1 Timotiu 6 – YCB & NIRV

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Timotiu 6:1-21

Àwọn ẹrú

1Jẹ́ kí gbogbo àwọn tí i ṣe ẹrú lábẹ́ ìsìnrú máa ka àwọn olówó tí ó ni wọ́n yẹ sí ọlá gbogbo, kí a má bà á sọ̀rọ̀-òdì sí orúkọ Ọlọ́run àti ẹ̀kọ́ rẹ̀. 2Àwọn ti ó ní ọ̀gá onígbàgbọ́, kí wọn má ṣe ṣàìbọ̀wọ̀ fún wọn nítorí tí wọn jẹ́ arákùnrin; ṣùgbọ́n kí wọn túbọ̀ máa sìn wọ́n, nítorí àwọn tí í ṣe alábápín iṣẹ́ rere wọn jẹ́ onígbàgbọ́ àti olùfẹ́.

Ìfẹ́ owó

Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa kọ́ ni, kí o sì máa fi gbani níyànjú. 3Bí ẹnikẹ́ni bá ń kọ́ni ní ẹ̀kọ́ mìíràn, ti kò sì gba ọ̀rọ̀ ti ó yè kooro, ti Jesu Kristi Olúwa wa, àti ẹ̀kọ́ ti ó bá ìwà-bí-Ọlọ́run mu, 4Ó gbéraga, kò mọ̀ nǹkan kan, bí kò ṣe ìyànjú àti ìjà nípa ọ̀rọ̀ èyí tí ó ń mú ìlara, ìjà, ọ̀rọ̀ búburú wá, 5àti ọ̀rọ̀ àríyànjiyàn àwọn ènìyàn ọlọ́kàn èérí ti kò sí òtítọ́ nínú wọn, tiwọn ṣe bí ọ̀nà sí èrè ni ìwà-bí-Ọlọ́run; yẹra lọ́dọ̀ irú àwọn wọ̀nyí.

6Ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn èrè ńlá ni. 7Nítorí a kò mú ohun kan wá sí ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mu ohunkóhun jáde lọ. 8Bí a sì ni oúnjẹ àti aṣọ, ìwọ̀nyí yẹ́ kí ó tẹ́ wa lọ́rùn. 9Ṣùgbọ́n àwọn tí ń fẹ́ di ọlọ́rọ̀ a máa bọ́ sínú ìdánwò àti ìdẹ̀kùn, àti sínú òmùgọ̀ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ púpọ̀ tí í pa ni lára, irú èyí tí ó máa ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé. 10Nítorí ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò ohun búburú gbogbo; èyí tí àwọn mìíràn ń lépa tí a sì mú wọn ṣìnà kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì fi ọ̀pọ̀ ìbànújẹ́ gún ara wọn lọ́kọ̀.

Ọ̀rọ̀ ìyànjú fún Timotiu

11Ṣùgbọ́n ìwọ ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí; kí ó sì máa lépa òdodo, ìwà-bí-Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́ sùúrù, ìwà tútù. 12Máa ja ìjà rere ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú nínú èyí tí a pè ọ sí, ti ìwọ sì ṣe ìjẹ́wọ́ rere níwájú ẹlẹ́rìí púpọ̀. 136.13: Jh 18.37.Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, tí ń sọ ohun gbogbo di ààyè, àti níwájú Jesu Kristi, ẹni tí ó jẹ́rìí níwájú Pọntiu Pilatu, 14kí ìwọ pa àṣẹ wọ̀nyí mọ́ ní àìlábàwọ́n, ní àìlẹ́gàn, títí di ìfarahàn Olúwa wa Jesu Kristi. 15Èyí ti yóò fihàn ní ìgbà tirẹ̀, Ẹni tí í ṣe Olùbùkún àti Alágbára kan ṣoṣo náà, ọba àwọn ọba, àti Olúwa àwọn Olúwa. 16Ẹnìkan ṣoṣo tí ó jẹ àìkú, tí ń gbé inú ìmọ́lẹ̀ tí a kò lè súnmọ́, ẹni tí ènìyàn kan kò rí rí, tí a kò sì lè rí: ẹni tí ọlá àti agbára títí láé ń ṣe tirẹ̀. Àmín.

17Kìlọ̀ fún àwọn tí ó lọ́rọ̀ ní ayé ìsinsin yìí kí wọn ma ṣe gbéraga, bẹ́ẹ̀ ni kí wọn má ṣe gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run alààyè, tí ń fi ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀lọ́pọ̀ láti lò; 18kí wọn máa ṣoore, kí wọn máa pọ̀ ní iṣẹ́ rere, kí wọn múra láti pín fún ni, kí wọn ni ẹ̀mí ìbá kẹ́dùn; 19kí wọn máa to ìṣúra ìpìlẹ̀ rere jọ fún ara wọn dé ìgbà tí ń bọ̀, kí wọn lè di ìyè tòótọ́ mú.

20Timotiu, máa ṣọ ohun tí a fi sí ìkáwọ́ rẹ, yà kúrò nínú ọ̀rọ̀ asán àti ìjiyàn ohun tí a ń fi èké pè ni ìmọ̀; 21èyí tí àwọn ẹlòmíràn jẹ́wọ́ rẹ̀ tí wọ́n sì ṣìnà ìgbàgbọ́.

Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹ̀lú rẹ.

New International Reader’s Version

1 Timothy 6:1-21

1All who are forced to serve as slaves should consider their masters worthy of full respect. Then people will not speak evil things against God’s name and against what we teach. 2Some slaves have masters who are believers. They shouldn’t show their masters disrespect just because they are also believers. Instead, they should serve them even better. That’s because their masters are loved by them as believers. These masters are committed to caring for their slaves.

People Who Teach Lies or Love Money

These are the things you are to teach. Try hard to get the believers to do them. 3Suppose someone teaches something different than I have taught. Suppose that person doesn’t agree with the true teaching of our Lord Jesus Christ. Suppose they don’t agree with godly teaching. 4Then that person is proud and doesn’t understand anything. They like to argue more than they should. They can’t agree about what words mean. All of this results in wanting what others have. It causes fighting, harmful talk, and evil distrust. 5It stirs up trouble all the time among people whose minds are twisted by sin. The truth they once had has been taken away from them. They think they can get rich by being godly.

6You gain a lot when you live a godly life. But you must be happy with what you have. 7We didn’t bring anything into the world. We can’t take anything out of it. 8If we have food and clothing, we will be happy with that. 9People who want to get rich are tempted. They fall into a trap. They are tripped up by wanting many foolish and harmful things. Those who live like that are dragged down by what they do. They are destroyed and die. 10Love for money causes all kinds of evil. Some people want to get rich. They have wandered away from the faith. They have wounded themselves with many sorrows.

Paul Gives a Final Command to Timothy

11But you are a man of God. Run away from all these things. Try hard to do what is right and godly. Have faith, love and gentleness. Hold on to what you believe. 12Fight the good fight along with all other believers. Take hold of eternal life. You were chosen for it when you openly told others what you believe. Many witnesses heard you. 13God gives life to everything. Christ Jesus told the truth when he was a witness in front of Pontius Pilate. In the sight of God and Christ, I give you a command. 14Obey it until our Lord Jesus Christ appears. Obey it completely. Then no one can find fault with it or you. 15God will bring Jesus back at a time that pleases him. God is the blessed and only Ruler. He is the greatest King of all. He is the most powerful Lord of all. 16God is the only one who can’t die. He lives in light that no one can get close to. No one has seen him. No one can see him. Honor and power belong to him forever. Amen.

17Command people who are rich in this world not to be proud. Tell them not to put their hope in riches. Wealth is so uncertain. Command those who are rich to put their hope in God. He richly provides us with everything to enjoy. 18Command the rich to do what is good. Tell them to be rich in doing good things. They must give freely. They must be willing to share. 19In this way, they will store up true riches for themselves. It will provide a firm basis for the next life. Then they will take hold of the life that really is life.

20Timothy, guard what God has trusted you with. Turn away from godless chatter. Stay away from opposing ideas that are falsely called knowledge. 21Some people believe them. By doing that they have turned away from the faith.

May God’s grace be with you all.