2 Kronika 30 – YCB & NTLR

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 30:1-27

Hesekiah ṣe àsè ìrékọjá

1Hesekiah sì ránṣẹ́ sí gbogbo Israẹli àti Juda, ó sì kọ ìwé sí Efraimu àti Manase, kí wọn kí ó wá sínú ilé Olúwa ní Jerusalẹmu láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli. 2Nítorí tí ọba ti gbìmọ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àti gbogbo ìjọ ènìyàn ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ ìrékọjá mọ́ ní oṣù kejì. 3Nítorí wọn kò lè pa á mọ́ ní àkókò náà, nítorí àwọn àlùfáà kò tí i ya ara wọn sí mímọ́ tó; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ènìyàn kò tí ì kó ara wọn jọ sí Jerusalẹmu. 4Ọ̀rọ̀ náà sí tọ́ lójú ọba àti lójú gbogbo ìjọ ènìyàn. 5Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n fi àṣẹ kan lélẹ̀, láti kéde ká gbogbo Israẹli láti Beerṣeba àní títí dé Dani, láti wá pa àjọ ìrékọjá mọ́ sí Olúwa Ọlọ́run Israẹli ní Jerusalẹmu: nítorí wọn kò pa á mọ́ ní ọjọ́ púpọ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́.

6Bẹ́ẹ̀ àwọn oníṣẹ́ tí ń sáré lọ pẹ̀lú ìwé láti ọwọ́ ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀ sí gbogbo Israẹli àti Juda; àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ ọba, wí pé,

“Ẹ̀yin ọmọ Israẹli ẹ yí padà sí Olúwa Ọlọ́run Abrahamu, Isaaki, àti Israẹli, òun ó sì yípadà sí àwọn ìyókù nínú yín, tí ó sálà kúrò lọ́wọ́ àwọn ọba Asiria. 7Kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe dàbí àwọn baba yín, àti bí àwọn arákùnrin yín tí ó dẹ́ṣẹ̀ sí Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn, nítorí náà ní ó ṣe fi wọ́n fún ìdahoro bí ẹ̀yin ti rí. 8Ǹjẹ́ kí ẹ̀yin kí ó má ṣe ṣe ọlọ́rùn líle, bí àwọn baba yín, ṣùgbọ́n ẹ jọ̀wọ́ ara yín lọ́wọ́ fún Olúwa, kí ẹ sì wọ inú ibi mímọ́ rẹ̀ lọ, ti òun ti ìyàsímímọ́ títí láé. Kí ẹ sì sin Olúwa, Ọlọ́run yín kí gbígbóná ìbínú rẹ̀ kí ó lè yípadà kúrò ní ọ̀dọ̀ yín. 9Nítorí bí ẹ̀yin bá tún yípadà sí Olúwa, àwọn arákùnrin yín, àti àwọn ọmọ yín, yóò rí àánú níwájú àwọn tí ó kó wọn ní ìgbèkùn lọ, kí wọn kí ó lè tún padà wá sí ilẹ̀ yí: nítorí Olúwa Ọlọ́run yín, oníyọnu àti aláàánú ni, kì yóò sì yí ojú rẹ̀ padà kúrò lọ́dọ̀ yín, bí ẹ̀yin bá padà sọ́dọ̀ rẹ̀.”

10Bẹ́ẹ̀ ni àwọn oníṣẹ́ náà kọjá láti ìlú dé ìlú, ní ilẹ̀ Efraimu àti Manase títí dé Sebuluni, ṣùgbọ́n wọ́n fi wọ́n rẹ́rìn-ín ẹlẹ́yà, wọ́n sì gàn wọ́n. 11Síbẹ̀ òmíràn nínú àwọn ènìyàn Aṣeri àti Manase àti Sebuluni rẹ̀ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì wá sí Jerusalẹmu. 12Ní Juda pẹ̀lú, ọwọ́ Ọlọ́run wá láti fún wọn ní ọkàn kan láti pa òfin ọba mọ́ àti tí àwọn ìjòyè, nípa ọ̀rọ̀ Olúwa.

13Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì péjọ ní Jerusalẹmu, láti pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní oṣù kejì. 14Wọ́n sì dìde, wọ́n sì kó gbogbo pẹpẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu lọ, àti gbogbo pẹpẹ tùràrí ni wọ́n kó lọ, wọ́n sì dà wọ́n sí odò Kidironi.

15Nígbà náà ni wọ́n pa ẹran ìrékọjá náà ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kejì: ojú sì ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, wọ́n sì yà ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì mú ẹbọ sísun wá sínú ilé Olúwa. 16Wọ́n sì dúró ní ipò wọn, bí ètò wọn gẹ́gẹ́ bí òfin Mose, ènìyàn Ọlọ́run: àwọn àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà, tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Lefi. 17Nítorí pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó wà nínú ìjọ ènìyàn náà tí kò yà ara wọn sí mímọ́: nítorí náà ni àwọn ọmọ Lefi ṣe ń tọ́jú àti pa ẹran ìrékọjá fún olúkúlùkù ẹni tí ó ṣe aláìmọ́, láti yà á sí mímọ́ sí Olúwa. 18Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, àní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú Efraimu àti Manase, Isakari, àti Sebuluni kò sá wẹ̀ ara wọn mọ́ síbẹ̀ wọ́n jẹ ìrékọjá náà, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́. Ṣùgbọ́n Hesekiah bẹ̀bẹ̀ fún wọn, wí pé, Olúwa, ẹni rere, dáríjì olúkúlùkù, 19tí ó múra ọkàn rẹ̀ láti wá Ọlọ́run, Olúwa Ọlọ́run àwọn baba rẹ̀ ṣùgbọ́n tí kì í ṣe nípa ìwẹ̀nùmọ́ mímọ́ 20Olúwa sì gbọ́ ti Hesekiah, ó sì mú àwọn ènìyàn náà láradá.

21Àwọn ọmọ Israẹli tí a rí ní Jerusalẹmu fi ayọ̀ ńlá pa àjọ àkàrà àìwú mọ́ ní ọjọ́ méje: àwọn ọmọ Lefi, àti àwọn àlùfáà yin Olúwa lójoojúmọ́, wọ́n ń fi ohun èlò olóhùn gooro kọrin sí Olúwa.

22Hesekiah sọ̀rọ̀ ìtùnú fún gbogbo àwọn ọmọ Lefi, tí ó lóye ní ìmọ̀ rere Olúwa: ọjọ́ méje ni wọ́n fi jẹ àsè náà wọ́n rú ẹbọ àlàáfíà, wọ́n sì ń fi ohùn rara dúpẹ́ fún Olúwa, Ọlọ́run àwọn baba wọn.

23Gbogbo ìjọ náà sì gbìmọ̀ láti pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́: wọ́n sì fi ayọ̀ pa ọjọ́ méje mìíràn mọ́. 24Nítorí Hesekiah, ọba Juda, ta ìjọ ènìyàn náà ní ọrẹ, ẹgbẹ̀rún (1,000) akọ màlúù, àti ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) àgùntàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn àlùfáà sì ya ara wọn sí mímọ́. 25Gbogbo ìjọ ènìyàn Juda pẹ̀lú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Lefi, àti gbogbo ìjọ ènìyàn tí ó ti inú Israẹli jáde wá, àti àwọn àjèjì tí ó ti ilẹ̀ Israẹli jáde wá, àti àwọn tí ń gbé Juda yọ̀. 26Bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ńlá sì wà ní Jerusalẹmu: nítorí láti ọjọ́ Solomoni, ọmọ Dafidi, ọba Israẹli, irú èyí kò sí ní Jerusalẹmu. 27Nígbà náà ni àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Lefi dìde, wọ́n sì súre fún àwọn ènìyàn náà: a sì gbọ́ ohùn wọn, àdúrà wọn sì gòkè lọ si ibùgbé mímọ́ rẹ̀, àní sí ọ̀run.

Nouă Traducere În Limba Română

2 Cronici 30:1-27

Celebrarea Paștelui

1Ezechia a trimis solie peste tot în Israel și Iuda și a scris scrisori chiar și celor din Efraim și Manase, chemându‑i la Casa Domnului, în Ierusalim, pentru a sărbători Paștele Domnului, Dumnezeul lui Israel. 2Regele se sfătuise la Ierusalim cu căpeteniile sale și cu toată adunarea să sărbătorească Paștele în luna a doua, 3pentru că nu au putut să‑l sărbătorească la vremea sa, deoarece nu se sfințiseră3 Verbul poate avea sensul de a pune pe cineva/ceva într‑o stare specială (fizic sau spiritual), a consacra, a pune deoparte pentru Dumnezeu (uneori printr‑un ritual de ungere cu ulei sau sânge, spălare și/sau rugăciune ori declarație publică). destui preoți, iar poporul nu se adunase la Ierusalim. 4Propunerea a plăcut atât regelui, cât și întregii adunări. 5Prin urmare, ei au dat o poruncă prin care urma să se străbată tot Israelul, de la Beer-Șeba până la Dan, pentru a‑i chema pe oameni la Ierusalim ca să sărbătorească Paștele Domnului, Dumnezeul lui Israel, căci demult nu‑l mai sărbătoriseră în mare număr, după cum era scris. 6Și, așa cum poruncise regele, mesagerii6, 10 Lit.: alergătorii. au dus în tot Israelul și în Iuda scrisorile regelui și ale căpeteniilor sale, în care se spunea:

„Fii ai lui Israel, întoarceți‑vă la Domnul, Dumnezeul lui Avraam, Isaac și Israel, iar El Se va întoarce la rămășița care a scăpat, la cei ce au scăpat din mâna împăraților Asiriei! 7Nu fiți ca părinții și ca frații voștri care au fost necredincioși față de Domnul, Dumnezeul părinților voștri, și pe care El i‑a lăsat pradă pustiirii, după cum vedeți astăzi. 8Acum, nu vă înțepeniți ceafa, ca părinții voștri! Dați mâna cu Domnul, veniți la Sfântul Lui Lăcaș, pe care l‑a sfințit pe vecie, și slujiți Domnului, Dumnezeul vostru, ca astfel să se depărteze de la voi apriga Lui mânie! 9Căci dacă vă veți întoarce la Domnul, frații voștri și fiii voștri vor găsi îndurare la cei ce i‑au luat captivi și se vor întoarce în țara aceasta, căci Domnul, Dumnezeul vostru, este plin de har și milostiv și nu‑Și va întoarce fața de la voi, dacă vă întoarceți la El.“

10Mesagerii au străbătut fiecare cetate din Efraim și Manase, până în Zabulon, însă oamenii râdeau de ei și‑i batjocoreau. 11Totuși, au existat unii din Așer, din Manase și din Zabulon care s‑au smerit și au venit la Ierusalim. 12De asemenea, și în Iuda, mâna lui Dumnezeu i‑a unit pentru ca ei să împlinească porunca regelui și a căpeteniilor, poruncă dată potrivit Cuvântului Domnului.

13În luna a doua, o mulțime de oameni s‑a adunat la Ierusalim ca să celebreze Sărbătoarea Azimelor. Era o adunare foarte mare. 14S‑au ridicat și au îndepărtat altarele care erau în Ierusalim, precum și toate altarele pentru tămâiere și le‑au aruncat în uedul14 Vezi nota de la 15:16. Chidron. 15Apoi, în a paisprezecea zi a lunii a doua, au înjunghiat mieii de Paște. Preoții și leviții, plini de rușine, s‑au sfințit și au adus arderi‑de‑tot la Casa Domnului. 16Ei stăteau la locurile lor, așa cum era hotărât cu privire la ei în Legea lui Moise, omul lui Dumnezeu; și preoții stropeau sângele pe care‑l luau de la leviți. 17Fiindcă erau mulți în adunare care nu se sfințiseră,17 Vezi nota de la 30:3. leviții au înjunghiat ei înșiși mieii de Paște pentru toți aceia care nu erau curați și nu puteau să îi închine17 Lit.: sfințească. Verbul poate avea sensul de a pune pe cineva/ceva într‑o stare specială (fizic sau spiritual), a consacra, a pune deoparte pentru Dumnezeu (uneori printr‑un ritual de ungere cu ulei sau sânge, spălare și/sau rugăciune ori declarație publică). ei Domnului. 18Căci majoritatea poporului, mulți din Efraim, din Manase, din Isahar și din Zabulon, nu se curățise și nu mâncase jertfa de Paște după cum era scris. Însă Ezechia s‑a rugat pentru ei, zicând: „Domnul, Care este bun, să‑i ierte 19pe toți aceia care s‑au hotărât în inimile lor să‑L caute pe Dumnezeu, pe Domnul, Dumnezeul părinților lor, chiar și fără sfânta curățire!“ 20Domnul l‑a ascultat pe Ezechia și a vindecat poporul.

21Fiii lui Israel prezenți la Ierusalim au celebrat, cu mare bucurie, Sărbătoarea Azimelor, timp de șapte zile. Leviții și preoții Îl lăudau pe Domnul în fiecare zi cu instrumentele de laudă ale Domnului.

22Ezechia a vorbit pe placul inimii tuturor leviților care arătaseră o bună înțelegere a slujbei Domnului. Ei au mâncat, timp de șapte zile, din partea cuvenită lor, au adus jertfe de pace și I‑au mulțumit Domnului, Dumnezeul părinților lor.

23Întreaga adunare s‑a sfătuit să mai celebreze încă șapte zile. Și au celebrat cu bucurie încă șapte zile, 24deoarece Ezechia, regele lui Iuda, oferise adunării o mie de tauri și șapte mii de oi, iar căpeteniile oferiseră adunării o mie de tauri și zece mii de oi, și deoarece mulți preoți se sfințiseră. 25Toată adunarea lui Iuda împreună cu preoții și leviții și toată adunarea celor sosiți din Israel, precum și străinii, cei sosiți din țara lui Israel și cei ce locuiesc în Iuda, s‑au bucurat împreună. 26A fost o mare bucurie în Ierusalim, așa cum nu a mai fost în Ierusalim din zilele lui Solomon, fiul lui David, regele lui Israel. 27Preoții și leviții s‑au ridicat și au binecuvântat poporul. Glasul lor s‑a făcut auzit, iar rugăciunea lor a ajuns până la Lăcașul Tău cel Sfânt, până la ceruri.