1 Timotiu 4 – YCB & SNC

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Timotiu 4:1-16

Àwọn ẹ̀kọ́ fun Timotiu

1Nísinsin yìí, èmi ń tẹnumọ́ ọ́ pé ní ìgbà ìkẹyìn àwọn mìíràn yóò kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọn yóò máa fiyèsí àwọn ẹ̀mí tí ń tannijẹ, àti ẹ̀kọ́ àwọn ẹ̀mí èṣù. 2Nípa àgàbàgebè àwọn tí ń ṣèké, àwọn tí ọkàn tìkára wọn dàbí èyí tí a fi irin gbígbóná jó. 3Àwọn tí ń dánilẹ́kun láti gbéyàwó tiwọn si ń pàṣẹ láti ka èèwọ̀ oúnjẹ ti Ọlọ́run ti dá fún ìtẹ́wọ́gbà pẹ̀lú ọpẹ́ àwọn onígbàgbọ́ àti àwọn ti ó mọ òtítọ́. 4Nítorí gbogbo ohun ti Ọlọ́run dá ni ó dára, kò sí ọkàn tí ó yẹ kí a kọ̀, bí a bá fi ọpẹ́ gbà á. 5Nítorí tí a fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àdúrà yà sí mímọ́.

6Bí ìwọ bá ń rán àwọn ará létí nǹkan wọ̀nyí, ìwọ ó jẹ́ ìránṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a fi ọ̀rọ̀ ìgbàgbọ́ àti ẹ̀kọ́ rere bọ́, èyí ti ìwọ ti ń tẹ̀lé. 7Ṣùgbọ́n kọ ọ̀rọ̀ asán àti ìtàn àwọn àgbà obìnrin, sì máa tọ́ ara rẹ sí ìwà-bí-Ọlọ́run. 8Nítorí ṣíṣe eré-ìdárayá ni èrè fún ohun díẹ̀, ṣùgbọ́n ìwà-bí-Ọlọ́run ni èrè fún ohun gbogbo, ó ní ìlérí ti ìgbé ayé ìsinsin yìí àti ti èyí tí ń bọ̀. 9Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ náà, ó sì yẹ fún ìtẹ́wọ́gbà gbogbo. 10Nítorí fún èyí ni àwa ń ṣe làálàá tí a sì ń jìjàkadì, nítorí àwa ní ìrètí nínú Ọlọ́run alààyè, ẹni tí í ṣe Olùgbàlà gbogbo ènìyàn, pẹ̀lúpẹ̀lú ti àwọn ti ó gbàgbọ́.

11Nǹkan wọ̀nyí ni kí ó máa paláṣẹ kí ó máa kọ́ni. 12Má ṣe jẹ́ kí ẹnikẹ́ni gan ìgbà èwe rẹ; ṣùgbọ́n kì ìwọ jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn tí ó gbàgbọ́, nínú ọ̀rọ̀, nínú ìwà híhù, nínú ìfẹ́, nínú ẹ̀mí, nínú ìgbàgbọ́, nínú ìwà mímọ́. 13Títí èmi ó fi dé, máa fiyèsí kíkàwé àti ìgbaniníyànjú àti ìkọ́ni. 14Má ṣe àìnání ẹ̀bùn tí ń bẹ lára rẹ, èyí tí a fi fún ọ nípa ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìgbọ́wọ́lé àwọn alàgbà.

15Máa fiyèsí nǹkan wọ̀nyí; fi ara rẹ fún wọn pátápátá; kí ìlọsíwájú rẹ lè hàn gbangba fún gbogbo ènìyàn. 16Máa ṣe ìtọ́jú ará rẹ àti ẹ̀kọ́ rẹ; máa dúró láìyẹsẹ̀ nínú nǹkan wọ̀nyí; nítorí ní ṣíṣe èyí, ìwọ ó gba ara rẹ àti tí àwọn ti ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ là.

Slovo na cestu

1 Timoteovi 4:1-16

1Duch pak světle praví, že v posledních časích odvrátí se někteří od víry, poslouchajíce duchů bludných a učení ďábelských, 2V pokrytství lež mluvících, a cejchované majících svědomí své, 3Zbraňujících ženiti se, přikazujících zdržovati se od pokrmů, kteréž Bůh stvořil k užívání s díkčiněním věřícím a těm, jenž poznali pravdu. 4Nebo všeliké stvoření Boží dobré jest, a nic nemá zamítáno býti, což se s díků činěním přijímá. 5Posvěcuje se zajisté skrze slovo Boží a modlitbu. 6Toto předkládaje bratřím, budeš dobrý služebník Jezukristův, vykrmený slovy víry a pravého učení, kteréhož jsi následoval. 7Světské pak a babské básně zavrz, ale cvič se v zbožnosti. 8Nebo tělesné cvičení malého jest užitku, ale zbožnost ke všemu jest užitečná, a má i nynějšího i budoucího života zaslíbení. 9Věrnáť jest tato řeč a hodná, aby všelijak oblíbena byla. 10Proto zajisté i pracujeme, i pohanění neseme, že naději máme v Bohu živém, kterýž jest spasitel všech lidí, a zvláště věřících. 11Ty věci předkládej a uč. 12Nižádný mladostí tvou nepohrdej, ale buď příkladem věrných v řeči, v lásce, v duchu, u víře, v čistotě. 13Dokudž k tobě nepřijdu, buďiž pilen čítání, a napomínání, i učení. 14Nezanedbávej daru, kterýž jest v tobě, jenž jest dán skrze proroctví s vzkládáním rukou starších na tě. 15O tom přemyšluj, v tom buď ustavičně, aby prospěch tvůj zjevný byl všechněm. 16Budiž sebe pilen i učení, a v tom trvej; nebo to čině, i samého sebe spasíš, i ty, kteříž tebe poslouchají.