2 Ọba 4 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 4:1-44

Òróró obìnrin opó

1Ìyàwó ọkùnrin kan láti ara ẹgbẹ́ wòlíì sọkún tọ Eliṣa wá, “Ìránṣẹ́ rẹ ọkọ mi ti kú, ó sì mọ̀ wí pé ó bu ọlá fún Olúwa. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, onígbèsè rẹ̀ ti ń bọ̀ láti wá kó ọmọ ọkùnrin mi gẹ́gẹ́ bí ẹrú rẹ̀.”

2Eliṣa dá a lóhùn pé, “Báwo ni èmi ṣe lè ràn ọ́ lọ́wọ́? Sọ fún mi; kí ni ìwọ ní ní ilé rẹ?”

Ó wí pé, “Ìránṣẹ́ rẹ kò ní ohunkóhun níbẹ̀ rárá, àyàfi òróró kékeré.”

3Eliṣa wí pé, “Lọ yíká kí o sì béèrè lọ́wọ́ gbogbo àwọn aládùúgbò fún ìkòkò òfìfo. Má ṣe béèrè fún kékeré. 4Nígbà náà, lọ sí inú ilé kí o sì pa lẹ́kun dé ní ẹ̀gbẹ́ ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin, dà òróró sínú gbogbo ìkòkò, gẹ́gẹ́ bí gbogbo rẹ̀ ti kún, kó o sí apá kan.”

5Ó sì fi sílẹ̀ lẹ́yìn náà ó ti ìlẹ̀kùn ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀. Wọ́n gbé ìkòkò wá fún un ó sì ń dà á. 6Nígbà tí gbogbo ìkòkò náà kún, ó sọ fún ọmọ rẹ̀ pé, “Ẹ gbé òmíràn fún mi wá.”

Ṣùgbọ́n wọ́n dáhùn pé, “Kò sí ìkòkò tí ó kù mọ́.” Nígbà náà ni òróró kò dà mọ́.

7Ó sì lọ ó sì lọ sọ fún àwọn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì wí pé, “Lọ, ta òróró náà kí o sì san gbèsè rẹ. Ìwọ àti ọmọ rẹ kí ẹ máa sinmi lórí èyí tí ó kù.”

Ọmọ arábìnrin kan ará Ṣunemu jí dìde sáyé

8Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu. Obìnrin ọlọ́rọ̀ kan sì wà níbẹ̀, ẹni tí ó rọ̀ ọ́ kí ó dúró jẹun. Bẹ́ẹ̀ ni nígbàkígbà tí ó bá ń kọjá lọ, ó máa ń dúró níbẹ̀ láti jẹun. 9Ó sọ fún ọkọ rẹ̀, “Mo mọ̀ pé ọkùnrin tí ó máa ń sábà wá sí ọ̀dọ̀ wa jẹ́ ọkùnrin mímọ́ Ọlọ́run. 10Jẹ́ kí a ṣe yàrá kékeré kan sórí ilé kí a sì gbé ibùsùn àti tábìlì oúnjẹ, àga kan àti fìtílà fún un. Nígbà náà ó lè dúró níbẹ̀ ní ìgbàkúgbà tí ó bá wá sọ́dọ̀ wa.”

11Ní ọjọ́ kan nígbà tí Eliṣa wá, ó lọ sí orí òkè ní yàrá rẹ̀ ó sì dùbúlẹ̀ síbẹ̀. 12Ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Gehasi pé, “Pe ará Ṣunemu.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é wá, ó sì dúró níwájú rẹ̀. 13Eliṣa wí fún un pé, “Wí fún un, ‘Ìwọ ti lọ ṣe gbogbo àníyàn iṣẹ́ ìyìnrere fún wa. Nísinsin yìí kí ni a lè ṣe fún ọ?’ ”

“Ṣé a lè jẹ́ agbẹnusọ fún ọ ní ọ̀dọ̀ ọba tàbí olórí ogun?”

14“Kí ni a lè ṣe fún obìnrin yìí?” Eliṣa béèrè.

Gehasi wí pé, “Bẹ́ẹ̀ ni, kò ní ọmọ, ọkọ rẹ̀ náà sì tún di arúgbó.”

15Nígbà náà Eliṣa wí pé, “Pè é,” bẹ́ẹ̀ ni ó sì pè é, ó sì dúró ní àbáwọlé ẹnu-ọ̀nà. 16Eliṣa sọ wí pé, “Ìwòyí ọdún tí ń bọ̀, ìwọ yóò fi ọwọ́ rẹ gbé ọmọ.”

“Bẹ́ẹ̀ kọ́, olúwa mi!” n kò fi ara mọ́ ọn. “Jọ̀wọ́, ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, ma ṣe ṣi ìránṣẹ́ rẹ lọ́nà!”

17Ṣùgbọ́n obìnrin náà lóyún ní ọdún kejì ní àkókò náà, ó bí ọmọ ọkùnrin kan, gẹ́gẹ́ bí Eliṣa ti sọ fún un.

18Ọmọ náà dàgbà, ní ọjọ́ kan, ó jáde lọ sí ọ̀dọ̀ baba rẹ̀, ó wà pẹ̀lú àwọn olùkórè. 19“Orí mi! Orí mi!” Ó wí fún baba rẹ̀.

Baba rẹ̀ sọ fún ìránṣẹ́, “Gbé e lọ sọ́dọ̀ ìyá rẹ̀.” 20Lẹ́yìn ìgbà tí ìránṣẹ́ náà ti gbé e sókè tí ó sì gbé e tọ ìyá rẹ̀ lọ, ọmọ ọkùnrin náà jókòó sórí ẹsẹ̀ rẹ̀ títí ó fi di ọ̀sán gangan, nígbà náà ó sì kú. 21Ó lọ sí òkè ó sì tẹ́ ọmọ náà lórí ibùsùn ènìyàn Ọlọ́run, ó sì tìlẹ̀kùn, ó jáde lọ.

22Ó pe ọkọ rẹ̀ ó sì wí pé, “Jọ̀wọ́ rán ọ̀kan lára àwọn ìránṣẹ́ rẹ àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kan kí èmi kí ó lè lọ sí ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run kíákíá kí n sì padà.”

23“Kí ni ó dé tí o fi fẹ́ lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ lónìí?” Ó béèrè. “Kì í ṣe oṣù tuntun tàbí ọjọ́ ìsinmi.”

Ó wí pé, “Gbogbo rẹ̀ ti dára.”

24Ó sì di kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ní gàárì ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Máa nìṣó; má ṣe dẹ́sẹ̀ dúró dè mí àyàfi tí mo bá sọ fún ọ.” 25Bẹ́ẹ̀ ni ó sì jáde wá, ó sì wá sọ́dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè Karmeli.

Nígbà tí ó sì rí i láti òkèrè, ènìyàn Ọlọ́run sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ Gehasi, “Wò ó! Ará Ṣunemu nì! 26Sáré lọ pàdé rẹ̀ kí o sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀, ‘Ṣé o wà dáradára? Ṣé ọkọ rẹ wà dáradára? Ṣé ọmọ rẹ wà dáradára?’ ”

Ó wí pé, “Gbogbo nǹkan wà dáradára.”

27Nígbà tí ó dé ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run ní orí òkè, ó gbá a ní ẹsẹ̀ mú. Gehasi wá láti wá lé e dànù, ṣùgbọ́n ènìyàn Ọlọ́run wí pé, “Fi í sílẹ̀! Ó wà nínú ìpọ́njú kíkorò, ṣùgbọ́n Olúwa fi pamọ́ fún mi kò sì sọ ìdí rẹ̀ fún mi.”

28“Ṣé mo béèrè ọmọ lọ́wọ́ rẹ, olúwa mi?” Obìnrin náà wí pé, “Ṣé mi ò sọ fún ọ pé kí o, ‘Má ṣe fa ìrètí mi sókè’?”

29Eliṣa wí fún Gehasi pé, “Ká agbádá rẹ sínú ọ̀já àmùrè, mú ọ̀pá mi sí ọwọ́ rẹ kí o sì sáré. Tí o bá pàdé ẹnikẹ́ni má ṣe kí i, tí ẹnikẹ́ni bá kí ọ, má ṣe dá a lóhùn, fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ ọkùnrin náà.”

30Ṣùgbọ́n ìyá ọmọ náà wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti ń bẹ láààyè àti gẹ́gẹ́ bí ó ti wà láààyè, èmi kò ní í fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni ó sì dìde ó sì tẹ̀lé e.

31Gehasi sì ń lọ síbẹ̀ ó sì fi ọ̀pá náà lé ojú ọmọ náà, ṣùgbọ́n kò sí ohùn tàbí ìdáhùn. Bẹ́ẹ̀ ni Gehasi padà lọ láti lọ bá Eliṣa láti sọ fún un pé, “Ọmọ ọkùnrin náà kò tí ì dìde.”

32Nígbà tí Eliṣa dé inú ilé, níbẹ̀ ni òkú ọmọ ọkùnrin náà dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn. 33Ó sì wọ ilé, ó sì ti ìlẹ̀kùn mọ́ àwọn méjèèjì ó sì gbàdúrà sí Olúwa. 34Nígbà náà ó dé orí ibùsùn, ó sùn sórí ọmọ ọkùnrin náà, ẹnu sí ẹnu, ojú sí ojú, ọwọ́ sí ọwọ́. Gẹ́gẹ́ bí ó ti nà ara rẹ̀ lórí rẹ̀, ara ọmọ náà sì gbóná. 35Eliṣa yípadà lọ, ó sì rìn padà ó sì jáde wá sínú ilé nígbà náà ó sì padà sí orí ibùsùn ó sì tún nà lé e ní ẹ̀ẹ̀kan sí i. Ọmọ ọkùnrin náà sì sín ní ìgbà méje ó sì ṣí ojú rẹ̀.

36Eliṣa sì pe Gehasi ó sì wí pé, “Pe ará Ṣunemu.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí ó dé, ó wí pé, “Gba ọmọ rẹ.” 37Ó sì wọlé, ó sì kúnlẹ̀ síwájú ẹsẹ̀ rẹ̀ ó sì tẹ̀ orí sílẹ̀. Nígbà náà ó sì mú ọmọ rẹ̀ ó sì jáde lọ.

Ikú nínú ìkòkò

38Eliṣa padà sí Gilgali ìyàn sì wà ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì ṣe ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Gbé ìkòkò ńlá ka iná kí o sì se ọbẹ̀ aláta díẹ̀ fún àwọn ọkùnrin yìí.”

39Ọ̀kan lára wọn jáde lọ sí orí pápá láti kó ewébẹ̀ jọ àti láti wá àjàrà igbó. Ó sì kó díẹ̀ nínú ẹ̀fọ́ gbọ̀rọ̀ rẹ̀ jọ, ó sì ka a kún aṣọ agbádá rẹ̀. Nígbà tí ó padà dé, ó sì gé wọn sínú ìkòkò ọbẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó mọ ohun tí wọ́n ń jẹ. 40Wọ́n da ọbẹ̀ náà jáde fun àwọn ọkùnrin náà, ṣùgbọ́n bí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí ní jẹ oúnjẹ náà, wọ́n sọkún jáde, “Ìwọ ènìyàn Ọlọ́run ikú ń bẹ nínú ìkòkò yìí!” Wọn kò sì le jẹ ẹ́.

41Eliṣa sì wí pé, “Mú ìyẹ̀fun díẹ̀ wá,” Ó sì fi sínú ìkòkò ó sì wí pé, “Kí ó sì fi fún àwọn ènìyàn láti jẹ.” Kò sì sí ohun tí ó léwu nínú ìkòkò náà.

42Ọkùnrin kan wá láti Baali-Ṣaliṣa, ó sì mú àkàrà àkọ́so èso, ogún ìṣù àkàrà barle, tí wọ́n dín láti ara àkọ́so èso àgbàdo, àti pẹ̀lú síírí ọkà tuntun nínú àpò rẹ̀ wá fún ènìyàn Ọlọ́run náà. Òun sì wí pé, “Fún àwọn ènìyàn láti jẹ.”

43“Báwo ni èmi yóò ṣe gbé èyí ka iwájú àwọn ọgọ́rùn-ún ènìyàn?” ìránṣẹ́ rẹ̀ béèrè.

Ṣùgbọ́n Eliṣa dá a lóhùn pé, “Gbé e fún àwọn ènìyàn láti jẹ, nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ: ‘Wọn yóò jẹ yóò sì tún ṣẹ́kù.’ ” 44Nígbà náà ó gbé e ka iwájú wọn, wọ́n sì jẹ ẹ́, wọ́n sì ní èyí tó ṣẹ́kù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

列王紀下 4:1-44

以利沙幫助窮寡婦

1有一個先知的妻子哀求以利沙說:「你僕人——我丈夫怎樣敬畏耶和華,你是知道的。如今他去世了,債主來取我的兩個孩子做奴隸。」 2以利沙問她:「我該怎樣幫你呢?告訴我,你家裡有什麼?」婦人答道:「婢女家什麼也沒有,只有一瓶油。」 3以利沙說:「你去向所有的鄰居借空器皿,要儘量多借一些。 4然後回家關上門,你和你兒子在屋裡把那瓶油倒在所有借來的器皿中,裝滿的放在一邊。」 5於是,婦人辭別以利沙,回去後把自己和兒子關在屋裡,兒子遞給她器皿,她就倒油。 6器皿都裝滿了,她對兒子說:「再拿個器皿給我。」兒子說:「已經沒有了。」這時,油止住了。 7婦人將經過告訴上帝的僕人,上帝的僕人對她說:「你去把油賣了還債,你們母子可以用剩下的錢度日。」

以利沙和書念婦人

8一天,以利沙路過書念,那裡一位富有的婦人挽留他吃飯。此後以利沙每次路過那裡,總到她家裡吃飯。 9那婦人對丈夫說:「我看常路過我們這裡的這位是上帝聖潔的僕人。他常路過我們這裡, 10不如我們在房頂上給他蓋一間小屋,裡面放床、桌子、椅子和燈。這樣,他來我們家時,可以在那裡休息。」

11一天,以利沙又到了那裡,便在那間小屋裡休息。 12以利沙吩咐僕人基哈西去請書念的婦人。她來了,站在以利沙面前。 13以利沙吩咐基哈西說:「你對她說,『你為我們費了不少心,我們該為你做些什麼呢?要不要我們在王或元帥面前為你說些好話呢?』」她答道:「我在本族中安居無事。」 14以利沙基哈西:「我們能為她做什麼呢?」基哈西說:「她沒有兒子,丈夫也已經老了。」 15以利沙說:「你再去請她來。」她來了,站在門口。 16以利沙對她說:「明年這時候,你必抱一個兒子。」她說:「上帝的僕人,我主啊,不要騙我。」 17那婦人果然懷了孕,在第二年的那時候生了一個兒子,應驗了以利沙對她說的話。

18孩子漸漸長大。一天,他到收割的人那裡找他父親。 19突然,他對他父親喊道:「我的頭啊!我的頭啊!」他父親見狀,立刻吩咐僕人抱他到他母親那裡。 20僕人把他抱起來,送到他母親那裡。孩子坐在母親的膝上,到中午就死了。 21他母親上樓把他放在上帝僕人的床上,關上門出來。 22她叫來丈夫,對他說:「請你預備一個僕人和一頭驢,我好趕快去見上帝的僕人,然後返回來。」 23她丈夫說:「今天不是朔日4·23 朔日」即每月初一。,也不是安息日,你為什麼要去見他?」婦人說:「平安無事。」 24她騎上驢,對僕人說:「快走吧!我不吩咐你,就不要慢下來。」

25她就去迦密山見上帝的僕人。上帝的僕人遠遠望見她,就對僕人基哈西說:「你看,書念的婦人來了! 26你跑去迎接她,問問她和她的丈夫與孩子都好嗎。」

婦人對以利沙的僕人說:「一切都好。」

27可是,她上山見到上帝的僕人後,就抱住他的腳。基哈西想要推開她,但上帝的僕人說:「由她吧!因為她心裡非常痛苦。耶和華沒有告訴我發生了什麼事。」 28婦人說:「我何嘗向我主求過兒子呢?我不是對你說不要騙我嗎?」 29以利沙吩咐基哈西:「你要束上腰帶,拿著我的杖去她家。路上不論遇見誰,都不要問候他。有人問候你,也不要作答。去把我的杖放在孩子臉上。」 30孩子的母親說:「我憑永活的耶和華和你的性命起誓,你若不同去,我決不離開你。」於是,以利沙跟她同去。 31基哈西先趕到,把杖放在孩子臉上,可是孩子一點動靜也沒有。他就回去找以利沙,路上碰見他,便說:「孩子還沒醒過來。」

32以利沙進了屋子,看見孩子死了,躺在床上, 33就關上門,向耶和華祈禱。 34禱告後,他上床伏在孩子身上,口對口,眼對眼,手對手,孩子的身體漸漸變暖了。 35然後,以利沙起來在房內來回走了一趟,又上床伏在孩子身上。孩子打了七個噴嚏,便睜開了眼睛。 36以利沙基哈西請那婦人來。婦人來了,以利沙對她說:「把你兒子抱走吧。」 37婦人進來,在以利沙腳前下拜,然後抱起兒子出去了。

用麵粉解毒

38以利沙回到吉甲,那裡正鬧饑荒。一群先知坐在他面前,他吩咐僕人把一口大鍋放在火上給他們煮湯。 39有個先知到田間摘野菜,看見一棵野瓜藤,便摘了一兜野瓜回來,切碎了放進鍋裡,卻不知道那是什麼瓜。 40湯煮好後倒出來給眾人喝,他們剛喝了一點,就叫道:「上帝的僕人啊,湯裡有毒!」他們都不敢喝了。 41以利沙說:「拿點麵粉來。」他把麵粉撒在鍋裡,說:「倒出來給眾人喝吧。」於是,湯裡沒有毒了。

用二十個餅餵飽百人

42巴力·沙利沙來了一個人,他帶了二十個用初熟大麥做的餅和一些麥穗送給上帝的僕人。上帝的僕人說:「分給眾人吃吧。」 43僕人說:「這些怎麼夠一百人吃呢?」以利沙說:「你只管分給眾人吃。因為耶和華說,『眾人都能吃飽,並且還會剩下。』」 44於是,僕人將食物擺在眾人面前,他們都吃飽了,果然還有剩餘,正如耶和華所言。