1 Timotiu 5 – YCB & CCBT

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Timotiu 5:1-25

Ìmọ̀ràn nípa àwọn opó, àwọn alàgbà àti àwọn ẹrú

1Má ṣe bá àgbàlagbà ọkùnrin wí, ṣùgbọ́n kí ó máa gbà á níyànjú bí i baba; àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bí arákùnrin. 2Àwọn àgbàlagbà obìnrin bí ìyá; àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin bí arábìnrin nínú ìwà mímọ́.

3Bọ̀wọ̀ fún àwọn opó ti í ṣe opó nítòótọ́. 4Ṣùgbọ́n bí opó kan bá ni ọmọ tàbí ọmọ ọmọ, jẹ́ kí wọn kọ́kọ́ kọ́ bí a ti ń ṣe ìtọ́jú ilé àwọn tìkára wọn, kí wọn sì san oore àwọn òbí wọn padà; nítorí pé èyí ni ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà níwájú Ọlọ́run. 5Ǹjẹ́ ẹni ti í ṣe opó nítòótọ́, ti ó ṣe òun nìkan, a máa gbẹ́kẹ̀lé Ọlọ́run, a sì máa dúró nínú ẹ̀bẹ̀ àti nínú àdúrà lọ́sàn àti lóru. 6Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá fi ara rẹ fún ayé jíjẹ, ó kú nígbà tí ó wà láààyè. 7Nǹkan wọ̀nyí ni kí wọn máa paláṣẹ, kí wọn lè wà láìlẹ́gàn. 8Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni kò bá pèsè fún àwọn tirẹ̀, pàápàá fún àwọn ará ilé rẹ̀, ó ti sẹ́ ìgbàgbọ́, ó burú ju aláìgbàgbọ́ lọ.

9Kọ orúkọ ẹni tí kò bá dín ni ọgọ́ta ọdún sílẹ̀ bí opó, lẹ́yìn ti ó ti jẹ́ aya ọkọ kan. 10Ẹni ti a jẹ́rìí rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ẹni ti ó ti tọ́ ọmọ dàgbà, ti ó ń ṣe ìtọ́jú àlejò, tí ó sì ń wẹ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, tí ó ti ran àwọn olùpọ́njú lọ́wọ́, tí ó sì ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.

11Ṣùgbọ́n ma ṣe kọ orúkọ àwọn opó tí kò dàgbà; nítorí pé nígbà tiwọn bá ti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lòdì sí Kristi, wọn á tún fẹ́ láti gbéyàwó. 12Wọn á di ẹlẹ́bi, nítorí tí wọn ti kọ ìgbàgbọ́ wọn ìṣáájú sílẹ̀. 13Àti pẹ̀lú wọn ń kọ́ láti ṣe ọ̀lẹ, láti máa kiri láti ilédélé, kì í ṣe ọ̀lẹ nìkan, ṣùgbọ́n onísọkúsọ àti olófòófó pẹ̀lú, wọn a máa sọ ohun tí kò yẹ. 14Nítorí náà, mo fẹ́ kí àwọn opó tí kò dàgbà máa gbéyàwó, kí wọn máa bímọ, kí wọn máa ṣe alábojútó ilé, kí wọn má ṣe fi ààyè sílẹ̀ rárá fún ọ̀tá náà láti sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn. 15Nítorí àwọn mìíràn ti yípadà kúrò sí ẹ̀yìn Satani.

16Bí ọkùnrin tàbí obìnrin kan tí ó gbàgbọ́ bá ní àwọn opó, kí ó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, kí a má sì di ẹrù lé ìjọ, kí wọn lè máa ran àwọn ti í ṣe opó nítòótọ́ lọ́wọ́.

17Àwọn alàgbà ti ó ṣe àkóso dáradára ni kí a kà yẹ sí ọlá ìlọ́po méjì, pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ti ó ṣe làálàá ni ọ̀rọ̀ àti ni kíkọ́ni. 185.18: De 25.4; 1Kọ 9.9; Mt 10.10; Lk 10.7; 1Kọ 9.14.Nítorí tí Ìwé Mímọ́ wí pé, “Ìwọ kò gbọdọ̀ di màlúù ti ń tẹ ọkà lẹ́nu,” àti pé, “Ọ̀yà alágbàṣe tọ́ sí i.” 195.19: De 19.15.Má ṣe gba ẹ̀sùn sí alàgbà kan, bí kò ṣe láti ẹnu ẹlẹ́rìí méjì mẹ́ta. 20Bá àwọn tí ó ṣẹ̀ wí níwájú gbogbo ènìyàn, kí àwọn ìyókù pẹ̀lú bà á lè bẹ̀rù. 21Mo pàṣẹ fún ọ níwájú Ọlọ́run, àti Kristi Jesu, àti àwọn angẹli àyànfẹ́ kí ìwọ máa ṣàkíyèsí nǹkan wọ̀nyí, láìṣe ojúsàájú, láti fi ègbè ṣe ohunkóhun.

22Má ṣe fi ìkánjú gbe ọwọ́ lé ẹnikẹ́ni, bẹ́ẹ̀ ni kí ó má sì ṣe jẹ́ alábápín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn, pa ara rẹ mọ́ ní ìwà mímọ́.

23Ma ṣe máa mu omi nìkan, ṣùgbọ́n máa lo wáìnì díẹ̀ nítorí inú rẹ, àti nítorí àìlera ìgbàkúgbà.

24Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíràn a máa hàn gbangba, a máa lọ ṣáájú sí ìdájọ́; tí àwọn ẹlòmíràn pẹ̀lú a sì máa tẹ̀lé wọn. 25Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ pẹ̀lú ni iṣẹ́ rere wa máa ń hàn gbangba; bí wọn kò tilẹ̀ tí ì hàn, wọn kò lè fi ara sin títí.

Chinese Contemporary Bible (Traditional)

提摩太前書 5:1-25

信徒的責任

1不要斥責年長的,要像對待父親一樣勸他們;對待青年男子要情同手足; 2對待年長的婦女要情同母親;對待青年女子要心思純正,視她們如姊妹。

3要敬重和幫助那些真正有需要的寡婦。 4如果寡婦有兒孫,就要叫她們的兒孫在家中學習盡孝道,奉養她們,以報答養育之恩,這是上帝所悅納的。 5真正有需要、無依無靠的寡婦仰賴上帝的幫助,晝夜不住地禱告祈求。 6但貪圖享受的寡婦雖然活著,卻已經死了。 7你當教導眾人這些事,好叫他們無可指責。 8誰不照顧自己的親屬,尤其是不照顧自己的家人,就是違背真道,比不信的人還壞。

9列入名冊的寡婦必須年滿六十歲,在婚姻上從一而終, 10並且在善事上有好名聲,如教養兒女、接待外人、服侍聖徒、救助困苦、竭力做各種善事。

11不要把年輕的寡婦列入名冊,因為當她們情慾衝動,無法持守對基督的委身時,就想再嫁, 12以致違背了起初的誓言而受審判。 13況且,她們不僅懶散成性,四處串門,還說長道短,好管閒事,搬弄是非。 14所以,我建議年輕的寡婦再嫁,生兒育女,料理家務,不要給仇敵毀謗的機會, 15因為有些人已經偏離正道,去追隨撒旦了。 16女信徒的家裡若有寡婦,就應該自己照顧她們,免得加重教會的負擔,這樣教會才能照顧那些真正無依無靠的寡婦。

17那些善於管理教會的長老,尤其是那些辛勤傳道和教導人的,理當得到加倍的尊敬和報酬。 18因為聖經上說:「牛在踩穀時,不可籠住牠的嘴。」又說:「做工的得報酬是應該的。」 19若有人向你控告長老,必須有兩三個證人,否則不要受理。 20那些一直犯罪的人,你要當眾責備他們,以警戒眾人。

21我在上帝和主耶穌基督以及蒙揀選的眾天使面前吩咐你:要遵行這些話,不要有成見,不要偏心; 22為人行按手禮,不要操之過急。不要沾染別人的罪,要潔身自好。

23你的胃不好,經常生病,不要只喝水,要稍微喝一點酒。

24有些人的罪很明顯,自招審判,有些人的罪日後才暴露出來。 25同樣,有些善行很明顯,不明顯的也不會被長久埋沒。