Deuteronomi 18 – YCB & TCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Deuteronomi 18:1-22

Ọrẹ fún àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi

118.1-8: Nu 18.20-24.Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi, àní gbogbo ẹ̀yà Lefi, wọn kì yóò ní ìpín tàbí ogún láàrín Israẹli, wọn yóò máa jẹ nínú ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa, nítorí òun ni ogún un tiwọn. 2Wọn kì yóò ní ìní láàrín àwọn arákùnrin wọn; Olúwa ni yóò jẹ́ ìní i tiwọn, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí fún wọn.

3Gbogbo èyí ni yóò jẹ́ ìpín àwọn àlùfáà láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn tí ó fi akọ màlúù tàbí àgùntàn rú ẹbọ; wọn yóò fi èjìká àti ẹ̀rẹ̀kẹ́ méjèèjì àti gbogbo inú fún àlùfáà. 4Àkọ́so irúgbìn ọkà rẹ, ti wáìnì àti ti òróró rẹ, àti àkọ́rẹ́ irun àgùntàn rẹ ni ìwọ yóò fi fún wọn. 5Nítorí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n àti àwọn ọmọ wọn láti inú gbogbo ẹ̀yà láti dúró àti láti ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa títí láé.

6Tí ọmọ Lefi kan bá sì wá láti ibikíbi nínú àwọn ìlú u yín ní Israẹli, níbi tí ó ń gbé ṣe àtìpó, tí ó sì wá gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ rẹ̀ sí ibi tí Olúwa yóò yàn. 7Nígbà náà ni ó lè máa ṣe ìránṣẹ́ ní orúkọ Olúwa Ọlọ́run rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Lefi arákùnrin rẹ̀ ti ń dúró ṣe iṣẹ́ ìsìn níwájú Olúwa níbẹ̀. 8Wọn yóò ní ìpín kan láti jẹ, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti gba owó nípa títa ogún baba rẹ̀.

Ohun ìríra

9Nígbà tí o bá wọ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi fún ọ, ìwọ kò gbọdọ̀ kọ́ láti tẹ̀lé àwọn ọ̀nà ìríra àwọn orílẹ̀-èdè náà tí ó wà níbẹ̀. 1018.10,11: Ek 22.18; Le 19.26,31; 20.6,27.Má ṣe jẹ́ kí a rí ẹnikẹ́ni láàrín yín tí ó fi ọmọ rẹ̀ ọkùnrin tàbí ọmọ rẹ̀ obìnrin la iná já (fi ọmọ rẹ rú ẹbọ) kí ẹnikẹ́ni má ṣe lọ fọ àfọ̀ṣẹ, tàbí ṣẹ́ oṣó, tàbí túmọ̀ àwọn àmì nǹkan tí ń bọ̀, tàbí àjẹ́, 11tàbí afògèdè, tàbí jẹ́ a bá iwin gbìmọ̀ tàbí oṣó tàbí abókùúsọ̀rọ̀. 12Ẹnikẹ́ni tó bá ṣe nǹkan wọ̀nyí jẹ́ ìríra sí Olúwa, àti nítorí àwọn ìwà ìríra wọ̀nyí ni Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò fi lé àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí jáde kúrò níwájú rẹ. 1318.13: Mt 5.48.O ní láti jẹ́ aláìlẹ́gàn níwájú Olúwa Ọlọ́run rẹ.

Wòlíì

14Àwọn orílẹ̀-èdè tí ìwọ yóò gba ilẹ̀ tí wọ́n ń gbé, wọ́n fetí sí tí àwọn tí ó ń ṣe oṣó tàbí ṣe àfọ̀ṣẹ. Ṣùgbọ́n, ní ti ìwọ, Olúwa Ọlọ́run rẹ kò fi ààyè gbà ọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. 1518.15-19: Ap 3.22,23; 7.37.Olúwa Ọlọ́run rẹ yóò gbé wòlíì kan dìde gẹ́gẹ́ bí èmi láàrín àwọn arákùnrin rẹ. Tìrẹ ni kí o gbọ́. 16Nítorí èyí ni ohun tí ìwọ béèrè lọ́wọ́ Olúwa Ọlọ́run rẹ ní Horebu ní ọjọ́ àjọ, nígbà tí ìwọ wí pé, “Kí àwa má ṣe gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run wa tàbí rí iná ńlá yìí mọ́. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́ àwa yóò kú.”

17Olúwa sì wí fún mi pé, “Ohun tí wọ́n sọ dára. 18Èmi yóò gbé wòlíì kan dìde fún wọn láàrín àwọn arákùnrin wọn bí ìwọ, Èmi yóò fi ọ̀rọ̀ mi sí i ní ẹnu, yóò sì sọ fún wọn gbogbo ohun tí mo ti paláṣẹ fún un. 1918.19: Ap 3.23.Ẹnikẹ́ni tí kò bá sì tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi tí wòlíì náà yóò sọ ní orúkọ mi, èmi fúnra à mi yóò sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. 20Ṣùgbọ́n bí wòlíì kan bá kùgbù sọ ọ̀rọ̀ kan tí èmi kò paláṣẹ fún un láti sọ ní orúkọ mi tàbí wòlíì tí ó sọ̀rọ̀ ní orúkọ ọlọ́run mìíràn, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ ní láti kú.”

21Ṣùgbọ́n ìwọ lè wí ní ọkàn rẹ pé, “Báwo ni àwa yóò ṣe mọ ọ̀rọ̀ tí Olúwa kò sọ?” 22Nígbà tí ohun tí wòlíì bá sọ ní orúkọ Olúwa kò bá wá sí ìmúṣẹ tàbí jẹ́ òtítọ́, ìyẹn ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa kò sọ, irú wòlíì bẹ́ẹ̀ tí sọ láìwádìí. Kí ẹ má ṣe bẹ̀rù rẹ̀.

Tagalog Contemporary Bible

Deuteronomio 18:1-22

Mga Handog para sa mga Pari at sa mga Levita

1“Ang mga pari na mga Levita, at ang iba pang mga sakop ng lahi ni Levi ay walang lupaing mamanahin sa Israel. Makakakain lang sila sa pamamagitan ng mga handog sa pamamagitan ng apoy para sa Panginoon, dahil ito ang kanilang mana. 2Wala silang mamanahing lupain hindi tulad ng kapwa nila Israelita; ang Panginoon ang kanilang mana ayon sa ipinangako niya sa kanila.

3“Balikat, pisngi at tiyan ang mga bahaging mula sa baka o tupa na mula sa handog ng mga tao ang nakalaan para sa mga pari. 4Ibigay din ninyo sa mga pari ang naunang bahagi ng inyong trigo, bagong katas ng ubas, langis at balahibo ng tupa. 5Sapagkat sa lahat ng lahi ng Israel, sila at ang kanilang mga angkan ang pinili ng Panginoon na inyong Dios para maglingkod sa kanya magpakailanman.

6“Ang sinumang Levita na naninirahan sa kahit saang lugar ng Israel ay makakapunta sa lugar na pinili ng Panginoon, 7at makapaglilingkod siya roon sa Panginoon na kanyang Dios, katulad ng kapwa niya Levita na naglilingkod doon sa presensya ng Panginoon. 8Makakatanggap din siya ng kanyang bahagi sa mga handog kahit na mayroon pa siyang tinatanggap mula sa iba na kanyang ikinabubuhay.

Ang mga Kasuklam-suklam na Kaugalian

9“Kapag nakapasok na kayo sa lupaing ibinibigay sa inyo ng Panginoon na inyong Dios, huwag ninyong susundin ang kasuklam-suklam na mga kaugalian ng mga naninirahan doon. 10Wala ni isa man sa inyo na magsusunog ng kanyang anak bilang handog. At huwag din kayong manghuhula, mangkukulam, 11manggagaway, gumagawa ng mga ginagawa ng mga espiritista, at makikipag-usap sa espiritu ng mga patay. 12Kinasusuklaman ng Panginoon ang sinumang gumagawa ng mga bagay na ito. Ito ang dahilan kung bakit palalayasin ng Panginoon na inyong Dios ang mga bansa sa inyong harapan. 13Wala dapat kayong maging kapintasan sa harap ng Panginoon na inyong Dios.

Ang mga Propeta

14“Ang mga bansang ito na palalayasin ninyo ay sumasangguni sa mga mangkukulam at mga manghuhula. Pero kayo, pinagbabawalan ng Panginoon na inyong Dios sa paggawa nito. 15Sa halip, magpapadala sa inyo ang Panginoon na inyong Dios ng isang propeta na mula sa inyo at kadugo ninyo tulad ko. At kailangang makinig kayo sa kanya. 16Sapagkat ito ang hinihingi ninyo sa Panginoon na inyong Dios nang magtipon kayo roon sa Horeb. Sinabi ninyo sa Panginoon, ‘Huwag nʼyong iparinig sa amin ang boses nʼyo o ipakita ang naglalagablab na apoy dahil baka mamatay kami.’

17“Kaya sinabi ng Panginoon sa akin, ‘Mabuti ang kanilang hinihingi. 18Magpapadala ako sa kanila ng isang propeta na mula sa kanila at kadugo nila tulad mo. Ipasasabi ko sa kanya ang lahat ng gusto kong sabihin sa kanila. 19Parurusahan ko ang sinumang hindi makikinig sa aking mga salita na sinasabi ng propeta na ito sa pamamagitan ng aking pangalan. 20At kailangang patayin ang sinumang propetang magsasalita sa aking pangalan nang hindi ko inuutusan o magsasalita sa pangalan ng ibang dios.’

21“Maaaring isipin ninyo, ‘Paano ba namin malalaman kung iyon nga ay mensahe ng Panginoon?’ 22Kapag ang sinabi ng propeta na gumamit ng pangalan ng Panginoon ay hindi mangyari o magkatotoo, ang mensahe niya ay hindi galing sa Panginoon. Gawa-gawa lang iyon ng propeta, kaya huwag kayong matakot sa kanya.