2 Kronika 4 – YCB & NRT

Yoruba Contemporary Bible

2 Kronika 4:1-22

Àwọn ìpèsè fún ilé Olúwa

1Ó ṣe pẹpẹ idẹ, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní gígùn, ogún ìgbọ̀nwọ́ ní fífẹ̀ àti ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá fún gíga. 24.2-5: 1Ọb 7.23-26.Ó ṣe agbada dídà ńlá tí ó rí róbótó tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá láti etí kan dé etí èkejì ìgbọ̀nwọ́ márùn-ún sì ni gíga rẹ̀. 3Lábẹ́ etí, àwòrán àwọn akọ màlúù yíká mẹ́wàá sí ìgbọ̀nwọ́ kan. Àwọn akọ màlúù náà ni á dá ní ọ̀nà méjì ní àwòrán kan pẹ̀lú okùn.

4Okùn náà dúró lórí akọ màlúù méjìlá, mẹ́ta kọjú sí àríwá, mẹ́ta kọjú sí ìwọ̀-oòrùn, mẹ́ta kọjú sí gúúsù mẹ́ta kọjú sí ìlà-oòrùn. Òkun náà sì sinmi lórí wọn àti gbogbo ìhà ẹ̀yìn wọn sì wà ní apá àárín. 5Ó nípọn tó ìbú àtẹ́lẹwọ́, etí rẹ̀ sì dàbí etí ife ìmumi, bí i ìtànná lílì ó sì dá ìwọ̀n ẹgbẹ̀ẹ́dógún bati dúró.

64.6–5.1: 1Ọb 7.38-51.Ó ṣe ọpọ́n mẹ́wàá fún fífọ nǹkan, ó sì gbé márùn-ún ka ìhà gúúsù àti márùn-ún ní àríwá. Nínú wọn ni ó ti ń fọ àwọn nǹkan tí wọ́n ń lò fún ẹbọ sísun ṣùgbọ́n, àwọn àlùfáà ní ó ń lo Òkun fún fífọ nǹkan.

7Ó ṣe ìgbé fìtílà dúró mẹ́wàá ti wúrà gẹ́gẹ́ bí èyí tí a yàn fún wọn. A sì gbé wọn kalẹ̀ sínú ilé Olúwa márùn un ní ìhà gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá.

8Ó ṣé tábìlì mẹ́wàá, ó sì gbé wọn sí inú ilé Olúwa, márùn un ní gúúsù àti márùn-ún ní ìhà àríwá. Ó ṣé ọgọ́ọ̀rún ọpọ́n ìbùwọ́n wúrà.

9Ó ṣe àgbàlá àwọn àlùfáà àti ààfin ńlá àti àwọn ìlẹ̀kùn fún ààfin, ó sì tẹ́ àwọn ìlẹ̀kùn náà pẹ̀lú idẹ. 10Ó gbé Òkun náà ka orí ìhà gúúsù ní ẹ̀bá Igun gúúsù àríwá.

11Huramu ṣe àwọn ìkòkò pẹ̀lú, àti ọkọ́ àti àwọn ọpọ́n ìbùwọ́n.

Bẹ́ẹ̀ ni Huramu parí iṣẹ́ tí ó ti dáwọ́lé fún ọba Solomoni ní ilé Ọlọ́run:

12Àwọn òpó méje;

àwọn ọpọ́n méjì rìbìtì tí ó wà lórí òpó méjèèje náà;

àti iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì láti bo ọpọ́n rìbìtì náà tí ó wà lórí àwọn òpó naà;

13Ọgọ́rùn-ún mẹ́rin pomegiranate fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n méjì naà, ẹsẹ̀ méjì pomegiranate ni fún iṣẹ́ ẹ̀wọ̀n kan, láti bo ọpọ́n rìbìtì méjì náà tí ó wà lórí àwọn òpó náà;

14Ó sì ṣe àgbéró ó sì ṣe agbada sí orí wọn;

15Agbada ńlá kan àti màlúù méjìlá lábẹ́ rẹ̀;

16Àwọn ìkòkò àti ọ̀kọ̀ àti àmúga ẹran àti gbogbo ohun èlò tí ó fi ara pẹ́ ẹ.

Gbogbo ohun èlò ti Huramu-Abi fi idẹ dídán ṣe fún Solomoni ọba, fún ilé Olúwa jẹ́ idẹ dídán. 17Ọba dà wọ́n ní ilẹ̀ amọ̀ ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Jordani ní àárín méjì Sukkoti àti Sereda. 18Gbogbo nǹkan wọ̀nyí tí Solomoni ṣe ní iye lórí púpọ̀ tí a kò le mọ ìwọ̀n iye idẹ tí ó wọ́n.

19Solomoni pẹ̀lú ṣe gbogbo ohun èlò tí ó wà ní ilé Ọlọ́run:

pẹpẹ wúrà

tábìlì èyí tí àkàrà ìfihàn wà lórí rẹ̀;

20Àwọn ọ̀pá fìtílà tí a fi ojúlówó wúrà ṣe pẹ̀lú fìtílà wọn kí wọn lè máa jó gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ní iwájú ibi mímọ́ jùlọ gẹ́gẹ́ bí a ṣe fi lélẹ̀;

21Pẹ̀lú ìtànná wúrà àti fìtílà àti ẹ̀mú ni ó jẹ́ kìkìdá wúrà tí ó gbópọn;

22Pẹ̀lú ọ̀pá fìtílà, àti àwokòtò àti ṣíbí àti àwokòtò tùràrí àti àwọn ìlẹ̀kùn wúrà ti inú tẹmpili: àwọn ìlẹ̀kùn ibi mímọ́ sí ibi mímọ́ jùlọ àti àwọn ìlẹ̀kùn à bá wọ inú gbọ̀ngàn ńlá.

New Russian Translation

2-я книга Паралипоменон 4:1-22

Храмовые принадлежности

(3 Цар. 7:23–51)

1Он сделал бронзовый жертвенник 20 локтей в длину, 20 локтей в ширину и 10 локтей в высоту4:1 Около 9 м в длину и ширину и 4,5 м в высоту.. 2Он вылил из бронзы круглый бассейн, названный «морем», размером в 10 локтей от края до края и 5 локтей в высоту4:2 Около 4,5 м и 2,3 м.. Мерная нить 30 локтей4:2 Около 14 м. в длину окаймляла его. 3Снизу его окружали два ряда подобия быков — по десять на локоть.4:3 Около 45 см. Быки были отлиты с морем одним литьем.

4Море стояло на двенадцати быках, три из которых смотрели на север, три на запад, три на юг и три на восток. Море покоилось на них, а их зады были обращены внутрь, к центру. 5Море было в ладонь4:5 Около 7,5 см. толщиной, а его край был как край чаши, как цветок лилии. Море вмещало в себя 3 000 батов4:5 Около 66 000 л..

6Он сделал десять умывальников и поставил пять из них на южной стороне и пять на северной. В них промывали части животных, предназначенные для всесожжения, а морем пользовались для омовений священники.

7Он сделал десять золотых светильников по установленному образцу и поставил их в храме: пять на южной стороне и пять на северной.

8Он сделал десять столов и поставил их в храме: пять на южной стороне и пять на северной. Еще он сделал сто золотых кропильных чаш.

9Он сделал двор для священников, большой двор и двери для двора, и покрыл двери бронзой. 10Затем он поставил море на южной стороне, в юго-восточном углу дома.

11Еще он сделал горшки, лопатки и кропильные чаши.

На этом Хирам завершил всю работу, которую выполнял для царя Соломона в доме Божьем. Он сделал:

12две колонны,

две чашеобразные капители для колонн,

две сетки, украшавшие чашеобразные капители,

13четыреста гранатовых плодов для двух сеток (два ряда гранатов для каждой сетки, украшавшей чашеобразные капители),

14подставки с умывальниками,

15море и двенадцать быков под ним,

16горшки, лопатки, вилки для мяса и другие принадлежности.

Все предметы, которые Хирам-Авий сделал царю Соломону для дома Господа, были из полированной бронзы. 17Царь велел отлить ее в глиняных формах в долине Иордана между Суккотом и Цередатой4:17 Вариант названия Цартан (см. 3 Цар. 7:46).. 18Всех этих предметов, которые сделал Соломон, было так много, что вес бронзы остался неизвестным.

19Еще Соломон сделал все принадлежности для Божьего дома:

золотой жертвенник,

столы для хлеба Присутствия,

20подсвечники из чистого золота со светильниками, чтобы они горели перед внутренним святилищем, как предписано,

21золотые цветы, лампады и щипцы (они были из чистого золота),

22ножницы для фитилей, кропильные чаши, блюда и кадильницы — все из чистого золота,

а также золотые двери храма: внутренние двери в Святое Святых и внешние двери дома.