Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Johanu 1:1-13

11: 3Jh 1.Alàgbà,

Sì àyànfẹ́ obìnrin ọlọ́lá àti àwọn ọmọ rẹ̀, àwọn tí mo fẹ́ ní òtítọ́, kì í sì í ṣe èmi nìkan, ṣùgbọ́n gbogbo àwọn tí ó mọ òtítọ́ pẹ̀lú; 2nítorí òtítọ́ tí ń gbé inú wa, yóò sì bá wa gbé títí.

3Oore-ọ̀fẹ́, àánú, àti àlàáfíà, láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba, àti láti ọ̀dọ̀ Jesu Kristi, Ọmọ Baba, yóò wà pẹ̀lú wa nínú òtítọ́ àti nínú ìfẹ́.

4Mo yọ̀ gidigidi pé mo rí nínú àwọn ọmọ rẹ tí ń rìn nínú òtítọ́, gẹ́gẹ́ bí Baba ti pa àṣẹ fún wa. 55: Jh 13.34.Ǹjẹ́ nísinsin yìí, mo bẹ̀ ọ́, obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe bí ẹni pé èmi ń kọ̀wé òfin tuntun kan sí ọ, bí kò ṣe èyí ti àwa tí ní ní àtètèkọ́ṣe, pé kí àwa fẹ́ràn ara wa. 66: 1Jh 5.3.Èyí sì ni ìfẹ́, pé, kí àwa máa rin nípa òfin rẹ̀, èyí ni òfin náà, àní bí ẹ ti gbọ́ ni àtètèkọ́ṣe, pé, kí ẹ̀yin rìn nínú rẹ̀.

77: 1Jh 2.22.Nítorí ẹlẹ́tàn púpọ̀ ti jáde wa sínú ayé, àwọn tí kò jẹ́wọ́ pé Jesu Kristi wá nínú ara. Èyí ni ẹlẹ́tàn àti aṣòdì sí Kristi. 8Ẹ kíyèsára yín, kí ẹ má ba à sọ iṣẹ́ tí ẹ tí ṣe nù, ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin lè rí èrè kíkún gbà. 9Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń rú òfin tí kò si dúró nínú ẹ̀kọ́ Kristi, kò mọ Ọlọ́run. Ẹni tí ó bá dúró nínú ẹ̀kọ́, òun ni ó mọ Baba àti Ọmọ. 10Bí ẹnikẹ́ni bá tọ̀ yín wá, tí kò sì mu ẹ̀kọ́ yìí wá, ẹ má ṣe gbà á sí ilé, kí ẹ má sì ṣe kí i kú ààbọ̀. 11Nítorí ẹni tí ó bá kí kú ààbọ̀, ó ní ọwọ́ nínú iṣẹ́ búburú rẹ̀.

1212: 1Jh 1.4; 3Jh 13.Bí mo tilẹ̀ ní ohun púpọ̀ láti ṣe alábápín pẹ̀lú yín, síbẹ̀ èmi kò fẹ́ lo ìwé ìkọ̀wé àti jẹ́lú ìkọ̀wé. Ṣùgbọ́n èmi ní ìrètí láti tọ̀ yín wá àti láti bá a yín sọ̀rọ̀ lójúkojú, kí ayọ̀ yín bá à le è kún.

13Àwọn ọmọ arábìnrin rẹ àyànfẹ́ kí ọ.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

約翰二書 1:1-13

1我這作長老的寫信給蒙揀選的女士1·1 學者一般認為「蒙揀選的女士」是指教會。和你的兒女,就是我本著真理所愛的。你們不單是我所愛的,也是一切認識真理的人所愛的。 2我們愛你們,因為真理在我們裡面,並且永遠與我們同在。

3從父上帝和祂兒子耶穌基督而來的恩典、憐憫和平安也必在真理和愛中與我們同在!

彼此相愛

4你的兒女當中有人按照我們從父領受的命令遵行真理,我知道後非常欣慰。 5女士啊,我現在勸你,我們大家要彼此相愛。這不是新命令,而是我們從起初就已經領受的命令。 6愛就是遵行上帝的命令,這是你們從起初就聽過又當遵行的命令。

提防騙子

7因為現在世上有許多騙子出來迷惑人,他們否認耶穌基督曾降世為人。這樣的人是騙子,是敵基督者。 8你們要謹慎,好得到完滿的賞賜,免得我們前功盡棄。 9誰偏離基督的教導,誰心中就沒有上帝;誰遵守基督的教導,誰就有父和子與他同在。 10若有人到你們那裡不傳基督的教導,不要請他到家裡,也不要問候他, 11因為問候他就是與他同流合污。

結語

12我還有許多事要告訴你們,但不想藉助紙墨,而是希望有機會到你們那裡與你們當面暢談,使我們充滿喜樂。

13你那蒙揀選之姊妹的兒女問候你。