2 Kronika 5 – YCB & CARST

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 5:1-14

1Nígbà tí gbogbo iṣẹ́ tí Solomoni ti ṣe fún tẹmpili Olúwa ti parí, ó kó gbogbo àwọn nǹkan tí Dafidi baba rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀: wúrà àti fàdákà àti gbogbo ohun èlò ọ̀ṣọ́, ó sì fi wọ́n sínú ìṣúra ilé Ọlọ́run.

A gbé àpótí ẹ̀rí wọ inú tẹmpili

2Nígbà náà ni Solomoni pe àwọn àgbàgbà Israẹli jọ sí Jerusalẹmu, gbogbo àwọn olórí ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan àti àwọn olóyè àwọn ìdílé Israẹli, kí wọn kí ó gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa gòkè wá láti Sioni ìlú Dafidi. 3Gbogbo àwọn ọkùnrin Israẹli péjọ sí ọ̀dọ̀ ọba ní àkókò àjọ àgọ́.

4Gbogbo àwọn àgbàgbà Israẹli sì wá, àwọn ọmọ Lefi gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa. 5Wọ́n sì gbé àpótí ẹ̀rí náà gòkè àti àgọ́ ìpàdé àti gbogbo ohun èlò mímọ́ tí ó wà nínú àgọ́. Àwọn àlùfáà tí wọ́n jẹ́ ọmọ Lefi ni ó mú wọn gòkè wá. 6Nígbà náà ni ọba Solomoni àti gbogbo ìjọ ènìyàn Israẹli tí ó péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, wà níwájú àpótí ẹ̀rí náà wọ́n sì fi àgùntàn àti màlúù tí a kò le è kà tán rú ẹbọ, bẹ́ẹ̀ ni a kò le è mọ iye wọn tán nítorí bí wọ́n ti pọ̀ tó.

7Nígbà náà ni àwọn àlùfáà gbé àpótí ẹ̀rí ti májẹ̀mú Olúwa wá sí ipò rẹ̀, sí ibi inú lọ́hùn ún ilé Olúwa, Ibi Mímọ́ Jùlọ, wọ́n gbé e sí abẹ́ ìyẹ́ àwọn kérúbù. 8Àwọn Kérúbù na ìyẹ́ wọn bo ibi àpótí ẹ̀rí náà àti àwọn ọ̀pá tí ó gbé e ró. 9Àwọn ọ̀pá rẹ̀ náà gùn tó bẹ́ẹ̀ tí a fi rí orí àwọn ọ̀pá náà láti ibi àpótí ẹ̀rí náà níwájú Ibi Mímọ́ náà, ṣùgbọ́n a kò rí wọn lóde. Níbẹ̀ ni ó sì wà títí di òní yìí. 10Kò sí ohun kan nínú àpótí ẹ̀rí náà bí kò ṣe wàláà méjì tí Mose fi sínú rẹ̀ ní Horebu, ní ìgbà tí Olúwa fi bá àwọn ọmọ Israẹli dá májẹ̀mú lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti.

11Lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà jáde wá láti Ibi Mímọ́. Gbogbo àwọn àlùfáà tí ó wà níbẹ̀ ni ó ya ara wọn sí mímọ́ láìbìkítà fún ìpín wọn. 12Gbogbo àwọn ọmọ Lefi tí wọ́n jẹ́ akọrin: Asafu, Hemani, Jedutuni àti àwọn ọmọ wọn àti àwọn ẹbí wọn, wọ́n dúró ní igun ìlà-oòrùn pẹpẹ náà wọ́n wọ aṣọ ọ̀gbọ̀ tuntun wọ́n ń lo kimbali, dùùrù àti ohun èlò orin olókùn. Ìwọ̀n ọgọ́fà àwọn àlùfáà tí wọ́n ń fun ìpè ni wọ́n tẹ̀lé wọn. 135.13,14: 1Ọb 8.10-11.Àwọn afùnpè àti àwọn akọrin pa ohùn wọn pọ̀ sí ọ̀kan ṣoṣo, láti fi ìyìn àti ọpẹ́ fun Olúwa. Wọ́n fi ìpè, kimbali àti àwọn ohun èlò orin mìíràn mọ́ ọn, wọ́n gbé ohùn wọn sókè láti fi yin Olúwa, wọ́n ń kọrin pé,

“Ó dára;

ìfẹ́ rẹ̀ wà títí láéláé.”

Nígbà náà ni ìkùùkuu ojú ọ̀run kún inú tẹmpili Olúwa, 14tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn àlùfáà kò le è ṣiṣẹ́ ìsìn wọn nítorí ìkùùkuu náà, nítorí ògo Olúwa kún inú tẹmpili Ọlọ́run.

Священное Писание (Восточный перевод), версия для Таджикистана

2 Летопись 5:1-14

1Когда вся работа, которую Сулаймон делал для храма Вечного, была завершена, он принёс те вещи, которые посвятил Вечному его отец Довуд, – серебро, золото и всю утварь – и положил их в сокровищницы храма Всевышнего.

Перенесение сундука соглашения в храм

(3 Цар. 8:1-13)

2Сулаймон созвал в Иерусалим старейшин Исроила, всех глав исроильских родов и кланов, чтобы перенести сундук соглашения с Вечным из Города Довуда, то есть Сиона, в храм5:2 Городом Довуда или Сионом называли старую часть города, откуда сундук соглашения был перенесён в храм, находившийся в новой, северной части Иерусалима.. 3И все исроильтяне собрались у царя во время праздника Шалашей5:3 Праздник Шалашей – иудейский праздник в память о попечении Всевышнего во время скитаний в пустыне (см. Лев. 23:33-43; Чис. 29:12-39; Втор. 16:13-17). в седьмом месяце (в начале осени).

4Когда прибыли старейшины Исроила, левиты подняли сундук 5и понесли его и шатёр встречи со всей священной утварью, находящейся в нём. Священнослужители-левиты несли их, 6а царь Сулаймон и всё общество исроильтян, которое собралось вокруг него, шли перед сундуком и приносили в жертву столько мелкого и крупного скота, что его невозможно было ни пересчитать, ни исчислить.

7Священнослужители принесли сундук соглашения с Вечным на его место во внутреннее святилище храма, в Святая Святых, и поставили его под крыльями херувимов. 8Херувимы простирали свои крылья над местом сундука и накрывали сундук и шесты для его переноски. 9Эти шесты были такие длинные, что их концы было видно со святилища, находящегося перед Святая Святых, но снаружи их не было видно. Они находятся там и по сегодняшний день.

10В сундуке же ничего не было, кроме двух каменных плиток, которые Мусо положил в него у горы Синай5:10 Букв.: «у Хорива». Хорив – другое название горы Синай., где Вечный заключил с исроильтянами соглашение после того, как они вышли из Египта.

11Священнослужители вышли из святилища. Все священнослужители, которые были там, освятились, независимо от их отделов. 12Все левиты, которые были музыкантами, – Ософ, Еман, Иедутун со своими сыновьями и сородичами – стояли с восточной стороны жертвенника, одетые в тонкий лён, и играли на тарелках, лирах и арфах. Им вторили сто двадцать священнослужителей, которые трубили в трубы. 13Трубящие и поющие звучали в унисон, как один голос, вознося Вечному хвалу и благодарность. Под звуки труб, тарелок и других музыкальных инструментов они прославляли Вечного:

– Он благ;

милость Его – навеки!

Затем храм Вечного заполнило облако, 14и священнослужители не могли совершать свою службу из-за него, потому что слава Вечного наполнила храм Всевышнего.