2 Kọrinti 11 – YCB & CCB

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Kọrinti 11:1-33

Paulu àti àwọn aposteli ẹlẹ́kọ̀ọ́ èké

111.1: 2Kọ 11.21.Mo rò wí pé ẹ ó faradà díẹ̀ nínú ìwà òmùgọ̀ mi ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ ni, mo fẹ́ kí ẹ gbà mí láàyè. 211.2: Ho 2.19-20; Ef 5.26-27.Nítorí pé èmi ń jowú lórí i yín bí ẹni ìwà-bí-Ọlọ́run, nítorí tí mo ti fì yín fún ọkọ kan, kí èmi bà á lè mú yín wá bí wúńdíá tí ó mọ́ sọ́dọ̀ Kristi. 311.3: Gẹ 3.4.Ṣùgbọ́n ẹ̀rù ń bà mí, kí ó má bà á jẹ́ pé, bí ejò ti tan Efa jẹ́ nípasẹ̀ àrékérekè rẹ̀, a lè mú ọkàn yín ṣáko lọ kúrò nínú òtítọ́ yín àti ìfarajì fún Kristi. 411.4: Ga 1.6.Nítorí bí ẹnìkan bá wá tí ó sì wàásù Jesu mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí a ti wàásù rí tàbí bí ẹ̀yin bá gba ẹ̀mí mìíràn, yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà tàbí ìyìnrere mìíràn yàtọ̀ sí èyí tí ẹ ti gbà, tí ẹ sì ti yára tẹ́wọ́ gbà á.

511.5: 2Kọ 12.11; Ga 2.6.Nítorí mo rò pé èmi kò rẹ̀yìn nínú ohunkóhun sí àwọn àgbà Aposteli. 611.6: 1Kọ 1.17.Bí mo tilẹ̀ jẹ́ òpè nínú ọ̀rọ̀ sísọ, kì í ṣe nínú ìmọ̀; ní ọ̀nàkọnà ni àwa ti fi èyí hàn dájúdájú fún yín nínú ohun gbogbo. 711.7: 2Kọ 12.13; 1Kọ 9.18.Tàbí ẹ̀ṣẹ̀ ni mo dá bí èmi ti ń rẹ ara mí sílẹ̀ kí a lè gbé yín ga, nítorí tí mo wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín lọ́fẹ̀ẹ́. 811.8: Fp 4.15,18.Èmí ń ja ìjọ mìíràn ni olè nípa gbígba ìpèsè owó ki èmi bà á lè sìn yín. 9Nígbà tí mo sì wà pẹ̀lú yín, tí mo sì ṣe aláìní, èmi kò dẹ́rù pa ẹnikẹ́ni, nítorí ohun tí mo ṣe aláìní ni àwọn ará tí ó ti Makedonia wá ti mú wá. Bẹ́ẹ̀ ni nínú ohun gbogbo mo pa ara mi mọ́ láti má ṣe jẹ́ ẹrù fún yín, èmi yóò sì pa ara mi mọ́ bẹ́ẹ̀. 1011.10: 1Kọ 9.15.Ó jẹ́ òtítọ́, Kristi tí ń bẹ nínú mi pé kò sí ẹni tí ó lè dá mi lẹ́kun ìṣògo yìí ni gbogbo ẹkùn Akaia. 1111.11: 2Kọ 12.15.Nítorí kín ni? Nítorí èmi kò fẹ́ràn yín ni bí? Ọlọ́run mọ̀.

1211.12: 1Kọ 9.12.Èmi yóò tẹ̀síwájú láti máa ṣe ohun ti èmi ń ṣe láti le mú ìjákulẹ̀ bá àwọn tí wọn ń wá ọ̀nà láti bá wa dọ́gba nínú èyí ti àwa ń ṣògo lé lórí. 13Nítorí irú àwọn ènìyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn èké Aposteli àwọn ẹni ti ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn, tí ń pa wọ́n dà di aposteli Kristi. 14Kì í sì í ṣe ohun ìyanu; nítorí Satani, tìkára rẹ̀ ń pa ara rẹ̀ dàbí angẹli ìmọ́lẹ̀. 15Nítorí náà kì í ṣe ohun ńlá bí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pẹ̀lú bá pa ara wọn dàbí àwọn ìránṣẹ́ òdodo; ìgbẹ̀yìn àwọn ẹni tí yóò rí gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.

Paulu ṣògo nínú ìjìyà rẹ̀

16Mo sì tún wí pé, kí ẹnikẹ́ni má ṣe rò pé òmùgọ̀ ni mí; ṣùgbọ́n bí bẹ́ẹ̀ bá ni, ẹ gbà mí bí òmùgọ̀ kí èmi lè gbé ara mi ga díẹ̀. 1711.17: 1Kọ 7.12,25.Ohun tí èmi ń sọ, èmi kò sọ ọ́ nípa ti Olúwa, ṣùgbọ́n bí òmùgọ̀ nínú ìgbẹ́kẹ̀lé ìṣògo yìí. 18Ọ̀pọ̀lọpọ̀, ni ó ń ṣògo nípa ti ara, èmi ó ṣògo pẹ̀lú. 1911.19: 1Kọ 4.10.Nítorí ẹ̀yin fi inú dídùn gba àwọn òmùgọ̀ nígbà tí ẹ̀yin tìkára yín jẹ́ ọlọ́gbọ́n. 20Nítorí ẹ̀yin faradà á bí ẹnìkan bá sọ yín dí òǹdè, bí ẹnìkan bá jẹ́ yín run, bí ẹnìkan bá gbà lọ́wọ́ yín, bí ẹnìkan bá gbé ara rẹ̀ ga, bí ẹnìkan bá gbá yín lójú. 21Èmi ń wí lọ́nà ẹ̀gàn, bí ẹni pé àwa jẹ́ aláìlera!

Ṣùgbọ́n nínú ohunkóhun tí ẹnìkan ti ní ìgboyà, èmi ń sọ̀rọ̀ bí òmùgọ̀, èmi ní ìgboyà pẹ̀lú. 22Heberu ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Israẹli ni wọ́n bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. Irú-ọmọ Abrahamu ní òun bí? Bẹ́ẹ̀ ni èmi. 2311.23: Ap 16.23; 2Kọ 6.5.Ìránṣẹ́ Kristi ni wọ́n bí? Èmi ń sọ bí òmùgọ̀, mo ta wọ́n yọ; ní ti làálàá lọ́pọ̀lọ́pọ̀, ní ti pàṣán, mo rékọjá, ní ti túbú nígbàkígbà, ní ti fífẹ́rẹ kú nígbà púpọ̀. 2411.24: De 25.3.Nígbà márùn-ún ni mo gba pàṣán ogójì dín ẹyọ kan lọ́wọ́ àwọn Júù. 2511.25: Ap 16.22; 14.19.Nígbà mẹ́ta ni a fi ọ̀gọ̀ lù mí, ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ni a sọ mí ní òkúta, ẹ̀ẹ̀mẹta ni ọkọ̀ ojú omi mi rì, ọ̀sán kan àti òru kan ni mo wà nínú ibú. 2611.26: Ap 9.23; 14.5.Ní ìrìnàjò nígbàkígbà, nínú ewu omi, nínú ewu àwọn ọlọ́ṣà, nínú ewu àwọn ará ìlú mi, nínú ewu àwọn aláìkọlà, nínú ewu ni ìlú, nínú ewu ní aginjù, nínú ewu lójú Òkun, nínú ewu láàrín àwọn èké arákùnrin. 2711.27: 1Kọ 4.11.Nínú làálàá àti ìrora, nínú ìṣọ́ òru nígbàkígbà, nínú ebi àti òǹgbẹ, nínú àwẹ̀ nígbàkígbà, nínú òtútù àti ìhòhò. 28Pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí tí ó jẹ́ tí òde, ọ̀pọ̀ ni èyí tí ń wọn n dúró tì mí lójoojúmọ́, àní àníyàn fún gbogbo ìjọ. 2911.29: 1Kọ 9.22.Ta ni ó ṣe àìlera, tí èmi kò ṣe àìlera? Tàbí a mú kọsẹ̀, tí ara mi kò gbiná?

30Bí èmi yóò bá ṣògo, èmi ó kúkú máa ṣògo nípa àwọn nǹkan tí ó jẹ́ ti àìlera mi. 31Ọlọ́run àti Baba Olúwa wá Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́ olùbùkún jùlọ láéláé mọ̀ pé èmi kò ṣèké. 3211.32-33: Ap 9.24-25.Ní Damasku, baálẹ̀ tí ó wà lábẹ́ ọba Areta fi ẹgbẹ́ ogun ká ìlú àwọn ará Damasku mọ́, ó ń fẹ́ láti mú mi bí arúfin. 33Láti ojú fèrèsé nínú agbọ̀n ni a sì ti sọ̀ mí kalẹ̀ lẹ́yìn odi, tí mo sì bọ́ lọ́wọ́ rẹ̀.

Chinese Contemporary Bible (Simplified)

哥林多后书 11:1-33

保罗与假使徒

1请你们多包涵,听我说几句愚妄话吧!我知道你们一定会包容我。 2我要求你们忠贞不渝,正如上帝要求祂的子民忠贞不渝一样。因为我曾把你们当作贞洁的少女许配给一位丈夫——基督。 3但我真怕你们会像被狡猾的蛇欺骗的夏娃一样,思想受迷惑,失去了对基督纯真专一的心。 4有人来传另一位耶稣——与我们所传的不同,或要你们接受另一个灵——与你们所接受的不同,或要你们相信另一种福音——与你们所相信的不同,你们竟欣然容忍。 5我想,我一点也不比那些“超级使徒”差。 6我虽然不善辞令,但我认识真理。这一点,我在各样的事上已经向你们证明了。

7我为了把福音白白地传给你们,甘愿卑微,以擢升你们,我这样做有罪吗? 8我“抢夺”其他教会,拿了他们的资助,来服侍你们。 9我在你们那里经济拮据的时候,没有拖累过你们任何人,因为马其顿来的弟兄姊妹补足了我的缺乏。我没有在任何方面成为你们的负担,将来也不会成为你们的负担。 10我凭我心中基督的真理说,亚该亚地区无人会阻止我这样夸口。 11为什么呢?难道我不爱你们吗?上帝知道我爱你们!

12我现在所做的,将来还会继续做下去,为了要断绝那些投机分子的机会,使他们无法吹嘘自己的职分与我们一样。 13其实这些人是假使徒,为人诡诈,冒充基督的使徒。 14这不足为奇,因为连撒旦都装成光明的天使, 15它的爪牙若冒充公义的仆人,又何足为奇呢?他们最终必得到应得的报应。

保罗的诸多苦难

16我再说,谁也别把我当作傻瓜。如果你们真的当我是傻瓜,就把我当傻瓜看待吧!好让我也能说几句自夸的话。 17我这样说,并不是主的意思,而是像一个傻瓜一样夸口。 18既然许多人凭血气夸口,我当然也可以夸口。 19因为你们这些聪明人竟然甘愿忍受那些傻瓜, 20就算有人奴役、剥削、利用、侮辱你们,打你们耳光,你们都能逆来顺受! 21惭愧得很,我必须说,我们太软弱了,做不出那样的事!

然而,别人敢夸口的,让我再讲一句傻话,我也敢。 22他们是希伯来人,我也是。他们是以色列人,我也是。他们是亚伯拉罕的子孙,我也是。 23他们自称是基督的仆人,我说句狂话,我更是!我比他们更辛苦,坐牢更多,身受更重的鞭打,经常出生入死。 24我被犹太同胞鞭打了五次,每次三十九鞭11:24 三十九鞭”希腊文是“四十鞭减一鞭”。25罗马人用棍打了三次,被人用石头打了一次,遇到船难三次,曾在大海上漂浮了一天一夜。 26我常常四处奔波,遭遇江河的危险、盗贼的威胁、同胞的威胁、外族的威胁,城中的危险,旷野的危险,海上的危险和假信徒的威胁。 27我劳碌困苦,不得安眠,又饥又渴,挨饿受冻,赤身露体。 28此外,我还挂虑众教会的事,天天承受着压力。 29有谁软弱,我不感同身受呢?有谁失足犯罪,我不心急如焚呢?

30如果一定要夸耀,我情愿夸耀自己的软弱。 31主耶稣的父——永受称颂的上帝知道我不撒谎。 32大马士革的时候,亚哩达王手下的总督吩咐人把守城门,要逮捕我。 33我只好藏在筐子里,被人从城墙上的窗户缒下去,才逃出了他的魔掌。