Deuteronomi 19 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 19:1-21

Ìlú ààbò

119.1-13: Ek 21.12-14; Nu 35.Nígbà tí Olúwa Ọlọ́run rẹ bá ti pa àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò fi ilẹ̀ wọn fún ọ run, àti nígbà tí ìwọ bá ti lé wọn jáde tí o sì dó sí àwọn ilẹ̀ àti ilé wọn gbogbo. 2Ìwọ yóò ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara à rẹ láàrín ilẹ̀ rẹ tí Olúwa Ọlọ́run fún ọ láti ni. 3Ṣe àwọn ọ̀nà sí wọn àti kí o pín ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún sí ọ̀nà mẹ́ta nítorí kí apànìyàn lè sá níbẹ̀.

4Èyí ni òfin nípa apànìyàn, tí ó sì sá síbẹ̀ láti pa ẹ̀mí rẹ̀ mọ́. Ẹni tí ó pa aládùúgbò láìmọ̀ọ́mọ̀ṣeé láìjẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́. 5Bí àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan lè lọ sínú igbó pẹ̀lú aládùúgbò rẹ̀ láti gé igi, bí ó sì ti gbé àáké e rẹ̀ láti gé igi náà lulẹ̀, bí àáké náà bá yọ tí ó sì bà aládùúgbò rẹ̀, tí òun sì kú. Ọkùnrin yìí lè sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú yìí láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là. 6Bí kò ṣe bẹ́ẹ̀, agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lè máa lépa rẹ̀ nínú ìbínú, kí ó sì lé e bá nítorí pé ọ̀nà jì, kí ó sì pa á bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò yẹ sí ikú, nígbà tí ó ṣe é sí aládùúgbò rẹ̀ láìjẹ́ pé ó ti ní àrankàn pẹ̀lú u rẹ̀ láti ọjọ́ pípẹ́. 7Ìdí nìyìí tí mo fi pa á láṣẹ fún ọ láti ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀ fún ara rẹ.

8Olúwa Ọlọ́run rẹ bá sì fẹ́ agbègbè rẹ, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìbúra fún àwọn baba ńlá a yín, tí ó sì fún ọ ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ti ṣe ìlérí fún wọn, 9nítorí tí ìwọ fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ tẹ̀lé gbogbo òfin yìí tí mo pàṣẹ fún ọ lónìí yìí, kí o fẹ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ, kí o sì rìn ní ọ̀nà an rẹ̀ ní gbogbo ìgbà náà, kí o ya ìlú mẹ́ta sọ́tọ̀. 10Ṣe èyí kí a má ṣe ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀ ni ilẹ̀ rẹ, èyí tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fún ọ gẹ́gẹ́ bí ogún, kí ìwọ kí ó má bá a jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ títa.

11Ṣùgbọ́n tí ọkùnrin kan bá kórìíra arákùnrin rẹ̀, tí ó sì lúgọ dè é, tí ó mú u tí o lù ú pa, tí ọkùnrin náà sì sálọ sí ọ̀kan nínú àwọn ìlú wọ̀nyí, 12àwọn àgbàgbà ìlú rẹ yóò sì ránṣẹ́ pè é ìwọ, yóò sì mú un padà láti ìlú náà, wọn yóò sì fi í lé àwọn agbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ lọ́wọ́ kí ó lè kú. 13Má ṣe ṣàánú fún un. O ní láti fọ ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ kúrò ni Israẹli, kí ó bá à lè dára fún ọ.

14Má ṣe pa òkúta ààlà aládùúgbò rẹ dà tí aṣíwájú rẹ fi lélẹ̀ nínú ogún tí ó gbà nínú ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ fi fún ọ láti ni ní ìní.

Ẹlẹ́rìí

1519.15: Nu 35.30; De 17.6; Mt 18.16; 2Kọ 13.1; 1Tm 5.19; Hb 10.28.Ẹlẹ́rìí kan ṣoṣo kò tó láti dájọ́ ọkùnrin kan tí o fi ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ yóò wù kí ó lè ṣẹ̀ lẹ́bi. A ó fi ìdí ọ̀rọ̀ múlẹ̀ láti orí ẹ̀rí ẹni méjì tàbí mẹ́ta.

1619.16-20: El 20.16; 23.1; Le 19.16; De 5.20.Tí alárankàn ẹlẹ́rìí èké bá dúró láti fi ẹ̀sùn ẹ̀ṣẹ̀ kan ọkùnrin kan, 17àwọn méjèèjì tí àríyànjiyàn wà láàrín wọn gbọdọ̀ dúró níwájú Olúwa níwájú àwọn àlùfáà àti àwọn adájọ́ tí ó wà ní ibi iṣẹ́ ní ìgbà náà. 18Àwọn adájọ́ gbọdọ̀ ṣe ìwádìí fínní fínní bí ẹ̀rí bá sì jẹ́ irọ́, tí ó fi ẹ̀rí èké sun arákùnrin rẹ̀, 1919.19: 1Kọ 5.13.nígbà náà ni kí ó ṣe sí i gẹ́gẹ́ bí ó ṣe fẹ́ ṣe sí arákùnrin rẹ̀. O ní láti wẹ búburú kúrò láàrín rẹ. 20Àwọn ènìyàn tókù yóò gbọ́ nípa èyí, wọn yóò sì bẹ̀rù, kí irú nǹkan búburú bẹ́ẹ̀ máa tún sẹ̀ mọ́ láàrín yín. 2119.21: El 21.23-26; Le 24.20; Mt 5.38.Má ṣe fi àánú hàn, ẹ̀mí fún ẹ̀mí, ojú fún ojú, eyín fún eyín, apá fún apá, ẹsẹ̀ fún ẹsẹ̀.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

申命記 19:1-21

設立避難城

1「你們的上帝耶和華毀滅那些民族,把他們的土地賜給你們,使你們趕走他們,住進他們的城邑和房屋後, 2-3你們要把土地劃分為三個地區,在每個地區設立一座避難城,修好通往這三座城的道路,以便誤殺人者可以逃往最近的避難城。

4「如果有人無意間殺了素無冤仇的同伴,他可以逃往避難城,以保住性命。 5例如,有人和朋友去森林砍樹,斧頭脫柄,誤殺了朋友,他就可以逃往避難城,以保住性命。 6否則,如果避難城離誤殺人者太遠,怒火中燒的報仇者就會追上去殺死他。其實他是不該死的,因為他與被誤殺的人素無冤仇。 7因此,我吩咐你們要設立三座避難城。

8-9「如果你們謹遵我今天吩咐你們的這一切誡命,愛你們的上帝耶和華,一生遵行祂的旨意,祂就會按照祂對你們祖先所起的誓,擴張你們的疆域,把應許給你們祖先的土地賜給你們。那時,你們要再設三座避難城, 10免得無辜人的血流在你們的上帝耶和華賜給你們作產業之地,以致你們擔當枉殺無辜的罪。

11「如果有人因憎恨鄰居而暗中埋伏,殺了鄰居,然後逃到避難城, 12他本城的長老要派人去把他帶回來,交給復仇的人,將他處死。 13不可憐憫他,要從以色列除掉這種濫殺無辜的罪,這樣你們才會順利。

14「在你們的上帝耶和華將要賜給你們作產業之地,你們不可挪動鄰居的界石,因為那是先人立的。

15「如果人犯了什麼罪或有什麼過失,不可憑一個證人作證就定罪,要有兩三個證人才可以定案。 16如果有人作偽證誣陷別人, 17訴訟雙方要站在耶和華面前,讓當值的祭司和審判官定奪。 18審判官要仔細審查案件,如果發現那人作偽證, 19就要按照他企圖加給被誣告者的傷害處罰他。這樣,就從你們當中除掉了罪惡。 20其他人聽說後,都會害怕,不敢再做這種惡事。 21你們對惡人不可心軟,要以命償命,以眼還眼,以牙還牙,以手還手,以腳還腳。