2 Kọrinti 9 – YCB & NVI

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 9:1-15

19.1: 2Kọ 8.4.Nísinsin yìí, nípa ti ìpín fún ni fún àwọn ènìyàn mímọ́, kò tún yẹ mọ́ fún mi láti kọ̀wé sí yin ju bẹ́ẹ̀ lọ. 29.2: Ro 15.26; 2Kọ 8.10.Nítorí mo mọ ìtara láti ṣe ìrànlọ́wọ́ yín, èyí tí mo ti ṣògo fún àwọn ará Makedonia nítorí yín, pé, àwọn ara Akaia ti múra tan níwọ̀n ọdún kan tí ó kọjá ìtara yín sì ti rú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sókè. 39.3: 1Kọ 16.2.Ṣùgbọ́n mo ti rán àwọn arákùnrin, kí ìṣògo wa nítorí yín má ṣe jásí asán ní ti ọ̀ràn yìí; pé gẹ́gẹ́ bí mó ti wí, kí ẹ̀yin lè múra tẹ́lẹ̀. 4Kí ó má ba à jẹ́ pé, bí àwọn nínú ara Makedonia bá bá mi wá, tí wọ́n sì bá yín ní àìmúra sílẹ̀, ojú a sì tì wá kì í ṣe ẹ̀yin, ní ti ìgbẹ́kẹ̀lé yìí. 5Nítorí náà ni mo ṣe rò pé ó yẹ láti gba àwọn arákùnrin níyànjú, kí wọn kọ́kọ́ tọ̀ yín wá, kí ẹ sì múra ẹ̀bùn yín, tí ẹ ti ṣe ìlérí tẹ́lẹ̀ sílẹ̀, kí ó lè ti wà ní lẹ́bi ẹ̀bùn gidi, kí ó má sì ṣe dàbí ohun ti a fi ìkùnsínú ṣe.

Ìfúnrúgbìn tọkàntọkàn

6Ṣùgbọ́n èyí ni mo wí pé, ẹni tí ó bá fúnrúgbìn kín ún, kín ún ni yóò ká; ẹni tí ó bá sì fúnrúgbìn púpọ̀, púpọ̀ ni yóò ká. 79.7: Òw 22.8.Kí olúkúlùkù ènìyàn ṣe gẹ́gẹ́ bí ó ti pinnu ní ọkàn rẹ̀; kì í ṣe àfi ìkùnsínú ṣe, tàbí ti àìgbọdọ̀ má ṣe; nítorí Ọlọ́run fẹ́ onínúdídùn ọlọ́rẹ. 89.8: Ef 3.20.Ọlọ́run sì lè mú kí gbogbo oore-ọ̀fẹ́ máa bí sí i fún yín; kí ẹ̀yin tí ó ní ànító ohun gbogbo, nígbà gbogbo, lè máa pọ̀ sí i ní iṣẹ́ rere gbogbo. 99.9: Sm 112.9.Gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ ọ pé:

“Ó tí fọ́nká; ó ti fi fún àwọn tálákà,

òdodo rẹ̀ dúró láéláé.”

109.10: Isa 55.10; Ho 10.12.Ǹjẹ́ ẹni tí ń fi irúgbìn fún afúnrúgbìn, àti àkàrà fún oúnjẹ, yóò fi irúgbìn fún un yín, yóò sì sọ ọ́ di púpọ̀, yóò sì mú èso òdodo yín bí sí i. 11Bẹ́ẹ̀ ni a ó sọ yín di ọlọ́rọ̀ nínú ohun gbogbo, fún ìlawọ́ yín gbogbo tí ń ṣiṣẹ́ ọpẹ́ sí Ọlọ́run nípa wa.

12Nítorí iṣẹ́ ìránṣẹ́ ìsìn yìí kò kún ìwọ̀n àìní àwọn ènìyàn mímọ́ nìkan, ṣùgbọ́n ó túbọ̀ pọ̀ sí i nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọpẹ́ sí Ọlọ́run. 139.13: 2Kọ 8.4; Ro 15.31.Nítorí ìdúró yin lábẹ́ ìdánwò iṣẹ́ ìsìn yìí, wọn yóò yin Ọlọ́run lógo fún ìgbọ́ràn yín ní gbígba ìyìnrere Kristi àti nípa ìlawọ́ ìdáwó yín fún wọn àti fún gbogbo ènìyàn. 14Àti nínú àdúrà fún un yín, ọkàn wọn ń ṣe àfẹ́rí yín nítorí ọ̀pọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run ti ń bẹ nínú yín. 159.15: Ro 5.15-16.Ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run nítorí aláìlèfẹnusọ ẹ̀bùn rẹ̀!

Nueva Versión Internacional

2 Corintios 9:1-15

1No hace falta que les escriba acerca de esta ayuda para los creyentes, 2porque sé que tienen buenos deseos de ayudar. Esto lo he comentado con orgullo entre los macedonios. Les he dicho que, desde el año pasado, ustedes los de Acaya estaban preparados para dar. El entusiasmo de ustedes ha motivado a la mayoría de ellos. 3Sin embargo, les envío a estos dos hermanos en la fe para que todos vean por qué estamos orgullosos de ustedes. Así estarán preparados, como ya he dicho que lo estarán. 4De este modo, si algunos macedonios van conmigo a verlos, no los encontrarán desprevenidos. Pues, si así fuera, sentiríamos gran vergüenza de haber confiado tanto en ustedes. Creo que para ustedes también sería una vergüenza. 5Así que me pareció necesario pedirles a estos hermanos que se adelantaran a visitarlos. Ellos les ayudarán con los preparativos que faltan para recolectar esa generosa ofrenda que ustedes habían prometido. Eso hará que su ofrenda se vea como un acto de generosidad, y nadie dirá que son tacaños.

Dar con generosidad

6Recuerden esto: El que siembra poco, poco cosechará, y el que siembra mucho, mucho cosechará. 7Cada uno debe dar según lo que haya decidido en su corazón, no de mala gana ni por obligación. Dios ama al que da con alegría. 8Y Dios puede hacer que reciban muchísimas cosas, de modo que siempre, en toda circunstancia, tengan todo lo necesario. De esa manera tendrán para ayudar en gran manera a los demás. 9Como dicen las Escrituras:

«Repartió sus bienes entre los pobres;

sus actos de justicia permanecen para siempre».

10Dios, que le da semilla al que siembra, también le dará pan para que coma. Él aumentará los cultivos y hará que ustedes tengan mucho más para dar. 11Ustedes serán ricos en todo sentido, para que en toda ocasión puedan ser generosos. Nosotros llevaremos esa ayuda a los necesitados, y su gran generosidad hará que muchos den gracias a Dios.

12Esta manera de servir a los demás no solo suple las necesidades de los creyentes, también hace que ellos den muchísimas gracias a Dios. 13En efecto, al recibir esta demostración de servicio, ellos alabarán a Dios. Pues, luego de aceptar la buena noticia de Cristo, ustedes han demostrado obediencia al dar de manera generosa para ellos y para todos. 14Además, cuando ellos oren por ustedes, lo harán con mucho cariño. Lo harán porque han visto el enorme amor inmerecido que Dios tiene por ustedes. 15¡Gracias a Dios por ese amor! ¡No hay palabras para describirlo!