1 Tẹsalonika 2 – YCB & BPH

Bíbélì Mímọ́ Yorùbá Òde Òn

1 Tẹsalonika 2:1-20

Iṣẹ́ Paulu ní ìjọ Tẹsalonika

1Ẹ̀yin pàápàá mọ̀ ará, pé ìbẹ̀wò wa sí i yín kì í ṣe ní asán. 22.2: Ap 16.19-24; 17.1-9; Ro 1.1.Àwa tí jìyà, a sì fi àbùkù kàn wá ní ìlú Filipi bí ẹ̀yin ti mọ̀, ṣùgbọ́n nípa ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run wa ní àwa fi ìgboyà sọ ìyìnrere fún un yín pẹ̀lú àtakò líle. 3Nítorí ọ̀rọ̀ ìyànjú wa kì í ṣe ti ẹ̀tàn, tàbí ti èrò àìmọ́, tàbí láti inú àrékérekè. 4Ṣùgbọ́n bí a ti kà wá yẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run, bí ẹni tí a fi ìyìnrere lé lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni àwa ń sọ, kì í ṣe bí ẹni tí ń wu ènìyàn, bí kò ṣe Ọlọ́run tí ń dán ọkàn wa wò. 52.5: Ap 20.33.A mọ̀ pé a kò lo ọ̀rọ̀ dídùn, tàbí ìbòjú ojúkòkòrò fún yín, Ọlọ́run ni ẹlẹ́rìí wa. 62.6: 1Kọ 9.1.A kò béèrè ìyìn lọ́dọ̀ yín tàbí fún ara wa. Gẹ́gẹ́ bí aposteli Kristi a ò bá ti di àjàgà fún un yín. 72.7: 1Tẹ 2.11; Ga 4.19.Ṣùgbọ́n àwa ṣe pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ láàrín yín tí a sì ṣe ìtọ́jú yín.

Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti ń tọ́jú àwọn ọmọ rẹ̀, 82.8: 2Kọ 12.15; 1Jh 3.16.bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àwa ti ní ìfẹ́ inú rere sí yín, inú wa dùn jọjọ láti fún yín, kì í ṣe ìyìnrere Ọlọ́run nìkan, ṣùgbọ́n ẹ̀mí àwa fúnra wa pẹ̀lú, nítorí ẹ̀yín jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n fún wa. 9Nítòótọ́ ẹ rántí, ará, iṣẹ́ àti làálàá wa; lọ́sàn án àti lóru ni àwa ń ṣiṣẹ́ kí ìnáwó wa má bà á di ìṣòro fún ẹnikẹ́ni bí a ti ń wàásù ìyìnrere Ọlọ́run fún un yín. 10Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí wà, bẹ́ẹ̀ náà sì ni Ọlọ́run pẹ̀lú, bí a ṣe gbé ìgbé ayé mímọ́, òdodo àti àìlẹ́gàn láàrín ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́. 112.11: 1Kọ 4.14.Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin sì ti mọ̀ bí àwa tí ń ba olúkúlùkù yín lò gẹ́gẹ́ bí baba ti ń bá àwọn ọmọ rẹ̀ sọ̀rọ̀ 122.12: 1Pt 5.10.ìyànjú, ìtùnú àti tí a ń bẹ̀ yín láti gbé ìgbésí ayé tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, ẹni tí ó ń pè yín sínú ìjọba àti ògo òun tìkára rẹ̀.

132.13: 1Tẹ 1.2.Àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nítorí pé, ẹ kò ka ọ̀rọ̀ ìwàásù wa sí ọ̀rọ̀ ti ara wa. Pẹ̀lú ayọ̀ ni ẹ gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí a wí gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, òtítọ́ sì ni pé, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni, èyí tí ó ń ṣiṣẹ́ nínú ẹ̀yin tí ó gbàgbọ́. 14Nítorí, ẹ̀yin ara, ẹ jẹ́ àwòkọ́ṣe àwọn ìjọ Ọlọ́run tí o wà ní Judea nínú Kristi Jesu. Nítorí pé ẹ̀yin pẹ̀lú jìyà irú ohun kan náà lọ́wọ́ àwọn ará ìlú yín, gẹ́gẹ́ bí àwọn pẹ̀lú ti jìyà lọ́wọ́ àwọn Júù, 152.15: Lk 24.20; Ap 2.23; 7.52.àwọn tí wọ́n pa Jesu Olúwa àti àwọn wòlíì, tí wọ́n sì tì wa jáde. Wọn kò ṣe èyí tí ó wu Ọlọ́run, wọ́n sì ṣe lòdì sí gbogbo ènìyàn 162.16: Ap 9.23; 13.45,50; 14.2,5,19; 17.5,13; 18.12; 21.21,27; 25.2,7; 1Kọ 10.33; Gẹ 15.16; 1Tẹ 1.10.nínú ìgbìyànjú wọn láti dá ìwàásù ìyìnrere dúró láàrín àwọn aláìkọlà kí wọn kí ó lè rí gbàlà. Ẹ̀ṣẹ̀ wọn ń di púpọ̀ sí i lójoojúmọ́. Ṣùgbọ́n ní ìkẹyìn, ìbínú Ọlọ́run ti wá sórí wọn ní ìgbẹ̀yìn.

Paulu n fẹ́ láti rí àwọn ìjọ Tẹsalonika

172.17: 1Kọ 5.3.Ẹ̀yin ará olùfẹ́, lẹ́yìn ìgbà tí a ti kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀ (nínú ara, kì í ṣe ọkàn), pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtara ni àwa ṣe àníyàn tí a sì fẹ́ gidigidi láti fi rí i yín. 18Nítorí àwa fẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ yín—àní èmi, Paulu, gbìyànjú ní ọ̀pọ̀ ìgbà láti wá, ṣùgbọ́n èṣù ú dè wá lọ́nà. 192.19: Fp 4.1; 1Tẹ 3.13; 4.15; 5.23; Mt 16.27; Mk 8.38.Kí ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, tàbí adé wa nínú èyí tí a ó ṣògo níwájú Jesu Olúwa nígbà tí òun bá dé? Ṣé ẹ̀yin kọ́ ni? 202.20: 2Kọ 1.14.Nítòótọ́, ẹ̀yin ni ògo àti ayọ̀ wa.

Bibelen på hverdagsdansk

1. Thessalonikerbrev 2:1-20

Paulus forsvarer sig mod eventuelle anklager

1Det var altså absolut umagen værd, at vi kom til jeres by. 2I ved, hvordan vi lige forinden var blevet forfulgt og mishandlet i Filippi, men Gud gav os frimodighed til at forkynde budskabet om Kristus for jer, selvom det betød mere forfølgelse. 3-4Det gjorde vi, fordi Gud anså os for værdige til at få hans budskab betroet. Vores tjeneste udspringer ikke af vildfarelse, urene motiver eller uærlighed. Derfor er vi heller ikke ude på at blive anerkendt af mennesker, men kun af Gud, som kender vores motiver.

5Som I ved, prøvede vi ikke at vinde jer med smigrende ord, og Gud ved, at vi ikke prøvede at udnytte jer økonomisk under et eller andet fromt påskud. 6Vi søgte heller ikke menneskers anerkendelse, hverken jeres eller andres. 7Skønt vi som Kristi apostle kunne have stillet krav til jer, gjorde vi det ikke. I stedet tog vi os af jer med nænsomhed som en mor, der sørger for sine børn. 8Og vi kom til at holde så meget af jer, at vi besluttede ikke kun at give jer Guds ord. Nej, vi gav alt, hvad vi havde i os. 9I husker nok, hvordan vi sled i det. Dag og nat arbejdede vi for at tjene til vores ophold, så vi ikke skulle ligge nogen af jer til byrde. Og samtidig forkyndte vi budskabet om Kristus for jer. 10I ved, og Gud ved, hvor retsindigt, redeligt og uangribeligt vi færdedes iblandt jer. 11-12Som en far taler opmuntrende og formanende til sine børn, sådan formanede og opmuntrede vi jer og indprentede hver eneste af jer, at I skal leve, så det bringer Gud ære. Han har jo kaldet jer ind i sit rige for at dele sin herlighed med jer.

Guds ord forhindres ikke af forfølgelser

13Vi er virkelig taknemmelige til Gud over, at I tog imod vores budskab, ikke som menneskeord, men som Guds ord. Og det er jo netop det, det er! Det er også derfor, det gør sin gerning i jer, som tror. 14I oplever nu det samme som menighederne i Judæa. I er blevet forfulgt af jeres landsmænd, ligesom de er blevet af deres. 15De vantro jøder slog nemlig både deres egne profeter og Herren Jesus ihjel. Og nu forfølger de også os. De er fjender af både Gud og mennesker, 16for de prøver at hindre os i at forkynde Guds budskab for alle folkeslagene, så de kan få det evige liv. På den måde er deres synd blevet så stor, at Guds fulde dom nu hænger over hovedet på dem.

Paulus længes efter at besøge dem

17Kære venner, vi har været adskilt fra jer et stykke tid, dog kun rent fysisk, for i vores tanker har vi altid været sammen med jer, og vi længes meget efter at se jer igen. 18Vi vil meget gerne besøge jer, og jeg, Paulus, har forsøgt at komme af sted indtil flere gange, men Satans håndlangere har hidtil hindret os. 19I betyder så meget for os. I giver os håb og glæde, og når Herren Jesus Kristus kommer igen, vil I være blandt dem, som vi kan være stolte af. 20Ja, allerede nu er I vores stolthed og glæde.