Daniẹli 1 – YCB & SNC

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Daniẹli 1:1-21

Ẹ̀kọ́ Daniẹli ní Babeli

1Ní ọdún kẹta tí Jehoiakimu jẹ ọba Juda, Nebukadnessari ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu, ó sì kọlù ú pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. 2Olúwa sì fa Jehoiakimu ọba Juda lé e lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó lọ sí ilé òrìṣà ní Babeli, sí inú ilé ìṣúra òrìṣà rẹ̀.

3Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá. 4Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò ní àbùkù ara, tí wọ́n rẹwà, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ hàn, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí òye tètè ń yé àti àwọn tí ó kún ojú òsùwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba kí ó kọ́ wọ́n ní èdè àti onírúurú ẹ̀kọ́ ìwé ti àwọn Babeli. 5Ọba pèsè oúnjẹ ojoojúmọ́ àti wáìnì láti orí tábìlì i rẹ̀ fún wọn, ó sì kọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ fún ọba.

6Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó wá láti Juda: Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah. 7Olórí àwọn ìwẹ̀fà fún wọn ní orúkọ tuntun: Ó fún Daniẹli ní Belteṣassari, ó fún Hananiah ní Ṣadraki, ó fún Miṣaeli ní Meṣaki àti Asariah ní Abednego.

8Ṣùgbọ́n Daniẹli pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun kò ní ba ara òun jẹ́ pẹ̀lú oúnjẹ àti wáìnì ọba, nígbà náà ni ó gba ààyè lọ́wọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà wí pé òun kò fẹ́ ba ara òun jẹ́ ní ọ̀nà yìí. 9Ọlọ́run mú kí Daniẹli rí ojúrere àti àánú gbà láti ọwọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà, 10ṣùgbọ́n olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ fún Daniẹli pé, “Mo bẹ̀rù olúwa mi, ẹni tí o ti pèsè oúnjẹ àti ohun mímu rẹ. Báwo ni ìrísí rẹ yóò ṣe burú jù ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ rẹ lọ? Nígbà náà ni èmi yóò fi orí mi wéwu lọ́dọ̀ ọba.”

11Nígbà náà ni Daniẹli sọ fún olùṣọ́ tí olórí àwọn ìwẹ̀fà yàn lórí i Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah pé, 12“Jọ̀wọ́ dán àwa ìránṣẹ́ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá. Má ṣe fún wa ní ohun kankan, àfi ewébẹ̀ láti jẹ àti omi láti mu. 13Nígbà náà ni kí o fi ìrísí i wa wé ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba, kí o sì ṣe àwa ìránṣẹ́ rẹ ní ìbámu pẹ̀lú u bí o bá ṣe rí i sí.” 14Bẹ́ẹ̀ ni ó sì gbà láti dán wọn wò fún ọjọ́ mẹ́wàá.

15Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwàá ara wọn le, wọ́n sì sanra ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba lọ. 16Bẹ́ẹ̀ ni olùṣọ́ mú oúnjẹ àdídùn àti wáìnì tí ó yẹ kí wọ́n mu kúrò, ó sì fún wọn ní ewébẹ̀ dípò rẹ̀.

17Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ní ìmọ̀ àti òye nínú gbogbo onírúurú ìwé àti ẹ̀kọ́ ọ wọn: Daniẹli sì ní òye ìran àti àlá ní oríṣìíríṣìí.

18Ní òpin ìgbà tí ọba dá, pé kí a mú wọn wá sínú ààfin, olórí àwọn ìwẹ̀fà mú wọn wá síwájú ọba Nebukadnessari. 19Ọba sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì rí i pé kò sí ẹni tí ó dàbí i Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah; nítorí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ọba. 20Nínú gbogbo ọ̀ràn ọgbọ́n àti òye tí ọba ń béèrè lọ́wọ́ wọn, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn amòye àti ọlọ́gbọ́n tí ó wà ní gbogbo ìjọba rẹ̀.

21Daniẹli sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kìn-ín-ní ọba Kirusi.

Slovo na cestu

Daniel 1:1-21

1Léta třetího kralování Joakima krále Judského, přitáhl Nabuchodonozor král Babylonský k Jeruzalému, a oblehl jej. 2I vydal Pán v ruku jeho Joakima krále Judského, a něco nádobí domu Božího. Kterýž zavezl je do země Sinear, do domu boha svého, a nádobí to dal vnésti do domu pokladu boha svého. 3Rozkázal také král Ašpenazovi, správci dvořanů svých, aby přivedl z synů Izraelských, z semene královského a z knížat, 4Mládence, na nichž by nebylo žádné poškvrny, a krásného oblíčeje, a vtipné ke vší moudrosti, a schopné k umění i k nabývání jeho, a v kterýchž by byla síla, aby stávali na palácu královském, a učili se liternímu umění a jazyku Kaldejskému. 5I nařídil jim král odměřený pokrm na každý den z stolu královského, i vína, kteréž on sám pil, a aby je tak choval za tři léta, a po dokonání jich aby stávali před králem. 6Byli pak mezi nimi z synů Juda: Daniel, Chananiáš, Mizael a Azariáš. 7I dal jim správce dvořanů jména. Nazval Daniele Baltazarem, Chananiáše pak Sidrachem, a Mizaele Mizachem, a Azariáše Abdenágem. 8Ale Daniel uložil v srdci svém, aby se nepoškvrňoval pokrmem z stolu královského, a vínem, kteréž král pil. Pročež hledal toho u správce nad dvořany, aby se nemusil poškvrňovati. 9I způsobil Bůh Danielovi milost a lásku u správce nad dvořany. 10A řekl správce nad dvořany Danielovi: Já se bojím pána svého krále, kterýž vyměřil pokrm váš a nápoj váš, tak že uzřel-li by, že tváře vaše opadlejší jsou, nežli mládenců těch, kteříž podobně jako i vy chování býti mají, způsobíte mi to u krále, že přijdu o hrdlo. 11I řekl Daniel služebníku, kteréhož ustanovil správce dvořanů nad Danielem, Chananiášem, Mizaelem a Azariášem: 12Zkus, prosím, služebníků svých za deset dní, a nechť se nám vaření dává, kteréž bychom jedli, a voda, kterouž bychom pili. 13A potom nechť se spatří před tebou tváře naše a tváře mládenců, kteříž jídají pokrm z stolu královského, a jakž uhlédáš, učiň s služebníky svými. 14I uposlechl jich v té věci, a zkusil jich za deset dní. 15Po skonání pak desíti dnů spatříno jest, že tváře jejich byly krásnější, a byli tlustší na těle než všickni mládenci, kteříž jídali pokrm z stolu královského. 16Protož služebník brával ten vyměřený pokrm jejich, a víno nápoje jejich, a dával jim vaření. 17Mládence pak ty čtyři obdařil Bůh povědomostí a rozumností ve všelikém literním umění a moudrostí; nadto Danielovi dal, aby rozuměl všelikému vidění a snům. 18A když se dokonali dnové, po kterýchž rozkázal král, aby je přivedli, přivedl je správce dvořanů před Nabuchodonozora. 19I mluvil s nimi král. Ale není nalezen mezi všemi těmi, jako Daniel, Chananiáš, Mizael a Azariáš. I stávali před králem. 20A ve všelikém slovu moudrosti a rozumnosti, na kteréž se jich doptával král, nalezl je desetkrát zběhlejší nade všecky mudrce a hvězdáře, kteříž byli ve všem království jeho. 21I zůstával tu Daniel až do léta prvního Cýra krále.