Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Samuẹli 1:1-27

1Lẹ́yìn ikú Saulu, Dafidi ti ibi tí ó ti ṣẹ́gun àwọn ará Amaleki bọ̀, ó sì dúró ní Siklagi ní ọjọ́ méjì. 2Ní ọjọ́ kẹta, ọkùnrin kan dé láti ibi ibùdó Saulu, pẹ̀lú aṣọ rẹ̀ tí ó ti ya; àti erùpẹ̀ ní orí rẹ̀. Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ Dafidi, ó wólẹ̀ fún un láti bu ọlá fún un.

3Dafidi sì béèrè pé, “Ibo ni ìwọ ti wá?”

“Èmi sá láti ibùdó àwọn ọmọ Israẹli.”

4Dafidi béèrè pé, “Kí ni ó ṣẹlẹ̀?” “Sọ fún mi.”

Ó wí pé, “Àwọn ọkùnrin náà sá láti ojú ogun. Ọ̀pọ̀ wọn ṣubú, wọ́n sì kú. Saulu àti ọmọ rẹ̀ ọkùnrin Jonatani sì kú pẹ̀lú.”

5Nígbà náà, ní Dafidi sọ fún ọ̀dọ́mọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Báwo ni o ṣe mọ̀ pé Saulu àti ọmọkùnrin rẹ̀ Jonatani ti kú.”

61.6-10: 1Sa 31.1-13; 1Ki 10.1-12.Ọ̀dọ́mọkùnrin náà sọ pé, “mo wà ní orí òkè Gilboa níbẹ̀ ni Saulu fi ara tí ọkọ̀ rẹ̀, àwọn kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin sì ń lépa rẹ̀. 7Nígbà tí ó wò yíká, tí ó rí mí, ó pè mi, mo sì wí pé, ‘Kí ni mo lè ṣe?’

8“Ó bi mí wí pé, ‘Ta ni ìwọ?’

“Mo dáhùn pé, ‘Ará a Amaleki.’

9“Nígbà náà ó wí fún mi pé, ‘Dúró lórí ì mi kí o sì pa mí! Èmi wà nínú ìrora ikú, ṣùgbọ́n mo wà láààyè.’

10“Nígbà náà, mo dúró lórí i rẹ̀, mo sì pa á nítorí mo mọ̀ wí pé, lẹ́yìn ìgbà tí ó ti ṣubú, kò le è yè mọ́. Mo sì mú adé tí ó wà lórí rẹ̀, idẹ tí ó wà ní apá a rẹ̀, mo sì kó wọn wá síbí fún olúwa mi.”

11Nígbà náà ni, Dafidi àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀, di aṣọ wọn mú, wọ́n sì fà á ya. 12Wọ́n ṣọ̀fọ̀, wọ́n sì sọkún, wọ́n sì gbààwẹ̀ títí di ìrọ̀lẹ́ fún Saulu àti ọmọ rẹ̀ Jonatani àti fún àwọn ọmọ-ogun Olúwa, àti fún àwọn ilé Israẹli, nítorí wọ́n ti ṣubú nípa idà.

13Dafidi sọ fún ọkùnrin tí ó mú ìròyìn wá fún un pé, “Níbo ni ó ti wá?”

O dáhùn pé, “Ọmọ àlejò ni mo jẹ́, ará Amaleki.”

14Dafidi béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Kí ni ó dé tí ìwọ kò fi bẹ̀rù láti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè láti fi pa ẹni ààmì òróró Olúwa?”

15Nígbà náà Dafidi pe ọ̀kan nínú ọkùnrin, ó sì wí pé, “Lọ, gbé e lulẹ̀!” Nígbà náà ó gbé e lulẹ̀, ó sì kú. 16Nítorí Dafidi wí fún un pé, “Ẹ̀jẹ̀ rẹ yóò wà lórí ara rẹ, nítorí ẹnu ara rẹ ni o fi sọ pé ‘Mo pa ẹni ààmì òróró Olúwa.’ ”

17Dafidi sì fi orin ọ̀fọ̀ yìí ṣọ̀fọ̀ lórí Saulu àti lórí Jonatani ọmọ rẹ̀, 18Ó sì pàṣẹ pé kí a kọ́ àwọn ọkùnrin Juda ní orin arò yìí tí ó jẹ́ ti ọrun (a kọ ọ́ sí inú ìwé Jaṣari):

19“Ògo rẹ, Israẹli ni a pa ní òkè gíga rẹ.

Wò bí àwọn alágbára ṣe ń ṣubú!

20“Ẹ má ṣe sọ ọ́ ní Gati,

ẹ má ṣe kéde rẹ̀ ní òpópónà Aṣkeloni,

kí àwọn ọmọbìnrin Filistini má bá à yọ̀,

kí àwọn ọmọbìnrin aláìkọlà má ba à dunnú.

21“Ẹ̀yin òkè Gilboa,

kí ẹ̀yin kí ó má ṣe rí ìrì tàbí òjò,

tàbí oko tí ó mú èso ọrẹ wá.

Nítorí ibẹ̀ ni asà alágbára ti ṣègbé,

asà Saulu, bí ẹni pé a kò fi òróró yàn án.

22“Ọrun Jonatani kì í padà

bẹ́ẹ̀ ni idà Saulu kì í padà lásán,

láì kan ẹ̀jẹ̀ àwọn tí a pa,

àti ẹran àwọn alágbára.

23Saulu àti Jonatani—

ní ọjọ́ ayé, wọ́n fẹ́ràn ara, wọn sì dùn,

ní ikú, wọn kò sì yà ara wọ́n.

Wọ́n yára ju idì lọ,

wọ́n lágbára ju kìnnìún lọ.

24“Ẹ̀yin ọmọbìnrin Israẹli,

ẹ sọkún lórí Saulu,

ẹni tí ó fi aṣọ ọ̀gbọ̀ dáradára wọ̀ yín,

ẹni tí ó fi wúrà sí ara aṣọ yín.

25“Wò ó bí alágbára ti ṣubú ní ojú ogun!

Jonatani, ìwọ tí a pa ní òkè gíga.

26Ọkàn mi gbọgbẹ́ fún ọ Jonatani arákùnrin mi;

ìwọ ṣọ̀wọ́n fún mi.

Ìfẹ́ rẹ sí mi jẹ́ ìyanu,

ó jẹ́ ìyanu ju ti obìnrin lọ.

27“Wò ó bí alágbára ti ṣubú!

Ohun ìjà sì ti ṣègbé!”

Korean Living Bible

사무엘하 1:1-27

사울이 죽은 소식을 듣는 다윗

1사울이 죽었을 때 다윗은 아말렉군을 무찌르고 시글락으로 돌아온 지 이틀째가 되었다.

2그 다음날 이스라엘군의 진지에서 한 사람이 왔다. 그는 자기 옷을 찢고 머리에 티끌을 끼얹은 채 다윗 앞에 나와 땅에 엎드려 절하였다.

3그러자 다윗이 그에게 물었다. “네가 어디서 왔느냐?” “이스라엘군의 진지에서 도망쳐 나왔습니다.”

4“무슨 일이냐? 나에게 말하라.” “우리 군대는 전쟁에 패하여 도주하다가 수많은 병사가 죽고 사울과 그의 아들 요나단도 죽었습니다.”

5“그들이 죽은 것을 네가 어떻게 아느냐?”

6“내가 우연히 길보아산에 올라갔을 때 사울왕은 자기 창을 의지하고 있었고 적 전차와 마병은 그에게 바싹 다가오고 있었습니다.

7이 순간 왕이 나를 보더니 자기에게 오라고 불렀습니다. 그래서 내가 갔더니

8왕은 ‘네가 누구냐?’ 하고 물었습니다. 그때 내가 ‘아말렉 사람입니다’ 하고 대답하자

9왕은 나에게 ‘아직도 내가 목숨이 붙어 있어 고통스러우니 너는 이리 와서 나를 죽여라’ 하였습니다.

10그래서 나는 왕이 더 이상 살 수 없을 것 같아서 그를 죽인 후 왕관을 벗기고 그의 팔찌를 뽑아 당신에게 이렇게 가져왔습니다.”

11이 말을 듣자 다윗과 그의 부하들은 자기들의 옷을 찢고

12전쟁터에서 죽은 사울과 그의 아들 요나단과 여호와의 백성과 이스라엘을 생각하며 하루 종일 슬퍼하고 금식하였다.

13다윗은 그 소식을 전한 청년에게 “너는 어디 사람이냐?” 하고 물었다. 그가 “나는 1:13 암시됨.이스라엘에 이주 해 온 아말렉 사람입니다” 하고 대답하자

14“네가 어째서 하나님이 세우신 왕을 죽였느냐?” 하고 다윗은 호통을 친 다음

15그의 부하 하나를 불러 “이 자를 죽여라!” 하고 명령하였다. 그러자 그는 그 아말렉 사람을 단숨에 칼로 쳐서 죽여 버렸다.

16그때 다윗이 “너는 네 죄값으로 죽었다. 이것은 네가 스스로 하나님이 세우신 왕을 죽였다고 고백했기 때문이다” 하고 말하였다.

다윗이 사울과 요나단의 죽음을 슬퍼함

17-18다윗은 사울과 요나단을 애도하는 노래를 지어 그것을 모든 유다 사람들에게 가르치라고 명령했는데 이것은 야살의 책에 이렇게 기록되어 있다:

19오, 이스라엘이여, 너의 영광이

산 위에서 사라졌구나!

힘 센 용사들이

엎드러지고 말았네.

20이 일을 블레셋 사람들에게

말하지 말아라.

그들이 들으면 즐거워할 것이다.

가드와 아스글론성에

알리지 말아라.

이방 민족이 우쭐댈까 하노라.

21오, 길보아 산들아,

네 위에 이슬이나 비가

내리지 않을 것이며 네 땅은 언제나

1:21 또는 ‘제물 낼 밭도 없을지어다’황무지가 될 것이다.

거기에 용사들의 방패가

버려졌으니

사울의 방패에

기름칠을 할 수 없게 되었구나.

22요나단의 활은

반드시 적의 피와 기름을 적셨고

사울의 칼은

헛되이 돌아오는 법이 없었다.

23사랑스럽고 아름답던

사울과 요나단,

그들은 생전에도 함께 있더니

죽을 때에도

서로 떠나지 않았구나.

그들은 독수리보다 빠르고

사자보다 강하였다.

24오, 이스라엘의 딸들아,

사울을 위해 슬피 울어라.

그가 너희에게

화려한 옷을 입히고

너희 옷을 금 장식품으로 꾸몄다.

25용사들이 전쟁터에 쓰러졌구나.

요나단이 높은 산에서

죽음을 당했구나.

26내 형제 요나단이여,

내가 그대를 위해 슬퍼하노라.

그대는 나에게

얼마나 사랑스러웠던고!

나에 대한 그대의 사랑이

여인의 사랑보다 깊지 않았던가!

27용사들이 쓰러졌으니

그들의 무기가

쓸모없게 되었구나.