sì ti ń gbé níbẹ̀, 2mú díẹ̀ nínú ohun tí o pèsè láti inú erùpẹ̀ ilẹ̀ náà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ń fi fún ọ, kó wọn sínú agbọ̀n. Nígbà náà kí o lọ sí ibi tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò yàn gẹ́gẹ́ bí ibi tí orúkọ rẹ̀ yóò máa gbé. 3Kí o sì sọ fun àlùfáà tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní àsìkò náà, pé, “Mo sọ ọ́ di mí mọ̀ fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé mo ti wá sí ilẹ̀ tí Olúwa búra fún àwọn baba wa.” 4Àlùfáà yóò gbé agbọ̀n náà kúrò ní ọwọ́ rẹ, yóò sì gbé e kalẹ̀ níwájú pẹpẹ Olúwa Ọlọ́run rẹ. 5Nígbà náà ni ìwọ yóò sọ ní iwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Baba mi jẹ́ alárìnkiri ará Aramu, ó sì sọ̀kalẹ̀ wá sí Ejibiti pẹ̀lú ènìyàn díẹ̀, ó sì ń gbé níbẹ̀, ó sì wá di orílẹ̀-èdè olókìkí, alágbára, tí ó kún fún ọ̀pọ̀ ènìyàn. 6Ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti ṣe àìdára sí wa, wọ́n jẹ wá ní yà, wọ́n fún wa ní iṣẹ́ líle ṣe. 7Nígbà náà ni a kégbe pe Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wa, Olúwa sì gbọ́ ohùn wa, ó sì rí ìrora, làálàá àti ìnira wa. 8Nígbà náà ni Olúwa mú wa jáde wá láti Ejibiti pẹ̀lú ọwọ́ agbára àti apá nínà, pẹ̀lú ẹ̀rù ńlá àti iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu. 9Ó mú wa wá síbí, ó sì fún wa ní ilẹ̀ yìí, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti oyin; 10àti pé ní báyìí, mo mú àkọ́so ilẹ̀ tí ìwọ Olúwa ti fún mi wá.” Ìwọ yóò gbé agbọ̀n náà síwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì wólẹ̀ níwájú u rẹ̀. 11Ìwọ àti àwọn ọmọ Lefi àti àjèjì láàrín yín yóò máa yọ̀ nínú gbogbo oore tí Olúwa ti fi fún ọ àti fún àwọn ará ilé rẹ.

12Nígbà tí ìwọ bá ṣetán láti ya ìdámẹ́wàá gbogbo ohun tí o ti mú jáde ní ọdún kẹta sọ́tọ̀ sí apá kan. Ọdún ìdámẹ́wàá, ìwọ yóò fi fún ọmọ Lefi, àjèjì, aláìní baba àti opó, kí wọn kí ó lè jẹ ní àwọn ìlú rẹ, kí wọn sì yó. 13Nígbà náà ní kí o wí fún Olúwa Ọlọ́run rẹ pé, “Èmi ti mú ohun mímọ́ kúrò nínú ilé mi, èmi sì ti fi fún àwọn Lefi, àwọn àjèjì, àwọn aláìní baba àti àwọn opó, gẹ́gẹ́ bí ohun gbogbo tí ìwọ ti pàṣẹ. Èmi kò yípadà kúrò nínú àṣẹ rẹ bẹ́ẹ̀ ni èmi kò gbàgbé ọ̀kankan nínú wọn. 14Èmi kò jẹ lára ohun mímọ́ ní ìgbà tí mo ń ṣọ̀fọ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu nínú wọn ní ìgbà tí mo wà ní àìmọ́, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi nínú wọn fún òkú. Èmi ti ṣe ìgbọ́ràn sí Olúwa Ọlọ́run mi, èmi sì ti ṣe gbogbo ohun tí ó pàṣẹ fún mi. 15Wo ilẹ̀ láti ọ̀run wá, ibùgbé mímọ́ rẹ, kí o sì bùkún fún àwọn ènìyàn Israẹli, àti fún ilẹ̀ náà tí ìwọ ti fi fún wa, bí ìwọ ti búra fún àwọn baba ńlá wa, ilẹ̀ tí ó ń sàn fún wàrà àti fún oyin.”

Tẹ̀lé àṣẹ Olúwa

16Olúwa Ọlọ́run rẹ pàṣẹ fún ọ ní òní láti máa tẹ̀lé àwọn ìlànà àti òfin, kí o sì máa ṣe wọ́n pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo àyà rẹ. 17Ìwọ jẹ́wọ́ Olúwa ní òní pé Olúwa ni Ọlọ́run rẹ, àti pé ìwọ yóò máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀ gbogbo, àti pé ìwọ yóò máa pa ìlànà rẹ̀, àṣẹ rẹ̀ àti òfin rẹ̀ mọ́, àti pé ìwọ yóò máa ṣe ìgbọ́ràn sí i. 18Ní òní ni Olúwa jẹ́wọ́ rẹ pé ìwọ ni ènìyàn òun, ilé ìṣúra rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí, àti pé ìwọ yóò máa pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ mọ́. 19Òun sì jẹ́wọ́ pé, òun yóò gbé ọ sókè ju gbogbo orílẹ̀-èdè tí òun ti dá lọ, ní ìyìn, ní òkìkí àti ní ọlá; kí ìwọ kí ó le jẹ́ ènìyàn mímọ́ sí Olúwa Ọlọ́run rẹ gẹ́gẹ́ bí òun ti ṣe ìlérí.

Korean Living Bible

신명기 26:1-19

첫열매와 십일조

1“여러분은 여호와 하나님이 주시는 땅을 점령하여 그 곳에 살게 될 때

2그 해 추수한 모든 농작물의 첫열매를 광주리에 담아 여러분의 하나님 여호와께서 예배처로 지정하신 곳으로 가지고 가

3담당 제사장에게 주면서 ‘이것은 나의 하나님 여호와께서 우리 조상들에게 약속하신 땅에 내가 들어온 것을 인정하는 예물입니다’ 하고 말하십시오.

4그러면 제사장은 그 광주리를 받아 여러분의 하나님 여호와의 제단 앞에 놓아야 하며

5여러분은 여러분의 하나님 여호와 앞에서 이렇게 말해야 합니다. ‘내 조상은 떠돌아다니며 사는 아람 사람이었는데 그가 가족을 데리고 이집트로 내려갔습니다. 그들은 처음에 몇 사람밖에 되지 않았지만 후에 크고 강한 민족이 되었습니다.

6그러나 이집트 사람들이 우리를 학대하고 강제 노동으로 우리를 혹사시키므로

7우리가 조상들의 하나님 여호와께 부르짖었습니다. 그때 여호와께서는 우리의 부르짖음을 들으시고 우리가 당하는 고통과 시련을 보셨습니다.

8그러므로 여호와께서 큰 능력과 놀라운 기적으로 우리를 이집트에서 구출하여

9이 곳으로 인도해 내시고 26:9 원문에는 ‘젖과 꿀이 흐르는 땅’기름지고 비옥한 이 땅을 우리에게 주셨습니다.

10그래서 내가 여호와께서 주신 농작물의 첫열매를 가져왔습니다.’ 그러고서 여러분은 그것을 여러분의 하나님 여호와 앞에 놓고 그분에게 경배하십시오.

11그런 후에 여호와 하나님이 여러분과 여러분의 집에 주신 모든 좋은 것들에 대하여 여러분은 레위인과 여러분 가운데 사는 외국인과 함께 즐거워하십시오.

12“3년마다 한 번씩 여러분은 특별히 농작물의 십일조를 거두어 레위인과 외국인과 고아와 과부에게 주어 여러분의 성 안에서 먹고 살게 하십시오.

13여러분은 그렇게 한 다음에 여러분의 하나님 여호와 앞에서 이렇게 말하십시오. ‘내가 주께서 명령하신 대로 모든 십일조를 레위인과 외국인과 고아와 과부에게 주어 십일조에 관한 주의 명령을 어기지 않았고 그것을 잊지도 않았습니다.

14내가 슬픔을 당했을 때 십일조를 먹지 않았고 부정한 몸으로 그것을 만지지 않았으며 죽은 자에게 그것을 제물로 바치지도 않았습니다. 나는 나의 하나님 여호와께 순종하여 주께서 나에게 명령하신 모든 것을 그대로 다 실행하였습니다.

15주의 거룩한 처소인 하늘에서 내려다보시고 주의 백성 이스라엘에게 복을 주시며 또 주께서 우리 조상들에게 약속하신 대로 우리에게 주신 그 기름지고 비옥한 땅에 복을 내려 주소서.’ ”

여호와의 보배로운 백성

16“여러분은 오늘 여호와 하나님이 여러분에게 주시는 이 모든 법과 규정을 마음과 정성을 다하여 충실히 지키십시오.

17오늘 여러분은 여호와를 여러분의 하나님으로 인정하고 또 그분에게 순종하며 그분이 명령하신 모든 법과 규정을 지키겠다고 약속하였습니다.

18그리고 여호와께서도 약속하신 대로 여러분을 보배로운 자기 백성으로 인정하시고 여러분이 그분의 모든 명령을 지켜야 한다고 선언하셨습니다.

19여호와께서는 여러분을 다른 민족보다 뛰어난 민족이 되게 하시고 칭찬과 명예와 영광을 얻게 하시며 약속하신 대로 여러분을 그분의 거룩한 백성이 되게 하실 것입니다.”