2 Ọba 2 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

2 Ọba 2:1-25

Elijah gun kẹ̀kẹ́ iná lọ sí ọ̀run

1Nígbà tí Olúwa ń fẹ́ gbé Elijah lọ sí òkè ọ̀run nínú àjà, Elijah àti Eliṣa wà ní ọ̀nà láti Gilgali. 2Elijah wí fún Eliṣa pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Beteli.”

Ṣùgbọ́n Eliṣa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti dájú pé Olúwa wà láyé àti gẹ́gẹ́ bí ó ti yẹ, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beteli.

3Àwọn ọmọ wòlíì ní Beteli jáde wá sí ọ̀dọ̀ Eliṣa wọ́n sì béèrè pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ pé Olúwa yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?”

“Bẹ́ẹ̀ ni, èmi mọ̀,” Eliṣa dáhùn, “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”

4Nígbà náà Elijah sì wí fún un pé, “Dúró níbí, Eliṣa: Olúwa ti rán mi lọ sí Jeriko.”

Ó sì dá a lóhùn pé, “Bí ó ti dájú pé Olúwa yè àti tí ìwọ náà yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Wọ́n sì jọ lọ sí Jeriko.

5Àwọn ọmọ wòlíì tí ó wà ní Jeriko sì gòkè tọ Eliṣa wá wọ́n sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé, “Ṣé ìwọ mọ̀ wí pé Olúwa yóò gba ọ̀gá rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ lónìí?”

“Bẹ́ẹ̀ ni, èmi mọ̀,” Ó dá wọn lóhùn, “Ṣùgbọ́n ẹ má ṣe sọ nípa rẹ̀.”

6Nígbà náà Elijah wí fún un pé, “Dúró níbí; Olúwa rán mi lọ sí Jordani.”

Ó sì dá a lóhùn pé, “Gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ wí pé, Olúwa yè àti gẹ́gẹ́ bí o ti yè, èmi kò ní fi ọ́ sílẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn méjèèjì sì jọ ń lọ.

7Àádọ́ta àwọn ọkùnrin ọmọ wòlíì sì lọ láti lọ dúró ní ọ̀nà jíjìn, wọ́n sì kọ ojú da ibi tí Elijah àti Eliṣa ti dúró ní Jordani. 8Elijah sì mú agbádá ó sì ká a sókè ó sì lu omi náà pẹ̀lú rẹ̀. Omi náà sì pín sí ọ̀tún àti sí òsì, àwọn méjèèjì sì rékọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ.

9Nígbà tí wọ́n rékọjá, Elijah sì wí fún Eliṣa pé, “Sọ fún mi, kí ni èmi lè ṣe fún ọ kí ó tó di wí pé wọ́n gbà mí kúrò lọ́dọ̀ rẹ?”

“Jẹ́ kí èmi kí ó jogún ìlọ́po méjì ẹ̀mí rẹ.” Ó dá a lóhùn.

10“Ìwọ ti béèrè ohun tí ó ṣòro,” Elijah wí pé, “Síbẹ̀ tí ìwọ bá rí mi nígbà tí a bá gbà mí kúrò lọ́wọ́ rẹ, yóò jẹ́ tìrẹ bí bẹ́ẹ̀ kọ́ kò ní rí bẹ́ẹ̀.”

112.11: If 11.12.Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ń rìn lọ tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ pọ̀, lọ́gán kẹ̀kẹ́ iná àti ẹṣin iná yọ sí wọn ó sì ya àwọn méjèèjì nípa, Elijah sì gòkè lọ sí ọ̀run pẹ̀lú àjà. 12Eliṣa rí èyí ó sì kígbe sókè, “Baba mi! Baba mi! Kẹ̀kẹ́ àti ẹlẹ́ṣin Israẹli!” Eliṣa kò sì rí i mọ́. Ó sì mú aṣọ ara rẹ̀ ó sì fà wọ́n ya sọ́tọ̀.

13Ó sì mú agbádá tí ó ti jábọ́ láti ọ̀dọ̀ Elijah ó sì padà lọ, ó sì dúró lórí bèbè Jordani. 14Ó sì mú agbádá náà tí ó jábọ́ láti ọwọ́ rẹ̀, ó sì lu omi pẹ̀lú rẹ̀. “Níbo ni Olúwa Ọlọ́run Elijah wà?” Ó béèrè. Nígbà tí ó lu omi náà, ó sì pín sí apá ọ̀tún àti sí òsì, Eliṣa sì rékọjá.

15Àwọn ọmọ wòlíì láti Jeriko, tí wọ́n ń wò, wí pé, “Ẹ̀mí Elijah sinmi lé Eliṣa.” Wọ́n sì lọ láti lọ bá a, wọ́n sì dojúbolẹ̀ níwájú rẹ̀. 16“Wò ó,” wọ́n wí pé, “Àwa ìránṣẹ́ ni àádọ́ta ọkùnrin alágbára. Jẹ́ kí wọ́n lọ láti lọ wá ọ̀gá rẹ wá. Bóyá ẹ̀mí Olúwa ti gbé e sókè, ó sì gbé e kalẹ̀ lórí òkè ńlá tàbí lórí ilẹ̀.”

“Rárá,” Eliṣa dá a lóhùn pé, “Má ṣe rán wọn.”

17Ṣùgbọ́n wọ́n rọ̀ ọ́ títí ojú fi tì í láti gbà. Ó wí pé, “Rán wọn.” Wọ́n sì rán àádọ́ta ènìyàn tí ó wá a fún ọjọ́ mẹ́ta ṣùgbọ́n wọn kò rí i. 18Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, tí ó dúró ní Jeriko, ó wí fún wọn pé, “Ṣé èmi kò sọ fún un yín kí ẹ má lọ?”

Ìwòsàn omi

19Àwọn ọkùnrin ìlú wí fún Eliṣa, pé, “Wò ó, olúwa wa, ìtẹ̀dó ìlú yìí dára, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti rí i, ṣùgbọ́n omi náà burú, ilẹ̀ náà sì sá.”

20Ó sì wí pé, “Mú àwokòtò tuntun fún mi wá, kí o sì mú iyọ̀ sí inú rẹ̀.” Wọ́n sì gbé e wá fún un.

21Nígbà náà ó sì jáde lọ sí ibi orísun omi, ó sì da iyọ̀ sí inú rẹ̀, ó wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Èmi ti wo omi yìí sàn. Kò ní mú ikú wá mọ́ tàbí mú ilẹ̀ náà sá.’ ” 22Omi náà sì ti dára ni mímu títí di òní, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ tí Eliṣa ti sọ.

Wọ́n fi Eliṣa ṣe yẹ̀yẹ́

23Láti ibẹ̀ Eliṣa lọ sókè ní Beteli gẹ́gẹ́ bí ó ti ń rìn lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọ̀dọ́ kan jáde wá láti ìlú náà wọ́n sì fi ṣe ẹlẹ́yà. “Máa lọ sókè ìwọ apárí!” Wọ́n wí pé. “Máa lọ sókè ìwọ apárí!” 24Ó sì yípadà, ó sì wò wọ́n ó sì fi wọ́n bú ní orúkọ Olúwa. Nígbà náà beari méjì sì jáde wá láti inú igbó ó sì lu méjìlélógójì lára àwọn ọ̀dọ́ náà. 25Ó sì lọ sí orí òkè Karmeli láti ibẹ̀ ó sì padà sí Samaria.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

列王紀下 2:1-25

以利亞被接到天上

1耶和華用旋風接以利亞升天之前,以利亞以利沙正在離開吉甲的路上。 2以利亞以利沙說:「你留在這裡吧,耶和華吩咐我去伯特利。」以利沙說:「我憑永活的耶和華和你的性命起誓,我決不離開你。」於是二人前往伯特利3伯特利的眾先知出來見以利沙,問他:「你知道耶和華今天要接走你師傅嗎?」他說:「我知道,請不要作聲。」

4以利亞以利沙說:「你留在這裡吧,耶和華差遣我去耶利哥。」以利沙說:「我憑永活的耶和華和你的性命起誓,我決不離開你。」於是二人前往耶利哥5耶利哥的眾先知來見以利沙,問他:「你知道耶和華今天要接走你師傅嗎?」他說:「我知道,請不要作聲。」

6以利亞以利沙說:「你留在這裡吧,耶和華差遣我去約旦河。」以利沙說:「我憑永活的耶和華和你的性命起誓,我決不離開你。」於是二人繼續前行。 7先知中有五十人跟他們來到約旦河,遠遠地站著,他們二人則站在河邊。 8以利亞脫下外衣捲起來,用它擊打河水,水立即左右分開,二人腳踏乾地而過。

9到對岸後,以利亞以利沙說:「在我被接走之前,你要我為你做什麼?」以利沙說:「請將你的靈加倍地給我。」 10以利亞說:「這是個很難的要求。不過,我被接走的時候,如果你看得見我,就可以得到,否則就得不到。」 11他們邊走邊談,忽然有火馬拉的火車把他們二人隔開,以利亞乘著旋風升上了天。 12以利沙見此情景,便喊道:「我父啊!我父啊!以色列的戰車和騎兵啊!」以利沙以利亞消失在天空中,就悲傷地把自己的衣服撕成兩半。

13他拿起以利亞身上掉下來的外衣,回到約旦河邊, 14用它擊打河水,說:「以利亞的上帝耶和華在哪裡呢?」河水就左右分開,以利沙便過了河。

15耶利哥的先知們從遠處看見他,就說:「以利亞的靈降在以利沙身上了。」他們就上前迎接,俯伏在他面前, 16說:「僕人們這裡有五十個壯士,請讓他們去尋找你師傅吧,或許耶和華的靈把他放在某座山上或某個山谷裡了。」以利沙說:「你們不要派人去找了。」 17他們再三懇求,以利沙難以推辭,就讓他們派人去了。他們派去了五十人,找了三天也沒有找到。 18他們回來的時候,以利沙仍在耶利哥。他對他們說:「我不是早就告訴你們不要去嗎?」

以利沙行神蹟

19耶利哥城的人對以利沙說:「我主,你看這城地勢很好,只是水不好,地裡長不出莊稼。」 20以利沙說:「拿一個新碗裝些鹽給我。」他們就去照辦。 21以利沙走到水源那裡,把鹽倒在水中說:「耶和華說,『我潔淨了這水,從此它不會再使人死亡,也不會再使土地貧瘠。』」 22果然如以利沙所說,那裡的水變好了,直到如今。

23以利沙從那裡去伯特利,正在趕路的時候,從城裡出來一群少年譏笑他說:「禿頭,上去吧!禿頭,上去吧!」 24以利沙轉身看著他們,奉耶和華的名咒詛他們。林中隨即走出來兩隻母熊,咬死了其中的四十二個少年。 25以利沙伯特利上了迦密山,又從迦密山回到撒瑪利亞