2 Kronika 16 – YCB & HTB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kronika 16:1-14

Ìgbẹ̀yìn ọdún asà

1Ní ọdún kẹrìndínlógójì ìjọba Asa, Baaṣa ọba Israẹli gòkè wá sí Juda ó sì kọlu Rama, láti ma bá a jẹ́ kí ẹnikẹ́ni lè jáde tàbí wọlé tọ Asa ọba Juda lọ.

2Nígbà náà ni Asa mú wúrà àti fàdákà jáde nínú ilé ìṣúra ilé Olúwa àti ààfin ọba ó sì ránṣẹ́ sí Beni-Hadadi ọba Siria, ẹni tí ń gbé ní Damasku, ó wí pé, 3“Májẹ̀mú kan wà láàrín èmi àti ìrẹ, bí ó ti wà láàrín baba mi àti baba rẹ. Ẹ wò ó, mo fi wúrà àti fàdákà ránṣẹ́ sí ọ; lọ, ba májẹ̀mú tí o bá Baaṣa ọba Israẹli dá jẹ́, kí ó lè lọ kúrò ní ọ̀dọ̀ mi.”

4Beni-Hadadi sì gbọ́ ti Asa ọba, ó sì rán àwọn olórí ogun rẹ̀ lọ sí àwọn ìlú Israẹli, wọ́n sì kọlu Ijoni, Dani, Abeli-Maimu, àti gbogbo ìlú ìṣúra Naftali. 5Nígbà tí Baaṣa gbọ́ èyí, ó sì dá kíkọ́ Rama dúró, ó sì dá iṣẹ́ rẹ̀ dúró. 6Nígbà náà ní ọba Asa kó gbogbo àwọn ènìyàn Juda jọ, wọ́n sì kó òkúta àti igi Rama lọ èyí ti Baaṣa ń fi kọ́lé; ó sì fi kọ́ Geba àti Mispa.

7Ní àkókò náà wòlíì Hanani wá sí ọ̀dọ̀ Asa ọba Juda, ó sì wí fún un pé, “Nítorí tí ìwọ gbẹ́kẹ̀lé ọba Siria, ìwọ kò sì gbẹ́kẹ̀lé Olúwa Ọlọ́run rẹ, nítorí náà ni ogún ọba Siria ṣe bọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ. 8Àwa kì í ṣe ará Etiopia àti àwọn ará Libia àwọn alágbára ogun pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ kẹ̀kẹ́ àti àwọn ẹlẹ́ṣin? Síbẹ̀ nígbà tí ìwọ bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa yóò sì fi wọ́n lé ọwọ́ rẹ. 9Nítorí ojú Olúwa yí gbogbo ayé ká láti fi agbára fún àwọn ẹni tí ó ní ọkàn pípé sí i. Ìwọ ti ṣe ohun aṣiwèrè, láti ìsinsin yìí lọ, ìwọ yóò wà lójú ogun.”

10Asa sì bínú pẹ̀lú sí wòlíì nítorí èyí, ó sì mú un bínú gidigidi tí ó sì fi mú un sínú túbú. Ní àkókò náà Asa sì ni díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn náà lára.

11Àwọn iṣẹ́ ìjọba Asa, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ni akọ sínú ìwé ọba Juda àti Israẹli. 1216.12-14: 1Ọb 15.23,24.Ní ọdún kọkàndínlógójì ìjọba rẹ̀, Asa sì ṣe àìsàn pẹ̀lú ààrùn nínú ẹsẹ̀ rẹ̀. Bi ó tilẹ̀ jẹ pé ààrùn rẹ̀ lágbára, síbẹ̀ kódà nínú àìsàn rẹ̀ kò wá ìrànlọ́wọ́ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, ṣùgbọ́n lọ́dọ̀ àwọn oníṣègùn nìkan. 13Nígbà náà tí ó pé ọdún kọ́kànlélógójì rẹ̀, Asa kú, ó sì sùn pẹ̀lú àwọn ìjọba baba rẹ̀, 14wọ́n sì sin ín sínú isà òkú tí ó ti gbẹ́ jáde fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Wọ́n sì tẹ sí orí àkéte tí ó fi òórùn dídùn kún, àti onírúurú tùràrí tí a fi ọgbọ́n pèsè, wọ́n sì da iná ńlá nítorí rẹ̀.

Het Boek

2 Kronieken 16:1-14

1maar in het zes en dertigste regeringsjaar van Asa trok koning Basja van Israël tegen Juda op, en versterkte Rama, om te beletten, dat er nog iemand van koning Asa van Juda het land in- of uitging. 2Maar Asa nam zilver en goud uit de schatkamers van de tempel van Jahweh en van het koninklijk paleis, en zond er zijn beambten mee naar Ben-Hadad, den koning van Aram, die te Damascus woonde. Hij liet hem zeggen: 3Laat ons een verbond sluiten, zoals er een bestond tussen mijn vader en uw vader. Hierbij zend ik u zilver en goud. Verbreek dus uw verbond met Basja, den koning van Israël, dan zal hij wel van mij wegtrekken. 4Ben-Hadad willigde het verzoek van koning Asa in; hij zond zijn legeroversten naar de steden van Israël, en overweldigde Ijjon, Dan, Abel-Máim en alle opslagplaatsen in Neftali. 5Toen Basja dit hoorde, hield hij op met Rama te versterken en liet hij het werk rusten. 6Nu riep koning Asa heel Juda op, om de stenen en het hout weg te halen, waarmee Basja Rama had willen versterken en versterkte daarmee Géba en Mispa. 7Bij die gelegenheid kwam de ziener Chanani bij koning Asa van Juda, en sprak tot hem: Omdat gij op den koning van Aram gerekend hebt, en uw toevlucht niet hebt genomen tot Jahweh, uw God, daarom is de legermacht van den koning van Aram aan uw handen ontglipt. 8Hadden dan de Koesjieten en de Lybiërs soms geen groot aantal strijdwagens en een talrijke ruiterij? Maar omdat gij toen uw toevlucht tot Jahweh hebt genomen, heeft Hij ze aan u overgeleverd. 9Want de ogen van Jahweh doorvorsen de gehele aarde, om hen te helpen, wier hart onverdeeld op Hem is gericht. Gij hebt hiermede dwaas gehandeld; en van nu af aan zult ge oorlogen moeten voeren. 10Maar Asa ergerde zich aan den ziener, en was om die vermaning zo boos op hem, dat hij hem in de gevangenis liet zetten. Bij die gelegenheid mishandelde Asa nog andere mensen uit het volk. 11De geschiedenis van Asa de vroegere zowel als de en Israël. 12In het negen en dertigste jaar van zijn regering kreeg Asa een voetkwaal van ernstige aard; doch zelfs in zijn ziekte zocht hij geen hulp bij Jahweh, maar bij geneesheren. 13Asa ging bij zijn vaderen te ruste: hij stierf in het een en veertigste jaar van zijn regering. 14Hij werd begraven in het graf dat hij voor zich zelf had uitgehouwen in de Davidstad; men legde hem op een rustbed, dat men geheel had belegd met welriekende kruiden en verschillende soorten specerijen, kunstig gemengd, en ontstak ter ere van hem een buitengewoon groot dodenvuur.