2 Kọrinti 2 – YCB & CARSA

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 2:1-17

1Nítorí náà mo tí pinnu nínú ara mí pé, èmi kì yóò tún fi ìbànújẹ́ tọ̀ yin wá. 2Nítorí pé bí èmi bá mú inú yín bàjẹ́, ǹjẹ́ ta ni ẹni ti ìbá mú inú mí dùn ní àkókò tí inú mi bá bàjẹ́ bí kò ṣe ẹni tí mo ti ba nínú jẹ́? 3Èmi sì kọ̀wé bí mo tí kọ sí yín pé, nígbà tí mo bá sì de, kí èmi má ṣe ni ìbànújẹ́ lọ́dọ̀ àwọn ti ìbá mú mi ní ayọ̀, nítorí tí mo ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú gbogbo yín, wí pé ẹ̀yin yóò jẹ́ alábápín ayọ̀ mi. 4Nítorí pé nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wàhálà àti ìrora ọkàn mí ni mo ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ omijé kọ̀wé sí yín; kì í ṣe nítorí kí a lè bà yín nínú jẹ́, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin bá a lè mọ bí ìfẹ́ tí mo ní sí yín ṣe jinlẹ̀ tó.

Ìdáríjì fún ẹlẹ́ṣẹ̀

5Bí ẹnikẹ́ni bá fa ohun ìbànújẹ́ kì í ṣe èmi ni ó bà nínú jẹ́, bí kò ṣe ẹ̀yin fúnra yín, níwọ̀n ìyówù kí ó jẹ́; n kò fẹ́ sọ ọ́ lọ́nà líle jù. 6Ìyà náà tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti fi jẹ́ irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ tó fún un. 7Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin ìbá kúkú dáríjì í, kí ẹ sí tù ú nínú ní gbogbo ọ̀nà, kí ìbànújẹ́ má bà á bo irú ènìyàn bẹ́ẹ̀ mọ́lẹ̀. 8Nítorí náà mo bẹ̀ yín, ẹ fi ìdánilójú ìfẹ́ yín hàn sí irú ẹni náà. 9Ìdí tí mo ṣe kọ̀wé ni kí èmi ba à lè rí ẹ̀rí dìímú nípa ìgbọ́ràn yín nínú ohun gbogbo. 10Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá dáríjì ẹnikẹ́ni, èmi pẹ̀lú dáríjì í. Ohun tí èmi pẹ̀lú bá fi jì, nítorí tiyín ní mo fi jì níwájú Kristi. 11Kí Satani má ba à rẹ́ wa jẹ. Nítorí àwa kò ṣe aláìmọ́ àrékérekè rẹ̀.

Ìránṣẹ́ májẹ̀mú tuntun

122.12: Ap 16.8.Ṣùgbọ́n nígbà ti mo dé Troasi láti wàásù ìyìnrere Kristi, tí mo sì rí i wí pé Olúwa ti ṣí ìlẹ̀kùn fún mi, 13síbẹ̀ èmi kò ní àlàáfíà lọ́kàn mi, nítorí tí èmi kò rí Titu arákùnrin mi níbẹ̀. Nítorí ìdí èyí ni mo ṣe dágbére fún wọn, mo si rékọjá lọ sí Makedonia.

14Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run, ẹni tí ń yọ ayọ̀ ìṣẹ́gun lórí wá nígbà gbogbo nínú Kristi, tí a sì ń fi òórùn dídùn ìmọ̀ rẹ̀ hàn nípa wa níbi gbogbo. 15Nítorí òórùn dídùn Kristi ni àwa jẹ́ fún Ọlọ́run, nínú àwọn tí a ń gbàlà àti nínú àwọn tí ó ń ṣègbé. 16Fún àwọn kan, àwa jẹ́ òórùn sí ikú, àti fún àwọn mìíràn òórùn ìyè sí ìyè. Ta ni ó ha si tọ́ fún nǹkan wọ̀nyí? 17Nítorí àwa kò dàbí àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí ń fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣòwò jẹun; ṣùgbọ́n nínú òtítọ́ inú àwa ń sọ̀rọ̀ níwájú Ọlọ́run nínú Kristi gẹ́gẹ́ bí àwọn tí a rán láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.

Священное Писание (Восточный перевод), версия с «Аллахом»

2 Коринфянам 2:1-17

1Поэтому я решил больше не приходить к вам только для того, чтобы вас огорчать. 2Если я буду вас огорчать, то кто же сможет тогда порадовать меня? Кто, как не вы, которых я огорчаю? 3Я написал вам то послание2:3 Хотя некоторые верят, что здесь говорится о «Первом послании Паула верующим в Коринфе», большинство толкователей считает, что речь идёт о каком-то другом послании, которое было утрачено и до нас не дошло. для того, чтобы, придя к вам, не оказаться огорчённым теми, о ком я хотел бы радоваться, и я уверен, что моя радость – это наша общая радость. 4Мне очень нелегко было писать вам так; я писал со слезами и с болью в сердце. Но моей целью было не огорчить вас, а дать вам знать, как сильно я вас люблю.

Прощение грешника

5Тот, кто доставил мне печаль, огорчил не только меня, а отчасти, чтобы не сказать больше, и всех вас. 6Для этого человека достаточно того наказания, которое он уже получил от большинства из вас. 7А теперь простите его и успокойте, чтобы ему не быть подавленным невыносимой печалью. 8Умоляю вас, подтвердите свою любовь к нему.

9Я писал вам также для того, чтобы проверить вас, будете ли вы послушны во всём. 10А кого вы прощаете, того и я прощаю. А кого я прощаю, если ему действительно есть что прощать, того я прощаю ради вас перед аль-Масихом, 11чтобы Шайтан не смог нас перехитрить, а намерения Шайтана мы прекрасно знаем.

Переживания в Троаде

12Когда я пришёл в Троаду возвещать Радостную Весть об аль-Масихе, то Повелитель открыл мне дверь для служения. 13Но я не мог успокоиться, потому что не нашёл там моего брата по вере Тита. Поэтому я попрощался с верующими из Троады и отправился в Македонию2:13 Паул планировал встретиться в Троаде с Титом, который должен был прийти туда из Коринфа (см. 8:6). Но не дождавшись его, Паул пошёл ему навстречу..

Победа через аль-Масиха

14Я благодарен Аллаху, Который всегда ведёт нас, находящихся в единении с аль-Масихом, в Своей триумфальной процессии и повсюду распространяет через нас благоухание познания о Нём. 15Потому что мы для Аллаха благовоние, возжигаемое аль-Масихом, среди тех, кто принимает спасение2:15 Спасение – от пламени ада (см. Иуда 1:23), от гнева Аллаха и Его судов (см. Рим. 5:9), от суетной жизни (см. 1 Пет. 1:18), от греха (см. Мат. 1:21) и от Иблиса (см. 2 Тим. 2:26)., и тех, кто идёт к погибели. 16Для одних мы – запах смертоносный, для других – живительное благоухание. И кто способен на такое служение?! 17При этом мы не торгуем вразнос словом Аллаха, как это делают многие. Будучи в единении с аль-Масихом, мы говорим искренне перед Аллахом как люди, посланные Аллахом.