2 Kọrinti 6 – YCB & NVI-PT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 6:1-18

1Gẹ́gẹ́ bí alábáṣiṣẹ́pọ̀ nínú Ọlọ́run, ǹjẹ́, àwa ń rọ̀ yín kí ẹ má ṣe gba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lásán. 26.2: Isa 49.8.Nítorí o wí pé,

“Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà mi, èmi tí gbọ́ ohùn rẹ,

àti ọjọ́ ìgbàlà, èmi sì ti ràn ọ́ lọ́wọ́.”

Èmi wí fún ọ, nísinsin yìí ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, nísinsin yìí ni ọjọ́ ìgbàlà.

Àwọn wàhálà Paulu

3Àwa kò sì gbé ohun ìkọ̀sẹ̀ kankan si ọ̀nà ẹnikẹ́ni, ki iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa má ṣe di ìsọ̀rọ̀-òdì sí. 46.4: 2Kọ 4.8-11; 11.23-27.Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ni ọnà gbogbo, àwa ń fi ara wa hàn bí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ sùúrù, nínú ìpọ́njú, nínú àìní, nínú wàhálà, 56.5: Ap 16.23.nípa nínà, nínú túbú, nínú ìrúkèrúdò, nínú iṣẹ́ àṣekára, nínú àìsàn, nínú ìgbààwẹ̀. 6Nínú ìwà mímọ́, nínú ìmọ̀, nínú ìpamọ́ra, nínú ìṣeun, nínú Ẹ̀mí Mímọ́, nínú ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn. 76.7: 2Kọ 10.4; Ro 13.12; Ef 6.11-12.Nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́, nínú agbára Ọlọ́run, nínú ìhámọ́ra òdodo ní apá ọ̀tún àti ní apá òsì. 8Nípa ọlá àti ẹ̀gàn, nípa ìyìn búburú àti ìyìnrere: bí ẹlẹ́tàn, ṣùgbọ́n a jásí olóòtítọ́, 96.9: Ro 8.36.bí ẹni tí a kò mọ̀, ṣùgbọ́n a mọ̀ wá dájúdájú; bí ẹni tí ń kú lọ, ṣùgbọ́n a ṣì wà láààyè; bí ẹni tí a nà, ṣùgbọ́n a kò sì pa wá, 106.10: Ro 8.32; 1Kọ 3.21.bí ẹni tí ó kún fún ìbànújẹ́, ṣùgbọ́n àwa ń yọ̀ nígbà gbogbo; bí tálákà, ṣùgbọ́n àwa ń sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ dí ọlọ́rọ̀; bí ẹni tí kò ní nǹkan, ṣùgbọ́n àwa ni ohun gbogbo.

116.11: El 33.22; Isa 60.5.Ẹ̀yin ará Kọrinti, a ti bá yín sọ òtítọ́ ọ̀rọ̀, a ṣí ọkàn wa páyà sí yín. 12Àwa kò fa ìfẹ́ wa sẹ́yìn fún yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin fa ìfẹ́ yín sẹ́yìn kúrò lọ́dọ̀ wa. 13Ní sísán padà, ní ọ̀nà tí ó dára, èmi ń sọ bí ẹni pé fún àwọn ọmọdé, ẹ̀yin náà ẹ ṣí ọkàn yín páyà pẹ̀lú.

Má ṣe dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́

14Ẹ má ṣe fi àìdọ́gba dàpọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́, nítorí ìdàpọ̀ kín ni òdodo ní pẹ̀lú àìṣòdodo? Ìdàpọ̀ kín ni ìmọ́lẹ̀ sì ní pẹ̀lú òkùnkùn? 15Ìrẹ́pọ̀ kín ni Kristi ní pẹ̀lú Beliali? Tàbí ìpín wó ni ẹni tí ó gbàgbọ́ ní pẹ̀lú aláìgbàgbọ́? 166.16: 1Kọ 10.21; 3.16; Ek 25.8; 29.45; Le 26.12; El 37.27; Jr 31.1.Ìrẹ́pọ̀ kín ni tẹmpili Ọlọ́run ní pẹ̀lú òrìṣà? Nítorí ẹ̀yin ní tẹmpili Ọlọ́run alààyè; gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti wí pé:

“Èmi á gbé inú wọn,

èmi o sì máa rìn láàrín wọn,

èmi ó sì jẹ́ Ọlọ́run wọn,

wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.”

176.17: Isa 52.11.Nítorí náà,

“Ẹ jáde kúrò láàrín wọn,

kí ẹ sì yá ara yín si ọ̀tọ̀,

ni Olúwa wí.

Ki ẹ má ṣe fi ọwọ́ kan ohun àìmọ́;

Èmi ó sì gbà yín.”

18Àti,

6.18: Ho 1.10; Isa 43.6.“Èmi o sì jẹ́ Baba fún yín.

Ẹ̀yin ó sì jẹ́ ọmọkùnrin mi àti ọmọbìnrin mi,

ní Olúwa Olódùmarè wí.”

Nova Versão Internacional

2 Coríntios 6:1-18

1Como cooperadores de Deus, insistimos com vocês para não receberem em vão a graça de Deus. 2Pois ele diz:

“Eu o ouvi no tempo favorável

e o socorri no dia da salvação”6.2 Is 49.8.

Digo que agora é o tempo favorável, agora é o dia da salvação!

Os Sofrimentos de Paulo

3Não damos motivo de escândalo a ninguém, em circunstância alguma, para que o nosso ministério não caia em descrédito. 4Ao contrário, como servos de Deus, recomendamo-nos de todas as formas: em muita perseverança; em sofrimentos, privações e tristezas; 5em açoites, prisões e tumultos; em trabalhos árduos, noites sem dormir e jejuns; 6em pureza, conhecimento, paciência e bondade; no Espírito Santo e no amor sincero; 7na palavra da verdade e no poder de Deus; com as armas da justiça, quer de ataque quer de defesa6.7 Grego: à direita e à esquerda.; 8por honra e por desonra; por difamação e por boa fama; tidos por enganadores, sendo verdadeiros; 9como desconhecidos, apesar de bem conhecidos; como se estivéssemos morrendo, mas eis que vivemos; espancados, mas não mortos; 10entristecidos, mas sempre alegres; pobres, mas enriquecendo muitos outros; nada tendo, mas possuindo tudo.

11Falamos abertamente a vocês, coríntios, e abrimos todo o nosso coração! 12Não estamos limitando nosso afeto, mas vocês estão limitando o afeto que têm por nós. 13Numa justa compensação, falo como a meus filhos, abram também o coração para nós!

O Problema da Associação com os Descrentes

14Não se ponham em jugo desigual com descrentes. Pois o que têm em comum a justiça e a maldade? Ou que comunhão pode ter a luz com as trevas? 15Que harmonia entre Cristo e Belial? Que há de comum entre o crente e o descrente? 16Que acordo há entre o templo de Deus e os ídolos? Pois somos santuário do Deus vivo. Como disse Deus:

“Habitarei com eles

e entre eles andarei;

serei o seu Deus,

e eles serão o meu povo”6.16 Lv 26.12; Jr 32.38; Ez 37.27.

17Portanto,

“saiam do meio deles e separem-se”,

diz o Senhor.

“Não toquem em coisas impuras,

e eu os receberei”6.17 Is 52.11; Ez 20.34,41

18e

“serei o seu Pai,

e vocês serão meus filhos e minhas filhas”,

diz o Senhor todo-poderoso6.18 2Sm 7.8,14.