Amosi 5 – YCB & NASV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

Amosi 5:1-27

Wò mí kí o sì yè

1Gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, ìwọ ilé Israẹli, ìpohùnréré ẹkún tí mo ṣe nípa rẹ:

2“Wúńdíá Israẹli ṣubú

láì kò sì le padà dìde

ó di ẹni ìkọ̀tì ní ilẹ̀ rẹ̀

kò sí ẹni tí yóò gbé e dìde.”

3Èyí ni ohun tí Olúwa Olódùmarè wí:

“Ìlú tí ẹgbẹ̀rún (1,000) alágbára ti jáde,

yóò dín ku ọgọ́rùn-ún ní Israẹli.

Ìlú tí ọgọ́rùn-ún alàgbà ti jáde

yóò ṣẹ́kù ẹni mẹ́wàá.”

4Èyí ni ohun tí Olúwa sọ fún ilé Israẹli:

“Wá mi kí o sì yè;

5ẹ má ṣe wá Beteli,

ẹ má ṣe lọ sí Gilgali,

ẹ má ṣe rìnrìn àjò lọ sí Beerṣeba.

Nítorí dájúdájú a ó kó Gilgali ní ìgbèkùn,

A ó sì sọ Beteli di asán.”

6Ẹ wá Olúwa, ẹ̀yin yóò sì yè,

kí ó má ba à gbilẹ̀ bí iná ní Josẹfu

a sì jó o run

Beteli kò sì ní rí ẹni tí yóò bu omi pa á.

7Ẹ̀yin tí ẹ̀ sọ òdodo di ìkorò

tí ẹ sì gbé olódodo ṣánlẹ̀.

8Ẹni tí ó dá ìràwọ̀ Pleiadesi àti Orioni

ẹni tí ó sọ òru dúdú di òwúrọ̀

tí ó sọ ọjọ́ dúdú di ìmọ́lẹ̀

ẹni tí ó wọ́ omi Òkun jọ pọ̀

tí ó sì rọ̀ wọ́n sí orí ilẹ̀

Olúwa ni orúkọ rẹ̀,

9Ó fọ́n ìparun sí ìlú olódi

tí ó sì sọ àwọn ibùgbé àwọn ọmọ-aládé di ahoro.

10Ìwọ kórìíra ẹni tí ń bá ni wí ní ẹnu ibodè

ó sì ń pẹ̀gàn ẹni tí ń sọ òtítọ́.

11Ìwọ ń tẹ tálákà mọ́lẹ̀

o ń fi ipá gba ọkà lọ́wọ́ wọn.

Nítorí náà, ìwọ ti fi òkúta tí a gbẹ́ kọ́lé

ṣùgbọ́n ẹ kò sì ní gbé inú wọn,

Nítòótọ́ ìwọ ti gbin ọgbà àjàrà tí ó lẹ́wà.

Ìwọ kò ní mu wáìnì inú wọn.

12Nítorí mo mọ iye àìṣedéédéé rẹ

mo sì mọ bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ tí tóbi tó.

Ìwọ ni olódodo lára, ìwọ sì ń gba àbẹ̀tẹ́lẹ̀

o sì ń fi òtítọ́ du tálákà ní ilé ẹjọ́.

13Àwọn ọlọ́gbọ́n máa ń dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní àkókò wọ̀nyí,

nítorí búburú ni gbogbo ọjọ́.

14Wá rere, má ṣe wá búburú

kí ìwọ ba à le yè.

Nígbà náà ni Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun yóò wà pẹ̀lú rẹ.

Òun yóò sì wà pẹ̀lú rẹ bí ìwọ ṣe wí.

15Kórìíra búburú kí o sì fẹ́ rere

dúró ní orí òtítọ́ ní ilé ẹjọ́

bóyá Olúwa Ọlọ́run alágbára

yóò síjú àánú wo ọmọ Josẹfu tó ṣẹ́kù.

16Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí:

“Ẹkún yóò wà ní àwọn òpópónà

igbe ìnira yóò sì wà ní àwọn gbàgede ìlú.

A ó kó àwọn àgbẹ̀ jọ láti sọkún

àti àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ láti pohùnréré ẹkún.

17Ìpohùnréré ẹkún yóò wà ní gbogbo ọgbà àjàrà,

nítorí èmi yóò la àárín yín kọjá,”

ni Olúwa wí.

Ọjọ́ Olúwa

18Ègbé ni fún ìwọ tí ó pẹ́

nítorí ọjọ́ Olúwa

kí ni ìwọ fi pẹ́ fún ọjọ́ Olúwa?

Ìmọ́lẹ̀ yóò di òkùnkùn ní ojú ọjọ́.

19Gẹ́gẹ́ bí ènìyàn tí ó sá fún kìnnìún,

tí ó padà wá bọ́ sí ẹnu àmọ̀tẹ́kùn.

Yóò dàbí ẹni tí ó wọ ilé rẹ̀ lọ

tí ó sinmi lé ògiri ilé rẹ̀

tí ejò sì bù ú ṣán.

20Ǹjẹ́ ọjọ́ Olúwa kò ha ní ṣókùnkùn dípò kí ó ní ìmọ́lẹ̀?

Tí yóò sì ṣókùnkùn dúdú láìsí ìmọ́lẹ̀ kankan níbẹ̀.

21“Mo kórìíra, mo kẹ́gàn àwọn àsè ẹ̀sìn in yín,

Èmi kò sì ní inú dídùn sí àpéjọ yín.

22Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú ẹbọ sísun àti ọrẹ ọkà wá.

Èmi kò ní tẹ́wọ́ gbà wọ́n.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ mú àṣàyàn ọrẹ àlàáfíà wá.

Èmi kò ní náání wọn.

23Ẹ gbé ariwo orin yín sẹ́yìn!

Èmi kò ní fetísí ohun èlò orin yín.

24Jẹ́ kí òtítọ́ sàn bí odò

àti òdodo bí ìsun tí kò lé è gbẹ!

255.25-27: Ap 7.42-43.“Àbí ẹ̀yin mú ẹbọ àti ọrẹ tọ̀ mí wá

ní ogójì ọdún ní aginjù ìwọ ilé Israẹli?

26Ẹ̀yin ti gbé ibi ìrúbọ àwọn ọba yín sókè,

ibùgbé àwọn òrìṣà yín,

àní, ti àwọn òrìṣà yín tí ó níyì jùlọ,

èyí tí ẹ̀yin fi ọwọ́ ara yín ṣe.

27Nítorí náà èmi yóò rán an yín lọ sí ìgbèkùn ní ìkọjá Damasku,”

ni Olúwa wí, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ọlọ́run alágbára.

New Amharic Standard Version

አሞጽ 5:1-27

የእስራኤል ሕዝብ ለንስሓ መጠራት

1የእስራኤል ቤት ሆይ፤ ስለ እናንተ የምደረድረውን ይህን የሙሾ ቃል ስሙ፤

2“ድንግሊቱ እስራኤል ወደቀች፤

ከእንግዲህም አትነሣም፤

በገዛ ምድሯ ተጣለች፤

የሚያነሣትም የለም።”

3ጌታ እግዚአብሔር እንዲህ ይላል፤

“አንድ ሺሕ ብርቱዎችን ለእስራኤል የምታዘምት ከተማ፣

አንድ መቶ ብቻ ይቀሯታል፤

አንድ መቶ ብርቱዎችን የምታዘምተውም፣

ዐሥር ብቻ ይቀሯታል።”

4እግዚአብሔር ለእስራኤል ቤት እንዲህ ይላል፤

“እኔን ፈልጉ፤ በሕይወትም ትኖራላችሁ።”

5ቤቴልን አትፈልጉ፤

ወደ ጌልገላ አትሂዱ፤

ወደ ቤርሳቤህም አትሻገሩ፤

ጌልገላ በርግጥ ትማረካለች፤

ቤቴልም እንዳልነበረች5፥5 ሐዘን ትሆናለችና።

6እግዚአብሔርን ፈልጉ፤

በሕይወትም ትኖራላችሁ፤

አለዚያ እንደ እሳት የዮሴፍን ቤት ያወድማል፤

እሳቱም ቤቴልን ይበላል፤ የሚያጠፋውም የለም።

7እናንት ፍትሕን ወደ መራርነት የምትለውጡ፣

ጽድቅንም ወደ ምድር የምትጥሉ ወዮላችሁ!

8ሰባቱን ከዋክብትና ኦሪዮንን የሠራ፣

ጨለማውን ወደ ንጋት ብርሃን የሚለውጥ፣

ቀኑን አጨልሞ ሌሊት የሚያደርግ፣

የባሕሩንም ውሃ ጠርቶ፣

በገጸ ምድር ላይ የሚያፈስስ፣

ስሙ እግዚአብሔር ነው፤

9እርሱ በብርቱው ላይ ድንገተኛ ጥፋትን፣

በተመሸገውም ከተማ ላይ ውድመትን ያመጣል።

10እናንተ በፍርድ አደባባይ

የሚገሥጻችሁን ትጠላላችሁ፤ እውነት የሚናገረውንም ትንቃላችሁ።

11እናንተ ድኻውን ትረግጣላችሁ፤

እህል እንዲሰጣችሁም ታስገድዱታላችሁ፤

ስለዚህ በተጠረበ ድንጋይ ቤት ብትሠሩም፣

በውስጡ ግን አትኖሩም፤

ባማሩ የወይን ተክል ቦታዎች ወይን ብትተክሉም፣

የወይን ጠጁን ግን አትጠጡም፤

12ኀጢአታችሁ ምንኛ ታላቅ እንደ ሆነ፣

በደላችሁም የቱን ያህል እንደ በዛ እኔ ዐውቃለሁና።

ጻድቁን ትጨቍናላችሁ፤

ጕቦም ትቀበላላችሁ፤

በፍርድ አደባባይም ከድኻው ፍትሕ ትነጥቃላችሁ።

13ስለዚህ አስተዋይ ሰው በእንዲህ ያለ ጊዜ ዝም ይላል፤

ቀኖቹ ክፉዎች ናቸውና።

14በሕይወት ትኖሩ ዘንድ፣

መልካሙን እንጂ ክፉውን አትፈልጉ፤

ከዚያ በኋላ እንደ ተናገራችሁት፣

የሰራዊት አምላክ እግዚአብሔር ከእናንተ ጋር ይሆናል።

15ክፉውን ጥሉ፤ መልካሙንም ውደዱ፤

በፍርድ አደባባይም ፍትሕን አታጓድሉ፤

ምናልባትም የሰራዊት አምላክ እግዚአብሔር

ለዮሴፍ ትሩፍ ይራራ ይሆናል።

16ስለዚህ ጌታ የሰራዊት አምላክ እግዚአብሔር እንዲህ ይላል፤

“በየመንገዱ ሁሉ ወየው ተብሎ ይለቀሳል፤

በአደባባዩም የሥቃይ ጩኸት ይሆናል፤

ገበሬዎች ለልቅሶ፣

አልቃሾችም ለዋይታ ይጠራሉ።

17በየወይኑ ዕርሻ ሁሉ ወየው ተብሎ ይለቀሳል፤

እኔ በመካከላችሁ ዐልፋለሁና፤”

ይላል እግዚአብሔር

የእግዚአብሔር ቀን

18የእግዚአብሔርን ቀን ለምትሹ፣

ለእናንተ ወዮላችሁ!

የእግዚአብሔርን ቀን ለምን ትሻላችሁ?

ያ ቀን ጨለማ ነው እንጂ ብርሃን አይደለም።

19ይህ ቀን አንድ ሰው ከአንበሳ ሲሸሽ፣

ድብ እንደሚያጋጥመው፣

ወደ ቤቱም ገብቶ፣ እጁን በግድግዳው

ላይ ሲያሳርፍ፣

እባብ እንደሚነድፈው ነው።

20የእግዚአብሔር ቀን ብርሃን ሳይሆን ጨለማ፣

የብርሃን ጸዳል የሌለው ድቅድቅ ጨለማ አይደለምን?

21“ዓመት በዓላችሁን ተጸይፌአለሁ፤

ጠልቼውማለሁ፤ ጉባኤዎቻችሁ ደስ አያሰኙኝም።

22የሚቃጠል መሥዋዕትና የእህል ቍርባን ብታቀርቡልኝም፣

እኔ አልቀበለውም፤

ከሠቡ እንስሶቻችሁ የኅብረት መሥዋዕት5፥22 የሰላም መሥዋዕት በመባል የሚታወቀው ነው። ብታቀርቡልኝም፣

እኔ አልመለከተውም።

23የዝማሬህን ጩኸት ከእኔ አርቅ፤

የበገናህንም ዜማ አልሰማም።

24ነገር ግን ፍትሕ እንደ ወንዝ፣

ጽድቅም እንደማይደርቅ ምንጭ ይፍሰስ።

25“የእስራኤል ቤት ሆይ፤ አርባ ዓመት በምድረ በዳ፣

መሥዋዕትንና ቍርባንን አቅርባችሁልኝ ነበርን?

26ለራሳችሁ የሠራችሁትን፣

የንጉሣችሁን ቤተ ጣዖት፣

የጣዖቶቻችሁን ዐምድ፣

የአምላካችሁን5፥26 ወይም ንጉሣችሁን ሱኮትን ከፍ ከፍ አደረጋችሁት እንዲሁም ጣዖታችሁን ቀይዋን የከዋክብት አማልክታችሁን፣ ሰብዓ ሊቃናት የሞሌክን ቤተ ጣዖት እንዲሁም የአምላካችሁን የሬፋንን ከዋክብት ከፍ አደረጋችሁ ይላሉ። ኮከብ አንሥታችሁ ተሸከማችሁ።

27ስለዚህ ከደማስቆ ወዲያ እንድትሰደዱ አደርጋችኋለሁ፤”

ይላል ስሙ የሰራዊት አምላክ የሆነ እግዚአብሔር