2 Kronika 29 – YCB & CARSA

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 29:1-36

Hesekiah sọ ilé Olúwa di mímọ́

129.1,2: 2Ọb 18.1-3.Hesekiah sì jẹ́ ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n nígbà tí ó di ọba, ó sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu fún ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n orúkọ ìyá rẹ̀ sì ni Abijah ọmọbìnrin Sekariah. 2Ó sì ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ Dafidi ti ṣe.

3Ní oṣù àkọ́kọ́ ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba rẹ̀, ó sì ṣí àwọn ìlẹ̀kùn ilé Olúwa ó sì tún wọn ṣe. 4Ó sì mú àwọn àlùfáà wá àti àwọn ọmọ Lefi, ó sì kó wọn jọ yíká ìta ìlà-oòrùn. 5Ó sì wí pé, “Ẹ gbọ́ tèmi, ẹ̀yin ọmọ Lefi! Ẹ ya ara yín sí mímọ́ nísinsin yìí kí ẹ sì ya ilé Olúwa Ọlọ́run sí mímọ́, kí ẹ sì kó ohun àìmọ́ baba mi jáde kúrò ní ibi mímọ́. 6Àwọn baba wa jẹ́ aláìṣòótọ́; wọ́n sì ṣe ohun àìtọ́ níwájú Olúwa Ọlọ́run wa, wọ́n sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Wọ́n sì yí ojú wọn padà kúrò ní ibùgbé Olúwa, wọ́n sì pa ẹ̀yìn wọn dà sí i. 7Wọ́n sì tún ti ìlẹ̀kùn ìloro náà pẹ̀lú, wọ́n sì pa fìtílà. Wọn kò sì sun tùràrí tàbí pèsè ẹbọ sísun si ibi mímọ́ si Ọlọ́run Israẹli. 8Nítorí náà, ìbínú Olúwa ti ru sókè wá sórí Juda àti Jerusalẹmu ó sì ti fi wọ́n ṣe ohun èlò fún wàhálà, àti ìdààmú àti ẹ̀sín, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe fi ojú rẹ̀ rí i. 9Ìdí nìyí tí àwọn baba wa ṣe ṣubú nípa idà àti ìdí tí àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin àti àwọn aya wa tiwọn kó wọ́n ní ìgbèkùn. 10Nísinsin yìí ó wà ní ọkàn mi láti bá Olúwa Ọlọ́run Israẹli dá májẹ̀mú. Bẹ́ẹ̀ ni kí ìbínú rẹ̀ kíkan kí ó lè yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa. 11Àwọn ọmọ mi, ẹ má ṣe jáfara nísinsin yìí, nítorí tí Olúwa ti yàn yín láti dúró níwájú rẹ̀ láti sin, kí ẹ sì máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ àti láti sun tùràrí.”

12Nígbà náà àwọn ọmọ Lefi wọ̀nyí múra láti ṣe iṣẹ́:

nínú àwọn ọmọ Kohati,

Mahati ọmọ Amasai: àti Joẹli ọmọ Asariah;

nínú àwọn ọmọ Merari,

Kiṣi ọmọ Abdi àti Asariah ọmọ Jehaleeli;

nínú àwọn ọmọ Gerṣoni,

Joah, ọmọ Simma àti Edeni ọmọ Joah;

13nínú àwọn ọmọ Elisafani,

Ṣimri àti Jeieli;

nínú àwọn ọmọ Asafu,

Sekariah àti Mattaniah;

14nínú àwọn ọmọ Hemani,

Jehieli àti Ṣimei;

nínú àwọn ọmọ Jedutuni,

Ṣemaiah àti Usieli.

15Nígbà tí wọ́n sì ti kó ara wọn jọ pọ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin wọn, wọ́n sì ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì lọ láti gbá ilé Olúwa mọ́, gẹ́gẹ́ bí ọba ti pa á láṣẹ, ẹ tẹ̀lé ọ̀rọ̀ Olúwa. 16Àwọn àlùfáà sì wọ inú ilé Olúwa lọ́hùn ún lọ láti gbá a mọ́. Wọ́n sì gbé e jáde sí inú àgbàlá ilé Olúwa gbogbo ohun àìmọ́ tí wọ́n rí nínú ilé Olúwa. Àwọn ọmọ Lefi sì mú u wọ́n sì gbangba odò Kidironi. 17Wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìyàsímímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní oṣù kìn-ín-ní, àti ní ọjọ́ kẹjọ oṣù náà wọ́n sì dé ìloro Olúwa. Fún ọjọ́ mẹ́jọ mìíràn sí i, wọ́n sì ya ilé Olúwa sí mímọ́ fúnra rẹ̀. Wọ́n sì parí ní ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù kìn-ín-ní.

18Nígbà náà wọn sì lọ sí ọ̀dọ̀ ọba Hesekiah láti lọ jábọ̀ fún un: “Àwa ti gbá ilé Olúwa mọ́, pẹpẹ ẹbọ sísun pẹ̀lú gbogbo ohun ẹbọ rẹ̀, àti tábìlì àkàrà ìfihàn, pẹ̀lú gbogbo ohun èlò. 19A ti pèsè a sì ti yà sí mímọ́ gbogbo ohun èlò tí ọba Ahasi ti sọ di aláìmọ́ nínú àìṣòótọ́ rẹ̀ nígbà tí ó jẹ́ ọba; nísinsin yìí, wọ́n wà níwájú pẹpẹ Olúwa.”

20Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kejì, ọba Hesekiah sì kó olórí àwọn ìjòyè jọ, ó sì lọ sókè ilé Olúwa. 21Wọ́n sì mú akọ màlúù méje wá, àti àgbò méje, àti ọ̀dọ́-àgùntàn méje àti òbúkọ méje gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba, fún ibi mímọ́ àti fún Juda. Ọba pàṣẹ fun àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Aaroni, láti ṣe èyí lórí pẹpẹ Olúwa. 22Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì pa akọ màlúù, àwọn àlùfáà mú ẹ̀jẹ̀ náà, wọ́n sì fi wọ́n ara pẹpẹ. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni nígbà tí wọ́n pa àgbò, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọ́n orí pẹpẹ. Nígbà náà wọ́n sì pa ọ̀dọ́-àgùntàn, wọ́n sì fi ẹ̀jẹ̀ wọn ara pẹpẹ. 23Òbúkọ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n gbé wá síwájú ọba àti ìjọ ènìyàn, wọ́n sì gbé ọwọ́ lé wọn. 24Àwọn àlùfáà wọn sì pa òbúkọ, wọ́n sì gbé ẹ̀jẹ̀ kalẹ̀ lórí pẹpẹ fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣe ètùtù fún gbogbo Israẹli, nítorí ọba ti pàṣẹ kí a ṣe ẹbọ sísun àti ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún gbogbo Israẹli.

25Ó sì mú àwọn Lefi dúró nínú ilé Olúwa pẹ̀lú Kimbali, ohun èlò orin olókùn àti dùùrù ní ọ̀nà tí a ti paláṣẹ fún wọn láti ọ̀dọ̀ Dafidi àti Gadi aríran ọba àti Natani wòlíì. Èyí ni a pàṣẹ láti ọ̀dọ̀ Olúwa láti ọwọ́ àwọn wòlíì rẹ̀. 26Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Lefi sì dúró pẹ̀lú ohun èlò orin Dafidi, àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú ìpè wọn.

27Hesekiah sì pa á láṣẹ láti rú ẹbọ sísun lórí pẹpẹ, bí ẹbọ sísun náà ti bẹ̀rẹ̀, orin sí Olúwa bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ìpè àti pẹ̀lú ohun èlò orin Dafidi ọba Israẹli. 28Gbogbo ìjọ ènìyàn náà sì wólẹ̀ sìn, àwọn akọrin kọrin, àwọn afùnpè sì fọn ìpè, gbogbo wọ̀nyí sì wà bẹ́ẹ̀ títí ẹbọ sísun náà fi parí tán.

29Nígbà tí wọ́n sì ṣe ìparí ẹbọ rírú, ọba àti gbogbo àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tẹ ara wọn ba, wọ́n sì sìn. 30Pẹ̀lúpẹ̀lú Hesekiah ọba, àti àwọn ìjòyè pàṣẹ fún àwọn ọmọ Lefi, láti fi ọ̀rọ̀ Dafidi àti ti Asafu aríran, kọrin ìyìn sí Olúwa: wọ́n sì fi inú dídùn kọrin ìyìn, wọ́n sì tẹrí wọn ba, wọ́n sì sìn.

Ìrúbọ nínú tẹmpili

31Nígbà náà ni Hesekiah dáhùn, ó sì wí pé, nísinsin yìí, ọwọ́ yín kún fún ẹ̀bùn fún Olúwa, ẹ súnmọ́ ìhín, kí ẹ sì mú ẹbọ àti ọrẹ-ọpẹ́ wá sínú ilé Olúwa. Ìjọ ènìyàn sì mú ẹbọ àti ọrẹ-ọpẹ́ wá; àti olúkúlùkù tí ọkàn rẹ̀ fẹ́, mú ẹbọ sísun wá.

32Iye ẹbọ sísun, tí ìjọ ènìyàn mú wá, sì jẹ́ àádọ́rin akọ màlúù, àti ọgọ́rùn-ún àgbò, àti igba ọ̀dọ́-àgùntàn, gbogbo wọ̀nyí sì ni fún ẹbọ sísun sí Olúwa. 33Àwọn ohun ìyàsímímọ́ sì jẹ́ ẹgbẹ̀ta (600) màlúù, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́ta (3,000) àgùntàn. 34Ṣùgbọ́n àwọn àlùfáà kò pọ̀ tó, wọn kò sì le bó gbogbo àwọn ẹran ẹbọ sísun náà: nítorí náà àwọn arákùnrin wọn, àwọn Lefi ràn wọ́n lọ́wọ́, títí iṣẹ́ náà fi parí, àti títí àwọn àlùfáà ìyókù fi yà wọ́n sí mímọ́: nítorí àwọn ọmọ Lefi ṣe olóòtítọ́ ní ọkàn ju àwọn àlùfáà lọ láti ya ara wọn sí mímọ́. 35Àti pẹ̀lú, àwọn ẹbọ sísun pàpọ̀jù, pẹ̀lú ọ̀rá ẹbọ àlàáfíà, pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu fún ẹbọ sísun.

Bẹ́ẹ̀ ni a sì tún bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn ilé Olúwa. 36Hesekiah sì yọ̀, àti gbogbo ènìyàn pé, Ọlọ́run ti múra àwọn ènìyàn náà sílẹ̀, nítorí lójijì ni a ṣe nǹkan náà.

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

2 Летопись 29:1-36

Езекия – царь Иудеи

(4 Цар. 18:1-3)

1Езекии было двадцать пять лет, когда он стал царём, и правил он в Иерусалиме двадцать девять лет. Его мать звали Авия, она была дочерью Закарии. 2Он делал то, что было правильным в глазах Вечного, как и его предок Давуд.

Езекия очищает храм

3В первый месяц (ранней весной), на первом году своего правления, он открыл двери храма Вечного и починил их. 4Он привёл священнослужителей и левитов, собрал их на площади с восточной стороны 5и сказал им:

– Слушайте меня, левиты! Освятитесь сегодня сами и освятите храм Вечного, Бога ваших предков. Выбросите из святилища всякую скверну. 6Наши отцы поступали беззаконно, делая зло в глазах Вечного, нашего Бога, и оставили Его. Они отвернули свои лица от жилища Вечного и повернулись к нему спиной. 7Они заперли двери притвора и погасили светильники. Они не возжигали благовоний и не приносили всесожжений в святилище Бога Исраила. 8За это гнев Вечного обрушился на Иудею и Иерусалим. Он отдал их на позор, на опустошение и на посмеяние, как вы видите своими глазами. 9Поэтому наши отцы пали от меча, а наши сыновья, дочери и жёны в плену. 10И теперь я хочу заключить соглашение с Вечным, Богом Исраила, чтобы Его пылающий гнев на нас прекратился. 11Дети мои, не будьте же беспечными, потому что Вечный избрал вас служить Ему и возжигать благовония.

12И начали своё служение левиты:

из потомков Каафа – Махат, сын Амасая, и Иоиль, сын Азарии;

из потомков Мерари – Киш, сын Авди, и Азария, сын Иехаллелила;

из потомков Гершона – Иоах, сын Зиммы, и Еден, сын Иоаха;

13из потомков Элицафана – Шимри и Иеил;

из потомков Асафа – Закария и Маттания;

14из потомков Емана – Иехиил и Шимей;

из потомков Иедутуна – Шемая и Узиил.

15Собрав своих братьев и освятившись, они пришли очищать храм Вечного, как, следуя словам Вечного, повелел царь. 16Священнослужители прошли в святилище Вечного, чтобы очистить его. Они вынесли во двор храма Вечного всё нечистое, что нашли в храме Вечного. Левиты взяли это и отнесли в долину Кедрон. 17Приступив к освящению в первый день первого месяца, они подошли к притвору храма Вечного в восьмой день того же месяца. Ещё восемь дней они освящали сам храм и закончили на шестнадцатый день первого месяца.

18Они пришли к царю Езекии и сказали:

– Мы очистили весь храм Вечного, жертвенник для всесожжений со всей его утварью и стол, на который кладут священный хлеб, со всей его утварью. 19Всю утварь, которую во время своего правления убрал неверный царь Ахаз, мы приготовили и освятили. Она сейчас перед жертвенником Вечного.

Освящение храма

20На следующий день, ранним утром, царь Езекия собрал начальников города и отправился в храм Вечного. 21Они привели семь быков, семь баранов, семь ягнят и семь козлов, чтобы принести их в жертву за грех за царскую семью, за святилище и за всю Иудею. Царь велел священнослужителям, потомкам Харуна, принести их в жертву на жертвеннике Вечного. 22Быков закололи, и священнослужители, взяв крови, окропили ею жертвенник. Затем закололи баранов и окропили жертвенник их кровью. Затем закололи ягнят и окропили жертвенник их кровью. 23А козлов, которые были предназначены в жертву за грех, поставили перед царём и собранием, и они возложили на них руки. 24Затем священнослужители закололи козлов и принесли их кровь на жертвеннике как жертву за грех, чтобы очистить весь Исраил, потому что царь велел совершить всесожжение и принести жертву за грех за весь Исраил.

25Езекия поставил левитов с тарелками, лирами и арфами в храме Вечного, по указанию Давуда, царского провидца Гада и пророка Нафана. Это установление было дано Вечным через Его пророков. 26Левиты стояли наготове с музыкальными инструментами Давуда, а священнослужители – с трубами.

27Езекия велел принести на жертвеннике всесожжение. Когда жертвоприношение началось, началось и пение Вечному под голос труб и музыкальных инструментов Давуда, царя Исраила. 28Всё собрание совершало поклонение, певцы пели, а трубачи трубили. Так продолжалось, пока жертвоприношение не было завершено.

29Когда жертвы были принесены, царь и все, кто был с ним, преклонили колени и поклонились. 30Царь Езекия со своими приближёнными велел левитам славить Вечного словами Давуда и провидца Асафа. И они радостно пели хвалу, кланялись и прославляли Вечного. 31Езекия сказал:

– Итак, вы посвятили себя Вечному. Приступайте, несите жертвы и благодарственные приношения в храм Вечного.

Народ принёс жертвы и благодарственные приношения, а все, кто был к этому расположен, принесли и всесожжения. 32Жертв всесожжения, которые принёс народ, было общим счётом: семьдесят быков, сто баранов и двести ягнят – всё это для всесожжения Вечному. 33Других священных жертв было: шестьсот голов крупного и три тысячи голов мелкого скота. 34Но священнослужителей было слишком мало, чтобы освежевать все туши жертв всесожжения, и пока другие священнослужители не освятились, их сородичи левиты помогали им, пока работа не была сделана, потому что левиты отнеслись к освящению добросовестнее, чем священнослужители. 35Жертв всесожжения и жира жертв примирения с жертвенными возлияниями, которыми сопровождались всесожжения, было в изобилии.

Так было восстановлено служение в храме Вечного. 36Езекия и весь народ радовались тому, что сделал для Своего народа Аллах, ведь сделано это было так быстро.